Àwọn Èèyàn Ń Wá Ohun Tó Máa Fún Wọn Láyọ̀
NÍ ỌDÚN díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn tó wà nílẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Jámánì, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Kí ló lè fún èèyàn láyọ̀?” Ìpín mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wo sọ pé ìlera ara ni; ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́rin sọ pé ìgbéyàwó tó fini lọ́kàn balẹ̀ tàbí kí àjọgbé tọkọtaya dára ni; ìpín méjìlélọ́gọ́ta sọ pé kéèyàn jèrè ọmọ rẹ̀ ni; ìpín mọ́kànléláàádọ́ta sì rò pé iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé ni orísun ayọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló gbà pé kì í ṣe owó ló máa ń fúnni láyọ̀, síbẹ̀ ìpín mẹ́tàdínláàádọ́ta lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò yẹn ló dá lójú hán-ún pé owó lè fúnni láyọ̀. Kí wá ni òótọ́ ibẹ̀ gan-an?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ronú nípa ohun táwọn kan sọ pé owó ló ń mú kéèyàn láyọ̀. Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ọgọ́rùn-ún èèyàn tó lówó jù lọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé àwọn olówó wọ̀nyí kò láyọ̀ ju àwọn èèyàn yòókù lọ. Ẹnì kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìlera ọpọlọ sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ohun ìní wọn di ìlọ́po méjì láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, síbẹ̀ ayọ̀ tí wọ́n ní kò pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kódà, ìròyìn kan sọ pé: “Àkókò yẹn gan-an ni àwọn tó ní ìdààmú ọkàn wá pọ̀ sí i. Àwọn ọ̀dọ́langba tó gbẹ̀mí ara wọn pọ̀ ní ìlọ́po mẹ́ta ju ti tẹ́lẹ̀. Ìyè àwọn tọkọtaya tó kọra wọn sílẹ̀ sì di ìlọ́po méjì.” Nǹkan bí àádọ́ta orílẹ̀-èdè ni àwọn tó ṣe ìwádìí nípa ìsopọ̀ tó wà láàárín owó àti ayọ̀ tí sọ pé owó kò lè ra ayọ̀.
Ìkejì, báwo ni àwọn nǹkan bí ìlera ara, ìgbéyàwó tó fini lọ́kàn balẹ̀, àti iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé ti ṣe pàtàkì tó téèyàn bá ń wá ayọ̀? Tóò, tó bá jẹ́ pé dandan ni kéèyàn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí kó tó lè láyọ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí ara wọn ò yá àti gbogbo tọkọtaya tí àjọgbé wọn ò dára wá ńkọ́? Àwọn tọkọtaya tí kò bímọ àti gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí kò níṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé wá ńkọ́? Ṣé inú ìbànújẹ́ làwọn yẹn máa wà títí ayé ni? Ṣé ayọ̀ tí wọ́n sọ pé àwọn tára wọn le àtàwọn tí ìgbéyàwó wọn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nísinsìnyí ní máa pòórá tí ipò wọn bá yí padà ni?
Ṣé Ibi Tá À Ti Lè Rí Ayọ̀ La Ti Ń Wá A?
Gbogbo èèyàn ló fẹ́ láyọ̀. Èyí kò yani lẹ́nu nítorí pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Bíbélì pe Ẹlẹ́dàá wa, a sì dá èèyàn ní àwòrán Ọlọ́run. (1 Tímótì 1:11; Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Nítorí náà, ó ti di ìwà ẹ̀dá pé kí wọ́n máa wá ohun tó máa fún wọn láyọ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ló ti wá rí i pé níní ayọ̀ dá bíi kéèyàn wulẹ̀ kó yanrìn sọ́wọ́, àti ayọ̀ o àti yanrìn o, kò sí èyí tó ń dúró pẹ́ lọ́wọ́ ẹni nínú méjèèjì.
Àbí àwọn kan ti tàṣejù bọ ọnà tí wọ́n ń gbà wá ohun tó máa fún wọn láyọ̀ ni? Ohun tí Eric Hoffer tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí nípa àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn rò gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń wá ohun tó máa fún wọn láyọ̀ gan-an ni olórí ohun tó ń fa àìláyọ̀.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn tó bá jẹ́ pé ibi tá ò ti lè rí ayọ̀ la ti ń wá a. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé a máa ní ìjákulẹ̀ ṣáá ni. Yálà kéèyàn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ ni o; kó tiraka láti di olókìkí ni o; kó máa lépa láti mókè nínú ìṣèlú, nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tàbí nínú ọ̀ràn ìṣúnná owó; tàbí kéèyàn wulẹ̀ máa gbé ìgbésí ayé onímọtara ẹni nìkan, kó sì fẹ́ tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn lójú ẹsẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló ti kùnà láti fúnni láyọ̀. Abájọ táwọn kan fi wá ní irú èrò òdì tí òǹkọ̀wé kan ní, tó sọ pé: “Àyàfi tá a bá jáwọ́ nínú wíwá ohun tó máa fún wa láyọ̀ la fi lè ní ayọ̀”!
Ohun tó tún gbàfiyèsí ni pé ìwádìí tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí tún fi hàn pé ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ohun tó ń fúnni láyọ̀ ni kéèyàn máa ṣoore kó sì máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìdámẹ́rin lára wọn sì sọ pé ìgbàgbọ́ ẹni àti ìsìn téèyàn ń ṣe kó ipa pàtàkì nínú ohun tó ń múni láyọ̀. Láìsí àní-àní, ó yẹ ká túbọ̀ fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó ń fúnni láyọ̀ ní ti gidi. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé owó, ìdílé aláyọ̀, tàbí iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé ni olórí ohun tó ń fúnni láyọ̀. Ǹjẹ́ o gbà bẹ́ẹ̀?