Kíkojú Ìpèníjà Náà
LÁTỌDÚNMỌDÚN, àwọn ènìyàn ti dábàá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtọ́jú fún àrùn ADHD. Àwọn kan lára ìwọ̀nyí dá lórí oúnjẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìwádìí díẹ̀ fi hàn pé àwọn èròjà tí a ń fi sínú oúnjẹ kì í sábà fa araàbalẹ̀, àti pé, àwọn ojútùú tí a gbé karí oríṣi oúnjẹ kì í sábà gbéṣẹ́. Àwọn ọ̀nà míràn láti ṣètọ́jú àrùn ADHD ni lílo egbòogi, ètò ìyíwàpadà, àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ òye ìdáǹkanmọ̀.a
Lílo egbòogi. Níwọ̀n bí àrùn ADHD ti kan ìṣiṣẹ́gbòdì kan nínú ọpọlọ ni kedere, lílo egbòogi láti ṣe àdápadà ọ̀nà ìṣiṣẹ́ yíyẹ ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.b Bí ó ti wù kí ó rí, lílo egbòogi kì í gba ipò ẹ̀kọ́ kíkọ́. Ó wulẹ̀ ń ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ ni, nípa fífún un ní ìpìlẹ̀ kan tí yóò kọ́ ẹ̀kọ́ agbára ìṣeǹkan tuntun lé lórí.
Bákan náà, lílo egbòogi ti ran ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà alárùn ADHD lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gba ìṣọ́ra—fún tèwetàgbà—nítorí àwọn egbòogi arùmọ̀lára-sókè kan tí a ń lò fún ìtọ́jú àrùn ADHD lè di bárakú.
Ètò ìyíwàpadà. Pé ọmọ kan ní àrùn ADHD kò yọ àwọn òbí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrù iṣẹ́ wọn láti bá a wí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ náà lè ní àìní àrà ọ̀tọ̀ ní ìhà yí, Bíbélì gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Nínú ìwé rẹ̀, Your Hyperactive Child, Barbara Ingersoll sọ pé: “Òbí tí ó bá wulẹ̀ juwọ́ sílẹ̀, tí ó sì jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ aláraàbalẹ̀ ‘ya ewèlè’ kò ṣe ọmọ náà lóore kankan. Bíi ti àwọn ọmọ mìíràn, ọmọ aláraàbalẹ̀ kan nílò ìbáwí ṣíṣe déédéé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún ọmọ náà bí ẹnì kan. Èyí túmọ̀ sí àwọn ààlà ṣíṣe kedere, àti ẹ̀san òun ìjìyà yíyẹ.”
Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí pèsè ìlànà kedere, kí wọ́n sì ṣe déédéé nínú bíbójútó ìhùwà ọmọ náà. Síwájú sí i, ìlànà àṣetúnṣe déédéé gbọ́dọ̀ wà nínú àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́. Àwọn òbí lè fẹ́ fún ọmọ náà ní òmìnira díẹ̀ nínú ṣíṣètò àwọn ohun tí ó bá fẹ́ ṣe, títí kan àkókò fún iṣẹ́ àṣetiléwá, ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, máa bójú tó o déédéé. Rí i dájú pé ó rọ̀ mọ́ ìlànà àṣetúnṣe déédéé ojoojúmọ́ náà. Ìwé ìròyìn Phi Delta Kappan sọ pé: “Àwọn oníṣègùn, onímọ̀ nípa ìrònú òun ìhùwà, aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn olùkọ́ ní iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe kan fún ọmọ náà àti àwọn òbí rẹ̀, láti ṣàlàyé pé jíjẹ́ alárùn ADD tàbí alárùn ADHD kò fún ọmọ náà lómìnira láti ṣe ohun tó bá ti fẹ́ ṣáá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó wà gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ó lè ṣamọ̀nà sí ṣíṣèrànwọ́ yíyẹ fún ọmọ tí ọ̀ràn kàn náà.”
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ òye ìdáǹkanmọ̀. Èyí kan ríran ọmọ náà lọ́wọ́ láti yí èrò rẹ̀ nípa ara rẹ̀ àti àrùn tí ó ní pa dà. Dókítà Ronald Goldberg sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn àìlèpọkànpọ̀ máa ń rò pé àwọ́n ‘burẹ́wà, àwọn ya òmùgọ̀, àwọn sì burú,’ kódà bí wọ́n bá rẹwà, tí wọ́n ní làákàyè, tí wọ́n sì níwà rere pàápàá.” Nítorí náà, ó yẹ kí ọmọ tí ó bá ní àrùn ADD tàbí àrùn ADHD ní èrò rere nípa ìníyelórí ara rẹ̀, ó sì yẹ kí ó mọ̀ pé àwọn ìṣòro àìlèpọkànpọ̀ òun ṣeé yanjú. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbà ọ̀dọ́langba. Nígbà tí alárùn ADHD kan bá fi di aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ojúgbà, olùkọ́, ọmọ ìyá, àti bóyá, àwọn òbí pàápàá, ti ṣàríwísí rẹ̀ púpọ̀. Ó wá yẹ fún un nísinsìnyí láti gbé àwọn góńgó tí ọwọ́ lè tẹ̀ kalẹ̀, kí ó sì pinnu ìníyelórí ara rẹ̀ bí ó ṣe yẹ, kì í ṣe lọ́nà líle koko.
Àwọn àgbàlagbà alárùn ADHD pẹ̀lú lè lo àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tí a mẹ́nu bà lókè wọ̀nyí. Dókítà Goldberg kọ̀wé pé: “Ìyípadà tí a gbé karí ọjọ́ orí pọn dandan, àmọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ìgbàtọ́jú—lílo egbòogi níbi tó bá yẹ, ètò ìyíwàpadà, àti [ìdálẹ́kọ̀ọ́] òye ìdáǹkanmọ̀—jẹ́ ọ̀nà tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé.”
Ṣíṣètìlẹ́yìn
John, bàbá ọ̀dọ́langba alárùn ADHD kan, sọ fún àwọn òbí tí wọ́n wà nínú ipò jíjọra pé: “Mọ gbogbo ohun tí o bá lè mọ̀ nípa ìṣòro yìí. Ṣe àwọn ìpinnu ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o mọ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, fẹ́ràn ọmọ rẹ, mú kí iyì ara ẹni rẹ̀ dá a lójú. Fífojú àìjámọ́ǹkan wo ara rẹ̀ yóò mú un rẹ̀wẹ̀sì.”
Kí ọmọdé alárùn ADHD lè níṣìírí púpọ̀ tó, àwọn òbí méjèèjì ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Dókítà Gordon Serfontein kọ̀wé pé ó yẹ kí ọmọdé alárùn ADHD “mọ̀ pé, a fẹ́ràn òun nínú ilé àti pé ìfẹ́ náà ń wá láti inú ìfẹ́ tí ó wà láàárín àwọn òbí náà.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ó bani nínú jẹ́ pé a kì í sábà fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Dókítà Serfontein ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “A ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nínú ìdílé tí [ọmọdé alárùn ADHD kan] bá wà, àìṣọ̀kan àti ìwólulẹ̀ máa ń fi nǹkan bí ìdámẹ́ta pọ̀ ju ti inú ìdílé tí kò ti sí lọ.” Láti dènà irú àìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀, bàbá gbọ́dọ̀ kó ipa tó mọ́yán lórí nínú títọ́ ọmọdé alárùn ADHD. A kò gbọ́dọ̀ gbé ẹrù iṣẹ́ náà lé ìyá lórí pátápátá.—Éfésù 6:4; Pétérù Kíní 3:7.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kì í ṣe apá kan ìdílé náà, wọ́n lè ṣèrànwọ́ gidigidi. Lọ́nà wo? John tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Jẹ́ onínúure. Máa wò kọjá ohun tó hàn ní gbangba. Mọ ọmọ náà. Bá àwọn òbí náà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú. Báwo ni wọ́n ti ń ṣe sí? Kí ni wọ́n ń dojú kọ lójoojúmọ́?”—Òwe 17:17.
Àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni lè ṣe púpọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún ọmọdé alárùn ADHD náà àti àwọn òbí rẹ̀ lápapọ̀. Lọ́nà wo? Nípa fífòye báni lò nínú ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún. (Fílípì 4:5) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọmọdé alárùn ADHD kan lè máa da nǹkan rú. Kàkà kí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni tí ó ní ìfòyemọ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà àìgbatẹnirò pé, “O kò ṣe bójú tó ọmọ rẹ?” tàbí “O kò ṣe kúkú bá a wí?” òun yóò mọ̀ pé àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ tí títọ́ ọmọdé alárùn ADHD kan ní nínú lè ti mú ọkàn àwọn òbí náà pòrúurùu. Dájúdájú, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti mú kí ìwà ìbaǹkanjẹ́ ọmọ wọn mọ níwọ̀n. Síbẹ̀síbẹ̀, kàkà kí àwọn tí ó báni tan nínú ìgbàgbọ́ máa fìbínú jágbe mọ́ni, wọ́n gbọ́dọ̀ tiraka láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn, kí wọ́n sì “máa súre.” (Pétérù Kíní 3:8, 9) Ní tòótọ́, Ọlọ́run sábà máa “ń tu àwọn wọnnì tí a mú balẹ̀ nínú” nípasẹ̀ àwọn oníyọ̀ọ́nú onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn.—Kọ́ríńtì Kejì 7:5-7.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé lọ́dọ̀ ọkùnrin kìíní, Ádámù, ni a ti jogún gbogbo àìpé ẹ̀dá ènìyàn, títí kan ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ àti àrùn ADHD. (Róòmù 5:12) Wọ́n tún mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà, yóò mú ìlérí rẹ̀, láti mú ayé tuntun òdodo kan wá, nínú èyí tí àwọn àìsàn tí ń fa ìrora ọkàn kì yóò sí mọ́, ṣẹ. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:1-4) Ìdánilójú yìí jẹ́ ìdákọ̀ró ìṣírí fún àwọn tí wọ́n ní àwọn àrùn bí àrùn ADHD. John sọ pé: “Ọjọ́ orí, ìdálẹ́kọ̀ọ́, àti ìrírí ń ran ọmọkùnrin wa lọ́wọ́ láti lóye àrùn tí ó ní, àti láti bójú tó o. Ṣùgbọ́n kò ní rí ìwòsàn pátápátá nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Ìtùnú wa ojoojúmọ́ ni pé, nínú ayé tuntun, Jèhófà yóò ṣàtúnṣe àrùn tí ọmọkùnrin wa ní, yóò sì mú kí ó lè gbádùn ìgbésí ayé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jí! kò fọwọ́ sí ìtọ́jú pàtó kankan. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti rí i pé irú ìtọ́jú yòó wù kí wọ́n gbà kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.
b Àwọn kan ń nírìírí ìyọrísí búburú tí a kò fẹ́ nítorí lílo egbòogi, ó ní àníyàn àti àwọn ìṣòro ìmọ̀lára mìíràn nínú. Síwájú sí i, lílo egbòogi arùmọ̀lára-sókè lè mú kí ìfàro pọ̀ sí i fún àwọn olùgbàtọ́jú tí ó ní àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì ìfàro iṣan lójijì bí àwọn alárùn Tourette. Nítorí náà, lílo egbòogi ń béèrè àbójútó dókítà kan.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ọ̀rọ̀ Ìṣọ́ra fún Àwọn Òbí
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọmọdé ni kì í pọkàn pọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n ń ṣe nǹkan láìròówò, tí ara wọn kì í sì í balẹ̀. Níní àwọn àbùdá wọ̀nyí kì í fìgbà gbogbo tọ́ka sí àrùn ADHD. Nínú ìwé rẹ̀, Before It’s Too Late, Ọ̀mọ̀wé Stanton E. Samenow sọ pé: “Mo ti rí àìníye ìgbà tí a kì í bá ọmọ kan tí kò fẹ́ ṣe nǹkan kan wí nítorí pé a rò pé ó ní àìpé ara tàbí pé ó wà ní ipò kan tí kì í ṣe ẹ̀bi rẹ̀.”
Ọ̀mọ̀wé Richard Bromfield pẹ̀lú rí i pé ó yẹ láti ṣọ́ra. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, àwọn ènìyàn kan tí ọpọlọ wọn ti dà rú, tí wọ́n sì nílò egbòogi, ni a ti sọ pé àrùn ADHD ni wọ́n ní. Ṣùgbọ́n a ń fi àṣìṣe dárúkọ àrùn náà bíi pé òun ni gbogbo onírúurú ìṣekúṣe, ìwà àgàbàgebè, ìyẹǹkansílẹ̀ àti àwọn ìwà búburú mìíràn tí ń bẹ láàárín àwùjọ, tí wọn kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú àrùn ADHD nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ. Ní tòótọ́, ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àìnílànà nínú ìgbésí ayé òde òní—ìwà ipá àtìgbàdégbà, ìjoògùnyó àti, àwọn kókó abájọ tí kò múni gbọ̀n rìrì tó bẹ́ẹ̀, bí àwọn ilé tí kò ní ìṣètò, tí wọ́n kún fún ìdàrúdàpọ̀—fún araàbalẹ̀ tí ó fara jọ àrùn ADHD lágbára ju bí ìbàjẹ́ èyíkéyìí nínú ọpọlọ ti lè ṣe lọ.”
Nípa bẹ́ẹ̀, Dókítà Ronald Goldberg kìlọ̀ lòdì sí wíwo àrùn ADHD gẹ́gẹ́ bíi “kókó abájọ kan fún gbogbo àmì àrùn.” Ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé, kí a “máa rí i dájú pé gbogbo ìgbésẹ̀ yíyẹ ni a gbé láti ṣàwárí àrùn kí a lè dé orí ìpinnu títọ̀nà.” Àwọn àmì àrùn tí ó fara jọ ti àrùn ADHD lè jẹ́ ti èyíkéyìí lára ọ̀pọ̀ ìṣòro ti ara ìyára tàbí ti ìmọ̀lára. Nítorí náà, a nílò ìrànlọ́wọ́ dókítà tí ó nírìírí gan-an láti ṣàwárí àrùn lọ́nà pípéye.
Kódà, bí a bá tilẹ̀ ṣàwárí àrùn, yóò dára kí àwọn òbí ṣàgbéyẹ̀wò tibitire tí lílo egbòogi ní nínú. Egbòogi Ritalin lè mú àwọn àmì àrùn tí a kò fẹ́ kúrò, ṣùgbọ́n ó tún lè ní ìyọrísí tí a kò retí tẹ́lẹ̀, bí àìróorun-sùntó, hílàhílo tí ó pọ̀ sí i, àti ojora. Nípa bẹ́ẹ̀, Dókítà Richard Bromfield kìlọ̀ pé, kí a má ṣe kánjú jù láti lo egbòogi fún ọmọ kan nítorí kí a lè mú àwọn àmì àrùn rẹ̀ kúrò. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ọmọdé, àti àwọn àgbà tí ń pọ̀ sí i, ni a ń lo Ritalin fún láìyẹ. Nínú ìrírí mi, ó jọ pé lílo Ritalin sinmi lórí bí àwọn òbí àti olùkọ́ bá ti lè fàyè gba ìhùwà ọmọ tó. Mo mọ̀ nípa àwọn ọmọ kan tí a ti lò ó fún, kìkì láti jẹ́ kí ara rọ̀ wọ́n, kì í ṣe láti bójú tó àìní wọn.”
Nítorí náà, àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ yára jù láti sọ pé ọmọ àwọn ní àrùn ADHD tàbí ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí náà, kí wọ́n sì gba ìrànwọ́ amọṣẹ́dunjú kan. Bí ó bá ṣe kedere pé ọmọ kan ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ tàbí àrùn ADHD, àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò láti ní ìmọ̀ dáradára nípa ìṣòro náà, kí wọ́n lè gbégbèésẹ̀ lọ́nà tí yóò ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní jù lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọmọdé alárùn ADHD nílò ìbáwí onínúure tí ó ṣe déédéé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìgbóríyìnfúnni láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí ń kópa pàtàkì gan-an