ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 30-31
  • Ìgbà Wo Làrùn Éèdì Ò Ní Sí Mọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Làrùn Éèdì Ò Ní Sí Mọ́?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ṣe Pàtàkì Káwọn Òbí Máa Kọ́ Ọmọ Wọn
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Lárun Éèdì Tàbí Kòkòrò Tó Ń Fà Á
  • Ìwòsàn fún Àwọn Tó Lárùn Éèdì Ò Ní Pẹ́ Dé!
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 30-31

Ìgbà Wo Làrùn Éèdì Ò Ní Sí Mọ́?

Láti kékeré làwọn ọ̀dọ́ ti ń gbọ́ nípa àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n máa ṣèṣekúṣe tí wọ́n sì ń rí i. Bákan náà, fífi abẹ́rẹ fa oògùn olóró sára ti di pọ̀ọ́-ǹ-tọ̀, ọ̀nà míì tí wọ́n sì fi ń kárùn éèdì nìyẹn. Tó o bá wo báwọn èèyàn ṣe ń hùwà bíi pé kò sí nǹkan tó máa tẹ̀yìn ohun tí wọ́n bá ṣe wá báyìí, o lè máa ṣe kàyéfì pé bóyá làrùn éèdì lè dópin láé.

ÒDODO ọ̀rọ̀ làwọn oníṣègùn sọ nígbà tí wọ́n sọ pé ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà ki àrùn éèdì wọ̀ ni pé káwọn èèyàn yíwà wọn padà. Ìròyìn kan tó wá láti Ibùdó Tó Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ìran ọ̀dọ́ pátá, láìyọ àwọn kan sílẹ̀, ló yẹ ká máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko lórí ìlera ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa dènà àrùn àti bí wọ́n á ṣe máa lo ìgbésí ayé wọn lọ́nà tí wọn ò fi ní máa ṣe nǹkan tó lè jẹ́ kí wọ́n lùgbàdì àrùn éèdì. Ó yẹ káwọn òbí àti olùkọ́ kópa nínú irú ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko bẹ́ẹ̀.”

Ó ṣe kedere pé ó yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ewu kíkó àrùn éèdì kó tó di pé àwọn ẹgbẹ́ wọn tàbí àwọn ẹlòmíì kọ́ wọn ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. Kì í fìgbà gbogbo rọrùn o. Àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè gba ọmọ rẹ lọ́wọ́ ikú àìtọ́jọ́. Bíbá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ àti lílo oògùn olóró ò túmọ̀ sí pé ò ń kọ́ ọ ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ò ní jẹ́ kójú wọn là sódì.

Ó Ṣe Pàtàkì Káwọn Òbí Máa Kọ́ Ọmọ Wọn

Ọlọ́run retí pé káwọn òbí tó wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ àtijọ́ máa ṣàlàyé nípa ìbálòpọ̀ fáwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo ìlera wọn. Tá a bá sì wo òfin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, a óò rí àwọn ìlànà tó ṣe kedere nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà àtàwọn ohun tí wọ́n á máa ṣe tí wọ́n ò fi ní kárùn. (Léfítíkù 18:22, 23; 19:29; Diutarónómì 23:12, 13) Báwo ni wọn yóò ṣe máa kọ́ àwọn èèyàn láwọn òfin yìí? Jèhófà Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí . . . wà ní ọkàn-àyà rẹ.” Àwọn òbí níláti kọ́kọ́ lóye àwọn àǹfààní tó wà nínú títẹ̀ lé àwọn òfin wọ̀nyí àti àwọn ìjìyà tó wà fún àìtẹ̀lé wọn. Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.

Ó hàn gbangba pé á gba àkókò. Táwọn òbí bá wá àkókò tí wọ́n á fi máa ṣàlàyé àwọn ewu tó wà nínú ìlòkulò oògùn àti ìṣekúṣe fáwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin wọn, irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ kì í sábà lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà tó lè mú kí wọ́n kó àrùn éèdì àtàwọn àrùn mìíràn.a

Ìtùnú Fáwọn Tó Lárun Éèdì Tàbí Kòkòrò Tó Ń Fà Á

Ohun yòówù tá à báà ṣe láti dènà àrùn éèdì tàbí kòkòrò tó ń fà á ò lè fi bẹ́ẹ̀ tu àràádọ́tà ọ̀kẹ́ àwọn tó ti lárùn náà nínú. Yàtọ̀ sí ìyà tárùn náà máa ń fi jẹ àwọn tó bá mú, àwọn èèyàn tún máa ń fojú burúkú wò wọ́n, wọn kì í sì í fẹ́ dá sí wọn nítorí àrùn ara wọn. Èétirí? Èrò kan tó gbòde àmọ́ tí kì í ṣòótọ́ ni pé téèyàn bá ti fara kan ẹni tó ní kòkòrò àrùn éèdì pẹ́nrẹ́n báyìí, oluwa rẹ̀ ti lùgbàdì àrùn náà nìyẹn. Ẹni tó ń bẹ̀rù àìfẹ́ kárùn éèdì ò kúkú jẹ̀bi, ìdí ni pé àrùn náà máa ń ràn, tó bá sì ti mú èèyàn kò lẹ́rọ̀. Àwọn kan tiẹ̀ ti jẹ́ kí ìbẹ̀rù àrùn náà sọ àwọn tó lárùn ọ̀hún lára di àrísá iná, àkòtagìrì èjò mọ́ àwọn lọ́wọ́. Wọ́n ti kọ̀ láti fún àwọn tó lárùn náà ní ìtọ́jú, wọ́n ti lé wọn kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì, kódà wọ́n ti dáwọ́ jọ lù wọ́n.

Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ló fi àrùn éèdì ṣépè fáwọn ẹni ibi. Lóòótọ́, ká ní ọ̀pọ̀ àwọn tó lárùn náà lára ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lórí ìbálòpọ̀, ìlò oògùn àti ẹ̀jẹ̀ ni, wọn ì bá tí kárùn náà. (Ìṣe 15:28, 29; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àìsàn kì í ṣe ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń fìyà jẹ ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13; Jòhánù 9:1-3) Tí kòkòrò àrùn éèdì bá wọ èèyàn lára tàbí tó tiẹ̀ ti ní éèdì nítorí pé kò tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ṣùgbọ́n tí onítọ̀hùn bá ti yí ìwà rẹ̀ padà, ó lè fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run ò ní pa òun tì.

Àwọn ohun tí Jésù, Ọmọ Ọlọ́run gbélé ayé ṣe fi hàn pé Ọlọ́run mọ ìrora àwọn tó lárùn lílágbára, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tí Jésù pàdé adẹ́tẹ̀ kan nínú ìrìn àjò rẹ̀, “àánú ṣe é, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án.” Jésù lo agbára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ó sì mú adẹ́tẹ̀ náà lára dá. (Máàkù 1:40-42) Jésù ò fojú burukú wo àwọn aláìsàn. Ìfẹ́ tó fi hàn sí wọn jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run.—Lúùkù 10:22.

Ìwòsàn fún Àwọn Tó Lárùn Éèdì Ò Ní Pẹ́ Dé!

Kì í ṣe pé àwọn ìwòsàn tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ṣe mú ìfẹ́ Ọlọ́run dá wa lójú nìkan ni. Bíbélì sọ fún wa pé Jésù Kristi ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run. (Ìṣípayá 11:15) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé ó lágbára láti wo gbogbo àìsàn tó ń ṣe aráyé sàn ó sì wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó máa ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi dá wa lójú pé láìpẹ́, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aráyé ò lágbára láti dá àrùn éèdì dúró pé kó má tàn kálẹ̀, tí wọn ò sì lè fáwọn tó ti mú ní ìtọ́jú tó péye, ó dájú pé àrùn éèdì á dohun ìgbàgbé. Ọba Dáfídì sọ pé: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀, Ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì, ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn.”—Sáàmù 103:2, 3.

Nígbà wo lèyí máa ṣẹlẹ̀? Kí ni Ọlọ́run ń retí pé káwọn tó nírètí pé àwọn á gbádùn àwọn ìbùkún wọ̀nyí máa ṣe? A rọ̀ ọ́ pé kọ o tọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ láti lè kọ́ púpọ̀ sí i nípa ìlérí àgbàyanu tí Bíbélì ṣe yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ òbí ló ti rí i pé ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ń ran àwọn lọ́wọ́ láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn kéékèèké díẹ̀díẹ̀ nípa ìbálòpọ̀ àtàwọn ìlànà tó yẹ kí ọmọlúwàbí máa tẹ̀ lé.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi dá wa lójú pé láìpẹ́, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa ìbálòpọ̀ àti ìlòkulò oògùn lè dáàbò bò wọ́n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Bí Jésù ṣe lágbára láti wo aláìsàn sàn àtí bó ṣe máa ń fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ fi hàn pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́