ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 25-29
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Oògùn Tí Wọ́n Ṣe
  • “Àrùn Tálákà”
  • Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣòwò Oògùn
  • Àwọn Nǹkan Mìíràn Tó Ń Ṣèdíwọ́
  • Akitiyan Láti Dènà Rẹ̀
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
  • Ìgbà Wo Làrùn Éèdì Ò Ní Sí Mọ́?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 25-29

Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì

Nínú ìwé rẹ̀, AIDS Update 2003, Ọ̀mọ̀wé Gerald J. Stine kọ̀wé pé: “Látọjọ́ táláyé ti dáyé, kò tíì sí àìsàn kankan tó lágbára tó báyìí tí aráyé sì tíì mọ púpọ̀ nípa rẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú báyìí rí.” Ó sọ pé “àṣeyọrí ńláǹlà ló jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ̀ nípa àrùn éèdì tó báyìí.” Ibo ni wọ́n ti bá ìwádìí wọn dé?

ÌMỌ̀ ìjìnlẹ̀ àti ọgbọ́n ìṣègùn ti jẹ́ káwọn olùṣèwádìí lè ṣe àwọn àdàpọ̀ oògùn tó ń mú káwọn tó ní kòkòrò àrùn éèdì lára tún lè pẹ́ láyé sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe lórí àrùn éèdì láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan ti sèsoore. Ṣùgbọ́n ṣé báwọn ìsapá wọ̀nyí ṣe ń kẹ́sẹ járí fi hàn pé àjàkálẹ̀ àrùn panipani yìí ti ń ròkun ìgbàgbé nìyẹn? Ǹjẹ́ ìsapá àwọn onímọ̀ ìṣègùn àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn èèyàn lè dá ìtànkálẹ̀ àrùn éèdì dúró? Jẹ́ ká wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí.

Àwọn Oògùn Tí Wọ́n Ṣe

Ìwé ìròyìn Time ti September 29, 1986 gbé àkọlé gàdàgbà kan jáde tó sọ pé: “Ó Dà Bíi Pé Apá Ti Fẹ́ Ká Àrùn Éèdì O.” Ohun tó jẹ́ kí wọ́n sọ pé apá ti fẹ́ ká a lohun tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n dán oògùn tí wọ́n pè ní azidothymidine wò, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fáwọn kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì. A rí i pé ẹ̀mí àwọn tó lo oògùn yìí nínú àwọn tó ní kòkòrò náà lára túbọ̀ ń gùn sí i. Látìgbà náà wá, oríṣiríṣi àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì ti mú kí ẹ̀mí ẹgbẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rùn-ún èèyàn gùn sí i. (Wo àpótí náà, “Báwo Ni Oògùn Tó Ń Ṣèdíwọ́ fún Kòkòrò Tó Ń Fa Éèdì Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?” tó wà lójú ìwé 27) Báwo làwọn oògùn náà ṣe lágbára tó láti tọ́jú ẹni tí kòkòrò àrùn éèdì bá wà lára ẹ̀?

Láìka bínú àwọn èèyan ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbé oògùn azidothymidine tí wọ́n fi ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì yìí jáde, ìwé ìròyìn Time ròyìn pé “ó dá àwọn tó ń ṣèwádìí àrùn éèdì lójú pé oògùn náà kọ́ ló máa gbá àrùn éèdì wọlẹ̀.” Òótọ́ ni wọ́n kúkú sọ. Àwọn kan wà lára àwọn tó lárùn náà tóògùn ọ̀hún máa ń dà láàmú, nítorí náà, wọ́n ṣe àwọn oògùn míì tó ń ṣèdíwọ́ fáwọn kòkòrò tó ń fa éèdì. Nígbà tó ṣe, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Oògùn ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa lo àpapọ̀ àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì fáwọn tárùn éèdì tiwọn ti gogò. Inú àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tó ń tọ́jú àwọn tó lárùn éèdì dùn gan-an nígbà tó di pé wọ́n ń lo àwọn oògùn bí oríṣi méjì tàbí mẹ́ta tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì. Kódà, níbi àpéjọ àgbáyé kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 1996 lórí àrùn éèdì, dókítà kan kéde pé ó ṣeé ṣe káwọn oògùn náà lè pa gbogbo kòkòrò àrùn éèdì tó wà nínú ara!

Ó mà ṣe o, kò ju ọdún kan péré lọ tí wọ́n fi rí i pé kódà báwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń fi taratara tẹ̀ lé ìlànà lílo oríṣi mẹ́ta oògùn yìí, wọn ò lè rẹ́yìn kókòrò àrùn éèdì. Síbẹ̀, ìroyìn kan tó wá láti ọ̀dọ̀ ètò tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe lórí àrùn éèdì sọ pé “lílo àpapọ̀ oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì ti mú kí ẹ̀mí àwọn tó ní kòkòrò náà lára lè máa gùn sí i, kí ara wọn gbé kánkán sí i, kí wọ́n sì lè gbé ìgbésí ayé bíi tará yòókù.” Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Amẹ́ríkà àti nílẹ̀ Yúróòpù, lílò tí wọ́n ń lo oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì ti ń gba bí ìdámẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn tó ní éèdì lọ́wọ́ ikú. Bákan náà, àwọn ìwádìí kan ti fi hàn pé bí wọ́n bá fi àwọn kan lára oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì yìí tọ́jú àwọn aláboyún tó lárùn náà, ó lè dín bí wọ́n ṣe ń kárùn náà ran ọmọ inú wọn kù gan-an.

Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí kòkòrò yìí wà lára wọn ni ò rí àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì gbà. Kí ló fà á?

“Àrùn Tálákà”

Wọ́n máà ń lo oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì gan-an láwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti ń rówó gọbọi. Àmọ́, Àjọ Ìlèra Àgbáyé fojú bù ú pé láwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ẹni márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àwọn tó nílò àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì ló ń rí i gbà. Àwọn aṣojú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tiẹ̀ ṣàpèjúwe pípọ̀n tọ́ràn pọ̀n sọ́nà kan yìí bíi “rírólé apá kan, dákan sí” àti “ìwà tí kò yẹ ọmọlúwàbí, tí kò yẹ ká máa gbúròó irú ẹ̀ níbi táyé lajú dé.”

Láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà pàápàá, lílo ẹsẹ̀ gígùn kéèyàn tó lè rí oògùn gbà lè ṣẹlẹ̀. Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ròyìn pé ẹnì kan nínú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà mẹ́tà tárùn éèdì ń pa ni wọn ò tíì fún láwọn oògùn yẹn rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀fẹ́ ni wọ́n ń fún wọn lóògùn náà lórílẹ̀-èdè Kánádà, ńṣe ni wọ́n ń gbójú fo àwọn kan dá níbẹ̀. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé: “Àwọn tó nílò oògùn náà jù, ni ò rí i gbà, ìyẹn àwọn bí àwọn ọmọ onílẹ̀, àwọn obìnrin, àtàwọn tálákà.” Ìwé ìròyìn The Guardian gbé ọ̀rọ̀ kan jáde èyí tí ìyá kan nílẹ̀ Áfíríkà tó ní kòkòrò àrùn éèdì lára sọ, ó ní: “Ọ̀rọ̀ náà ò tiẹ̀ yé mi páàpáà. Kí ló dé táwọn òyìnbó tó ń bá ọkùnrin bíi tiwọn lò pọ̀ á fi máa gbáyé lọ témi á sì wá kú?” Ohun tó ń fà á kò ṣẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń ṣòwò oògùn.

Lọ́dún kan ṣoṣo, àpapọ̀ àwọn oògùn mẹ́ta tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì ń ná ẹnì kan tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún dọ́là lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tàbí nílẹ̀ Yúróòpù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí ẹ̀yà àwọn oògùn yìí kan tí kò sí orúkọ ilé iṣẹ́ ìpoògùn kankan lára wọn rà ní bí ọ̀ọ́dúnrún dọ́là tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ní kòkòrò yìí lára, tí wọ́n ń gbé níbi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ jù lọ bá talé ta ọ̀nà wọn, owó ẹ̀ ò tó ra àwọn oògùn yìí. Dókítà Stine parí ọ̀rọ̀ ọ̀hún pé: “Àrùn tálákà làrùn éèdì.”

Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣòwò Oògùn

Ṣíṣe àwọn oògùn tí kò sí orúkọ iléeṣẹ́ lára wọn àti títà wọ́n lówó pọ́ọ́kú ò rọrùn. Àwọn òfin táwọn orílẹ̀-èdè kan ṣe lórí ọ̀ràn oògùn ṣíṣe le débi pé kò sáyé fẹ́nikẹ́ni láti kàn dédé ṣe àwọn oògùn tílé iṣẹ́ kan ti ṣe jáde. Olórí iléeṣẹ́ ìpoògùn ńlá kan sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n fẹ́ ká kógbá sílé.” Ó sọ pé tí ẹnì kan bá lọ ṣe irú àwọn oògùn tí iléeṣe kan ti ṣe tó sì ń tà wọ́n sáwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, “kò ṣàánú àwọn iléeṣẹ́ ìpoògùn tó kọ́kọ́ ṣe àwọn oògùn yìí páàpáà.” Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń poògùn tún jiyàn pé bí èrè àwọn ṣe ń dín kù lè fa káwọn máà rówó ná sórí ìwádìí ìmọ̀ ìṣègùn àti ṣíṣe oògùn tuntun mọ́. Àwọn mìíràn ń bẹ̀rù pé àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò àrùn éèdì tí wọ́n ń ṣe fáwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà yìí lè di nǹkan táwọn oníṣòwò bìrìbìrì á bẹ̀rẹ̀ sí tà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.

Àwọn tó wà nídìí títa àwọn oògùn yìí lówó pọ́ọ́kú sọ pé ó ṣeé ṣe láti ṣe àwọn oògùn tuntun níye tí ò ní ju ìdámẹ́wàá tàbí ìdá ogún iye táwọn ilé iṣẹ́ ìpoògùn sọ pé ó ná àwọn láti ṣe é. Wọ́n tún sọ pé ó dà bíi pé àwọn ilé iṣẹ́ ìpoògùn ò ro tàwọn àrùn tó ń báwọn fínra láwọn orílẹ̀-èdè tí ò fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú mọ́ ìwàdìí àti oògùn tí wọ́n ń ṣe. Ìdí rèé tí Daniel Berman tó jẹ́ olùṣekòkáárí ìpolongo tí wọ́n pè ní Bọ́wọ́ Á Ṣe Tẹ Àwọn Oògùn Pàtàkì fi sọ pé: “Ó yẹ káwọn orílẹ̀-èdè para pọ̀ kí wọ́n sì fìdí ètò kan múlẹ̀ tá á jẹ́ kówó oògùn wálẹ̀ débi tápá àwọn èèyàn á fi ká a láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.”

Bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe rí i báyìí pé ó pọn dandan káwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fáwọn kòkòrò tó ń fa éèdì kárí ayé, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ èto kan tí yóò jẹ́ káwọn oògùn náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn mílíọ̀nù mẹ́ta tó ní kòkòrò àrùn éèdì tàbí àrùn ọ̀hún lára nígbà tọ́dún 2005 bá fi máa parí. Nathan Ford tó wà lára àwọn tó ṣètò Bọ́wọ́ Á Ṣe Tẹ Àwọn Oògùn Pàtàkì kìlọ̀ pé “Ètò tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gùn lé yìí ò tún gbọ́dọ̀ di àléèbá o. Ìlàjì àwọn tí ìṣirò fi hàn pé wọ́n lárùn éèdì tàbí kòkòrò àrùn náà lára tí wọ́n sì nílò ìtọ́jú rèé o, [tó bá fi máa di ọdún 2005] iye wọn á sì ti jù báyìí lọ fíìfíì.”

Àwọn Nǹkan Mìíràn Tó Ń Ṣèdíwọ́

Ká tiẹ̀ ní wọ́n kó àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì tó pọ̀ dáadáa lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn òkúta ìdènà mìíràn ṣì wà. Láìsí oúnjẹ àti omi tó mọ́, àwọn oògùn kan wà téèyàn ò lè lò, ṣùgbọ́n ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn wà láwọn ilẹ̀ kan tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni wọ́n ń jẹun láàárín ọjọ́ méjì. Ó ní àkókò pàtó lójúmọ́ tó yẹ kí wọ́n máa lo àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì (ó sì yẹ kí wọ́n lo ogún kóró tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lóòjọ́), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tárùn náà ń ṣe ò láago. Ó yẹ kí wọ́n wo bí ipò aláìsàn kan bá ṣe rí kí wọ́n tó sọ fún un bó ṣe yẹ kó máa lo oògùn. Ṣùgbọ́n àwọn oníṣègùn ò pọ̀ tó láwọn ilẹ̀ kan. Ó ṣe kedere pé á ṣòro gan-an láti lè jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà róògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì gbà.

Kódà àwọn tó lárùn yìí lára ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ò bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòrò tó wà nídìí lílo àpòpọ̀ àwọn oògùn yìí. Ìwádìí fi hàn pé ìṣòro tó tún ń fẹjú báyìí ni ti àìkìí lo gbogbo oògùn lákòókò tó yẹ kí wọ́n lò ó. Èyí sì lè fa kóògùn má ran àwọn kòkòrò náà mọ́. Àwọn tí oògùn ò ran kòkòrò àrùn éèdì tó wà lára wọn lè kó o ran àwọn ẹlòmíràn.

Dókítà Stine mẹ́nu kan àwọn ìṣòro mìíràn tó ń bá àwọn tó ní kòkòrò àrùn éèdì fínra. Ó ní: “Ohun tó mú kọ́rọ̀ ọ̀hún só síni lẹ́nu kó tún buyọ̀ sí i ni pé nígbà míì, bí alárùn á ṣe rí lẹ́yìn tí wọ́n bá tọ́jú ẹ̀ gan-an máa ń burú ju bó ṣe rí kí wọ́n tó tọ́jú ẹ̀ lọ, pàápàá tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú ẹ̀ kó tó di pé àìsàn náà bẹ̀rẹ̀ sí yọjú sí i lára.” Lára àtẹ̀yìnbọ̀ lílò táwọn tó ní kòkòrò àrùn éèdì lára ń lo àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì ni kí wọ́n ní àrùn àtọ̀gbẹ, kí ọ̀rá máa pọ̀ sí i láwọn ìbi kan lára wọn, kí èròjà cholesterol pọ̀ jù lára wọn kí eegun wọn má sì lágbára mọ́. Ó máa ń fa àwọn nǹkan mìí tó lè gbẹ̀mí wọn.

Akitiyan Láti Dènà Rẹ̀

Báwo làwọn akitiyan àtidènà àrùn yìí ṣe dín ìtànkálẹ̀ àrùn náà kù tó, àti pé báwo ló ti ṣe mú káwọn èèyan yí ìwà wọn tó lè mú kí wọ́n lùgbàdì àrùn padà? Wọ́n ṣe ìpolongo délé dóko kan lórílẹ̀-èdè Uganda lọ́dún 1990 láti la àwọn èèyàn lọ́yẹ̀ lórí àrùn éèdì. Ìpolongo yìí dín ìtànkálẹ̀ àrùn náà kù láti nǹkan bí ìpín mẹ́rìnlá nínú ọgọ́rùn-ún sí bí ìpín mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 2000. Bákan náà, lórílẹ̀-èdè Senegal, wọ́n ṣakitiyan láti jẹ́ káwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà mọ ewu tó wà nínú àrùn éèdì. Èyí sì ti dín bí àrùn náà ṣe ń ràn kù débi pé àwọn tó ń mú láàárín àwọn àgbàlagbà kò ju ìpín kan nínú ọgọ́rùn-ún lọ. Àwọn ohun tá a rí wọ̀nyẹn ń wúni lórí.

Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè míì ṣá, ìlàlóye lórí àrùn éèdì ò fi bẹ́ẹ̀ sèsoore. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún 2002 láàárín ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáfà [11,000] àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà fi hàn pé ìlàjì àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lo ọdún àkọ́kọ́ nílé ìwé gíga ló gbà pé àrùn éèdì ṣeé wò. Ìwádìí kan tí orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe lọ́dún kan náà fi hàn pé èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì àwọn ọmọkùnrin tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mọ́kànlá ni ò tíì gbọ́ nípa kòkòrò àrùn éèdì tàbí éèdì fúnra ẹ̀ rí. Kódà àwọn ọ̀dọ́ tó mọ̀ nípa rẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀ pé kò lóògùn gan-an ò tiẹ̀ bẹ̀rù mọ́. Dókítà kan sọ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, kòkòrò àrùn éèdì kàn dà bí ọkàn lára àwọn ìṣòro ìgbésí ayé wọn ni, bí ọ̀ràn rírí oúnjẹ tó dáa jẹ, irú ẹni tí wọ́n fẹ́ máa bá gbé, tàbí bóyá wọ́n á lọ síléèwé.”

Abájọ tí Àjọ̀ Ìlera Àgbáyé fi sọ pé “ó dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́ ló yẹ ká dojú kọ tá a bá fẹ́ kojú àjàkálẹ̀ àrùn yìí, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tó ti ń tàn kálẹ̀ gan-an.” Báwo la ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tí wọ́n ń gbọ́ nípa éèdì? Ǹjẹ́ a lè retí pé àrùn yìí á lọ lóòótọ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

Lọ́dún tó kọjá, nílẹ̀ Áfíríkà, ìdáméjì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó nílò àwọn oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò àrùn éèdì ló rí i gbà, bẹ́ẹ̀ sì rèé nílẹ̀ Amẹ́ríkà ìdá mẹ́rìnlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló rí i gbà

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Báwo Ni Oògùn Tó Ń Ṣèdíwọ́ fún Kòkòrò Tó Ń Fa Éèdì Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?a

Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan máa ń wà lára gbogbo ẹni tára ẹ̀ bá dá. Wọ́n máa ń fún agbóguntàrùn inú ara lágbára tó fi ń gbógun tàrùn tó bá fẹ́ wọlé. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí gan-an ni kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì máa ń dojú ìjà kọ. Tí kòkòrò yìí bá ti wọnú ara, á máa fi àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣara rindin kó lè máa pọ̀ sí i, á tipa bẹ́ẹ̀ dín agbára wọn kù títí tí agbóguntàrùn ara ò fi ní lágbára mọ́. Àwọn oògùn tó ń kojú kòkòrò tó ń fa éèdì kì í jẹ́ kó lè ṣe ọṣẹ́ burúkú tó ń mú kó pọ̀ sí i.

Ní báyìí, oríṣi oògùn mẹ́rin ló wà tí wọ́n fi ń dín ọṣẹ́ tó ń ṣe kù. Méjì kan wà lára wọn tí kì í jẹ́ kí kòkòrò àrùn éèdì lè wọlé sínú apilẹ̀ àbùdá èèyàn. Òmíràn wà tí kì í jẹ́ kó lè pọ̀ sí i, nítorí pé kì í jẹ́ kó lè fi èròjà protease tó wà nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ti ràn tẹ́lẹ̀ ṣara rindin. Ìkẹrin kì í tiẹ̀ jẹ́ kó lè wọnú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara páàpáà. Báwọn oògùn náà ṣe ń dí kòkòrò tó ń fa éèdì lọ́wọ́ láti pọ̀ sí i yìí, ó máa ń pẹ́ kó tó lè fa éèdì. Nígbà tó bá tó fa àrùn éèdì ló tó parí iṣẹ́ burúkú rẹ̀ nínú ara.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gbogbo àwọn tó ní kòkòrò éèdì lára kọ́ ni wọ́n máa ń sọ pé kí wọ́n lo oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò náà. Ó yẹ káwọn tó bá ní in lára tàbí tí wọ́n fura pé àwọn ní in lára lọ rí dókítà wọn kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn èyíkéyìí. Ìwé ìròyìn Jí! ò sọ pé irú ìtọ́jú kan ló dáa jù o.

[Àwòrán]

KẸ́ŃYÀ Dókítà ń ṣàlàyé fẹ́ni tó lárùn éèdì nípa oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fà á

[Credit Line]

© Àwòrán tí Sven Torfinn/Panos yà

[Àwòrán]

KẸ́ŃYÀ Ẹnì kan tó lárùn éèdì tó relé ìwòsàn lọ gba oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún kòkòrò tó ń fa éèdì

[Credit Line]

© Àwòrán tí Sven Torfinn/Panos yà

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ohun Tí Éèdì Ń Fojú Àwọn Obìnrin Rí

Ìdajì àwọn àgbàlagbà tó lárùn éèdì tàbí kòkòrò àrùn náà káàkiri àgbáyé ló jẹ́ obìnrin

Lọ́dún 1982, nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí i pé àwọn obìnrin lárùn éèdì, wọ́n rò pé bí wọ́n ṣe ń fi abẹ́rẹ́ fa oògùn sára ló fà á. Nígbà tó yá, wọ́n rí i pé wọ́n lè kó o nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo àti pé àwọn obìnrin gan-an ni éèdì tètè máa ń mú jù. Ìdajì àwọn àgbàlagbà tó lárùn éèdì tàbí kòkòrò àrùn náà káàkiri àgbáyé ló jẹ́ obìnrin. Ètò tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe lórí àrùn éèdì ròyìn pé: “Àwọn obìnrin lágbà lọ́mọdé nìṣòro àrùn éèdì ń ṣe lọ́ṣẹ́ jù, àwọn tó jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀nà làrùn yìí lè gbà kọ lù wọ́n, àwọn náà ló sì máa ń tọjú àwọn tárùn yìí bá dá gúnlẹ̀ àtàwọn tó ń kú lọ.”

Kí nìdí tárùn éèdì tó ń ràn láàárín àwọn obìnrin fi ń ká àwọn òṣìṣẹ́ tó ń tọ́jú wọn lára? Lára àwọn tí àrùn éèdì mú, àwọn obìnrin ni wọ́n sábà máa ń dájú sọ láwùjọ, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Tí obìnrin kan bá lóyún, ìṣòro ni fọ́mọ inú ẹ̀; bó bá sì ti bí àwọn ọmọ sílẹ̀, àtibójútó wọn á di ìṣòro, àgàgà tó bá jẹ́ pé òun nìkan ló ń dá tọ́mọ. Yàtọ̀ síyẹn, a lè sọ pé díẹ̀ la tíì mọ̀ nípa báwọn obìnrin tó bá lárùn éèdì ṣe máa ń ṣe àti irú ìtọ́jú tó yẹ ká fún wọn.

Àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan tiẹ̀ dìídì léwu fáwọn obìnrin ní pàtàkì. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn obìnrin ò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, tí wọ́n bá sì làwọn ò fẹ́ kí wọ́n báwọn lò pọ̀, wọ́n lè fipá mú wọn. Iye obìnrin tó bá wu àwọn ọkùnrin ni wọ́n lè bá lò pọ̀ tí wọ́n á sì máa tipa bẹ́ẹ̀ kó àrùn éèdì ràn wọ́n láìmọ̀. Àwọn ọkùnrin kan nílẹ̀ Áfíríkà máa ń bá àwọn ọmọbìnrin kéékèèké lò pọ̀ nítorí kí wọ́n má bàa kárùn éèdì tàbí nítorí ìgbàgbọ́ asán pé tẹ́nì kan bá bá ọmọbìnrin tí kò tíì mọ ọkùnrin lò pọ̀, àrùn éèdì tó wà lára onítọ̀hún lè lọ. Ìdí rèé tí Àjọ Ìlera Àgbáyé fi sọ pé: “Tá a bá fẹ́ dáàbò bo àwọn obìnrin lọ́wọ́ àrùn éèdì, àwọn ọkùnrin (àtàwọn obìnrin) ló yẹ ká dojú kọ.”

[Àwòrán]

PERU Ìyá kan tó ní kòkòrò àrùn éèdì lára tó gbé ọmọ rẹ̀ tí kò ní kòkòrò náà lára dání

[Credit Line]

© Àwòrán tí Annie Bungeroth/Panos yà

[Àwòrán]

THAILAND Gẹ́gẹ́ bí ara ètò ẹ̀kọ́ wọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó lárùn éèdì

[Credit Line]

© Àwòrán tí Ian Teh/Panos yà

[Àwòrán]

KẸ́ŃYÀ Ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n pè ní Ẹgbẹ́ Àwọn Obìnrin Tó Lárùn Éèdì

[Credit Line]

© Àwòrán tí Sven Torfinn/Panos yà

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn Èrò Òdì Nípa Àrùn Éèdì

◼ Àwọn tó bá ní kòkòrò àrùn éèdì lára máa ń gbẹ níwájú gbẹ lẹ́yìn ni. Dókítà Gerald J. Stine sọ pé: “Ó sábà máa ń tó ọdún mẹ́wàá sí méjìlà tí kòkòrò àrùn éèdì bá ti wà lára ẹnì kan kí onítọ̀hùn tó lárùn éèdì. Láàárín àkókò yìí, ohun tá á máa ṣe ẹni tí kòkòrò náà wà lára rẹ̀ kò ní pọ̀, ìyẹn tí nǹkan bá tiẹ̀ ṣe é ṣùgbọ́n ó lè kó kòkòrò náà ran àwọn ẹlòmíràn.”

◼ Àrùn àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ni éèdì. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ọdún 1980, làwọn èèyàn ti kọ́kọ́ ń ka àrùn éèdì sí àrùn àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Àmọ́ lójúmọ́ tó mọ́ lónìí yìí, ìbàlópọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin lọ̀nà pàtàkì tárùn éèdì ń gbà wọlé sáwọn tó pọ̀ jù lára.

◼ “Ìbálòpọ̀ tí ò léwu” ni ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe. Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ibùdó Tó Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ṣe sọ, “ọ̀pọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe ti fi hàn pé ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe lè tan àwọn kòkòrò àrùn éèdì àtàwọn àrùn mìíràn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ kálẹ̀.” A mọ̀ pé kò tíì wọ́pọ̀ pé kí kòkòrò àrùn éèdì wọnú ara nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe bíi tàwọn irú ìbálòpọ̀ tó kù. Síbẹ̀, ìbálòpọ̀ aláfẹnuṣe ti ń wọ́pọ̀ débi pé àwọn dókítà kan retí pé ó máa di ọ̀nà pàtàkì kan tí kòkòrò àrùn éèdì á máa gbà wọnú ara.

◼ Àrùn éèdì gbóògùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè fi oògùn tó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn kòkòrò tó ń fa éèdì tọ́jú àwọn kan lára àwọn tó ní kòkòrò náà kó má bàa tètè di éèdì sí wọn lára, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọn ò tíì rí oògùn ẹ̀ ṣe.

[Àwòrán]

ILẸ̀ CZECH Wọ́n ń wo ẹ̀jẹ̀ obìnrin yìí bóyá ó ní éèdì, tó ṣeé tọ́jú àmọ́ tí ò ṣeé wò

[Credit Line]

© Àwòrán tí Liba Taylor/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

ZAMBIA Àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì tí wọ́n ní kòkòrò éèdì lára ń dúró de oògùn wọn

[Credit Line]

© Àwòrán tí Pep Bonet/Panos yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́