ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 4-7
  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Dídènà Rẹ̀
  • Ìgbà Tó Yẹ Ká Ṣàyẹ̀wò
  • Báwo Ni Ìlàlóye Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?
  • Àwọn Ìtọ́jú Wo Ló Wà?
  • Ǹjẹ́ Àwọn Àjẹsára Ni Ojútùú Náà?
  • Akitiyan Tí Wọ́n Ti Ṣe Láti Ṣẹ́gun Àrùn Éèdì
    Jí!—2004
  • Àrùn Éèdì Gba Ilẹ̀ Áfíríkà Kan
    Jí!—2002
  • Aráyé Nílò Oògùn Éèdì Báyìíbáyìí!
    Jí!—2004
  • “Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Burú Jù Lọ Táráyé Ò Rírú Ẹ̀ Rí”
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 4-7

Bí A Ṣe Lè Gbógun Ti Àrùn Aids

NÍ BÁYÌÍ ná, àrùn AIDS kò lóògùn, kò sì jọ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìṣègùn yóò rí ọ̀kan láìpẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn egbòogi tuntun ń fawọ́ bí ó ṣe ń burú sí i sẹ́yìn, ohun tó ti dára jù ni láti má ṣe kó àrùn náà rárá. Àmọ́, kí a tó sọ̀rọ̀ lórí dídènà rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí bí fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS (fáírọ́ọ̀sì HIV) ṣe ń ti ara ẹnì kan dé ara ẹlòmíràn àti bí kì í ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀.

Ẹnì kan lè kó o lọ́nà mẹ́rin pàtó: (1) nípa lílo abẹ́rẹ́ tàbí ike abẹ́rẹ́ tó ti lárùn náà lára, (2) nípa bíbá ẹni tó ní in lò pọ̀ (lọ́nà ti abẹ́, ìdí, tàbí ẹnu), (3) nípa ìgbẹ̀jẹ̀sára àti àwọn èròjà tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu èyí ti dín kù díẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, níbi tí wọ́n ti ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ láti mọ̀ bóyá ó ní agbógunti àrùn HIV nínú, àti (4) láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV, tí ó lè kó o ran ọmọ rẹ̀ nínú oyún, nígbà ìbímọ, tàbí nígbà ìfọ́mọlọ́mú.

Bí Ibùdó Ìṣàkóso àti Ìdènà Àrùn ní United States (CDC) ṣe sọ, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lọ́wọ́lọ́wọ́ sọ pé, (1) a kì í kó àrùn AIDS bí a ti ń kó òtútù tàbí àrùn gágá, (2) a kì í kó o nípa wíwulẹ̀ jókòó ti ẹni tó ní in, tàbí fífara kàn án, tàbí rírọ̀ mọ́ ọn, (3) a kì í kó o nípa jíjẹ oúnjẹ tí ẹni tó ní in fọwọ́ kàn, tó sè, tàbí tó bù fúnni, (4) bẹ́ẹ̀ sì ni a kì í kó o nípa jíjọ lo ilé ìtura, tẹlifóònù, aṣọ, nǹkan ìjẹun tàbí ìmumi pẹ̀lú ẹni tó ní in. Ní àfikún sí i, ibùdó CDC sọ pé, ẹ̀fọn tàbí àwọn kòkòrò mìíràn kì í kó fáírọ́ọ̀sì náà ranni.

Àṣírí Dídènà Rẹ̀

Fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS máa ń fara sin sínú ẹ̀jẹ̀ àwọn tó bá ní in. Bí aláìsàn náà bá gbabẹ́rẹ́, ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ tó ní fáírọ́ọ̀sì náà nínú lè kù sára abẹ́rẹ́ tàbí ike abẹ́rẹ́ náà. Bí a bá lo abẹ́rẹ́ tó ní àrùn náà lára bẹ́ẹ̀ fún ẹlòmíràn, ó lè kó fáírọ́ọ̀sì ọ̀hún ràn án. Má bẹ̀rù láti bá dókítà tàbí nọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀ bí o bá ṣiyèméjì nípa abẹ́rẹ́ tàbí ike abẹ́rẹ́ kan. O lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀; ó kan ìwàláàyè rẹ.

Fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn AIDS náà tún ń wà nínú àtọ̀ tàbí omi abẹ́ àwọn alárùn náà. Ìdí nìyí tí ibùdó CDC fi dámọ̀ràn nípa ìdènà rẹ̀ pé: “Títakété ni ààbò kan ṣoṣo tó dájú. Bí o bá ní láti ní ìbálòpọ̀, rọ́jú di ìgbà tí ìwọ àti ẹnì kan tí kò lárùn náà bá wọnú àdéhùn onígbà pípẹ́, ìbátan ìṣòtítọ́ àjùmọ̀ní, bí ìgbéyàwó.”

Ṣàkíyèsí pé, láti dáàbò bo ara rẹ, o gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó nínú “ìbátan ìṣòtítọ́ àjùmọ̀ní.” Bí ìwọ bá ń ṣòtítọ́, ṣùgbọ́n tí ẹnì kejì rẹ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ó léwu. Èyí sábà máa ń jẹ́ ìṣòro ńlá kan fún àwọn obìnrin tí ń gbé àwùjọ tí àwọn ọkùnrin bá ti ń jẹ gàba lé wọn lórí ní ti ìbálòpọ̀ àti ìṣúnná. Ní àwọn ilẹ̀ kan, a kò gba àwọn obìnrin láyè láti bá àwọn ọkùnrin jíròrò ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé, kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ tí kò léwu.

Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ni kò lágbára. Ìwádìí kan láti ilẹ̀ kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà fi hàn pé àwọn obìnrin kan tí ń gbọ́ bùkátà ara wọn lè yẹra fún ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn tó ti kárùn, láìsí ìyọrísí tó le. Ní New Jersey, U.S.A., àwọn obìnrin kan ń kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀, bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ lo kọ́ńdọ̀mù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kọ́ńdọ̀mù lè dáàbò boni lọ́wọ́ fáírọ́ọ̀sì HIV àti àwọn àrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, a gbọ́dọ̀ máa lò wọ́n bó ṣe yẹ, déédéé.

Ìgbà Tó Yẹ Ká Ṣàyẹ̀wò

Karen, tí a sọ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, kò ní ọ̀nà tó jọjú láti gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ewu àkóràn. Ọkọ rẹ̀ ti kárùn náà lọ́pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbéyàwó wọn, wọ́n sì ṣègbéyàwó nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà àti àyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì HIV kò tíì gbilẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, àyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì HIV ti di ohun tó wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣiyèméjì nípa bóyá òún ní fáírọ́ọ̀sì HIV, ó bọ́gbọ́n mu láti kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà. Karen fúnni nímọ̀ràn pé: “Fọgbọ́n yan alábàágbéyàwó rẹ. Àṣìṣe nínú yíyàn yìí lè jẹ ọ́ níyà gidigidi, ó tilẹ̀ lè gba ẹ̀mí rẹ pàápàá.”

Ṣíṣe àyẹ̀wò náà nígbà tí ẹnì kan bá ṣe panṣágà tún lè dáàbò bo ẹnì kejì tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ náà. Ó lè pọndandan pé ká ṣe ọ̀pọ̀ àyẹ̀wò nítorí pé, a lè ṣàìrí fáírọ́ọ̀sì HIV nínú àyẹ̀wò títí di oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí ẹni náà ti kó o. Bí a bá tún bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ṣe panṣágà náà (tí ó túmọ̀ sí pé a dárí jì í), lílo kọ́ńdọ̀mù lè dáàbò boni lọ́wọ́ kíkó àrùn.

Báwo Ni Ìlàlóye Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?

Ó gbàfiyèsí pé, bí a tilẹ̀ ti kọ Bíbélì tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àrùn AIDS tó yọjú, títẹ̀lé àwọn ìlànà inú rẹ̀ ń dáàbò boni lọ́wọ́ àrùn náà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dẹ́bi fún ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí a kò bá ṣègbéyàwó, ó kan ìṣòtítọ́ sí alábàágbéyàwó ẹni nípá, ó sì sọ pé kìkì àwọn tí ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì bákan náà ni kí àwọn Kristẹni bá ṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 7:39; Hébérù 13:4) Ó tún ka gbogbo ìlòkulò òun ìjẹkújẹ àti jíjẹ ẹ̀jẹ̀, tí ń sọ ara dìbàjẹ́, léèwọ̀.—Ìṣe 15:20; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

Ó lọ́gbọ́n nínú pé kí o lóye àwọn ewu tó lè wà nínú àjọṣe pẹ̀lú àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV. Mímọ̀ nípa àrùn AIDS ń mú ènìyàn gbára dì láti dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àrùn náà.

Àjọ Agbógunti Àrùn AIDS sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè dènà àrùn AIDS. Títí a ó fi rí ìwòsàn fún àrùn AIDS, ìlàlóye ni ọ̀nà ìgbóguntì tó dára jù, ọ̀kan ṣoṣo tí [gbogbo àwùjọ ènìyàn] ní, ní báyìí.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ó dára pé kí àwọn òbí bá ara wọn àti àwọn ọmọ wọn sọ òdodo ọ̀rọ̀ nípa àrùn AIDS.

Àwọn Ìtọ́jú Wo Ló Wà?

Àmì àrùn kì í sábà fara hàn títí di ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti kó fáírọ́ọ̀sì HIV. Láàárín àkókò yẹn, ogun kan ń jà nínú ara lọ́hùn-ún. Fáírọ́ọ̀sì kọ̀ọ̀kan ń pamọ sí i, wọ́n sì ń pa àwọn sẹ́ẹ̀lì adènà àrùn. Àwọn sẹ́ẹ̀lì adènà àrùn máa ń jà padà. Níkẹyìn, bí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù fáírọ́ọ̀sì tuntun ṣe ń yọjú lójoojúmọ́, agbára wọn ń pọ̀ ju ti àwọn sẹ́ẹ̀lì adènà àrùn lọ.

A ti ṣe onírúurú oògùn láti ran adènà àrùn lọ́wọ́, àwọn oògùn tí orúkọ wọ́n díjú tó bẹ́ẹ̀ tí a ń fi àkékúrú orúkọ pè wọ́n—AZT, DDI, àti DDC. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà pé a lè retí kí àwọn oògùn wọ̀nyí ṣàǹfààní àgbàyanu, kí wọ́n sì tilẹ̀ ṣèwòsàn pàápàá, kíákíá ni irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ń ṣákìí. Yàtọ̀ sí pé wọn kì í wúlò mọ́ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n tún ń fa àwọn ewu tí a kò rò tẹ́lẹ̀ fún àwọn kan—dídín àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ kù, ìṣiṣẹ́gbòdì nínú ìdì ẹ̀jẹ̀, bíba iṣan ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ jẹ́.

Ní báyìí, ọ̀wọ́ oògùn mìíràn tún ti dé: àwọn oògùn tí ń dí ìṣiṣẹ́ èròjà proteinase lọ́wọ́. Àwọn dókítà ń kọ àkànpọ̀ egbòogi wọ̀nyí mẹ́ta fúnni lálòpọ̀, pẹ̀lú àwọn oògùn agbógunti-fáírọ́ọ̀sì mìíràn. Àwọn àyẹ̀wò ti fi hàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkànpọ̀ egbòogi mẹ́ta yìí kì í pa fáírọ́ọ̀sì náà, ó ń dá bí ó ṣe ń di púpọ̀ sí i nínú ara dúró, tàbí kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá a dúró.

Àkànpọ̀ egbòogi mẹ́ta ti mú ara àwọn aláìsàn le díẹ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ògbógi gbà pé lílo oògùn náà ń gbéṣẹ́ jù, bí àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV bá tètè lò ó, kí àwọn àmì àrùn tó bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, bóyá ó ṣeé ṣe kí a dènà àkóràn náà lọ́nà pípẹ́ títí, kó má lè di àrùn AIDS gidi. A kò tíì mọ bí ìtọ́jú yìí ṣe lè kápá àkóràn náà pẹ́ tó, nítorí pé ó ṣì jẹ́ tuntun.

Owó àkànpọ̀ egbòogi mẹ́ta yìí wọ́n púpọ̀. Ní ìpíndọ́gba, àkànpọ̀ egbòogi agbógunti fáírọ́ọ̀sì mẹ́ta àti àyẹ̀wò ibi ìwádìí ń náni ní 12,000 dọ́là lọ́dún. Yàtọ̀ sí ẹrù ìnáwó náà, aláìsàn tí ń lo àkànpọ̀ egbòogi mẹ́ta yóò máa pààrà ìdí fìríìjì tí a gbọ́dọ̀ tọ́jú àwọn oògùn náà sí ni. Àwọn oògùn kan wà ti yóò máa lò lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́, àwọn mìíràn, lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́. Yóò máa lo àwọn kan láìjẹun, yóò sì máa lo àwọn mìíràn lẹ́yìn oúnjẹ. Ìtọ́jú náà túbọ̀ máa ń díjú nígbà tí ó bá tún ní láti lo àwọn egbòogi mìíràn láfikún, nítorí àwọn àrùn mìíràn tí ó lè mú ẹni tó bá ní àrùn AIDS.

Ohun kan tí ń da àwọn dókítà láàmú jù ni ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí aláìsàn náà bá ṣíwọ́ lílo àkànpọ̀ egbòogi mẹ́ta náà. Àwọn fáírọ́ọ̀sì náà yóò tún bẹ̀rẹ̀ sí di púpọ̀ láìṣeédádúró, àwọn fáírọ́ọ̀sì tó sì ti jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìtọ́jú náà lè di èyí tí àwọn oògùn tí aláìsàn ti fi kò wọ́n lójú tẹ́lẹ̀ kò ràn mọ́. Àwọn oríṣi fáírọ́ọ̀sì HIV tí oògùn kò ràn yóò ṣòro tọ́jú. Ní àfikún sí i, a lè tàtaré àwọn fáírọ́ọ̀sì alágbára àrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyí sí àwọn ẹlòmíràn.

Ǹjẹ́ Àwọn Àjẹsára Ni Ojútùú Náà?

Àwọn kan tí ń wádìí nípa àrùn AIDS gbà pé lílo àjẹsára gbígbéṣẹ́, tí kò sì léwu ni ọ̀nà láti dáwọ́ àjàkálẹ̀ àrùn AIDS dúró lágbàáyé. Àwọn fáírọ́ọ̀sì tó ti di aláìlágbára la fi ṣe àwọn àjẹsára tó kẹ́sẹ járí nínú gbígbógun ti ibà pọ́njú, èèyi, àti ṣegede. Bí nǹkan ti sábà máa ń rí, bí a bá fi fáírọ́ọ̀sì tó ti di aláìlágbára sínú ara ènìyàn, ìgbékalẹ̀ adènà àrùn inú ara yóò ṣiṣẹ́ láti pa á run, yóò sì ṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà ìgbóguntì tí yóò múná dóko láti ṣẹ́gun ojúlówó fáírọ́ọ̀sì tó bá wọnú ara.

Àwọn ìdánrawò méjì tí a fi àwọn ọ̀bọ ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé, ìṣòro tó wà nínú ti fáírọ́ọ̀sì HIV ni pé, àwọn fáírọ́ọ̀sì tó ti di aláìlágbára náà pàápàá lè pani. Lọ́nà mìíràn, àjẹsára náà lè wá fa àrùn tí a ṣètò pé kí ó gbógun tì gan-an.

Ìjákulẹ̀ àti ìtánni-nísùúrù ni wíwá abẹ́rẹ́ àjẹsára ń já sí. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpòpọ̀ tí ì bá ti pa àwọn fáírọ́ọ̀sì tí kò lágbára tó bẹ́ẹ̀ tí a ti fi dánra wò kò tu irun kan lára fáírọ́ọ̀sì HIV. Láfikún sí i, fáírọ́ọ̀sì HIV máa ń yíra padà, tó mú kí ó ṣòro gbá mú láti bá jà. (Ní báyìí, ó kéré tán, ọ̀wọ́ fáírọ́ọ̀sì HIV tó wà lágbàáyé pé mẹ́wàá.) Ohun tí ń dá kún ìṣòro náà ni pé, àwọn sẹ́ẹ̀lì adènà àrùn tó yẹ kí abẹ́rẹ́ àjẹsára kó tira láti gbógun ti àrùn ni fáírọ́ọ̀sì náà ń kọ lù ní tààràtà.

Ìṣúnná tún ń kópa pàtàkì nínú ìwádìí. Àjọ Aṣàwárí Àjẹsára Àrùn AIDS Lágbàáyé, tó wà ní Washington, sọ pé, “àwọn ilé iṣẹ́ àdáni kò fi bẹ́ẹ̀ dá sí i.” Wọ́n sọ pé ohun tó fa èyí ni pé wọ́n ń bẹ̀rù pé, abẹ́rẹ́ àjẹsára kò ní fi bẹ́ẹ̀ mérè wá, nítorí èyí tó pọ̀ jù la ó tà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì gòkè àgbà.

Láìka àwọn ìṣòro náà sí, àwọn olùwádìí ń wádìí nìṣó nípa onírúurú ọ̀nà tí wọ́n fi lè rí àjẹsára tó kẹ́sẹ járí. Bí ó ti wù kí ó rí, ní báyìí ná, kò jọ pé a lè ṣe àjẹsára kan jáde láìpẹ́. Nígbà tí a bá jàjà gbé àjẹsára kan jáde láti ibi ìwádìí, ó kan iṣẹ́ eléwu, tó le, ti dídán an wò lára ènìyàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Wo Ní Ń Kó Fáírọ́ọ̀sì HIV?

Kárí ayé, nǹkan bí 16,000 ènìyàn ní ń kó o lójoojúmọ́. A gbọ́ pé ó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Nǹkan bí ìpín kan nínú 10 jẹ́ ọmọdé tí kò tó ọmọ ọdún 15. Àwọn tó kù jẹ́ àgbàlagbà tí àwọn obìnrin inú wọn lé ní ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún, tí àwọn tó sì lé ní ìdajì wà láàárín ọmọ ọdún 15 sí 24.—Àjọ Ìlera Àgbáyé àti Àjọṣe Ètò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Àrùn AIDS.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Ní In?

O kò lè mọ̀ pé ẹnì kan ní in nípa wíwulẹ̀ wo ẹni náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó lè jọ pé ara àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV tí àwọn àmì àrùn rẹ̀ kò fara hàn yá gágá, wọ́n lè kó fáírọ́ọ̀sì náà ran àwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ o kàn lè gbà pé òtítọ́ ni ẹnì kan sọ bí ó bá sọ pé òun kò ní in? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV fúnra wọn kò mọ̀ pé àwọn ní in. Àwọn tó mọ̀ lè fi ṣe àṣírí, tàbí kí wọ́n parọ́. Ìwádìí kan ní United States fi hàn pé ìpín 4 nínú 10 àwọn tó ní fáírọ́ọ̀sì HIV kò fi tó àwọn tí wọ́n ń bá lò pọ̀ létí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Bí Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Àrùn AIDS Ṣe Jẹ́ Síra Wọn

Fáírọ́ọ̀sì HIV ni “fáírọ́ọ̀sì tí ń mábùkù bá agbára ìdènà àrùn tó wà nínú ènìyàn,” òun ni fáírọ́ọ̀sì tí ń ba àwọn apá kan adènà àrùn tí ń bá àrùn jà nínú ara jẹ́ díẹ̀díẹ̀. Àrùn AIDS ni “àgbájọ àmì àrùn tí àìlèṣiṣẹ́ agbára ìdènà àrùn inú ara ń mú wá.” Òun ni apá tó kẹ́yìn nínú ìpele àìsàn tí fáírọ́ọ̀sì HIV ń fà. Orúkọ náà ṣàlàyé bí fáírọ́ọ̀sì HIV ti ba agbára adènà àrùn inú ara jẹ́ jìnnà, tó mú kí ó rọrùn fún àwọn àrùn tí agbára ìdènà àrùn inú ara ì bá ti gbógun tì láti borí aláìsàn náà.

[Credit Line]

CDC, Atlanta, Ga.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ó bọ́gbọ́n mu láti ṣàyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì HIV ṣáájú ríronú nípa ìgbéyàwó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́