Wọ́n Ṣì Ń Fi Ẹṣin Ro Ilẹ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
NÍ SÀNMÁNÌ tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ti gòkè àgbà yìí, ó lè ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́ pé àwọn àgbẹ̀ kan ṣì ń fi ẹṣin ro ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ibì kan ń bẹ tí a ti ń lo ọ̀wọ́ àwọn ẹṣin rọ̀bọ̀tọ̀ dípò lílo àwọn katakata.
A gbà pé àwọn oko tí a ń fi ẹṣin ro kò wọ́pọ̀ mọ́. Síbẹ̀, àwọn àǹfààní kan ń bẹ nínú lílo ẹṣin.
Lílò Wọ́n fún Iṣẹ́ Àgbẹ̀
Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ ni a ti ń lo ẹṣin fún ẹrù rírù. A mẹ́nu bà wọ́n nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn ará Sumer, àwọn ọmọ Hétì, àwọn ará Íjíbítì, àti àwọn ará China. Ṣùgbọ́n a pààlà sí ìwọ̀n tí a ń lò wọ́n dé nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Èyí jẹ́ nítorí pé a ka akọ màlúù sí ohun tí ó rọrùn láti bójú tó, ó sì tún lè di oúnjẹ nígbà tí kò bá wúlò fún iṣẹ́ mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, akọ màlúù kò yára tó ẹṣin.
Nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, a ti fi ẹṣin rọ́pò ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn. Ìtẹ̀jáde kan sọ pé lápá kan, èyí jẹ́ nítorí “ìmújáde àwọn ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ oko dídíjú [tí ó] sàn fún ìgbéṣẹ́ṣe yíyára kánkán, tí ó já gaara, ti ẹṣin ju ti akọ màlúù tí ń falẹ̀ lọ.”
Lẹ́yìn náà, onírúurú ẹṣin bíi Clydesdale ní Scotland, Suffolk Punch àti Shire ní ilẹ̀ England, àti Percheron, ní pàtàkì ní ilẹ̀ Faransé, di àmúlò nínú iṣẹ́ agbẹ̀. Àwọn ẹṣin tí kò yára, ṣùgbọ́n tí ó lágbára wọ̀nyí, ni a mú kí ó gun àwọn tí ara wọn fẹ́ nílẹ̀ láti ṣèmújáde irú ẹṣin àdàmọ̀di kan tí agbára rẹ̀ dín kù díẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó túbọ̀ yára. Irú àwọn àdàmọ̀di ẹranko bẹ́ẹ̀ ni a ń pè ní àwọn ẹṣin tí ń fa ohun èèlò ìṣiṣẹ́, èyí tí ń tọ́ka sí agbára wọn láti wọ́ àwọn ẹrù wíwúwo.
Fífi Ẹṣin Wé Katakata
Dájúdájú, a kò tí ì mú irú ẹṣin kan jáde tí ó ní agbára ìfaǹkan kan náà pẹ̀lú katakata ìgbàlódé. Ṣùgbọ́n ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ bí àwọn ẹṣin ṣe lágbára tó! Ní 1890, ẹṣin Clydesdale méjì tí ń fa ohun èèlò ìṣiṣẹ́ wọ́ ọkọ̀ ẹrù kan tí a di ẹrù kún bámúbámú, tí a sì há ẹsẹ̀ rẹ̀, nílẹ̀ tuurutu! Ní 1924, ẹṣin Shire ilẹ̀ England méjì ṣe bẹbẹ tí ó jọni lójú bákan náà, nígbà tí wọ́n wọ́ ẹrù tí a fojú díwọ̀n pé ó tó 50 tọ́ọ̀nù!
Àwọn ẹṣin tí ń fa ohun èèlò ìṣiṣẹ́ ní òye, wọ́n sì ń lo àtinúdá. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀wọ́ àwọn ẹṣin kan tí ń túlẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ máà nílò ìdarí kankan bí ojúlówó ẹṣin atọ́poro kan bá wà níbẹ̀. Ẹṣin atọ́poro náà ni yóò ṣáájú ọ̀wọ́ náà, tí yóò sì máa tẹ̀ lé aporo ìtúlẹ̀ léraléra. A rò pé ó ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀wọ́ náà láti túlẹ̀ lórí ìlà títọ́ gbọn-ọnran lọ́nà àràmàǹdà nítorí pé àwọn ẹṣin náà ń wọ ìbòjú, wọn kò sì lè bojú wẹ̀yìn bí àwọn ènìyàn tí ń wa katakatá ṣe máa ń ní ìtẹ̀sí láti ṣe.
Síwájú sí i, nígbà ìkórè, àwọn ẹṣin lè wúlò fún ọ̀pọ̀ nǹkan ju katakata lọ. Agbára wọn láti ṣẹ́rí sí ìdá mẹ́rin òbírípo gẹ́lẹ́—àti nígbà tí ó bá di dandan, ní ìdajì òbírípo—fi hàn pé wọn kì í bu apá kankan oko sílẹ̀ nígbà iṣẹ́ oko.
Àwọn Ọ̀wọ́ Ẹṣin Lẹ́nu Iṣẹ́
Ọ̀wọ́ ẹṣin kan tí ń ṣe ohun tí olùdarí wọn pa láṣẹ fún wọn jẹ́ ìran jíjọni lójú kan. A ń dá ọ̀wọ́ kan lẹ́kọ̀ọ́ láti dáhùn padà sí àṣẹ pàtó ní ọ̀nà pàtó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè àti ọ̀rọ̀ tí olùdarí kan ń lò gẹ́lẹ́ yàtọ̀ sí ti òmíràn. Àwọn ẹṣin náà máa ń dojúlùmọ̀ pẹ̀lú èdè ìró ohùn olùdarí kọ̀ọ̀kan. Oríṣi ìfé kan, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí láti ọ̀dọ̀ olùdarí náà, lè jẹ́ àmì fún àwọn ẹṣin náà láti gbéra sọ.
Ní Australia, ẹṣin apá ọ̀tún ọ̀wọ́ náà (lójú ìwòye olùdarí) ni ó wà lọ́nà jíjìn, tí ti apá òsì sì wà nítòsí. Ó ṣeé ṣe kí àfipè yìí wá láti inú ọ̀nà tí àwọn ará àtijọ́ ń gbà kó ọ̀wọ́ wọn ṣiṣẹ́, tí wọ́n sábà máa ń rìn ní apá òsì.
Ẹ wo bí ìran náà ti ń dùn mọ́ni tó nígbà tí ẹṣin mẹ́wàá tí ó wà ní ìsokọ́ra ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ bá ń ṣẹ́rí sí ìdá mẹ́rin òbírípo, ní ìdáhùn sí ìpè olùdarí wọn! Bí wọ́n bá máa ṣẹ́rí sí òsì, ẹṣin ìtòsí gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ díẹ̀díẹ̀ sẹ́yìn, nígbà tí àwọn yòó kù ń rìn ní ìdá mẹ́rin òbírípo yí i ká. Bí ó bá wáá jẹ́ ọ̀tún ni wọ́n máa ṣẹ́rí sí, ẹṣin tí ó wà lọ́nà jíjìn gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ díẹ̀díẹ̀ sẹ́yìn. Ní àwọn ibi tí ojú ọjọ́ ti gbẹ díẹ̀, àrímálèlọ ìran ni láti rí bí ọ̀wọ́ náà ṣe pa rẹ́ mọ́ àárín erukuru tí ó sọ lálá níbẹ̀rẹ̀, kí o sì tún wáá rí wọn bí ògiri ẹran ara ẹṣin tí ń dún ní àdúntúndún nígbà tí wọ́n bá parí ìṣẹ́rí náà!
A ń pe ẹṣin kọ̀ọ̀kan lórúkọ, ó sì ń dáhùn ní ìbámu pẹ̀lú ìró ohùn tí olùdarí ọ̀wọ́ náà bá lò. Bí ẹṣin kan bá bì rẹ̀yìn, ohùn líle díẹ̀, tí ń fi ìbániwí hàn ní pípe orúkọ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí a nílò. Nígbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ ìbẹ̀rẹ̀ pàápàá, àwọn ẹṣin sábà máa ń kọ́ pé jíju igi tàbí pàṣán máa ń bá irú ohùn bẹ́ẹ̀ rìn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí wọ́n bá ti kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, a kì í nílò ìbáwí líle koko lọ́pọ̀ ìgbà mọ́, bí a bá tilẹ̀ nílò rẹ̀ rárá.
Àpẹẹrẹ Ọjọ́ Iṣẹ́ Kan
Àgbẹ̀ kan lè jí ní nǹkan bí aago márùn-ún òwúrọ̀ láti bọ́ àwọn ẹṣin, kí òun náà sì jẹ oúnjẹ àárọ̀ nígbà tí àwọn ẹṣin bá ń jẹun lọ́wọ́. Àwọn ẹṣin mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ mu omi púpọ̀ kí iṣẹ́ ojúmọ́ náà tóó bẹ̀rẹ̀, nítorí pé wọn kì yóò ní ohunkóhun láti mu ṣáájú oúnjẹ ọ̀sán. A óò nu ara ẹṣin kọ̀ọ̀kan kí a tóó dì í ní gàárì. Èyí ń ṣèdíwọ́ fún ara yíyún, ó sì jẹ́ ìmọ̀lára alárinrin. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ẹsin náà ń ṣùùrù bo àgbẹ̀ náà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò si fi sùúrù dúró di ìgbà tí ó bá kàn án. Nígbà náà ni a óò dì wọ́n ní gàárì, tí a óò sì di àjàgà wọn pọ̀. Gbogbo èyí lè gba wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó sinmi lé iye ẹṣin tí ó wà nínú ọ̀wọ́ náà. Pẹ̀lúpẹ̀lú, a óò ṣètò àpò oúnjẹ fún oúnjẹ ọ̀sán àwọn ẹṣin náà. Ó ṣe tán, olùdarí nìkan kọ́ ni ó lẹ́tọ̀ọ́ sí oúnjẹ ọ̀sán!
Ọ̀wọ́ náà ń ṣe làálàá fún wákàtí mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá láìráhùn, bí ìdirùn àti àwọn ohun èlò bá dúró déédéé, àwọn ẹṣin kò níí dá egbò léjìká, tàbí fi èjìká ha nǹkan nígbà tí iṣẹ́ ọjọ́ náà bá parí. Bí ọjọ́ ti ń rọ̀, àti ènìyàn àti ẹranko ń láyọ̀ láti padà relé láti lọ baralẹ̀ jẹun, kí wọ́n mu omi lámutó, kí wọ́n sì sinmi dáradára.
Àwọn tí wọ́n ṣì ń fi ẹṣin ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ lè gbèjà ara wọn pé, àwọn ń gbádùn rẹ̀ ju títẹ́tí sí ìró ẹ̀rọ tí ń bú ramúramù látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ìparọ́rọ́ náà ń mú kí àgbẹ̀ náà nímọ̀lára pé òun jẹ́ apá kan ilẹ̀ náà. Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàkíyèsí ìṣẹ̀dá tó yí i ká ní kedere—ìró àwọn ẹyẹ tí ń tan ilẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú náà; òórùn àwọn ewéko tí ó lọ́rinrin; ìfọ́yángá èérún omi dídì bí ohun èèlò ìtúlẹ̀ ṣe ń la àárín ilẹ̀ tútù náà já ní òwúrọ̀ títutù nini kan—àwọn nǹkan kéékèèké tí a kì í fiyè sí nígbà tí ariwo katakatá bá ti bo àgbẹ̀ mọ́lẹ̀.
Òtítọ́ ni pé àwọn katakatá lè ṣiṣẹ́ fún wákàtí 24 lóòjọ́, bírà tí ẹṣin kò lè dá. Òtítọ́ tún ni pé àwọn katakatá lè ro ilẹ̀ púpọ̀ tí àbójútó wọn kò sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí katakata kan tí ó tí ì mú agódóńgbó kan jáde rí, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orísun ìdùnnú tí ó sọ fífi ẹṣin ṣiṣẹ́ di aláìlẹ́gbẹ́. Olùdarí náà tún lè gbádùn “ìjíròrò” pẹ̀lú àwọn ẹṣin rẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lọ. Wọ́n sì ń dáhùn padà nípa ṣíṣe ìgbọràn, pẹ̀lú etí wọn tí wọ́n nà síwájú láti fi gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó bá sọ.
Ṣíṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ kò rọrùn, ó tilẹ̀ ń tánni lókun nígbà míràn. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n ṣì ń ṣe iṣẹ́ oko wọn lọ́nà àtijọ́, pẹ̀lú ẹṣin, lè láyọ̀ púpọ̀ láti inú ṣíṣiṣẹ́ pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú àwọn ẹranko alágbára, òṣìṣẹ́kára inú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run wọ̀nyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ẹṣin lè wúlò fún ọ̀pọ̀ nǹkan ju katakata lọ