“Àwa Jáwọ́ Ńbẹ̀—Ìwọ náà Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!”
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JAPAN
Ìròyìn sọ pé, àwọn àlejò tí ń mu tábà, tó jọ pé wọ́n ń “dáná nínú ikùn wọn,” bá àwọn ọkọ̀ òkun Yúróòpù tó gúnlẹ̀ sí Japan ní apá ìparí àwọn ọdún 1500 wá. Ìyàlẹ́nu tí èyí jẹ́ fún àwọn ará Japan ló sún wọn dédìí dídán an wò, ìgbà tó sì fi máa di àwọn ọdún 1880, àṣà mímu tábà ti wọ́pọ̀ ní Japan. Ta ló lè rò pé àtọmọdọ́mọ àwọn ará Japan tí ẹnu yà náà yóò wá wà lára àwọn tí ń mu tábà jù lọ lágbàáyé lónìí?
“AFẸ́ ṣe bí àgbàlagbà, kí wọ́n lè máa fojú àgbàlagbà wò wá.”—Akio, Osamu, àti Yoko.
“Mo fẹ́ fọn.”—Tsuya.
“Mo fẹ́ ṣe ojúmìító ni.”—Toshihiro.
“A kò lérò pé tábà lè pa wá lára.”—Ryohei, Junichi, àti Yasuhiko.
“Mo fẹ́ fi paná ìrìndọ̀ àti èébì tó máa ń gbé mi láràárọ̀ nígbà tí mo lóyún kejì ni.”—Chieko.
“Kí n lè máa fi bo àwọn ọ̀ràn tí ń fa ìtìjú níbi tí a ti ń ṣèpàdé níbi iṣẹ́ ni mo ṣe ń mu ún.”—Tatsuhiko.
Àwọn ohun tí àwùjọ ènìyàn kan sọ pé ó fà á tí àwọn fi ń mu sìgá nìyẹn nígbà tí a bi wọ́n léèrè. Irú àwọn àlàyé yẹn ṣeé lóye, ní ti pé àwọn kan ń pe Japan ní párádísè àwọn amusìgá. Àmọ́, lọ́nà gbígbàfiyèsí, gbogbo àwọn tí a dárúkọ wọn lókè yẹn ni wọ́n ti jáwọ́ nínú àṣà mímu tábà. Àṣeyọrí ńlá ni èyí jẹ́ tí o bá gbé àwọn ìdíwọ́ tí ó yí wọn ká yẹ̀ wò. Ṣé o ń ṣe kàyéfì nípa bí wọ́n ṣe ṣe é ni? Jẹ́ kí a kọ́kọ́ gbé bí àṣà mímu tábà ṣe gbilẹ̀ tó ní Japan lónìí yẹ̀ wò.
Bí Ọ̀ràn Tábà Ṣe Rí
Nǹkan bí ìpín mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ọkùnrin Japan ló ń mu sìgá ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín méjìdínlọ́gbọ̀n péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin Amẹ́ríkà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí tí wọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nǹkan bí ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin, tí púpọ̀ lára wọn ṣì kéré wà lára ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ọ̀kẹ́ [34,000,000] ènìyàn tí ń mu sìgá ní Japan. Àpẹẹrẹ àwọn àgbàlagbà àti ìpolówó-ọjà tí a ṣe mọ̀ràn-ìnmọran-in ń dá kún pípọ̀ tí àwọn èwe tí ń mu sìgá ń pọ̀ sí i. Ní báyìí, wọ́n ti fòfin de pípolówó sìgá lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò ní Japan, bí wọ́n ṣe fòfin dè é ní United States ní ohun tí ó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn.
Síwájú sí i, ó rọrùn láti rí sìgá rà lórí àwọn ẹ̀rọ ìtajà káàkiri àwọn àdúgbò ní Japan. Tí ọwọ́ àwọn ènìyàn bá tẹ páálí sìgá tán, díẹ̀ lára wọn ló ń kọbi ara sí ìsọfúnni yẹpẹrẹ, tí kò gbéṣẹ́ tí wọ́n tẹ̀ sára rẹ̀. Àkọlé náà lè wulẹ̀ kà pé: “Má ṣe jẹ́ kí a mu sìgá púpọ̀; ó lè ṣèpalára.” Láfikún sí pé àwọn ènìyàn kì í sábà mọ nǹkan kan nípa bí tábà ṣe léwu gan-an tó, àpẹẹrẹ burúkú tí wọ́n ń rí lára àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn mélòó kan tún máa ń ru àwọn ará Japan sókè láti mu sìgá, èyí tí ń sún wọn ní èrò tí kò tọ̀nà náà pé, kò séwu.
Abájọ tí àwọn tí ń ṣe alágbàwí ìgbógunti àṣà mímu sìgá fi ń káàánú nípa bí ilẹ̀ Japan kò ṣe náání mímú kí púpọ̀ lára àwọn ará ibẹ̀ jáwọ́ nínú tábà mímu. Àmọ́ àwọn olùkọ́ ti ń rí ìjẹ́pàtàkì kíkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn pé sìgá mímu ń wu ìlera àti ìwàláàyè wọn léwu. Òtítọ́ ni pé àwọn tí ń mu sìgá ní Japan ń rí irú àwọn àmì àrùn tí àwọn tí ń mu sìgá níbòmíràn ń rí—ìrìndọ̀, àìlèmídélẹ̀, ikọ́ àwúlamilójú, inú rírun, kí oúnjẹ má wuni í jẹ, kí òtútù tètè máa múni, àti bóyá, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, kí àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, àrùn ọkàn, tàbí àwọn àrùn mìíràn pani láìtọ́jọ́.
Láti April 1, 1985, àwọn ilé iṣẹ́ aládàáni ló ń ṣe tábà ní Japan, èyí tí ó fòpin sí àwọn ẹ̀wádún tí ìjọba fi ń nìkan darí ṣíṣe é. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìjọba ṣì ń ṣètìlẹ́yìn fún un gbágbáágbá, èyí tí ń bẹ́gi dínà ìtẹ̀síwájú èyíkéyìí láti ṣèdíwọ́ fún àṣà mímu sìgá. Èyí jẹ́ kí a lóye ìdí tí àwọn ẹgbẹ́ tí ń gbógun ti àṣà mímu sìgá ṣe ka Japan sí ibi ààbò àwọn amusìgá nísinsìnyí. Ó sì jẹ́ kí a lóye ìdí tí ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri fi sọ pé àwọn dókítà tí a ní ń kédàárò pé Japan jẹ́ “àwùjọ tí ń ṣètìlẹ́yìn fún àṣà mímu sìgá.”
Láti mọ bí àwọn kan ṣe ṣàṣeyọrí láti jáwọ́ ńbẹ̀, wo àpótí náà, “Bí A Ṣe Jáwọ́ Ńbẹ̀.”
Báwo Lo Ṣe Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀?
Àmọ̀ràn tí àwọn amutábà tẹ́lẹ̀ rí gbani, bí àwọn tí a kọ sínú àpótí yẹn, kò yàtọ̀ síra, òun ni pé: Má ṣe kámikàmìkámi nípa jíjáwọ́ ńbẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́-ọkàn láti tẹ́ ẹ lọ́rùn ni ìsúnniṣe àkọ́kọ́. Nínífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò rẹ̀ sì jẹ́ ìsúnniṣe dáradára mìíràn. Gbé góńgó kan kalẹ̀, kí o sì rí i pé o ń ṣe é. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé o fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀—sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kí o sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ. Bó bá ṣeé ṣe, jáwọ́ ńbẹ̀ lójijì. Sì sa gbogbo ipá rẹ láti má ṣe wà nítòsí ibi tí wọ́n bá ti ń mu sìgá.
Bí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, túbọ̀ máa dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa. Bí o bá ń wà láàárín wọn, wàá tètè gbàgbé òòfà-ọkàn láti mu sìgá. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń kọ́ ẹni tí ń mu sìgá lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sú ọ. Ràn án lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju àṣà burúkú náà lọ.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwés 20, 21]
“Bí A Ṣe Jáwọ́ Ńbẹ̀”
Mieko: “Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọkàn mi sọ fún mi pé n kò lè jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ète tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ ni pé kí àwọn ọmọ mi ṣáà mọ ọ̀nà ìyè. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ tí mo wá mọ̀ pé òbí kan gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ó gba ìsapá láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí mo gbàdúrà fún, nǹkan kò sì rọgbọ fún mi rárá fún àkókò díẹ̀. Ṣùgbọ́n n kò jẹ́ gbàgbé ìmọ̀lára ẹ̀rí ọkàn rere tí mo ní nígbà tí mo já ara mi gbà pátápátá kúrò nínú ìwà eléèérí bíburújáì yìí.”
Masayuki: “Lẹ́yìn jíjẹ́ ẹni tí ń mu páálí mẹ́ta lójúmọ́ àti lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láti jáwọ́ ńbẹ̀, mo jáwọ́ nínú sìgá mímu nígbẹ̀yìngbẹ́yín, n kò sì mu tábà mọ́. Ìdílé mi, Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi, àti Jèhófà Ọlọ́run ló ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ ńbẹ̀. Ó ya gbogbo àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ ní báńkì lẹ́nu pé mo ti jáwọ́ ńbẹ̀. Mo dábàá pé, láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn oníbàárà wa, kí àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ ní gbangba gbọ̀ngàn báńkì yé mu sìgá lákòókò iṣẹ́. Wọ́n ṣiṣẹ́ lórí àbá tí mo dá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín ọgọ́rin nínú gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ nígbà náà ló ń mu sìgá. Ìgbésẹ̀ yìí ti wá di èyí tí gbogbo ọ̀tàlérúgba [260] ẹ̀ka báńkì wa mú lò.”
Osamu: “Nígbà tí mo mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nínú Bíbélì, mo mọ̀ pé mo ní láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà mí tó bí ọdún kan. Kódà, lẹ́yìn tí mo jáwọ́ ńbẹ̀ pàápàá, mo ní láti máa bá òòfà-ọkàn láti mu sìgá jà fún oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà. Mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé ó gbọ́dọ̀ wà lọ́kàn èmi fúnra mi láti jáwọ́ ńbẹ̀.”
Toshihiro: “Ẹbọ ìràpadà Jésù wọ̀ mí lọ́kàn gan-an tí mo fi ronú pé, ó kéré tán, mo lè jáwọ́ nínú sìgá mímu.”
Yasuhiko: “Ìpinnu mi láti ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, kí n sì jáwọ́ nínú sìgá mímu dáàbò bo ẹ̀mí mi. Lọ́jọ́ kan, gáàsì jò, ó sì bo iyàrá tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ǹ bá ti finá sí sìgá, ilé ì bá sì ti gbiná. Ṣùgbọ́n, nítorí pé mo ti jáwọ́ nínú sìgá mímu lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn, èmi náà rèé tí mo ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lónìí yìí.”
Akio: “Nígbà tí ẹ̀dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo fura pé sìgá tí mo ń mu ló ń bá mi jà. Àmọ́, n kò jáwọ́ ńbẹ̀. Ìyàwó mi, tó ti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló kọ́kọ́ sọ òkodoro ọ̀rọ̀ fún mi nípa àwọn ewu tó wà nínú àṣà mímu sìgá. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower sì fi kọ́ mi pé ẹni tó ń mu sìgá ń pa ara rẹ̀ àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ lára. Mo yáa jáwọ́ ńbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀!”
Ryohei: “Ìyàwó mi ló máa ń lọ ra sìgá fún mi—ogún páálí ló máa ń rà lẹ́ẹ̀kan náà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó kọ̀ láti máa ra nǹkan náà tó mọ̀ pé yóò pa mí lára fún mi. Nítorí náà, mo ṣí ṣọ́ọ̀bù tábà tèmi fúnra mi. Mo ń mu páálí mẹ́ta ààbọ̀ lójúmọ́. Nígbà tó yá, Àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìpẹ́ láìjìnnà, ó wù mí láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́. Nítorí náà, mo jáwọ́ nínú sìgá mímu kí n lè tóótun fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.”
Junichi: “Ìwàláàyè mi ló jẹ ọmọbìnrin mi kékeré tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lọ́kàn. Ó mú mi ṣèlérí pé n óò jáwọ́ nínú sìgá mímu, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.”
Tsuya: “Nígbà àkọ́kọ́ tí mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, bí mo ṣe wọlé ni mo ní kí wọ́n bá mi wá àwo tí wọ́n ń da eérú sìgá sí àti ìṣáná. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé kò sẹ́ni tí ń mu sìgá nínú gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Mo mọ̀ pé mo ní láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ọjọ́ mẹ́jọ tí mo lò nínú ipò àìfararọ ní ilé ìwòsàn mú un dá mi lójú pé n kò tún ní fẹ́ nírìírí ìrora tí pípadà máa mu ún lè fà.”
Yoko: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa kókó ọ̀rọ̀ náà nínú àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, mo sì ṣàyẹ̀wò nípa bí Jésù ṣe kọ oògùn líle tí wọ́n gbé fún un nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n kàn án mọ́ òpó igi oró. Mo gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, mo sọ fún un pé mo fẹ́ jẹ́ aláìlábààwọ́n tí ń yin orúkọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, n kò tún mu sìgá mọ́. Nígbà tí àwọn tó yí mi ká ń mu sìgá, díẹ̀ ló kù kí n fa èéfín sìgá wọn símú, àmọ́ mo tètè sá sẹ́yìn, nítorí pé n kò fẹ́ kí nǹkan kan tún sún mi sí sìgá mímu.”
Gbogbo àwọn amusìgá tẹ́lẹ̀ rí yìí ti pinnu láti má ṣe mu sìgá mọ́. Ìwọ ha ń mu sìgá, tí o sì fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà yìí bí?
Mieko
Osamu
Yasuhiko
Akio àti aya rẹ̀, Sachiko
Junichi àti Meri, ọmọbìnrin rẹ̀
Yoko