Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Mo ń kọ́ nípa iṣẹ́ àbójútó ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, mo sì fẹ́ láti gbóríyìn fún yín nítorí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Ó Ha Wà fún Ọ Bí?” (July 22, 1997) Àwọn àpilẹ̀kọ náà ṣe ṣókí, ó kún fún ẹ̀kọ́, ó sì péye lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì. Ẹ kò fọwọ́ sí ẹ̀tanú tí àwọn kan ní àti ariwo tí wọ́n ń pa láìnídìí ẹ̀rù tí àwọn kan ní [proofreader: pls choose one of these expressions] nípa Ìsokọ́ra Alátagbà Internet. Ní ìhà kejì, ẹ kò ṣàìmẹ́nuba àwọn ewu gidi tó ní.
L. E., Ítálì
Mo ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa kọ̀ǹpútà, mo sì sábà máa ń ra àwọn ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa kọ̀ǹpútà, kí n lè máa mọbi tí nǹkan dé dúró. Kò tíì sí èyí tí ó láyà tó láti ṣe bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣàkó nípa àwọn àǹfààní àti ewu Ìsokọ́ra Alátagbà Internet.
A. A. S., Brazil
Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, mo ti ń gbọ́ nǹkan púpọ̀ nípa Ìsokọ́ra Alátagbà Internet, ṣùgbọ́n n kì í lóye wọn dáradára. Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yín ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó rọrùn, tó sì dùn lóye.
A. H., Íńdíà
Ẹ kọ̀wé lọ́nà tí àwọn òǹkàwé tí kò mọ̀ nípa Ìsokọ́ra Web Kárí Ayé pàápàá lè gbà tètè lóye rẹ̀. Ẹ tún ràn wá lọ́wọ́ láti séra ró, kí a sì ṣírò ohun tí lílo ìpèsè yìí yóò náni.
E. K., Etiópíà
Dídánilẹ́bi Ọmọ ọdún 15 ni mí, àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Ó Fi Ń Jẹ́ Ẹ̀bi Mi Nígbà Gbogbo?” (July 22, 1997), mú kí n ṣomi lójú. Èmi ni mo kéré jù nínú ìdílé, wọ́n sì máa ń fòòró ẹ̀mí mi nígbà gbogbo. Ẹ ṣeun tí ẹ kọ̀wé nípa èyí.
N. H., United States
Kòtò Àfonífojì Ńlá Inú mi dùn dẹ́yìn láti ka àpilẹ̀kọ náà, “Kòtò Àfonífojì Ńlá Náà,” (July 22, 1997) lọ́pọ̀ ìgbà. Ńṣe ló dà bí rírin ìrìn àjò kan. Ọkọ mi ti ṣiṣẹ́ ní Áfíríkà rí, mo sì ti láǹfààní láti rìnrìn àjò kan lọ sí ìhà gúúsù Tanzania. N kò gbójú kúrò nínú ìran tí mo ń wò láti ojú fèrèsé ọkọ̀ Land Rover wa. Ohun gbogbo ló ṣe kedere tó sì jojú ní gbèsè ní Áfíríkà; ó tẹ èrò kan tí kò lè pa rẹ́ mọ́ mi lọ́kàn.
B. S., Kánádà
Àwọn Ọmọ Tí Ń Ní Láárí Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kíkọyọyọ náà, “Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ní Láárí.” (August 8, 1997) Ó wúlò fún mi gan-an, ó sì fún mi níṣìírí. Mo ní ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́ta kan, àpilẹ̀kọ yìí sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ojú ìwòye rẹ̀, kí n sì mú ọ̀nà tí mo ń gbà bá a wí dára sí i. Mo dúpẹ́ látọkànwá lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí.
P. S., Ítálì
Àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀rọ̀ Líle, Ọkàn Tí A Ni Lára,” wọ̀ mí lọ́kan gan-an. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi ni mo ti ń ṣàríwísí ara mi. Ó dùn mọ́ mi pé dípò kí ẹ máa ṣàríwísí àwọn tí wọ́n ti forí ti ọ̀pọ̀ ìjìyà, ńṣe ni ẹ gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Kí Jèhófà máa bù kún yín nìṣó, kí ó sì máa ṣatọ́nà kíkọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣàǹfààní, tó sì tuni lára bẹ́ẹ̀.
L. D., Kánádà
Mo nírètí pé àwọn àpilẹ̀kọ náà yóò la ojú àwọn ẹlòmíràn sí ohun tó fa ọ̀pọ̀ lára ìdààmú ọkàn tí ọ̀pọ̀ lára wa ti ní. Ẹ ṣeun fún jíjíròrò kókó ọ̀rọ̀ yìí.
L. B., United States
Àwọn àpilẹ̀kọ bí èyí máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ mi bí olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ́léósinmi dáadáa. Ẹ ṣeun púpọ̀ pé ẹ ń mú kí a máa mọ nǹkan tí ń lọ, ẹ sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sunwọ̀n sí i.
G. R., Mexico
Àwọn àpilẹ̀kọ náà fún mi nírètí. Ìdílé tí nǹkan kò ti gún régé ni mo ti wá, ó sì ṣòro fún mi láti rí ara mi bí ẹni tí ó yẹ láti sin Jèhófà, kí n sì máa bójú tó ọmọbìnrin mi kékeré. N ó sa gbogbo agbára mi láti tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn inú àpilẹ̀kọ náà. Ẹ ṣeun tí ẹ bìkítà.
A. A., United States