Wíwo Ayé
Tábà àti Iṣẹ́
Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé: “Dídín iye owó tí a ń ná sórí tábà kù yóò fi kún ìríṣẹ́ṣe” ní àwọn agbègbè kan ní United States. A lo ìfojú díwọ̀n ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lójú ìwòye ohun tí ń lọ lọ́wọ́, tí a ṣe lórí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà, láti fi bí níná owó tí a ti ná tẹ́lẹ̀ lórí tábà sórí àwọn ohun mìíràn ì bá ti mú ìbísí wá nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín tó nínú iṣẹ́ kárí orílẹ̀-èdè. Ìròyìn náà sọ pé àwọn agbègbè tí a ti ń gbin tábà kì bá tí pàdánù iṣẹ́ tó bí ilé iṣẹ́ tábà ṣe fojú bù ú. Ìròyìn náà sọ pé: “Àníyàn gíga jù lọ nípa tábà yẹ kí ó jẹ́ lórí bí ipa rẹ̀ ṣe kàmàmà tó lórí ìlera, kì í ṣe ipa tí ó ní lórí ìríṣẹ́ṣe.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Los Angeles Times ṣe wí, Ẹgbẹ́ Oníṣègùn America pẹ̀lú rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn olùdókòwò láti ta ìpín wọn nínú àwọn ilé iṣẹ́ tábà 13. Scott Ballin, ti Ẹgbẹ́ Ìtọ́jú Àrùn Ọkàn Nílẹ̀ America, sọ pé: “A kò gbọdọ̀ máa kọ́wọ́ ti àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ta àrùn àti ikú ní orílẹ̀-èdè yìí àti lókè òkun.”
Àwọn Ilé Gíga Jù Lọ Lágbàáyé
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú èyí tí ó lé ní ọ̀rúndún kan, àwọn ilé gíga jù lọ lágbàáyé kò sí ní United States. Ìgbìmọ̀ Àwọn Ilé Gíga àti Ibùgbé Ìgboro, tí ó jẹ́ olùpinnu àgbáyé nípa àwọn ilé àwòṣífìlà, ti fi ìtayọ lọ́lá yẹn fún àwọn Ilé Gogoro Petronas Méjì tí ó jọra ní Kuala Lumpur, Malaysia. Ilé tí ó ga jù lọ tẹ́lẹ̀, Ilé Gogoro Sears ní Chicago, ni ó ṣì ga jù lọ bí a bá fi àwọn ọ̀pá gàgàrà tẹlifíṣọ̀n rẹ̀ kún ìwọ̀n náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbìmọ̀ náà pinnu pé àwọn ọ̀pá gàgàrà wọ̀nyẹn kò sí lára ìṣètò ìkọ́lé ilé náà. Kíkọ́ irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ jẹ́ àmì ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé lọ́nà yíyani lẹ́nu ní agbègbè náà, lójú àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ní onírúurú orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Éṣíà. Ní gidi, àwọn Ilé Gogoro Petronas Méjì náà yóò pàdánù ipò náà nígbà tí iṣẹ́ bá parí lórí Ibùdó Ìdókòwò Àgbáyé, tí a ṣètò pé kí ó parí ní òpin ẹ̀wádún yìí ní Shanghai, China.
Ìdásílẹ̀ Àwọn Ẹyẹ Òkun Ni Bí?
Nígbà tí epo àìfọ̀ bá dà sójú òkun nítòsí ilẹ̀, ó lè nípa búburú gbáà lórí àwọn ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn. Nígbà míràn, àwọn àjọ—tí ọ̀pọ̀ wọn ní àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni—ń yára gbégbèésẹ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe. Ọ̀kan lára àwọn ohun àkọ́kọ́ ni láti nu epo kúrò lára àwọn ẹyẹ òkun tí epo bá bo ara wọn. Ṣùgbọ́n báwo ni ìgbésẹ̀ yìí ṣe gbéṣẹ́, tí ó sì pẹ́ tó? Ìwádìí òde òní fi hàn pé lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí a nù lára tí a sì dá padà sí ibùgbé àdánidá wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ ń kú láàárín ọjọ́ mẹ́wàá. Èé ṣe? Yàtọ̀ sí ìgbọ̀nrìrì tí ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń fọwọ́ kàn wọ́n ń mú bá wọn, àwọn ẹyẹ náà yóò ti gbé epo díẹ̀ mì nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti fi àgógó nu epo kúrò lára ìyẹ́ wọn, kí wọ́n sì tún wọn tò dáradára, èyí yóò sì pa wọ́n níkẹyìn. Láti gbógun ti èyí, a ń fún àwọn ẹyẹ tí a bójú tó ní Britain ní àpòpọ̀ kaolin, èédú, àti ṣúgà, kí wọ́n lè ṣu àwọn oró májèlé náà dà nù. Àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti ibùgbé wọn, tí ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀, parí ọ̀rọ̀ sí pé, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ẹyẹ náà ní ń wà láàyè pẹ́ tó láti bímọ, a sì gbọ́dọ̀ wo irú ìnùlára bẹ́ẹ̀ bí “ìgbòkègbodò òde ara tí kò já mọ́ nǹkan.”
Àrùn Mẹ́dọ̀wú Oríṣi C àti Ẹ̀jẹ̀
Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Àjọ Orílẹ̀-Èdè Faransé Lórí Ìlera Aráàlú pari èrò sí pé “láàárín 500,000 sí 600,000 ènìyàn ní ilẹ̀ Faransé ti kó fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi C.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Le Monde ti Paris ṣe wí, ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àkóràn fáírọ́ọ̀sì àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi C náà wá láti inú ìfàjẹ̀ síni lára tàbí gígún abẹ́rẹ́. Ní àfikún, àwọn ènìyàn kan ti kó o nípa lílo àwọn ohun èèlò tí a kò sè dáadáa nígbà ìtọ́jú ìṣègùn. Àrùn mẹ́dọ̀wú oríṣi C lè yọrí sí ìsúnkì ẹ̀dọ̀ki tàbí jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ki.
Nígbà Tí O Bá Ṣíwọ́ Sìgá Mímu
Láàárín 20 ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ṣíwọ́ sìgá mímu, ìyípadà sí rere bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ nínú ara. Ìwé ìròyìn Reader’s Digest tẹ àwọn ìyípadà tí ń ṣara láǹfààní wọ̀nyí jáde pé wọ́n ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn àkókò pàtó kan lẹ́yìn tí amusìgá kan bá ṣíwọ́ sìgá mímu. Ogún ìṣẹ́jú: Ìwọ̀n ìfúnpá àti ìtújáde ẹ̀jẹ̀ padà sílẹ̀ sí bí ó ti yẹ kí ó rí; ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ọwọ́ àti ẹsẹ̀ lọ sókè sí bí ó ti yẹ kí ó rí. Wákàtí mẹ́jọ: Ìwọ̀n afẹ́fẹ́ májèlé carbon monoxide inú ẹ̀jẹ̀ lọ sílẹ̀ sí bí ó ti yẹ kí ó rí; ìwọ̀n afẹ́fẹ́ oxygen inú ẹ̀jẹ̀ lọ sókè sí bí ó ti yẹ kí ó rí. Wákàtí 24: Ṣíṣeé ṣe kí ìkọlù ọkàn àyà ṣẹlẹ̀ dín kù. Wákàtí 48: Àwọn góńgó iṣan tún bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà; agbára ìtọ́wò àti ìgbóòórùn túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i; ó túbọ̀ rọrùn láti rìn. Ọ̀sẹ̀ méjì sí oṣù mẹ́ta: Ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ dára sí i; ìgbéṣẹ́ ẹ̀dọ̀fóró lọ sókè sí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún. Oṣù kan sí mẹ́sàn-án: Ikọ́ híhú, hòrò ihò imú dídí, àárẹ̀, àti èémí tí kò délẹ̀ dín kù; àwọn ìyọjáde onírun inú ẹ̀dọ̀fóró hù padà. Ọdún kan: Ewu ìdínkù ìṣàn ẹ̀jẹ̀ sínú ẹran ọkàn àyà jẹ́ ìdajì ewu kan náà fún ẹni tí ń mu sìgá.
Ìbálòpọ̀ àti Ìwà Ipá Láti Ibi Ìkówèésí
Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Advocate, ti Stamford, Connecticut, ṣe wí, àwọn ibi ìkówèésí kan ní Connecticut, U.S.A., ń fàyè gba àwọn ọmọdé láti mú àwọn fíìmù tí ń ṣàgbéyọ ṣíṣe eré ìfẹ́ àti àwòrán ìwà ipá jáde. Nígbà míràn, àwọn ọmọdé ní òmìnira láti lo àwọn kọ̀m̀pútà ibi ìkówèésí tí a so pọ̀ mọ́ ìgbékalẹ̀ Internet. Èyí ń mú ọ̀pọ̀ ìbéèrè wá sójú táyé nípa irú àwọn ohun tí ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọ̀dọ́langba. Ó mú ọ̀pọ̀ òbí gbọ̀n rìrì, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ ibi ìkówèésí gbà gbọ́ pé àwọn òbí nìkan ni ó ní ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó ohun tí àwọn ọmọ wọn ń mú jáde láti ibi ìkówèésí náà. Alábòójútó ibi ìkówèésí, Renee Pease, sọ pé: “Ipò ọ̀ràn tí kò gún gẹ́gẹ́ ni,” pẹ̀lú ìlóhùnsí pé, “ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ìtàn àròsọ lè ṣàìtọ́ fún àwọn ọmọdé.”
Dídábẹ́ fún Àwọn Obìnrin
Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin ará Áfíríkà kan tí a fún láyè ibi ìsádi ní United States tún ti pe àfiyèsí lọ́tun sí dídábẹ́ fún àwọn obìnrin. Obìnrin náà sọ pé òun ń sá fún dídábẹ́ náà tí ó jẹ́ ipò àfilélẹ̀ fún ìgbéyàwó tipátipá kan. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà, wọ́n máa ń dábẹ́ fún ọmọbìnrin kan ní kékeré tàbí nígbà tí wọ́n bá ń gbà á sí ẹgbẹ́ àgbà obìnrin. Wọ́n sábà máa ń ṣe èyí láìsí lílo egbòogi àìmọ̀rora lára, tàbí àwọn ìgbésẹ̀ ìmọ́tótó kankan. Yàtọ̀ sí ohun tí ń náni ní ti èrò ìmọ̀lára, àbájáde rẹ̀ lè jẹ́ kíkó àrùn, ìṣẹ̀jẹ̀ rẹpẹtẹ, àìrọ́mọbí, àti ikú. (Wo ìtẹ̀jáde Jí!, April 8, 1993, ojú ìwé 20 sí 24.) Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ṣe wí, a fojú bù ú pé láàárín 80 mílíọ̀nù sí mílíọ̀nù 115 àwọn obìnrin ti fojú winá àṣà yìí. A ti gbé ìgbésẹ̀ láti sọ ọ́ di ohun tí ko bófin mu ní United States.
Ṣíṣọ́ Ìrìnsí Àwọn Oyin
A ti lẹ àwọn ọ̀pá radar kíkéré jù lọ lágbàáyé, tí ó ga ní kìkì mìlímítà 16, mọ́ ẹ̀yìn àwọn oyin mélòó kan ní ilẹ̀ Britain. Àwọn ọ̀pá náà jẹ́ ìhùmọ̀ tí ń mú kí a lè ṣọ́ ìrìnsí àwọn oyin náà. A retí pé àfidánrawò náà yóò mú kí a lè ṣe àwọn ọ̀pá tí ó túbọ̀ kéré sí i níkẹyìn, tí a óò lè lẹ̀ mọ́ ara irù ilẹ̀ Áfíríkà, láti ṣọ́ bí kòkòrò náà ṣe ń fò. Èyí lè mú kí a túbọ̀ kápá àrùn sunrunsunrun tí àwọn kòkòrò wọ̀nyí ń kó kiri. A kò nílò àwọn bátìrì kankan láti fún àwọn ọ̀pá náà lágbára, níwọ̀n bí wọ́n ti lè gba gbogbo agbára tí wọ́n nílò láti inú àmì ìṣọ́ni tí ń dé náà. Àfikún àǹfààní mìíràn ni pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì retí pé wọn yóò lè mú ìmọ̀ wọn nípa ìṣesí àwọn oyin gbòòrò sí i pẹ̀lú èrò láti túbọ̀ ṣàwárí àwọn ilé oyin lọ́nà gbígbéṣẹ́ sí i.
A So Tẹlifíṣọ̀n Pọ̀ Mọ́ Wárápá
Mímú tẹlifíṣọ̀n tí ń lo sátẹ́láìtì wọ Íńdíà, tí ó ń pèsè ìran wíwò oníwákàtí 24 lóòjọ́, ń yọrí sí ìbísí àwọn ìṣòro ìgbékalẹ̀ ètò iṣan ara láàárín àwọn ọmọdé. Àwọn ògbógi nínú ìmọ̀ nípa ètò iṣan ara ni ó sọ èyí níbi àpérò Ìsọfúnni Lọ́ọ́lọ́ọ́ Nípa Iṣan Ara Jákèjádò Ilẹ̀ Íńdíà—1996. Olórí ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ètò iṣan ara ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìṣègùn ti Amritsar, Dókítà Ashok Uppal, sọ pé: “Àwọn ọmọdé ti wáá ń tẹjú mọ́ tẹlifíṣọ̀n fún wákàtí púpọ̀ sí i, tí ó sì ń yọrí sí ìbísí nínú ohun tí àwọn onímọ̀ nípa ètò iṣan ara pè ní ‘wárápá tí ìrusókè ìmọ̀lára àwòrán ìmọ́lẹ̀ ń fà tàbí wárápá tí tẹlifíṣọ̀n ń fà.’” Dókítà Uppal rọ àwọn òbí láti dín àkókò tí àwọn ọmọ wọn fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù tàbí kí wọ́n máa fún wọn ní àkókò ìsinmi déédéé, láàárín àwọn àkókò ìwòran gígùn.
A Dá Panipani Mọ̀
Lẹ́tà ìròyìn Health InterAmerica ròyìn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ará Mexico díẹ̀ ní ń mu tábà, púpọ̀ àwọn tí ó lé ní 40 ọdún ní àwọn àrùn ẹ̀dọ̀fóró tí mímú tábà ń fà. Kí ló fà á? Àwọn olùwádìí sọ láìpẹ́ pé ó jẹ́ “síseǹkan pẹ̀lú àdògán.” Gẹ́gẹ́ bí Peter Paré, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìṣègùn kan ṣe sọ, a kò fiyè sí ìṣòro náà tó bẹ́ẹ̀ nítorí “a kò sábà ń ka èéfín igi sí ewu pàtàkì kan sí ìlera. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń sọ pé àìlùkìkì ọkàn àyà ló fa ikú, nígbà tí okùnfà náà ní gidi jẹ́ fífa èéfín igi sínú ré kọjá ààlà.” Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n rẹ̀ pé 400 mílíọ̀nù ènìyàn kárí ayé wà nínú ewu, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ àwọn obìnrin àrọko tí ń lo àdògán nínú àwọn ilé kéékèèké tí ìfẹ́lọfẹ́bọ̀ afẹ́fẹ́ kò jíire tó. Ṣíṣe àwọn ihò àbájáde èéfín yóò ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Dókítà Paré ṣe wí, “ìpèníjà títóbi jù lọ ni yíyí ọkàn àwọn ènìyàn padà láti yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún padà.”