ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àrùn AIDS àti Ìdàgbàsókè
  • Agbára Ìkàwé àti Ìríṣẹ́ṣe
  • Ìkórìíra Aáyán
  • Ìbísí Nínú Ipò Òṣì
  • Sísọ Oògùn Líle Di Bárakú ní Europe
  • “Ipá Ìdarí Láti Má Sanra”
  • Níní Ọkàn Ìfẹ́ Tí A Kò Retí sí Bíbélì
  • Ọ̀rẹ́ Kan Jálẹ̀ Gbogbo Ìgbésí Ayé
  • Máa Jẹ Èso Lójoojúmọ́
  • Ṣíṣètọ́jú Wèrè
  • Ó Léwu Ju Mímu Sìgá Lọ Kẹ̀?
  • Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Yẹ Kó O Máa Ṣeré Ìmárale?
    Jí!—2005
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àrùn AIDS àti Ìdàgbàsókè

Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Ìdàgbàsókè ròyìn láìpẹ́ yìí pé, kárí ayé, àjàkálẹ̀ àrùn AIDS ti fawọ́ ìdàgbàsókè ẹ̀dá ènìyàn sẹ́yìn ní ìwọ̀n ọdún 1.3. Àwọn tí ó kàn jù lọ ni àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà—Zambia ti pàdánù èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá ìdàgbàsókè ẹ̀dá ènìyàn; Tanzania ti pàdánù ọdún mẹ́jọ; Rwanda ti pàdánù ọdún méje; Ilẹ̀ Olómìnira Àárín Gbùngbùn Áfíríkà ti pàdánù èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́fà. Àrùn AIDS tún ti dín iye ọdún ìwàláàyè tí a fojú sùn kù. Ní Àríwá America àti Europe, àrùn AIDS ti di okùnfà ikú tí ó gbawájú jù lọ láàárín àwọn àgbàlagbà tí kò ì pé ọdún 45. Kárí ayé, 6,000 ènìyàn ń ní fáírọ́ọ̀sì HIV lójúmọ́, ìpíndọ́gba ẹnì 1 láàárín ìṣẹ́jú àáyá 15. Ọjọ́ orí iye tí ó lé ní ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí àrùn AIDS ń pa wà láàárín 20 ọdún sí ọdún 45.

Agbára Ìkàwé àti Ìríṣẹ́ṣe

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Vancouver Sun ṣe sọ, Àjọ Ìpèsè Ìsọfúnni Oníṣirò ti Kánádà sọ pé: “Láàárín ìpín 56 sí 64 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ ni kò mọ̀wé dójú ìwọ̀n.” Ìwádìí kan tí a ṣe ní 1995 láti ṣe àyẹ̀wò agbára ìkàwé nínú ìtàn ọlọ́rọ̀ wuuru, kíka àwọn àkọsílẹ̀, àti kíka nọ́ńbà fi hàn pé, ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà ní ìṣòro ní àgbègbè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ìwé agbéròyìnjáde Sun náà sọ pé, ní ibi “àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ‘tí ó lọ́jọ́ lórí jù,’ bí iṣẹ́ àgbẹ̀, ìwakùsà, ìṣeǹkanjáde àti ìkọ́lé, . . . ó jọ pé ìmọ̀wé lọ sílẹ̀ jù lọ.” Pẹ̀lú bí ìgbanisíṣẹ́ ṣe ń lọ sílẹ̀ ní àwọn apá wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe kí a ti àwọn ilé iṣẹ́ kan pa tàbí kí a dá àwọn òṣìṣẹ́ tí kò mọ̀wé tó bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì dúró lẹ́nu iṣẹ́. John O’Leary, ààrẹ àjọ ìmọ̀wéékà, sọ pé, “jíjẹ́ ẹni tí kò mọ̀wé tó bẹ́ẹ̀ ní 1996 túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí a fi ọ̀pọ̀ àǹfààní ara ẹni àti ti iṣẹ́ ṣíṣe dù.”

Ìkórìíra Aáyán

Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà University of California at Berkeley Wellness Letter ṣe sọ, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé láàárín mílíọ̀nù 10 sí 15 àwọn ènìyàn United States ní èèwọ̀ ara lòdì sí aáyán. Bi ẹnì kan tí ó ní èèwọ̀ ara yìí bá bá ara rẹ̀ níbi tí àwọn aáyán wà, ó lè ní “ara yíyún, àsín-ìnsíntán, tàbí àwọn àmì àrùn òtútù àyà.” Lẹ́tà ìròyìn náà sọ pé, “èyí tí ó tó ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí ó ní àrùn òtútù àyà ni ó kórìíra aáyán.” Àwọn aáyán kò fi dandan jẹ́ àmì pé ilé ìgbọ́únjẹ dọ̀tí. Kódà, lẹ́tà Wellness Letter náà sọ pé, “wọ́n lè wà ni ilé ìgbọ́únjẹ tó mọ́ jù lọ.” Wọ́n ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, bí o bá fi rí aáyán kan ṣoṣo nínú ilé kan, ó ṣeé ṣe kí àwọn aáyán tí o kò rí, tí ń kiri nínú ilé náà, tó 1,000. Takọtabo aáyán kan lè mú nǹkan bí 100,000 irú ọmọ jáde láàárín ọdún kan péré.

Ìbísí Nínú Ipò Òṣì

Iye àwọn ènìyàn tí kò lè pèsè àwọn ohun kòṣeé-mánìí ìgbésí ayé fúnra wọn kárí ayé—tí a túmọ̀ sí pé owó tí ń wọlé fún wọn lọ́dún dín sí 370 dọ́là—jẹ́ nǹkan bíi bílíọ̀nù 1.3, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́ta gbogbo olùgbé ayé. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ní gbogbogbòò, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní àǹfààní oúnjẹ púpọ̀ tó, omi tí kò lẹ́gbin, ìpèsè ìlera, ilé bíbójúmu, ẹ̀kọ́ ìwé, àti ìgbanisíṣẹ́. Ní apá púpọ̀ jù lọ, a ń fojú kéré wọn nínú àwọn àwùjọ tí wọ́n ń gbé, wọn kò sì lágbára láti yí ipò wọn pa dà. Gẹ́gẹ́ bí Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Ìdàgbàsókè ṣe sọ, iye àwọn ènìyàn tí kò lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé fúnra wọn ń fi iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 25 lọ́dọọdún pọ̀ sí i.

Sísọ Oògùn Líle Di Bárakú ní Europe

Àjọ tuntun kan ní Europe, tí ń tọpa ìlò àti àṣìlò egbòogi, ti tẹ ìròyìn ọdọọdún rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́ ti ilẹ̀ Faransé náà, Le Monde, ṣe wí, ìwádìí wọn fi hàn pé, àwọn tí wọ́n ti sọ heroin di bárakú ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe wà “láàárín 500,000 sí mílíọ̀nù kan.” Nígbà tí ó jọ pé sísọ kokéènì di bárakú kò pọ̀ sí i tàbí pé ó tilẹ̀ ń dín kù ní àwọn ìlú ńlá pàtàkì-pàtàkì ilẹ̀ Europe, ńṣe ni ó ń pọ̀ sí i ní àwọn ìlú kéékèèké. Àwọn àmújáde ewéko cannabis bíi hashish àti marijuana ni ó ṣì jẹ́ oògùn líle tí a ń lò jù lọ ní Europe. Ohun tí ń kọ àwọn ògbóǹkangí lóminú ni bí òkìkí àwọn àpèjẹ onírẹ́jẹ́, níbi tí a ti ń da àwọn oògùn líle pọ̀ mọ́ egbòogi àti ọtí líle, ṣe ń pọ̀ sí i. Ní Àríwá Europe, àwọn egbòogi eléròjà amphetamine, egbòogi Ecstasy (tí a mú jáde láti ara èròjà methamphetamine), àti egbòogi LSD ń lókìkí sí i láàárín àwọn èwe.

“Ipá Ìdarí Láti Má Sanra”

Lábẹ́ àkọlé náà, “Gbígbógunti Ipá Ìdarí Láti Má Sanra,” ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times ròyìn pé: “Iye àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà ọmọbìnrin tí kò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí ń ní àrùn àìtó ẹ̀jẹ̀ nítorí àwọn àṣà ìgbàlódé ti oúnjẹ jíjẹ.” Àwọn dókítà ti sọ bí ìtẹ̀sí náà ṣe ń kọ wọ́n lóminú gidigidi tó. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n ń di ẹ̀bi náà ru àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ohun ìṣaralóge “nítorí ipa búburú tí wọ́n ń ní lórí àwọn ọ̀dọ́ tí ó ṣeé fi nǹkan mú lọ́kàn.” Ìròyìn yẹn sọ pé, ní ìran tó kọjá gẹ́lẹ́, àfiṣàpẹẹrẹ oge kan ń wọn ìpín mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún dín sí ti obìnrin kan ní gbogbogbòò. Lónìí, ó fi ìwọ̀n ìpín 23 nínú ọgọ́rùn-ún fúyẹ́ sí i. Ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times sọ pé: “Àwọn apá tí ìyàn ti mú ni a ń kà sí oge gan-an, àti pé àwọn ènìyàn tó gbẹ kan egungun—tí àwọ̀ ara wọn ṣì, tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, tí kò jẹun kánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra . . . —ni a ń fi hàn nísinsìnyí bí àfiṣàpẹẹrẹ.” Lábẹ́ ìsúnniṣe láti bá irú àfiṣàpẹẹrẹ yìí mu, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin tí kò fẹ́ sanra ní ń jẹun lọ́nà tí ń fi àwọn èròjà iron, protein, àti fítámì tí kò ṣeé máà ní dù wọ́n.

Níní Ọkàn Ìfẹ́ Tí A Kò Retí sí Bíbélì

Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé: “Ìlàjì mílíọ̀nù ẹ̀dà Májẹ̀mú Tuntun ní Èdè Danish [ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì] ni a ti pín fúnni—ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan fún nǹkan bí ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo agbo ilé tí ń bẹ ní Copenhagen.” Wọ́n ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí apá kan ayẹyẹ ipa tí Copenhagen kó gẹ́gẹ́ bí Olú Ìlú Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Europe ní 1996. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti sọ tẹ́lẹ̀ pé, láàárín ìpín 10 sí 20 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbo ìdílé tí ń bẹ ní Copenhagen yóò kọ ẹ̀bùn náà. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Morten Aagaard, akọ̀wé gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Bíbélì ti Danish ṣe wí, “kìkì ìpín kan tàbí méjì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbo ilé náà” ni ó kọ ẹ̀bùn náà. Wọ́n ń wéwèé irú ìpínkiri kan náà fún Stockholm, Sweden, ní 1998.

Ọ̀rẹ́ Kan Jálẹ̀ Gbogbo Ìgbésí Ayé

Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse ròyìn pé, ní Germany, ẹni 9 nínú 10 sọ pé àwọn ní ọ̀rẹ́ kan jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé. Ìwádìí kan tí Ẹgbẹ́ Ìwádìí Àwùjọ Ẹ̀dá Ènìyàn Lọ́nà Sáyẹ́ǹsì ṣe, nínú èyí tí wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn tí ó lé ní 1,000, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 16 sí 60 lẹ́nu wò, ló fi èyí hàn. Wọ́n ka ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti àìlábòsí sí èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn kókó abájọ nínú ìṣọ̀rẹ́ wíwàpẹ́títí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ni wọ́n gbà pé àìdúróṣinṣin àti ìsẹ́ni yóò fòpin sí irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pe: “Ìpín 16 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára wọn ni yóò retí pé kí ọ̀rẹ́ rere kan yá [àwọn] ní owó nínú ipò pàjáwìrì kan.” Ní ìhà kejì, ìpín púpọ̀ kan nínú ọgọ́rùn-ún ka rírí ìtìlẹ́yìn ọ̀rẹ́ kan gbà nígbà àìsàn sí ohun tí ó ṣe pàtàkì gidigidi.

Máa Jẹ Èso Lójoojúmọ́

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ọlọ́dún 17 kan tí a ṣe fún 11,000 ènìyàn, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn British Medical Journal ṣe sọ, jíjẹ èso tútù lójoojúmọ́ ní í ṣe pẹ̀lú dídín ewu àrùn ọkàn àyà kù. Lára àwọn tí ń jẹ èso tútù lójoojúmọ́ nínú àwọn tí a lò fún ìwádìí náà, àwọn tí àrùn ọkàn àyà pa fi ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù, àwọn tí àrùn ẹ̀gbà pa fi ìpín 32 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Àwọn tí ó kú lára àwọn tí ń jẹ èso tútù lójoojúmọ́ fi ìpín 21 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù sí ti àwọn tí kì í jẹ èso déédéé tó bẹ́ẹ̀. Àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan láti Britain àti Sípéènì sọ pé, àwọn oúnjẹ tí kò ní èso nínú ń dá kún àwọn àrùn inú òpójẹ̀ bí àrùn ẹ̀gbà àti àrùn ọkàn àyà láàárín àwọn ènìyàn kan. Ní báyìí, àwọn olùwádìí ń dábàá jíjẹ oúnjẹ tó ní ewébẹ̀ àti èso nínú nígbà márùn-ún lóòjọ́, ó kéré tán, fún àǹfààní ìlera dídára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn British Medical Journal ṣe wí, bí kò bá sí àwọn èso àti ewébẹ̀ tútù, àwọn tí a kó pa mọ́ sínú yìnyín náà lè mú àbájáde jíjọra wá.

Ṣíṣètọ́jú Wèrè

Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ti Kánádà sọ pé: “Ògì oat gbígbóná fẹlifẹli, ohùn orin tí ń dún jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àti àyíká tí a fìṣọ́ra ṣètò kì í ṣe àwárí tuntun nínú ìṣègùn, ṣùgbọ́n wọ́n ń yí ìtọ́jú àwọn arúgbó pa dà sí rere.” Lílo àwọn ìyípadà rírọrùn tí kò sì gbówó lórí nínú ọ̀nà tí a gbà ń wẹ̀ fún àwọn aláìsàn, tí a sì gbà ń bọ́ wọn ń dín ìdàrúdàpọ̀ ọkàn àti àníyàn wọn kù. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn náà sọ pé, gbígbé oríṣi oúnjẹ kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lásìkò àtijẹun ń gba aláìsàn náà lọ́wọ́ ṣíṣe ìpinnu èwo ni yóò kọ́kọ́ jẹ, tí ó sábà máa ń da ẹnì kan tí ó ya wèrè lọ́kàn rú. Ìmúratán láti ṣèyípadà sí ọ̀nà ìṣeǹkan tilẹ̀ ti ń mú kí lílò tí àwọn aláìsàn ń lo àwọn egbòogi ayímọ̀lára-padà dín kù lọ́nà kíkọyọyọ.

Ó Léwu Ju Mímu Sìgá Lọ Kẹ̀?

Ìwé agbéròyìnjáde The Medical Post ròyìn pé, gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìpèsè Ìsọfúnni Oníṣirò ti Kánádà ṣe sọ, “ọ̀nà ìgbésí ayé ìjókòó-sójú-kan ń wu ìlera léwu ju ìlọ́po méjì ti mímu sìgá lọ.” Nígbà tí ó ṣeé ṣe kí nǹkan bíi mílíọ̀nù méje àwọn ará Kánádà ní àwọn àìsàn líle koko, kí wọ́n sì tètè kú nítorí mímu tábà, àwọn tí ó dojú kọ irú ewu ìlera kan náà nítorí àìṣeré-ìmárale jẹ́ láàárín mílíọ̀nù 14 sí 17. A máa ń tọ́ka sí àìní àkókò, agbára, àti ìsúnniṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn kókó abájọ pàtàkì tí ń ṣèdíwọ́ fún ṣíṣe eré ìmárale déédéé. Ó tún ṣeé ṣe kí àwọn ajókòó-sójúkan máa jẹ àwọn oúnjẹ eléròjà fats púpọ̀, kí wọ́n má sì jẹ èso àti ewébẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Post náà sọ pé: “Góńgó lọ́ọ́lọ́ọ́ ti jíjèrè àǹfààní púpọ̀ jù lọ fún ọkàn àyà ni láti mú kí àwọn ènìyàn máa ṣeré ìmárale ó kéré tán, fún 30 ìṣẹ́jú, lọ́jọ́ kẹtakẹta, ní ìwọ̀nba tàbí jinlẹ̀jinlẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́