ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 23-24
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • “Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”
    Jí!—2002
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 23-24

Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!

Ní Ọjà Àárín Gbùngbùn Ìlú Lilongwe lórílẹ̀-èdè Màláwì ni Grace ti ń ta àwọn bàtà olówó ńláńlá. Inú ẹ̀ ń dùn ara ẹ̀ sì yá gágá. Àṣé bó ṣe máa ń rẹ́rìn-ín yẹn ni ò jẹ́ kó hàn lára ẹ̀ pé ó ti kàgbákò.

Inú Grace àtọkọ ẹ̀ dùn dédìí nígbà tí wọ́n bí Tiyajane, ọmọbìnrin wọn lọ́dún 1993. Nígbà yẹn, ó dà bíi pé ara rẹ̀ dá ṣáṣá. Àmọ́, kò pẹ́ ló bẹ̀rẹ̀ sí rù tí oríṣiríṣi àìsàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é. Nígbà tí Tiyajane pé ọmọ ọdún mẹ́ta, àrùn éèdì gbẹ̀mí ẹ̀.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọkọ Grace náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Lọ́jọ́ kan ló dìgbò lulẹ̀ wọ́n sì gbé e lọ sílé ìwòsàn. Ṣùgbọ́n, ó kọjá agbára àwọn dókítà. Báwọn àìsàn tó ń bá éèdì rìn ṣe pa ọkọ Grace nìyẹn, lọ́dún kẹjọ tí wọ́n ṣègbéyàwó.

Grace ń dá gbé nínú yàrá kan ní ìgbèríko ìlú Lilongwe báyìí. Èèyàn lè rò pé nígbà tí ò tíì ju ọmọ ọgbọ̀n ọdún lọ, kó bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ lákọ̀tun ló kù. Àmọ́ Grace ṣàlàyé pé: “Mo ti ní kòkòrò tó máa ń fa àrùn éèdì lára, torí náà, mi ò ní lọ́kọ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò ní bímọ kankan.”

Ó DUNNI pé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ nirú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé lórílẹ̀-èdè Màláwì, kódà ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè yẹn ló ní kòkòrò àrùn éèdì lára. Ìwé ìròyìn Globe and Mail sọ pé nílé ìwòsàn tó wà ní ìgbèríko kan, “ìdámẹ́ta àwọn aláìsàn tí wọ́n gbà ni kò yẹ kí wọ́n gbà, tó fi hàn pé wọ́n ti pọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tó ju ìdajì lọ lára àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn nílé ìwòsàn náà ò lè ṣiṣẹ́ mọ́” nítorí pé éèdì ti mú wọn. Bí kòkòrò àrùn éèdì ṣe ń tàn kálẹ̀ ní apá Àríwá Áfíríkà tiẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́dún 2002, ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ ètò tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dá sílẹ̀ lórí àrùn éèdì sọ pé: “Ní báyìí, ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé àwọn tó wà lápá Àríwá Áfíríkà sábà máa ń gbé láyé. Tí kì í bá ṣe ti àrùn éèdì, ó yẹ kó jẹ́ méjìlélọ́gọ́ta.”

Kòkòrò àrùn éèdì àti àrùn ọ̀hún fúnra rẹ̀ ti di àgbákò kárí ayé báyìí, ó ti kọjá ìṣòro ilẹ̀ Áfíríkà. Ètò tí àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè dá sílẹ̀ lórí àrùn éèdì ṣírò rẹ̀ pé ó tó mílíọ̀nù mẹ́rin àwọn èèyàn tí wọ́n ti tójú bọ́ lórílẹ̀-èdè Íńdíà tí wọ́n ní kòkòrò àrùn éèdì lára, ó fi kún un pé: “Tá a bá fi iye àwọn tó lárùn yìí lọ́wọ́lọ́wọ́ pè, kòkòrò àrùn éèdì ló máa jẹ́ olúborí nínú àwọn kòkòrò tó ń pààyàn láàárín ọdún 2000 sí 2009.” Ńṣe làrùn yìí ń ràn mọ̀-ọ̀n bí iná ọyẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè tí kò sí lábẹ́ àjọ Kájọlà, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira tó ní èyí tó pọ̀ jù lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Soviet Union tẹ́lẹ̀ nínú. Ìròyìn kan sọ pé lórílẹ̀-èdè Uzbekistan, “àwọn èèyàn tí wọ́n ròyìn pé wọ́n lárùn éèdì lọ́dún 2002 nìkan pọ̀ ju gbogbo àwọn tó ní in lọ́dún mẹ́wàá ṣáájú ìgbà náà.” Kòkòrò àrùn éèdì ṣì wà lára ohun tó ń pa àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí mẹ́rìnlélógójì jù lọ.

Ọdún 1986 ni ìwé ìròyìn Jí! kọ́kọ́ gbé ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde lórí àrùn éèdì. Lọ́dún náà, Dókítà H. Mahler ẹni tó jẹ́ olùdarí Àjọ Ìlera Àgbáyé nígbà náà, ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí èèyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá ti ní kòkòrò àrùn éèdì lára. Ó ti tó bí ogún ọdún tó ti sọ̀rọ̀ náà báyìí, àwọn tó ti ní àrùn éèdì jákèjádò ayé sì ti pọ̀ tó mílíọ̀nù méjìlélógójì, bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí yìí tó ìlọ́po mẹ́wàá báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i! Ohun táwọn ògbógi ń sọ ni pé dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ń fì lókè. Ètò tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dá sílẹ̀ torí àrùn éèdì sọ pé: “Ìṣirò fi hàn pé láàárín ọdún 2000 sí ọdún 2020, mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́rin èèyàn ni éèdì máa pa láìtọ́jọ́ láwọn orílẹ̀-èdè márùndínláàádọ́ta tárùn náà ti ń bá wọn fínra jù lọ.”

Pẹ̀lú bí ríràn tárùn éèdì ń ràn ṣe wá dójú ẹ̀ báyìí, aráyé nílò oògùn tí wọ́n á fi wò ó ní báyìíbáyìí. Ìdí rèé táwọn oníṣègùn fi ń ṣèwádìí lójú méjèèjì lórí bí wọ́n á ṣe ṣẹ́gun kòkòrò àrùn éèdì. Ibo ni wọ́n ti bá ìjàkadì tí wọ́n ń bá àrùn panipani yìí jà dé? Ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání láti máa retí pé òpin lè dé bá àrùn éèdì?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

Káàkiri àgbáyé iye àwọn tó ní kòkòrò àrùn éèdì lára tàbí tí wọ́n tiẹ̀ lárùn náà á tó mílíọ̀nù méjìlélógójì; mílíọ̀nù méjì àbọ̀ nínú wọn ló jẹ́ ọmọdé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ÍŃDÍÀ Àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni, elétò ìlera ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àrùn éèdì

[Credit Line]

© Àwòrán tí Peter Barker/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

BRAZIL Òṣìṣẹ́ ìjọba kan ń tu obìnrin tí àrùn éèdì ń hàn léèmọ̀ nínú

[Credit Line]

© Àwòrán tí Sean Sprague/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

THAILAND Òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ń tọ́jú ọmọ ọwọ́ kan tí wọ́n bí kòkòrò àrùn éèdì mọ́

[Credit Line]

© Àwòrán tí Ian Teh/Panos yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́