ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbàyíkájẹ́ àti Àrùn Jẹjẹrẹ Ìgbà Ọmọdé
  • Ìsìn ní Brazil
  • Ọwọ́ Ta Ní Ìhùmọ̀ Ìgbókèèrè-Darí-Tẹlifíṣọ̀n Ń Wà?
  • Ìbálòpọ̀ Nígbà Ọ̀dọ́langba
  • Ìṣòro Ọwọ́ Fífọ̀
  • Ìbúrẹ́kẹ Ọrọ̀ Ajé àti Ipò Òṣì
  • Àwọn Ilé Tó Wà Níbi Eléwu ní Ítálì
  • Ẹ̀jẹ̀ àti Àkóràn Fáírọ́ọ̀sì HIV
  • Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Lọ́nà Àṣejù
  • Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Àwọn Erin
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìbàyíkájẹ́ àti Àrùn Jẹjẹrẹ Ìgbà Ọmọdé

Lẹ́yìn ṣíṣàtúpalẹ̀ ìwádìí ọlọ́dún 27 kan, tí a fi 22,400 ọmọdé ará Britain ṣe, àwùjọ àwọn onímọ̀ nípa àrùn kan, rí i pé àwọn ọmọ tí a bí ní ìwọ̀n kìlómítà márùn-ún sí orísun ìbàyíkájẹ́ wà nínú ewu kí àrùn leukemia àti àrùn jẹjẹrẹ ìgbà ọmọdé mìíràn pa wọ́n ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ju àwọn ọmọ mìíràn lọ. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, wíwà láìláàbò lọ́wọ́ àwọn ohun abàyíkájẹ́ tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri ni “ọ̀nà tí ó ṣeé ṣe jù lọ” kí a máa gbà ṣokùnfà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ ìgbà ọmọdé tí ń pọ̀ sí i. Ó jọ pé àwọn ohun abàyíkájẹ́ tí ń fà á ni ìrútúú epo ọkọ̀ tàbí àwọn adárútúrútú kẹ́míkà eléròjà carbon tí ń gbẹ láìsí ooru rẹpẹtẹ, tí a ń fọ́n jáde láti àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá bíi ti ilé iṣẹ́ ìfọpo, ilé iṣẹ́ aṣemọ́tò, ilé iṣẹ́ amúnáwá, ilé iṣẹ́ irin, àti ilé iṣẹ́ sìmẹ́ǹtì. Ìwádìí náà tún ròyìn pé, àwọn tí àrùn jẹjẹrẹ ń pa ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ọmọ tí a bí níbi tí kò jìn ju kìlómítà mẹ́rin lọ sí títì tàbí sí ojú irin. Àwọn tó tẹ ìwádìí náà jáde sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ epo mọ́tò àti epo rọ̀bì ló ń fà á.

Ìsìn ní Brazil

Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé ìwádìí àìpẹ́ yìí kan sọ pé, “ìpín 99 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Brazil ló gba Ọlọ́run gbọ́.” Bí ìwádìí tí a ṣe lọ́dọ̀ iye ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 náà ṣe sọ, ìpín 72 nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé àwọn jẹ́ Kátólíìkì, ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún kò sì sọ pé àwọn ń ṣe ìsìn pàtó kan. Àwọn tó kù jẹ́ ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Brazil àti àdàlú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Áfíríkà òun Brazil. Lẹ́tà ìròyìn ENI náà sọ pé: “Nígbà tí a bi wọ́n bóyá wọ́n lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ilé ìsìn kan ní òpin ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú, ìpín 57 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé àwọn kò lọ.” Ìpín 44 péré nínú ọgọ́rùn-ún ló gbà gbọ́ nínú ìjìyà ayérayé. Nígbà tí ìpín 69 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Brazil gbà gbọ́ pé ọ̀run wà, ìpín 32 péré nínú ọgọ́rùn-ún ló retí láti lọ síbẹ̀.

Ọwọ́ Ta Ní Ìhùmọ̀ Ìgbókèèrè-Darí-Tẹlifíṣọ̀n Ń Wà?

Àwọn olùwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ EURISPES (Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Ọ̀ràn Ìṣèlú, Ètò Ọrọ̀ Ajé àti Àwùjọ Ẹ̀dá Ènìyàn), ní Ítálì, gbé àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe lórí àṣà wíwo tẹlifíṣọ̀n jáde láìpẹ́ yìí. Ìdílé àwọn ará Ítálì tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000. Lára àwọn ìbéèrè tí wọ́n bi wọ́n ni èyí tí a fi mọ ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó sábà máa mú ìhùmọ̀ ìgbókèèrè-darí-tẹlifíṣọ̀n, tí àpilẹ̀kọ inú ìwé agbéròyìnjáde kan pè ní ọ̀pá àṣẹ òde òní, dání, kí ó sì máa lò ó, nínú ìdílé náà. Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ wọn, bàbá ni wọ́n sọ pé ó ní ìdarí náà lọ́wọ́. Àwọn ọmọ ló wà nípò kejì bí olùṣèpinnu bí ó bá di ti yíyí tẹlifíṣọ̀n sí ìkànnì. Ìyá ló wà nípò tó kẹ́yìn nínú ìjìjàdù agbára láti mú ìhùmọ̀ ìgbókèèrè-darí-tẹlifíṣọ̀n dání nínú ìdílé.

Ìbálòpọ̀ Nígbà Ọ̀dọ́langba

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Weekend Concord ti Nàìjíríà ṣe sọ, ìwádìí àìpẹ́ yìí kan rí i pé “àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà wà lára àwọn tí ń ní ìbálòpọ̀ jù lọ lágbàáyé.” Nǹkan bí ìpín 68 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin àti ìpín 43 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 14 sí 19 jẹ́wọ́ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ “láìpẹ́ lẹ́yìn tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà.” Èyí ti yọrí sí ọ̀pọ̀ oyún àìròtẹ́lẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Concord náà sọ pé, ìwádìí mìíràn tí a ṣe lọ́tọ̀ fi hàn pé “ìpín 71 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí kò pé ọdún 19 [lọ́jọ́ orí] tí ń kú ní Nàìjíríà ń kú nítorí àwọn ìṣòro tó rọ̀ mọ́ ìṣẹ́yún.”

Ìṣòro Ọwọ́ Fífọ̀

Àpilẹ̀kọ àìpẹ́ yìí kan nínú ìwé agbéròyìnjáde ìṣègùn ti ilẹ̀ Faransé náà, Le Quotidien du Médecin, tẹnu mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ń dani láàmú tó jọ pé ó ń pọ̀ sí i—àìkìífọwọ́-ẹni ká tó jẹun àti lẹ́yìn lílo ilé ìtura. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Frédéric Saldmann ṣe sọ, àìní ìmọ́tótó ara ẹni tó rọrùn yí jẹ́ ewu ńlá kan tí ń dé bá ìlera nítorí jíjẹ oúnjẹ alárùn, ó sì jọ ìṣòro kan tí ó tàn kálẹ̀. Àpilẹ̀kọ náà mẹ́nu ba ìwádìí kan, nínú èyí tí a ti rí i pé àwọn àwo ẹ̀pà ní àwọn ilé ìtura ilẹ̀ England ní ìtọ̀ nínú láti ọ̀dọ̀ ènìyàn 12 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwádìí mìíràn ní ilé ẹ̀kọ́ kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé fífọ ọwọ́ déédéé tí olùkọ́ kan bójú tó dín iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kì í wá sílé ẹ̀kọ́ nítorí àrùn tó jẹ mọ́ oúnjẹ kù ní ìpín 51 nínú ọgọ́rùn-ún, ó sì dín àwọn tí kì í wá nítorí àrùn tó jẹ mọ́ èémí kù ní ìpín 23 nínú ọgọ́rùn-ún. Àpilẹ̀kọ náà parí ọ̀rọ̀ nípa títẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkọ́ àwọn ọmọdé ní irú ìlànà ìpìlẹ̀ ìlera bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ọmọ ọwọ́.

Ìbúrẹ́kẹ Ọrọ̀ Ajé àti Ipò Òṣì

Lẹ́tà ìròyìn HCHR News, lẹ́tà ìròyìn láti Ọ́fíìsì Alábòójútó Àgbà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé fi ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè láti 1975 sí 1985, “iye àwọn òtòṣì lágbàáyé fi ìpín 17 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè.” Lónìí, ipò ọrọ̀ ajé àwọn ènìyàn burú ju bí ó ti rí ní ọdún mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn ní orílẹ̀-èdè 89. Ní 70 orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ìpele owó tí ń wọlé tilẹ̀ kéré gan-an sí èyí tí ń wọlé ní 20 ọdún, àti nínú àwọn ọ̀ràn kan, ní 30 ọdún sẹ́yìn lọ. Lẹ́tà ìròyìn HCHR News náà parí ọ̀rọ̀ pé, ìbúrẹ́kẹ ọrọ̀ ajé ti ṣàǹfààní fún “àwọn orílẹ̀-èdè kéréje kan” péré.

Àwọn Ilé Tó Wà Níbi Eléwu ní Ítálì

Láàárín ọ̀rúndún tó kọjá, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ti gbẹ̀mí ènìyàn tó lé ní 120,000 ní Ítálì. Síbẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ròyìn pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù 25 ará Ítálì ní ń gbé ní àwọn àgbègbè tí “ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún ilé tó wà níbẹ̀ kò láàbò lọ́wọ́ àwọn ìsẹ̀lẹ̀.” Lára àwọn ilé tó wà níbi eléwu náà ni àwọn ilé ìwòsàn, ilé iṣẹ́ panápaná, àti àwọn ilé mìíràn tí ó yẹ kí ó jẹ́ ibi ìsádi bí ìjábá kan bá ṣẹlẹ̀. Lọ́dọọdún ni a ń ná ìpíndọ́gba 7,000 bílíọ̀nù owó lire (bílíọ̀nù 4 dọ́là, United States) ní Ítálì láti ṣàtúnṣe ìbàjẹ́ tí ìjábá ilẹ̀ àti ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ń fà. Ògbógi kan ṣàlàyé pé, “lọ́pọ̀ ìgbà, a ti ná iye owó gọbọi yẹn lẹ́yìn àwọn ìjábá . . . láti ṣàtúnkọ́ [àwọn ilé] lọ́nà tí kò tọ̀nà kan náà àti ní àwọn ibi eléwu púpọ̀ kan náà.”

Ẹ̀jẹ̀ àti Àkóràn Fáírọ́ọ̀sì HIV

Iye tí ó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 22 tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV tàbí àrùn AIDS lágbàáyé ló ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ẹgbẹ́ Panos, ẹgbẹ́ aṣàkójọ-ìròyìn kan tó fìdí sọlẹ̀ sí London, sọ pé: “Ìfàjẹ̀sínilára ló fa iye tí ó pọ̀ tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àkóràn fáírọ́ọ̀sì HIV tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìpèsè ẹ̀jẹ̀ léwu nítorí pé àwọn àyẹ̀wò ìṣàwárí fáírọ́ọ̀sì HIV ní àwọn ibi ìwádìí kò ṣeé gbára lé délẹ̀délẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní Pakistan, àwọn ibùdó ìfẹ̀jẹ̀pamọ́ tó ní ohun èlò ìṣàwárí fáírọ́ọ̀sì HIV kò tó ìdajì. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ̀lẹ̀ fáírọ́ọ̀sì HIV tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ni ìfàjẹ̀sínilára ń fà. Láti ìgbà tí a ti kọ́kọ́ ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS ní èyí tó ti lé ní ọdún 15 sẹ́yìn, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 mílíọ̀nù ènìyàn lágbàáyé tó ti kó fáírọ́ọ̀sì HIV, fáírọ́ọ̀sì tó ń fa àrùn náà.

Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Lọ́nà Àṣejù

Nínú ìwádìí àìpẹ́ yìí kan, a fọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọdé ará Brazil tó ní másùnmáwo lẹ́nu wò. Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin ṣe sọ, ìpín púpọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé ni làásìgbò bá nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà àṣejù. Nígbà tí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé ń ní pákáǹleke nítorí àwọn ìṣòro ìdílé tàbí ikú ìbátan kan, ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún ní làásìgbò nítorí pé wọ́n rí Ọlọ́run bí ẹni tí ń gbẹ̀san ṣáá, tí gbogbo ète rẹ̀ jẹ́ láti fìyà jẹni. Lẹ́tà ìròyìn ENI ròyìn pé, ìwádìí náà “rọ àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé Ọlọ́run ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì lè lóye wọn.”

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Àwọn Erin

Àwọn tán-án-ná erin tóbi tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ìró ohùn tí wọ́n ń mú jáde ń kùn yùn ní ìwọ̀n 20 tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan—ó kéré gan-an sí ìwọ̀n tí ènìyàn lè gbọ́. Irú ìró tó kéré bẹ́ẹ̀ ń rìn jìnnà gan-an, àwọn erin sì lè gbọ́ ọ láti ibi tó jìnnà tó kìlómítà 1.5. Wọ́n tún lè mọ ìyàtọ̀ 150 ìró ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nípa dídáhùn tàbí rírìn lọ síhà ibi tí ìró àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn àti àwọn tó ń bá ìdílé wọn kẹ́gbẹ́ ti ń wá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn erin kì í dáhùn sí ìró àwọn àjèjì tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bínú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ wọn. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ròyìn pé, lẹ́yìn ìwádìí ní Ọgbà Ẹ̀dá Amboseli ti Orílẹ̀-Èdè, ní Kẹ́ńyà, onímọ̀ nípa ìhùwàsí ẹranko, Ọ̀mọ̀wé Karen McComb, láti Yunifásítì Sussex ti ilẹ̀ Britain, ṣàlàyé pé “kò sí ẹranko mìíràn tí ó tí ì ṣàgbéyọ irú ìsokọ́ra ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbígbòòrò bẹ́ẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́