ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/8 ojú ìwé 30-31
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kọ́lẹ́rà Tún Rú Yọ
  • Sísọ̀rọ̀ Nípa Àlàáfíà Àgbáyé
  • Ó Ṣì Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́
  • “Àwọn Ońṣẹ́ Ikú”
  • Olórí Ẹ̀sìn Buddha Dámọ̀ràn Wíwá Òtítọ́
  • Oògùn Apakòkòrò Àdánidá
  • Marijuana—Oògùn Lílé Ni Bí?
  • Omi Dídì ní Íjíbítì Ìgbàanì
  • Ìṣírasílẹ̀ sí Oòrùn
  • Àṣà Tí Ń Náni Lówó
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Àwọn Ewu Wo Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Lílo Oògùn Olóró—O Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀!
    Jí!—2001
Jí!—1998
g98 2/8 ojú ìwé 30-31

Wíwo Ayé

Kọ́lẹ́rà Tún Rú Yọ

Kọ́lẹ́rà tún ti pa dà dé sí Gúúsù Amẹ́ríkà lọ́nà tí ó gbàfiyèsí lẹ́yìn tí ó ti lọ fún ohun tí ó lé ní 100 ọdún. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, “Láti 1991, mílíọ̀nù 1.4 ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ni a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì ti pa 10,000 ènìyàn.” Ohun tó túbọ̀ fi kún ìdààmú àwọn alábòójútó ètò ìlera ni ti oríṣi bakitéríà kọ́lẹ́rà tuntun kan tí ó yọjú ní 1992, tí ó ti kọ lu 200,000 ènìyàn ní Íńdíà, Bangladesh, àti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà nítòsí. Kọ́lẹ́rà jẹ́ akọ àrùn àrunṣu, ó sì máa ń pa ìwọ̀n ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó bá kọ lù àyàfi tí ìtọ́jú tí ó tó bá wà. Àmọ́ dídènà rẹ̀ sàn ju wíwá ìwòsàn lọ. Síse omi mímu àti mílíìkì, lílé eṣinṣin dà nù, àti ṣíṣan àwọn oúnjẹ tí a kò tí ì sè nínú omi tí a fi èròjà chlorine sí jẹ́ ọ̀nà ààbò tí ó ṣe pàtàkì.

Sísọ̀rọ̀ Nípa Àlàáfíà Àgbáyé

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ọdọọdún Yearbook 1997 ti Àjọ Ìṣèwádìí Àlàáfíà Àgbáyé ní Stockholm ṣe sọ, ó jọ pé àwọn ogun ẹlẹ́kùnjẹkùn tí wọ́n ti kópa pàtàkì nínú Ogun Tútù náà nígbà kan rí ti dópin. Ní 1989, ọdún tí Ogun Tútù náà jà kẹ́yìn, “ìforígbárí oníhàámọ́ra ogun pàtàkì” 36 ló ṣẹlẹ̀. Iye náà lọ sílẹ̀ sí 27 ní 1996, gbogbo rẹ̀ pátápátá ló jẹ́ ogun abẹ́lé àyàfi èyí tó ṣẹlẹ̀ láàárín Íńdíà àti Pakistan. Síwájú sí i, bí a ti fi iye ènìyàn tó kú díwọ̀n rẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìforígbárí wọ̀nyí ni kò le mọ́ tàbí kí ó máa bá a lọ niwọ̀n tí kò pọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Star, tí wọ́n ń ṣe ní Gúúsù Áfíríkà parí èrò sí pé: “Kò sí ìran mìíràn tí ó tí ì sún mọ́ àlàáfíà àgbáyé tó báyìí.” Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ìṣàkóso Amẹ́ríkà . . . ti fún ayé ní Àlàáfíà Lábẹ́ Ìdarí Amẹ́ríkà, sànmánì alálàáfíà àgbáyé àti ìtòròmini tí a kò rí irú rẹ̀ ní ọ̀rúndún yìí, tí a kì í sábà rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.”

Ó Ṣì Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́

Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀dà Bíbélì ni a ṣì ń tẹ jáde ju àwọn ìwé mìíràn lọ.” Àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti ń ṣèpínkiri Bíbélì jù lọ ní China, United States, àti Brazil. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ àjọ United Bible Societies (UBS) ti sọ, 19.4 mílíọ̀nù ẹ̀dà Bíbélì lódindi ni a pín kiri ní 1996. Àkójọ àkọsílẹ̀ tuntun ni èyí, ó sì fi ìpín 9.1 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju ti 1995 lọ. John Ball, olùṣekòkárí ìtẹ̀jáde fún àjọ UBS, sọ pé, lójú pé “ìpínkiri náà pọ̀ gan-an ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé tó bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ púpọ̀ jọjọ ṣì wà tí a ní láti ṣe bí a óò bá jẹ́ kí ó rọrùn fún olúkúlùkù ènìyàn láti lè rí Ìwé Mímọ́ kà.”

“Àwọn Ońṣẹ́ Ikú”

Ìròyìn Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) fún ọdún 1997 sọ pé, àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn tí wọ́n lọ́rọ̀ ń sọ “ìṣòro” àrùn di “ìlọ́po méjì” fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Bí ìwé agbéròyìnjáde The Daily Telegraph ti London ṣe sọ, àrùn ọkàn àyà, àrùn ẹ̀gbà, àtọ̀gbẹ, àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan ti ń pọ̀ gan-an bí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti ń gba àwọn àṣà sìgá mímu, jíjẹ oúnjẹ tí èròjà afáralókun àti ọ̀rá pọ̀ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì ń dín ìgbòkègbodò eré ìmárale ṣíṣe kù. Dókítà Paul Kleihues, olùdarí kan fún àjọ WHO sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń pẹ́ láyé sí i tí a bá wò káàkiri ayé, èyí ‘kò já mọ́ nǹkan kan, bí wọn kò bá ń gbádùn ayé wọn.’ Ó fi kún un pé: “Òótọ́ ni àwọn tí wọ́n sọ pé ońṣẹ́ ikú gidi ni wá sọ.” Àjọ WHO ń ṣalágbàwí ìgbétáásì kikankikan kan láti fún ìgbésí ayé tó gbámúṣé níṣìírí jákèjádò ayé. Ó sọ pé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óò ní “ipò ìṣòro ìrora jákèjádò ayé.”

Olórí Ẹ̀sìn Buddha Dámọ̀ràn Wíwá Òtítọ́

Eshin Watanabe, àlùfáà onípò gíga jù lọ tí ó sì jẹ́ olórí ọ̀kan lára ẹ̀ya ẹ̀sìn Buddha tí ó tí ì wà pẹ́ jù lọ ní Japan, sọ pé: “Kò dára láti máa ṣe agídí” tí ó bá kan ọ̀ràn ti ìsìn. Wọ́n bí í bóyá ohun tí ó ní lọ́kàn ni pé fífi ìdúróṣinṣin rọ̀ mọ́ èrò ìgbàgbọ́ dára, tí fífi agídí rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ kò sì dára, ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Daily News fa àlàyé tí ó ṣe yọ pé: “O gbọ́dọ̀ ronú lórí bóyá àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ tọ̀nà tàbí wọn kò tọ̀nà. Ó ṣe pàtàkì láti tún gbé wọn yẹ̀ wò ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn èrò ìgbàgbọ́ mìíràn. O tún gbọ́dọ̀ ronú lórí bóyá wọ́n jẹ́ òtítọ́ tàbí wọn kì í ṣe òtítọ́. A gbọ́dọ̀ tún gbé àwọn ohun wọ̀nyí yẹ̀ wò.” Watanabe ni olórí ẹ̀ya Tendai tí ó jáde láti ara ẹ̀sìn Buddha, tí wọ́n mú wá sí Japan láti China ní 1,200 ọdún sẹ́yìn.

Oògùn Apakòkòrò Àdánidá

Àwọn ènìyàn kan wulẹ̀ máa ń lá ojú ọgbẹ́ wọn bí wọ́n bá ṣèèṣì fi nǹkan ya ara wọn, bí àwọn ẹranko ṣe máa ń ṣe. Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, àwọn olùṣèwádìí ní Ilé Ìwòsàn St. Bartholomew ní London ti ṣàwárí pé itọ́ jẹ́ oògùn apakòkòrò àdánidá ní ti gidi. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Independent ṣe sọ, àwọn onímọ̀ ìpoògùn ní kí àwọn 14 kan tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn lá tojútẹ̀yìn ọwọ́ wọn, wọ́n sì ṣàwárí pé ìwọ̀n èròjà nitric oxide tí ó wà ní awọ ara wọn ti pọ̀ sí i gidigidi. Èròjà nitric oxide, kẹ́míkà alágbàra kan tí ó lè pa àwọn kòkòrò àrùn, gbára jọ nígbà tí èròjà nitrite tí ó wà nínú itọ́ kan awọ ara tí ó ní èròjà ásíìdì. Kẹ́míkà míràn, ascorbate, tí òun pẹ̀lú wà nínú itọ́, ran ìṣiṣẹ́ náà lọ́wọ́.

Marijuana—Oògùn Lílé Ni Bí?

Àwọn tí ń lo marijuana ti ń jiyàn tipẹ́tipẹ́ pé oògùn náà kì í ṣèpalára dé ìwọ̀n kan. Ìwé àtìgbàdégbà náà, Science, ròyìn pé, “ẹ̀rí tuntun fi hàn pé ipa [marijuana] lórí ọpọlọ jọ èyí tí àwọn oògùn ‘líle’ bíi heroin ń ní.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti United States, Sípéènì, àti Ítálì ni wọ́n ṣe ìwádìí náà. Lára àwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ ni pé, “èròjà arunisókè kan nínú marijuana—irú èròjà cannabis kan tí a mọ̀ sí THC—ń fa irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà inú ohun alààyè pàtàkì kan náà tí ó jọ pé ó ń fún ìfarajìn àwọn oògùn líle mìíràn, láti orí èròjà nicotine dé orí èròjà heroin, lókun: ìtújáde ásíìdì dopamine lápá kan ọ̀nà ‘sísan ẹ̀san ire’ fún ọpọlọ,” èyí tí ń mú kí àwọn ajoògùnyó túbọ̀ máa mu ún sí i. Nígbà tí a bá jáwọ́ lílo marijuana tí a ti ń lò fún ìgbà pípẹ́, ìwọ̀n kẹ́míkà míràn, irú ásíìdì peptide kan tí a ń pè ní èròjà tí ń tú èròjà corticotropin jáde (CRF), yóò lọ sókè nínú ọpọlọ. Èròjà CRF ló ń fa másùnmáwo àti àìbalẹ̀ ara tí ń ṣẹlẹ̀ bí ènìyàn bá jáwọ́ lílo àwọn oògùn líle apanilọ́bọlọ̀, ọtí líle, àti kokéènì. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, olùṣèwádìí kan sọ pé: “Yóò tẹ́ mi lọ́rùn bí àwọn ènìyàn kò bá tún ní máa ka èròjà THC sí oògùn líle ‘tí kì í ṣèpalára púpọ̀’ lẹ́yìn gbígbé gbogbo ẹ̀rí wọ̀nyí yẹ̀ wò.” Lọ́dọọdún, nǹkan bí 100,000 ènìyàn ní ń wá ìtọ́jú kúrò nínú ìfarajìn marijuana ní United States.

Omi Dídì ní Íjíbítì Ìgbàanì

Ìwé agbéròyìnjáde, The Countyline, ti Bryan, Ohio, sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Íjíbítì ìgbàanì kò ní fìríìjì àtọwọ́dá kan, wọ́n ń mú omi dídì jáde nípasẹ̀ ohun àrà àdánidá kan tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ipò ojú ọjọ́ bá gbẹ, tí ó sì báradé.” Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? “Bí oòrùn bá ti wọ̀, àwọn obìnrin Íjíbítì yóò bu omi sínú abọ́ pẹrẹsẹ, tí kò jinnú púpọ̀, tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, wọ́n óò sì gbé e sórí àwọn pòròpórò tí a tẹ́ sílẹ̀. Ìfàgbẹ lọ́nà yíyárakánkán tí ń ṣẹlẹ̀ ní ìtẹ́jú omi náà àti ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ abọ́ pẹrẹsẹ tí ó tutù náà dà pọ̀ mọ́ ìwọ̀n ìgbóná tí ń dín kù ní alẹ́ náà láti mú omi náà dì—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀n ìtutù àyíká náà kò tutù dé ìpele tí ó fi lè dì.”

Ìṣírasílẹ̀ sí Oòrùn

Ìwé agbéròyìnjáde The Vancouver Sun sọ pé: “Àrùn jẹjẹrẹ awọ ara tún ti ń jà kálẹ̀ gan-an ní Àríwá Amẹ́ríkà,” àwọn ará Kánádà sì ti “wà nínú ewu pé ẹnì kan lára àwọn méje níbẹ̀” ni yóò ṣe “níwọ̀n ìgbà tí ó bá fi wà láàyè.” Ìwé agbéròyìnjáde náà fi kún un pé: “Ìṣírasílẹ̀ sí oòrùn ni a gbà gbọ́ pé ó fa ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-un lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ara wíwú aronigógó.” Ìròyìn náà sọ pé, ńṣe ni a ń ba awọ ara tí a ṣí sílẹ̀ sí oòrùn láti pààrọ̀ àwọ̀ rẹ̀ jẹ́, ó sì ń jẹ́ kí awọ ara tètè gbó, ó sì máa ń tẹ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn rì. Ìwádìí káàkiri orílẹ̀-èdè tí a ṣe lọ́dọ̀ àwọn ará Kánádà tí iye wọn lé ní 4,000 fi hàn pé ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ló mọ ewu tó wà nínú ṣíṣí awọ ara wọn sílẹ̀ sí oòrùn, síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn tí kì í sábà gbé ìgbésẹ̀ ìdènà èyíkéyìí bí wọ́n bá tilẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rí. Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n láti Yunifásítì British Columbia náà, Ọ̀mọ̀wé Chris Lovato, ọ̀kan lára àwọn olórí olùṣèwádìí nínú ìwádìí náà, kìlọ̀ pé, “a ní láti sọ dídáàbòbo ara lọ́wọ́ oòrùn di àṣà” kí a sì tẹ “àwọn ọ̀nà tí ó láàbò tí ó sì bọ́gbọ́n mu láti gbádùn wíwà nínú oòrùn” mọ́ àwọn ènìyàn lọ́kàn.

Àṣà Tí Ń Náni Lówó

Sìgá mímú ń náni lówó. Èló ló ń náni? Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ìròyìn University of California Berkeley Wellness Letter ti sọ, bópẹ́bóyá, ó lè tó 230,000 dọ́là tàbí 400,000 dọ́là—tí ó sinmi lé bóyá o ń mu tó páálí sìgá kan tàbí méjì lóòjọ́. Lẹ́tà ìròyìn Wellness Letter náà sọ pé: “Ká ní o ṣì kéré, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá lónìí, tí o sì ń bá a lọ fún 50 ọdún, ká ní kò kọ́kọ́ pa ọ́. Bí o bá ń mu páálí kan tí iye rẹ̀ jẹ́ 2.50 dọ́là lóòjọ́ (láti mú nǹkan rọrùn, jẹ́ ká gbàgbé ọ̀ràn owó ọjà tí ń ga), àròpọ̀ ìyẹn yóò lé ní 900 dọ́là lọ́dún, tàbí 45,000 dọ́là láàárín 50 ọdún. Bí o bá ń kó owó yẹn lọ sí báńkì lọ́dọọdún tí èléwó ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún sì ń gorí rẹ̀, àròpọ̀ rẹ̀ lè fìrọ̀rùn di ìlọ́po mẹ́rin.” Tí a bá fi àfikún owó ìbánigbófò ẹ̀mí àti owó ṣíṣàtúnṣe (ilé, aṣọ, àti eyín) mọ́ ọn, àròpọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ àwọn iye tí a mẹ́nu kàn níṣàájú. Lẹ́tà náà fi kún un pé: “Ìyẹn kò sì sí lára owó tí ìwọ yóò ná sórí ìgbàtọ́jú fún àrùn tó ní í ṣe pẹ̀lú sìgá mímu bí owó ìbánigbófò ìlera rẹ kò bá kó gbogbo rẹ̀ mọ́ ọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́