Ilera ati Ayọ—Bawo ni Iwọ Ṣe Lè Rí Wọn?
TIPẸTIPẸ eniyan ti mọ isopọ timọtimọ ti ó wà laaarin ilera ati ayọ. Hippocrates, ẹni tí a rò pé ó jẹ́ “baba ìṣègùn,” wipe: “Eniyan ọlọgbọn kan yẹ ki o ronu nipa rẹ̀ sí pe ilera ni eyi ti ó tobi julọ ninu awọn ibukun eniyan.” Ọmọran ara Germany naa Arthur Schopenhauer ṣakiyesi pe: “Meji ninu ọta ayọ eniyan ni irora ati ìsúni.”
Ninu iwe naa Anatomy of an Illness as Perceived by the Patient, Norman Cousins sọ iriri rẹ ninu lilo ẹ̀rín lati gbejako ailera ti nhalẹ mọ iwalaaye rẹ ṣáá. Ó kere tan lapakan o ka a sí pe ikọfẹpada rẹ̀ jẹ́ nitori ẹ̀rín àrínjinlẹ̀ ti o gbadun nigba ti o nwo awọn ere sinima kọmẹdi. Awọn oniṣegun lóókọ lóókọ ti bẹrẹ sí ṣayẹwo anfaani ti ó ṣeeṣe ti awọn eroja kan bayii ti a npe ni endorphins, ti ntujade sinu ara nigba ti a bá nrẹrin in. A lè tipa bayii rí ọgbọn owe onimiisi naa pe: “Inu didun mu imularada rere wá.”—Owe 17:22.
Sibẹ, lọna ti ó takora, awọn oluwadii ti rí i pe ilera didara kò fi dandan sọ pe ki ayọ wa, nitori pe ọpọlọpọ onilera jẹ alailayọ. Iwadii ti a gbekari idahunpada si iwe ibeere fun isọfunni ati awọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti iye awọn eniyan ti wọn ju 100,000 lọ ṣamọna Jonathan Freedman sí ipari ero ti a kò reti naa pe eyi ti ó ju ipin 50 ninu ọgọrun un awọn ti wọn jẹ́ alailayọ pẹlu igbesi-aye wọn ni wọn ní ilera niti gidi.
Ilera ati Ayọ—Ni Ṣókí
Nigba naa, nibo ni awa nilati wò fun àpapọ̀ ilera ati ayọ ti ó ṣoro lati rí yii? Ijinlẹ oye kan ti ó fanilọkanmọra ni a fifunni ni ọpọ ọrundun sẹhin nipasẹ Confucius pe: “Ijọba rere yoo wa pẹtiti nigba ti a bá mu awọn wọnni tí wọ́n wà nitosi layọ, tí a sì fa awọn wọnni tí wọn jìnnàréré mọra.” Ni eyi ti ó tubọ sunmọ akoko wa, aṣaaju oṣelu Thomas Jefferson polongo pe gongo kanṣoṣo ti o jẹ ti ijọba ni “lati mú ayọ daju de iwọn ti ó ṣeeṣe julọ fun gbogbo awọn wọnni ti wọn wa papọ labẹ rẹ.”
Nitootọ, ayẹwo kínníkínní ṣipaya pe idahun didarajulọ sí ilepa araye fun alaafia ati ayọ pa afiyesi pọ sori ohun kan nitootọ—ijọba.
La ọpọ sanmani já, awọn eniyan ti bojuwo ibẹ—wo ijọba—fun ayọ wọn. Fun apẹẹrẹ, Ipolongo Ominira ti United States ní awọn ọrọ olokiki wọnyi ninu: “A di awọn otitọ wọnyi mú lati jẹ́ eyi ti o nfi ẹri araarẹ han kedere, pe gbogbo eniyan ni a dá dọgba, pe Ẹlẹdaa wọn fun wọn ni awọn Ẹtọ ti ko ṣajeji kan, pe lara iwọnyi ni Iye, Idasilẹ ati ilepa Ayọ wà.” Ṣakiyesi pe ijọba ti a ní lọkan nihin in ṣeleri kiki ẹtọ lati lepa ayọ fun awọn ọmọ abẹ rẹ. Niti ilera, ọpọlọpọ ijọba lọna ti ó gba ìgbóríyìn ti gbé awọn itolẹsẹẹsẹ lati mu ilera awọn ara ilu wọn sunwọn sii ga. Sibẹ, ilera daradara lapapọ fun ọpọlọpọ ni ó ti di eyi tí o ṣoro rí.
Sibẹ ki ni ti ijọba kan ti ó ṣeleri lati pese eyi ti ó ju bẹẹ lọ paapaa? Ki ni bi kò bá ṣeleri ilepa ayọ nikan ṣugbọn ayọ funraarẹ? Ati ki ni bi ó bá ṣeleri, kii ṣe idaniloju ilera, bikoṣe ilera didara funraarẹ? A kì yoo ha mu inu rẹ dùn pe nihin in ni kọkọrọ sí ilepa araye fun ilera ati ayọ sinmi lé?
Ọpọlọpọ lonii lè ronu pe eyi jẹ àlá ti ko le ṣẹ, sibẹ iru ijọba bẹẹ ni a sọ tẹlẹ ti a sì ṣapejuwe ni kulẹkulẹ de àyè kan. A lè rí isọfunni ti ó ṣee gbarale naa ninu Bibeli Mimọ, ijọba naa sì ni Ijọba ti Mesaya Ọlọrun.
Ijọba, tabi Iṣakoso, Ọlọrun
Bibeli sọrọ lọpọ igba nipa “ijọba Ọlọrun.” Ki tilẹ ni gan an? Webster’s New World Dictionary of the American Language ṣetumọ “ijọba” gẹgẹ bi “akoso kan tabi ilu tí ọba kan tabi ọbabinrin kan ti jẹ olori.” Kí á sọ ọ lọna rirọrun, Ijọba Ọlọrun jẹ́ iṣakoso kan, iṣakoso ọlọba kan tí Ọmọkunrin ati Ọba tí Ọlọrun fami ororo yàn, Jesu Kristi ndari. Bawo gan an ni ijọba yii ṣe ṣe pataki tó ninu ete Ọlọrun? Jẹ ki awọn ọrọ Jesu dahun: “Ẹ maa baa niṣo, nigba naa, ni wiwa ijọba naa . . . A o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ilẹ-aye gbigbe . . . Mo nilati kede ihinrere ijọba Ọlọrun, nitori idi eyi ni a ṣe rán mi wá. . . . A ti nkede ijọba Ọlọrun gẹgẹ ihinrere, oniruuru eniyan sì nyara tẹsiwaju siha rẹ.”—Matiu 6:33; 24:14; Luuku 4:43; 16:16, NW.
Ọrọ naa “ijọba” ni a lò ni igba ti o ju ọgọrun un kan lọ ninu awọn akọsilẹ Ihinrere ti igbesi-aye Jesu, nigba miiran ni pato gan an ni isopọ pẹlu ilera ati ayọ. Sakiyesi Matiu 9:35: “Jesu si rin si gbogbo ilu nla ati ileto, o nkọni ninu sinagọgu wọn, o sì nwaasu ihinrere ijọba, o sì nṣe iwosan arun ati gbogbo aisan ni ara awọn eniyan.” Bi o tilẹ jẹ́ pé Jesu so mimu alaafia didara wá pẹlu ikọnilẹkọọ rẹ̀ nipa Ijọba naa pọ̀, awa nilati ṣakiyesi pe wiwo awọn ailera san rẹ̀ wà ni ipo keji sí wiwaasu ati kikọni rẹ. A mọ ọn gẹgẹ bi “Olukọ,” kii ṣe “Amunilarada.” (Matiu 26:18; Maaku 14:14; Johanu 1:38) Oun kò gbajumọ mimu awọn eniyan lara dá tabi pipese itọju fun awọn alaisan ni pataki. Aniyan rẹ akọkọ ni Ijọba naa nigba gbogbo. Nipa ṣiṣetọju ailera awọn eniyan, o fi ìyọ́nú titobi rẹ han o sì fihan jade pe oun ni itilẹhin atọrunwa.
Awọn iwosan ti Jesu ṣe tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi apejuwe imupadabọsipo ilera eniyan ti oun yoo ṣaṣepari rẹ nigba ti Ijọba Ọlọrun ba nṣakoso ni kikun lori ilẹ-aye. Eyi ni a tun funlokun nipasẹ iran naa ti a ṣapejuwe rẹ ni Iṣipaya 22:1, 2: “O si fi odo omi iye kan hàn mí, ti ó mọ́ bi kristali, ti nti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá. Ni aarin igboro rẹ̀, ati niha ikinni keji odò naa, ni igi iye gbé wà, tii maa so oniruuru eso mejila, a si maa so eso rẹ̀ ni oṣooṣu: ewe igi naa si ni fun mimu awọn orilẹ-ede larada.”
Ṣugbọn nibo ni yoo ti ṣeeṣe fun wa lati gbadun eyi? O lè dabi eyi ti o dara ju lati jóòótọ́ lati ṣereti iru agbayanu imularada kan bẹẹ lati ṣẹlẹ lori ilẹ-aye. Bi o ti wu ki o ri, ranti awọn ọrọ Jesu ti ó ṣeeṣe ki iwọ funraarẹ ti sọ ninu adura pe: “Ki ijọba rẹ dé; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bii ti ọrun, bẹẹ ni ní aye.”—Matiu 6:10.
Ninu Ijọba ti Mesaya Ọlọrun, nigba naa, ni a ó ti rí ireti fun ilera ati ayọ gidi, ti o ṣee gbarale, ni ọjọ ọla. Bi o ti wu ki o ri, ibeere kan ṣì wa.
Awa Ha Le Gbadun Ilera ati Ayọ Nisinsinyi Bi?
Àní nisinsinyi, titẹle awọn ilana Bibeli niha ọdọ tiwa le fun wa lagbara lati gbadun iwọn ilera pupọ sii, papọ pẹlu ayọ pupọ sii. Gẹgẹ bi a ti ńgbé e jade lemọlemọ ni awọn oju-ewe iwe-irohin yii, awọn wọnni ti wọn fi Bibeli silo ninu igbesi-aye wọn ojoojumọ ni a saba maa ndaabobo kuro lọwọ awọn iṣoro ilera ti njẹ jade lati inu iwa palapala takọtabo, siga mimu, ọti amuju, ati ilokulo oogun. Wọn tun niriiri awọn anfaani igbesi-aye ti o parọrọ ju ati ajọṣepọ ti o dara ju pẹlu ibatan ati awọn ẹlomiran.
Bi o ti wu ki o ri, a ti rí i bayii, pe nini ilera daradara ko fi dandan yọrisi ayọ pipẹ titi. Ki ni yoo gba fun ọ lati gbadun iwọn ayọ pupọ sii?
Ninu iwadii ti a mẹnukan ṣaaju, Jonathan Freedman gbé ibeere yẹn yẹwo lọna jijinlẹ. Oun ṣayẹwo iru awọn okunfa gẹgẹ bi “Ifẹ ati Ibalopọ-takọtabo,” “Igba-ewe ati Ipo Agba,” “Owo ti nwọle ati Imọ-ẹkọ,” ani “Ilu ati Orilẹ-ede” paapaa. O le ru ọ lọkan soke lati mọ pe o ri awọn okunfa wọnyi pe wọn ni ipa ti ó mọniwọn lori ayọ tí ẹnikan ni ní ipilẹ. Fun apẹẹrẹ, ni titọka si apẹẹrẹ awọn eniyan ti wọn ni awọn ohun ti ara pupọ ṣugbọn ti wọn ṣì jẹ́ alailayọ sibẹ, ó pari ero pe: “Awa ti rí i pe, lọna ti ó yanilẹnu bakan ṣáá, kii ṣe owo ti nwọle tabi imọ-ẹkọ ni ó jọ bii pe ó kó ipa pataki julọ ninu ayọ.”
Awọn ipari ero rẹ ṣe gbohùngbohùn ọlọgbọn onkọwe Bibeli kan, apọsiteli Pọọlu, ẹni ti o wipe: “Ipokipo ti mo bá wà, mo ti kọ́ lati ní itẹlọrun ninu rẹ.” (Filipi 4:11) Ranti awọn ọrọ Jesu pẹlu pe: “[Ẹ] kiyesara ki ẹ sì maa ṣọra nitori ojukokoro: nitori igbesi-aye eniyan kii duro nipa ọpọ ohun tí ó ní.”—Luuku 12:15.
Nitootọ, Ọjọgbọn Freedman ri eyi: “Leralera, bi a ti nṣayẹwo awọn gbolohun ọrọ lati ẹnu awọn eniyan alailayọ ti o jọ bi pe wọn ni ohun gbogbo, a rí wọn ti wọn nsọ pe igbesi-aye wọn ko ni itumọ ati idari.” O fikun un pe: “Mo lọra lati ka eyi si bàbàrà jù, ṣugbọn o farahan pe iniyelori tẹmi maa ńnípa lori imọlara ẹnikan nipa ohun ti o jẹ ootọ, nigba ti aisi wọn dé iwọn kan npanilara tabi mu kí iniyelori ohun gbogbo miiran dinku.”
Ni ọjọ wa a rí ẹri otitọ awọn akiyesi wọnyi. Wò yika rẹ. Iwọ ko ha fẹrẹẹ ri gbogbo eniyan—awọn kan pẹlu ohun ìní diẹ, awọn kan pẹlu ohun ìní pupọ—ti wọn nle ayọ ṣugbọn wọn ko gbadun pupọ ninu rẹ? Loootọ, awọn kan ti jọ̀gọ̀nù wọn si ngbe ninu ijiya ainireti ni idakẹjẹẹ, sibẹ ọpọlọpọ ngbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi ẹni ti o wà lori ọlọ ti nyibiripo, wọn nlepa, ṣugbọn ọwọ wọn kò tẹ ohun ti wọn nlepa. Awọn kan ṣegbeyawo lati ni ayọ, ani nigba ti awọn aladuugbo wọn ngba ikọsilẹ fun idi kan naa. Awọn ẹlomiran nṣe iṣẹ àṣekúdórógbó, sibẹ ti awọn miiran nfiṣẹ silẹ fun awọn isinmi gigun ti o si nnani lowo. Gbogbo wọn nle gongo ti o ṣoro rí kan naa, lati jẹ onilera ati alayọ. Wọn ha rí i bi? Iwọ ha ti rí i bi?
Ilera Rẹ, Ayọ Rẹ
Otitọ naa ni pe, iwọ le ni iwọn ilera ati ayọ ti o pọ nisinsinyi. Lọna wo?
Dajudaju ó bá ọgbọn mu lati tọju ilera rẹ ni ọna ti ó wà deedee, iru bii fifi imọran Bibeli ti o gbeṣẹ silo. Fifoju tootọ wo awọn nǹkan yoo tun ṣeranlọwọ pẹlu. Iyẹn wemọ mimọ daju pe aisan le de ba ara alaipe wa, sibẹ ki a má jẹ ẹni ti a bo mọlẹ nigba ti iyẹn ba ṣẹlẹ. Eyi le beere fun isapa siwaju sii lati pa oju-iwoye onifojusọna fun rere mọ gẹgẹ bi a ti npa ọkan pọ sori ilera pipe ninu aye titun ti nbọ.
Lati rí i boya iwọ ni iwọn ayọ ti o ba ọgbọn mu nisinsinyi, beere awọn ibeere wọnyi lọwọ araarẹ: 1. Emi ni pataki ha nṣakoso igbesi-aye ara temi funraami bi? 2. Emi lọna ṣiṣekoko ha wa ni alaafia pẹlu araami ati awọn wọnni ti wọn yí mi ka bi? 3. Mo ha ni itẹlọrun nigba gbogbo pẹlu awọn aṣeyọri igbesi-aye mi gẹgẹ bi a ti fi imọlẹ Bibeli diwọn rẹ̀ bi? 4. Idile mi ati emi ha ngbadun jijẹ ẹni ti o le ṣiṣẹ sin Ọlọrun bi?
Dé iwọn titobi kan, yiyan naa jẹ tiwa. Ọpọlọpọ ninu wa ni ipilẹ le jẹ́ onilera, a si ni yiyan lati jẹ alayọ pẹlu. Ṣugbọn a gbọdọ ni gongo tẹmi ki a sì ṣiṣẹ lati lé wọn bá. Ranti awọn ọrọ Jesu: “Nibi ti iṣura yin ba gbé wà, nibẹ ni ọkan yin yoo gbé wà pẹlu.” (Matiu 6:21) A sì ni idi kan ti a gbekari Bibeli lati fojusọna fun ani ilera ati ayọ titobi ju labẹ iṣakoso pipe ti Ijọba Mesaya naa. Nigba naa ilera ati ayọ pipe perepere le jẹ́ tiwa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn eniyan alayọ ní inu didun lati ṣajọpin ireti wọn fun ilera pipe pẹlu awọn ẹlomiran