Kí Ní Ń Mú Àwọn Ènìyàn Láyọ̀?
Ó ti pé ẹ̀wádún méjì tí àwùjọ àwọn olùṣèwádìí jákèjádò ayé kan ti ń ṣe ìwádìí àfẹ̀sọ̀ṣe kan nípa ayọ̀. Kí ni wọ́n rí? Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Ó jọ pé kì í ṣe àwọn ipò òde ara ní ń fa ayọ̀ tó bẹ́ẹ̀.”
Ìwé ìròyìn nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yí tún sọ pé: “Bákan náà, ọrọ̀ kọ́ ní ń pinnu ayọ̀. Àwọn ènìyàn kò láyọ̀ sí i láàárín àkókò tí búrùjí àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn ń pọ̀ sí i. . . . Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, ìbátan tí ó wà láàárín owó tí ń wọlé àti ayọ̀ kò tó nǹkan.”
Àwọn ìwádìí náà fi àwọn ìtẹ̀sí mẹ́rin hàn tí ó jẹ́ ànímọ́ àwọn tí wọ́n láyọ̀: Wọ́n fẹ́ràn ara wọn, wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ ara ẹni gan-an; wọ́n lérò pé àwọn ní àkóso lórí ìgbésí ayé ara ẹni wọn; wọ́n máa ń wọ̀nà fún rere; wọ́n sì ń túra ká sí àwọn ẹlòmíràn. Ní àfikún, ìgbéyàwó tó já sí rere àti ipò ìbátan tímọ́tímọ́ ń mú kí ìgbésí ayé jẹ́ aláyọ̀, ó sì jọ pé ìwọ̀nyí ń mú kí ipò ìlera àti ẹ̀mí gígùn pọ̀ sí i.
Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí ń ṣe dáradára ní ti ìsìn tún ròyìn níní ayọ̀ púpọ̀. Ìwádìí kan tí a ṣe lórí èrò aráàlú ṣàwárí pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí wọ́n lẹ́mìí ìsìn gan-an sọ pé àwọn láyọ̀ ní ìlọ́po méjì ti àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ fara fún ìsìn. Àwọn ìwádìí mìíràn, títí kan ìwádìí kan tí àwọn orílẹ̀-èdè 16 kan pawọ́ pọ̀ ṣe ní lílo 166,000 ènìyàn ní orílẹ̀-èdè 14, fi hàn pé ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí a ròyìn pé àwọn kan ń ní nínú ìgbésí ayé ń pọ̀ sí i nígbà tí wọ́n bá ń dara pọ̀ mọ́ ìsìn, tí wọ́n sì ń lọ síbi ìjọsìn déédéé.”
Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni onísáàmù náà, Dáfídì, ti fi hàn pé ayọ̀ ẹnì kan ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìjọsìn oníṣọ̀kan ti Jèhófà Ọlọ́run, ní kíkọ̀wé pé: “Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ilé Olúwa.”—Orin Dáfídì 122:1.
Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kíní kejì láti ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì”! (Hébérù 10:24, 25) Ní tòótọ́, pípéjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ní irú ìgbàgbọ́ ṣíṣeyebíye kan náà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ fún àwọn olùfẹ́ òtítọ́ Bíbélì. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́, wọ́n sì ń ké sí ọ láti wá rí èyí fúnra rẹ nípa dídara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó sún mọ́ ọ.