ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/15 ojú ìwé 3-4
  • Ilera ati Ayọ—Wọn Ha Lè Jẹ́ Tirẹ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilera ati Ayọ—Wọn Ha Lè Jẹ́ Tirẹ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilera ati Ayọ—Bawo ni Iwọ Ṣe Lè Rí Wọn?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ohun Tó Máa Fún Wọn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ìgbé Ayé Aláyọ̀
    Jí!—2018
  • Ayọ Tootọ Ninu Ṣiṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/15 ojú ìwé 3-4

Ilera ati Ayọ—Wọn Ha Lè Jẹ́ Tirẹ Bi?

LATI IGBA ti awọn ọkunrin ati obinrin alaipe ti wà, ni wọn ti ńyánhànhàn fun ilera ati ayọ gidigidi. Bi o tilẹ jẹ pe dajudaju iwọnyi jẹ́ meji ti o ṣe pataki julọ lara awọn ohun ti eniyan nifẹẹ ọkan si, wọn ti jẹ ohun ti o ṣoro lati rí.

Awọn eniyan ti ronu pupọ gan an, wọn si ti pese imọran pupọ gan an lori, iwakiri yii. Dokita Dennis Jaffe ṣakiyesi pe: “Lonii, kọkọrọ naa si ilera ati iwosan pipẹ saba maa ńsinmi lori ihuwasi tìrẹ funraarẹ.” Abraham Lincoln sọ lẹẹkan rí pe: “Ó fẹrẹẹ jẹ pe awọn eniyan jẹ́ alayọ gẹgẹ bi wọn ti pinnu lati jẹ.” Iwọ ha gbà bẹẹ bi? Bawo ni iwọ ti fẹ ayọ gidigidi tó? Bawo ni rírí i gbà ti sinmi lori nini ilera ti o dara tó?

Awọn eniyan ti wo ibi gbogbo fun ayọ, ni titẹle ailonka awọn ohun ti o ṣeeṣe ki o jẹ ojútùú. Wọn ti ṣewadii ìmọ̀ ọ̀ràn, ẹkọ ifiṣemọronu ẹ̀dá, ati ẹkọ nipa ironu ọkan eniyan. Ninu iwakiri wọn fun ayọ, awọn kan ti ṣayẹwo imọ ijinlẹ, awọn iṣẹ ọnà, ati orin. Sibẹ o fẹrẹẹ ma si iyèméjì kankan pe apa ti o pọ julọ ninu ayọ tootọ ni o tanmọ nini ilera didara. “Bi iwọ ba ti ní ilera, iwọ wulẹ ti fẹrẹẹ ni ohun gbogbo,” ni ipolowo ọja olokiki kan lori tẹlifiṣọn sọ.

Ni lilepa ọna yii, ọpọlọpọ ti ṣayẹwo oniruuru àbá ero-ori nipa ilera, eyi ti gbogbo eniyan gbà ati eyi ti gbogbo eniyan kò gbà. O fẹrẹẹ jẹ gbogbo ile ikawe ni wọn fi ailonka awọn ṣiṣeeṣe ti idiwọn ounjẹ ati oriṣiriṣi itọju iṣegun han. “Ọpọlọpọ iwe ni a ti kọ lori ilera, bẹrẹ lati igba laelae,” ni ògbóǹtagí oniṣegun ọkan-aya ti a mọdunju naa Dokita Paul Dudley White sọ. “Ọkan lara eyi ti o dara julọ ni Regiment of Helthe ti a kọ ni nǹkan bi ẹgbẹrun ọdun sẹhin.”

Laika gbogbo eyi sí, iwakiri naa fun ilera ati ayọ ti jẹ́ ajánikulẹ̀ fun awọn eniyan ti o pọ julọ. Eyi ha yà ọ́ lẹnu, ni gbigbe bi a ti lero pe ọlaju wa ti tẹsiwaju tó yẹwo? Ni kedere, imọ ijinlẹ kò tii fi opin si aisan, ọjọ ogbo, ati iku.

Ṣugbọn yoo ha yà ọ́ lẹnu siwaju sii lati mọ pe sibẹ a kò tii ní ọna kan lati diwọn ayọ ko sì sí itumọ titẹnilọrun nipa ohun tí ó jẹ́? Ninu asọye kan ti nṣayẹwo “Awọn Ironujinlẹ Lori Ayọ,” Pierre Teilhard de Chardin pari ero pe: “Fun ọpọ ọrundun eyi ti jẹ ẹṣin ọrọ aimọye iwe, awọn iwadii, ayẹwo ẹnikọọkan ati ti ẹgbẹ awujọ, ọkan tẹle omiran; o si banininujẹ lati sọ pe, ìjákulẹ̀ patapata lati dori ifohunṣọkan ni ó ti wà. Fun ọpọlọpọ ninu wa, iyọrisi naa ni pe, ipari ero gbigbeṣẹ kanṣoṣo ti a lè dé ninu gbogbo ijiroro naa ni pe ko wulo lati maa bá iwakiri naa lọ.”

Imọlara rẹ nipa ayọ ha ni iyẹn bi? Beere lọwọ araarẹ awọn ibeere ara ẹni diẹ ṣugbọn tí ó jẹ́ alailabosi. Iwọ ha layọ nitootọ nisinsinyi bi? Tabi ayọ tootọ ni a lè ri kiki ni ọrun? Ifojusọna didaju eyikeyii ha wà pe a lè ní ilera ati ayọ, ani ki a tilẹ ni iwọnyi nihin in gan an lori ilẹ-aye?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́