ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/15 ojú ìwé 8-12
  • Ilepa Ìdásílẹ̀ Ní Senegal

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilepa Ìdásílẹ̀ Ní Senegal
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • ‘Jehofa Fẹ Ki Ẹ Gba Ile Yii’
  • Ninu Pápá Pẹlu Awọn Ojihin Iṣẹ Ọlọrun
  • Wọn Wà Lominira Lati Lepa Iṣẹ-isin Alakooko Kikun
  • Ikobinrinjọ Lodi Sí Ọkọ Kan Aya Kan Ti Kristẹni
  • Ijọsin Awo Lodi Sí Ijọsin Tootọ
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/15 ojú ìwé 8-12

Ilepa Ìdásílẹ̀ Ní Senegal

LORI omi gan an lati Dakar, olu ilu ti Senegal ode oni, ni Erekuṣu Gorée kekere wà. Lori rẹ ni irannileti ti kò dùn mọni ti apa ti ó bani ninu jẹ́ kan ninu itan wà—ile ẹrú ti a kọ ni 1776.

O jẹ́ ọkan lara ọpọlọpọ iru awọn ile bẹẹ ninu eyi ti a sé awọn ẹrú ti wọn tó lati 150 si 200 mọ ninu awọn ipo ẹlẹgbin fun ohun ti ó tó oṣu mẹta ṣaaju ki a tó fi ọkọ oju omi kó wọn lọ sí awọn ibi jijinna réré. Awọn idile ni a pín niya, awọn mẹmba idile naa kò sí ni rí araawọn lẹẹkan sii mọ; baba ni a le rán lọ sí Louisiana ni Ariwa America, iya sí Brazil tabi Cuba, ati awọn ọmọ si Haiti, Guyana, tabi Martinique. Ẹ wo iru aika ìdásílẹ̀ eniyan si ti eyi jẹ́! Eyi tun jẹ́ irannileti alagbara kan pe ominira jẹ́ anfaani ṣiṣọwọn kan ti ko fi igba gbogbo jẹ ìní gbogbo eniyan.

Mo mọ eyi lati inu iwe pẹlẹbẹ awọn arinrin ajo ti mo nka ninu ọkọ ofuurufu ti nlọ si Senegal, orilẹ-ede ti ó kángun si iwọ-oorun julọ lori òkìtì ilẹ gọngọ ti Iwọ-oorun Africa. Agbegbe ilẹ pápá ti savanna wà laaarin awọn aṣalẹ si iha ariwa ati ila-oorun ti igbo ẹgan kìjikìji si wà ni iha guusu. Nihin in iwọ le ri igi osè ọlọjọ pipẹ titobi rabata, pẹlu eso aṣeni ní kayefi rẹ̀ ti a npe ni burẹdi ọbọ, lati inu eyi ti a ti nmu ẹfun tartar jade. Eyi tun jẹ ilẹ awọn ọbọ ati awọn ẹyẹ oloriṣiriṣi àwọ̀ ati awọn abule ti o ṣajeji lọna fifanimọra ti wọn wà laaarin awọn igi mangoro.

Mo fẹhinti ni ijokoo mo si ronu nipa ibẹwo ti mo ti nduro dè tipẹ si ọna abawọ Iwọ-oorun Africa yii. Lonii, Senegal, pẹlu aadọta ọkẹ meje awọn olùgbé rẹ̀ lati oniruuru ẹya ibilẹ, ngbadun ìdásílẹ̀ kikun. Ṣugbọn o ha lè jẹ pe ẹnikan le wà lominra niti ara iyara, sibẹ ki o maa sinru fun awọn aṣa ati igbagbọ ninu ohun asan ti o fi ìdásílẹ̀ tootọ dù ú? Mo fojusọna pẹlu ìháragàgà lati pade awọn arakunrin mi nipa tẹmi ki nsì mọ funraami nipa itẹsiwaju otitọ ti nsọ awọn eniyan dominira ni apa aye yẹn.—Johanu 8:32.

‘Jehofa Fẹ Ki Ẹ Gba Ile Yii’

Akọkọ ninu itolẹsẹẹsẹ mi ni lati bẹ ẹka ọfiisi Watch Tower ati ile awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun wò ni Dakar. Bi a ti nde ile igbalode kan ni igberiko didakẹrọrọ kan, mo ṣakiyesi J titobi gadagba ni iwaju rẹ. Ibeere mi akọkọ nigba ti mo nṣebẹwo yika ẹka ọfiisi naa ni ohun ti lẹta J naa duro fun.

“Itan rẹ̀ dùn ún gbọ́ gan an ni, ni ẹni ti ó nmu mi lọ ṣalaye. “Nigba ti a nwa ile lilo fun ẹka ọfiisi ni 1985, a ṣebẹwo si ile yii, ti kikọ rẹ nlọ lọwọ nigba naa. Ṣugbọn a nimọlara pe o ti tobi ju fun aini wa. Nigba ti onile naa gbọ pe a jẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa, o nifẹẹ gidigidi lati fi ile naa háyà fun wa, gẹgẹ bi ó ti mọ pé a jẹ alailabosi. O wipe, ‘Ó dámi loju pe Ọlọrun, Jehofa, fẹ ki ẹ gba ile yii.’ Họwu, ẹ wo o! Ani J gadagba tilẹ wà ni iwaju rẹ! Nigba ti mo gbe e sibẹ, mo ronu pe yoo duro fun orukọ mi John, ṣugbọn ó wá dami loju nisinsinyi pe ó wà fun orukọ Ọlọrun, Jehofa!’ Inu wa ti dùn lati wa ninu ile daradara yii fun ohun ti o ju ọdun marun un lọ sẹhin.”

Lẹhin naa mo fẹ lati mọ bi iṣẹ iwaasu naa ṣe bẹrẹ ni Senegal.

“Omi otitọ ti ndanisilẹ ni a mu wọnu Senegal ni ibẹrẹ 1950 nipasẹ ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti o wá lati France fun iṣẹ agbaṣe kan. Ni 1965 ẹka ọfiisi ni a ṣí si Dakar lati bojuto iṣẹ ni awọn orilẹ-ede ti nsọ ede Faranse ti Senegal, Mali, ati Mauritania, ati bakan naa ni orilẹ-ede ti nsọ ede Gẹẹsi ti Gambia. Lati 1986 ni a ti nbojuto iṣẹ Guinea-Bissau pẹlu, nibi ti a ti nsọ ede Portuguese.”

Ni mimọ pe ohun ti o ju ipin 90 ninu ọgọrun un awọn eniyan ti ngbe ilẹ nihin in jẹ awọn ti kii ṣe Kristẹni, mo beere nipa itẹsiwaju ti a ti ni. Ẹni ti nmu mi lọ wipe, “Otitọ ni pe ọpọlọpọ awọn eniyan ni ilẹ wọnyi ko mọ Bibeli tobẹẹ, ṣugbọn iṣẹ naa ntẹsiwaju geerege. Ni January 1991 ó dùn mọ wa ninu lati ri 596 awọn olupokiki Ijọba. Iyẹn fihan pe awọn arakunrin adugbo ati awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ti nṣiṣẹ kára gan an.”

“Mo loye pe ọpọlọpọ awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ni wọn nṣiṣẹsin nihin in” ni mo ṣakiyesi.

“Bẹẹni, a ní nǹkan bi 60 ti a yàn sí oniruuru ipinlẹ ti a nbojuto, wọn sì wá lati orilẹ-ede 13. Wọn nṣiṣẹ kára wọn si ti ṣetilẹhin gidigidi lati mu ki iṣẹ naa ni ipilẹ rere. Ẹmi yii ni awọn arakunrin adugbo fihan jade ninu ifẹ ati itara wọn fun otitọ. Laika awọn iṣoro iru bii ainiṣẹlọwọ ati awọn ohun ìní ti ara ti ó mọniwọn sí, ọpọlọpọ awọn ara nlo wakati 15 ati ju bẹẹ lọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá loṣooṣu. A nireti pe iwọ yoo pade diẹ lara awọn oṣiṣẹ onitara wọnyi ninu ibẹwọ rẹ.”

Mo fojusọna fun ṣiṣe bẹẹ.

Ninu Pápá Pẹlu Awọn Ojihin Iṣẹ Ọlọrun

Margaret (ẹni ti o ti wà ninu iṣẹ-isin ojihin iṣẹ Ọlọrun fun ohun ti ó ju 20 ọdun lọ ṣaaju iku rẹ laipẹ yii) yọnda lati mú mi lọ pẹlu rẹ sí ipinlẹ rẹ̀ laaarin ilu naa. A wọ car rapide (ọkọ ero aarin ilu) lati niriiri igbesi-aye adugbo. Nitootọ, ó jẹ́ bọọsi kekere kan ti o maa nduro lemọlemọ. O gbe ero 25, bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹni ti ko lomi lara, emi le rí bi irin ajo kukuru naa iba ti fẹrẹẹ tunilara tó. Awọn obinrin meji ti wọn ṣajọpin ijokoo pẹlu mi laisi iyemeji kii ṣe alailomi lara, ṣugbọn mo faramọ ipo naa pẹlu ẹrin musẹ.

“Ni ipinlẹ mi ni isalẹ ilu, iwọ le rí ọpọlọpọ awọn ohun gbigbadun mọni,” ni Margaret ṣalaye nigba ti a dé ibi ti a nlọ. “Ṣe o rí awọn bata pẹlẹbẹ oniruuru wọnni?” ni obinrin naa beere, ni titọka si awọn isọ ti wọn wà lẹbaa ọna ẹlẹsẹ naa. “Awọ agutan ati ewurẹ ti a pa láró ni a fi ṣe wọn.” A sún mọ awọn oluṣe bata pẹlẹbẹ naa, Margaret bẹrẹ igbekalẹ iwaasu rẹ fun wọn ni ede wọn, Wolof. Wọn fetisilẹ daradara a sì fà wọn mọra nipasẹ awọn apejuwe Adamu ati Efa ninu iwe pẹlẹbẹ alaworan meremere naa.

Laipẹ awọn ọkunrin ti ntaja lẹgbẹẹ títì, ti a mọ sí bana-bana nihin in wá sọdọ wa, ni fifi oniruuru awọn nǹkan ti ko lonka lọ wa fun rírà. Awọn kan ńta ìgbálẹ̀, awọn miiran gbé aṣọ, àgádágodo, oogun, apamọwọ, ọsan, ati awọn òòyẹ̀ ẹyẹ paapaa wa fun títà. Ọkan fẹ lati ta kora, ti o jẹ ohun eelo orin olokun tín-ínrín ti wọn fi awẹ igbá kan, tabi akèrègbè ṣe, wọn fi igi ṣe ọrun rẹ; ọwọ mejeeji ni wọn si fi ńta á. Mo ṣakiyesi pe ni ẹ̀hìn rẹ aworan iboju kekere kan wà ti a ṣiṣẹ ọna rẹ pẹlu awọ, ìwo ewurẹ, ati ikarawun “oriire” keekeeke. A ṣalaye pe awa ki yoo ra ohunkohun ti a ba fi awọn ami ti o lè niiṣe pẹlu iṣẹ ajẹ tabi awọn aṣa ijọsin ti ko bá Kristẹni mu ṣe lọṣọọ. Si iyalẹnu wa, ọkunrin bana-bana naa gbà, ni fifihan pe oun jẹ Musulumi funra oun. O tọju kora naa pamọ sẹhin ẹwu gigun rẹ, tabi boubou, o si fetisilẹ daadaa bi Margaret ti fi iwe pẹlẹbẹ naa lọ ọ, eyi ti o jẹ́ ni ede Larubawa. A ru ú soke debi pe o gba iwe pẹlẹbẹ naa o si bẹrẹ sii ka a loju ẹsẹ nibẹ. Lẹhin ti o dupẹ gidigidi lọwọ wa, o kuro pẹlu iwe pẹlẹbẹ naa ati kora ti ko tà naa. A ní idaniloju pe yoo kẹkọọ iwe pẹlẹbẹ naa ni ile.

Lẹhin naa, mo bá John sọrọ, ẹni ti o ti jẹ́ ojihin iṣẹ Ọlọrun pẹlu fun ohun ti o ju 20 ọdun lọ.

“Awọn eniyan nihin in jẹ́ ẹni bi ọrẹ, iwọ si le ba eyi ti o fẹrẹẹ jẹ olukuluku eniyan ti o ba bá pade sọrọ,” ni John sọ fun mi. “Ìkíni ti ó gbajumọ ni ‘assalam alaikum’ ti o tumọsi ‘ki alaafia wà pẹlu rẹ,’ ọpọjulọ awọn eniyan si jẹ alalaafia. Eyi ni ilẹ teranga, tabi ẹmi alejo ṣiṣe, wọn sì fihan nipa inurere, àyẹ́sí eniyan, ati ọyaya.” O ti nrọrun fun mi lati ri idi ti ọpọlọpọ awọn ọdọ ajeji Ẹlẹrii lati ilẹ okeere fi le fi awọn idile ati ọrẹ wọn silẹ lati ṣiṣẹsin ni pápá ojihin iṣẹ Ọlọrun yii.

Wọn Wà Lominira Lati Lepa Iṣẹ-isin Alakooko Kikun

Ẹmi ojihin iṣẹ Ọlọrun ni ipa jijinlẹ lori awọn Ẹlẹrii adugbo. Eyi ni pataki ni o han kedere nitori pe ainiṣẹlọwọ ti o tàn kalẹ mu ki titẹwọgba iṣẹ-isin aṣaaju-ọna alakooko kikun di ipenija gidi kan. Marcel ati Lucien, ti a dá silẹ lominira kuro lọwọ ọpọlọpọ awọn aṣa apanirun nipa kikẹkọọ otitọ Bibeli, ṣalaye pe:

“A fẹ lati fi imọriri wa han nipa titẹwọgba iṣẹ-isin aṣaaju-ọna. Ṣugbọn iṣẹ àbọ̀ṣẹ́ ṣoro lati rí. A gbiyanju iṣẹ oko, ṣugbọn ko gbeṣẹ. Ṣiṣe agbafọ aṣọ gba ọpọjulọ ninu akoko wa. Nisinsinyi a wa lẹnu iṣẹ burẹdi ṣiṣe, ti awọn ile itaja melookan si jẹ onibaara wa deedee, eyi si nṣaṣeyọri daadaa.” Ni kedere o gba wọn ni ọpọlọpọ igbagbọ ati igboya, papọ pẹlu isapa ọlọkan rere, ṣugbọn eyi fi ẹri han pe ó ṣeeṣe lati wọnu iṣẹ-isin alakooko kikun naa ani nigba ti awọn ipo iṣunna owo ba ṣoro paapaa.

Nigba ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu Michel, oun nlọ si yunifasiti kan ni Dakar. “Ọkan mi bajẹ nipa ẹmi iwa palapala ọpọlọpọ awọn akẹkọọ, awọn ibeere ti ntojusuni si nwa sọkan mi lemọlemọ,” ni oun wí. “Eeṣe ti a fi mu eniyan lẹru sinu iru awọn aṣa ati ipo apanilara bẹẹ? Bibeli fun mi ni awọn idahun. Nṣe ni o dabi pe a gbé ẹru wiwuwo kuro ni ejika mi. Bi o tilẹ jẹ pe awọn obi mi fi dandan lé e pe ki nma a ba ikẹkọọ mi lọ, mo lọwọ ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna oluranlọwọ ati lẹhin naa mo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee fun iyoku akoko mi ti mo nilati fi wa ninu yunifasiti. Mo wa rii pe ṣisajọpin ihinrere pẹlu awọn miiran gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan, kii ṣe lilepa iṣẹ igbesi-aye kan ninu eto igbekalẹ ti yoo kógba sile laipẹ, nmu ayọ titobi julọ wá fun mi.” Michel nṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna akanṣe nisinsinyi ni Mbour.

Ikobinrinjọ Lodi Sí Ọkọ Kan Aya Kan Ti Kristẹni

Awọn aṣa adugbo kii figba gbogbo wà ni iṣọkan pẹlu awọn ilana Kristẹni, eyi si le gbé awọn ipenija alailẹgbẹ kalẹ. Alioune, alaboojuto oluṣalaga ni ọkan lara awọn ijọ mẹfa ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ni ilu Dakar ati agbegbe rẹ, rohin pe: “Nigba ti mo kọkọ gbọ́ nipa otitọ ti ńdánisílẹ̀ naa, mo ni iyawo meji. Gẹgẹ bi akikanju Musulumi kan, isin mi yọnda fun mi lati ni ju bẹẹ lọ paapaa. Baba mi ni mẹrin, ọpọjulọ ninu awọn ọrẹ mi si ni melookan. O jẹ ọna ti a tẹwọgba nihin in ni Africa.” Ṣugbọn ki ni ipa tí ọna igbesi-aye yii ńní?

“Nini ju aya kan lọ le ṣokunfa ọpọlọpọ iṣoro,” ni Alioune ṣalaye, “paapaa dé aye ibi ti o kan awọn ọmọ dé. Mo bi ọmọ mẹwaa nipasẹ aya mi akọkọ ati meji nipasẹ ikeji. Ninu iru awọn idile bẹẹ, baba saba maa njẹ ajeji sí awọn ọmọ rẹ, nitori naa wọn ko janfaani lati inu iranlọwọ ati ibawi rẹ̀. Ni afikun, ikobinrinjọ ko daabobo mi kuro lọwọ panṣaga pẹlu. Kakabẹẹ, ikora ẹni ni ijanu, ọkan lara eso ẹmi Ọlọrun, ni o ti ṣe iyẹn.” Nitori naa ki ni Alioune ṣe?

“Mo mu ki aya mi keji pada si ile awọn obi rẹ,” ó nbaa lọ, “mo fi ọgbọn ṣalaye pe kii ṣe pe mo ti ri ohun kan ti ko tẹ́ mi lọrun pẹlu rẹ, ṣugbọn o jẹ lati huwa ni ibamu pẹlu awọn ohun ti Ọlọrun beere fun. Mo ṣe awọn eto akanṣe lati bojuto gbogbo awọn ọmọ mi nipa ti ara ati nipa tẹmi, mo si kún fun ọpẹ pe lonii awọn pẹlu nṣiṣẹsin Jehofa. Ninu awọn mẹsan an ti wọn jẹ akede, marun un ti ṣe iribọmi, meji nṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna akanṣe, ati awọn mẹta yooku gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee ati oluranlọwọ. Otitọ ti sọ mi di ominira nitootọ kuro ninu ọpọlọpọ iṣoro ti o sopọ mọ titọ awọn ọmọ dagba.”

Ijọsin Awo Lodi Sí Ijọsin Tootọ

Eyi ti o tẹle e ninu iweewe irin ajo mi ni lati ṣebẹwo sí ẹkun Casamance ni guusu. A wu mi lori nipa bi gbogbo nǹkan ti farahan ni titutu yọ̀yọ̀ tó. Ibẹ ni a bominrin daradara nipasẹ Odo Casamance titobi fun nǹkan bi 180 ibusọ, agbegbe naa nmu ọpọ yanturu irẹsi, agbado, ati ẹpa jade. Ohun ti o wa gátagàta la eréko naa já ni awọn ahere ribiti, alájà meji, pẹlu awọn orule koriko ti o dabi arọ lati gbe omi ojo fun igba ẹẹrun. Olu ilu naa, Ziguinchor, ni o wa labẹ aabo ọpọlọpọ igi ọpẹ. Inu mi dun lati bá ijọ awọn eniyan Jehofa onitara kan nibẹ.

Dominic, ojihin iṣẹ Ọlọrun ti nṣiṣẹ ninu ati ni ayika Ziguinchor, sọ fun mi pe iṣẹ iwaasu ni agbegbe yii nbaa lọ lọna rere gidigidi. O wipe, “Ni nǹkan bi ọdun mẹwaa pere sẹhin, awọn akede 18 ni wọn wa ninu Ijọ Ziguinchor. Nisinsinyi 80 ló wà. Lati bojuto ibisi titobi yii, a ti kọ Gbọngan Ijọba titun meremere kan, ni lilo amọ pupa ti a rí gan an ni ibi ilẹ gbọngan naa. Iweweedawọle naa jasi ijẹrii nla kan fun awujọ naa. Awọn ọrọ olojurere ni awọn wọnni ti wọn ńrí awọn eniyan lati ọpọlọpọ oniruuru ede ti wọn nṣiṣẹ papọ pẹlu alaafia nsọ. Ni apejọ ayika ẹnu aipẹ yii, gongo iye awọn eniyan ti wọn wá jẹ 206, ti a sì baptisi awọn eniyan 4.”

Ọpọlọpọ awọn eniyan ni apa ibi yii ni Senegal ṣì ntẹle igbagbọ awọn babanla wọn pe gbogbo iṣẹda ni o ni ọkàn, ni jijọsin awọn agbara awo bi o tilẹ jẹ pe wọn njẹwọ jijẹ Kristẹni tabi Musulumi. Mo fetisilẹ daadaa si itan ti Victor, alagba kan ninu Ijọ Ziguinchor sọ.

“A bí mi sinu idile nla kan ti nṣe ijọsin awo ni Guinea. Ni igba ìbí mi, baba mi yà mi sí mimọ fun awọn ẹmi tabi ẹmi eṣu kan bayii. Lati jere ojurere rẹ, emi maa ngbe apo dudu kan jade nigba gbogbo lati abẹ bẹẹdi, gbé pẹpẹ kekere kan kalẹ, ki nsi fi ẹjẹ rubọ si ìwo ti ó duro fun ẹmi eṣu oludaabobo mi. Ani lẹhin ti mo di Katoliki paapaa, mo ṣì ni imọlara ìmúnilẹ́rú. Lẹhin ti mo ṣí lọ si Senegal, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu mi. Aya mi ati emi kẹkọọ pe awa ko le maa baa lọ ni ‘jijẹun nidii tabili Jehofa ati nidii tabili awọn ẹmi eṣu.’ (1 Kọrinti 10:21) Ṣugbọn nigba ti mo dawọ awọn irubọ duro, awọn ẹmi eṣu naa bẹrẹ si gbeja kò wá. Ẹru bà mi lati sọ apo dudu naa sode pẹlu gbogbo awọn ohun ẹmi eṣu ti nbẹ ninu rẹ nitori pe mo mọ nipa ọkunrin kan ti o ti ya wèrè nigba ti o ṣe iyẹn.” Ẹ wo inu ipo ainireti ti Victor bá araarẹ!

“Nikẹhin awọn ọrọ Roomu 8:31, 38, 39 fun wa ni okun ti a nilo lati kó ohun gbogbo ti o niiṣe pẹlu ijọsin awo danu. Nisinsinyi ti a ti gbẹ́kẹ̀ wa le Jehofa, a ti dá wa silẹ nitootọ. Gbogbo agbo ile mi ti ni ireti agbayanu ti iye ainipẹkun ninu paradise ilẹ-aye kan, nibi ti gbogbo eniyan yoo ti wà ni ominira kuro lọwọ idari awọn ẹmi eṣu.”

Nikẹhin, akoko tó fun mi lati kuro. Mo di awọn apo mi. Mo ronu siwa sẹhin lori ibẹwo manigbagbe mi si Senegal. Bawo ni o ti fun igbagbọ lokun tó fun mi lati pade ki nsì ba ọpọlọpọ awọn eniyan ti a ti sọ dominira kuro ninu oko ẹru ilokulo oogun, iwa palapala, ati igbagbọ ninu ohun asan sọrọ ti wọn si ngbadun ìdásílẹ̀ tootọ nisinsinyi. Laika awọn ipo iṣunna owo lilekoko sí, wọn nri ayọ ati itẹlọrun ninu ṣiṣiṣẹsin Jehofa, ẹni ti o mu ireti didaju ti iye ainipẹkun ninu paradise ilẹ-aye wa fun wọn. Bawo ni a ti kun fun ọpẹ tó sí i, ẹni ti o ti mu ki o ṣeeṣe lati ni iru ihinrere bẹẹ lati polongo kii ṣe kiki ni Senegal ṣugbọn yika aye pẹlu lakooko “ọdun itẹwọgba Oluwa [“Jehofa,” NW]”! (Aisaya 61:1, 2)—A kọ ọ ranṣẹ.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

SENEGAL

St. Louis

Louga

Thiès

Dakar

Kaolack

GAMBIA

Banjul

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Omi otitọ adanisilẹ ni a nṣajọpin rẹ lọfẹẹ ni awọn abule

Ile awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ati ẹka ọfiisi ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Dakar, Senegal

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lẹbaa etikun, pẹlu, awọn eniyan Senegal ngbọ ihin-iṣẹ Kristẹni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́