Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìwákiri Tí Ẹni Tí A Gbà Ṣọmọ Ṣe Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìrírí náà, “Ìyàlẹ́nu Amúniláyọ̀ Kan.” (February 22, 1997) Ó wọni lọ́kàn gidigidi láti kà nípa bí ọmọkùnrin yìí ṣe rí ìyá tó bí i tí ó sì mọ̀ pé ó tún jẹ́ arábìnrin rẹ̀ nípa ti ẹ̀mí!
M. G. D., Ítálì
Mo ṣomi lójú nígbà tí mo ń ka ìtàn ìgbésí ayé Dana Folz. Àwọn kan gba ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kan ṣọmọ, ó sì ti dàgbà kí ó tó pàdé ìyá tó bí i. Kì í ṣe ìpadàṣọ̀kan aláyọ̀ kan. Kódà lónìí pàápàá, kò ní ìmọ̀lára tó báradé nípa ìdílé wa. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí ìjẹ́pàtàkì fífi sùúrù àti ìfẹ́ hàn sí i.
M. D. L., Ajẹntínà
Mo rí ìwé ìròyìn yín nílé ìwẹ̀ ilé ìṣòwò kan ládùúgbò. Ó ní ọ̀kan lára àwọn ìrírí tó wọni lọ́kàn jù tí mo tí ì kà rí nínú! Nígbà púpọ̀ ni a ti bi mí pé: “Bí a bá lóyún ọmọ kan nípasẹ̀ ìfipábáni-lòpọ̀ ńkọ́? O kò ha gbà pé ìṣẹ́yún ló sàn jù nínú irú ipò wọ̀nyí bí?” Kò sí ìdáhùn jíjágaara kan tí a lè fúnni láti dáàbò bo ìwàláàyè ọmọ tí a kò ì bí náà ju ìṣẹ̀lẹ̀ ojú ayé wíwọnilọ́kàn, ti Dana Folz lọ.
M. P., United States
Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ N Ṣètò Mo jẹ́ òṣìṣẹ́ ààbò ìlú àti mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Àjọṣepọ̀ Ọlọ́pàá àti Ará Ìlú. Mo rí i pé àwọn ìmọ̀ràn tí ẹ dá nípa bí a ṣe lè dáàbò bo ìdílé ẹni lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn gbéṣẹ́, ó sì ṣàǹfààní gan-an. (“Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò—Bí Ó Ṣe Ń Nípa Lórí Rẹ,” nínú ìtẹ̀jáde March 8, 1997) Mo ti jẹ́ kí ìwé ìròyìn náà lọ kárí ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà tó kù nínú ìgbìmọ̀ náà. Ó tuni lára láti mọ̀ pé ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ọ̀daràn yóò dé lọ́jọ́ kan.
C. E. J. A., Nàìjíríà
Àwọn àpilẹ̀kọ náà wúlò ní pàtàkì nítorí pé mo ti ń bá ọkùnrin kan tí ó ti ń kópa nínú ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò fún ọdún 11 tó kọjá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣàlàyé pípé pérépéré nípa jíjá ìdè àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, òun náà lè já ara rẹ̀ gbà bí ó bá pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
A. M., United States
Àwọn Òdòdó Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí, mo sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Òdòdó Ń Fi Hàn Pé Ẹnì Kan Bìkítà.” (March 8, 1997) Ó kọ́ mi bí a ṣe ń ṣètọ́jú àwọn òdòdó kí wọ́n lè wà pẹ́.
L. C., Ítálì
Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń fẹ́ láti mọ bí a ṣe ń dáàbò bo òdòdó, nítorí pé mo fẹ́ràn wọn gan-an. Síbẹ̀, wọ́n wulẹ̀ sábà máa ń wọ́wé kíákíá ni. Àwọn ìmọ̀ràn inú Jí! ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi. Mo dúpẹ́ gidigidi fún iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe.
J. P., Mexico
Ìbí Ìràwọ̀ Àpilẹ̀kọ náà, “Ìbí Ìràwọ̀ Nínú ‘Ìtẹ́’ Idì Kan” (March 8, 1997), mú kí n dúró, kí n ronú díẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá rírẹwà, tí a kò bà jẹ́, tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe. Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni.
J. A., Australia
Ìgbàṣọmọ Àpilẹ̀kọ náà, “Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Àtọkànwá Kan” (March 8, 1997), bá mi mu gẹ́lẹ́. Mo di ìyá tí kò ṣègbéyàwó lọ́mọ ọdún 19. Ó bí ìyá mi nínú, ó sì bà á lọ́kàn jẹ́, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé òun kò láyọ̀ sí ìbí ọmọ náà. Mo pinnu pé ohun tí ó dára jù lọ fún ọmọ mi ni láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn bójú tó o. Lẹ́yìn tí mo di Kristẹni, ọdún 15 ni mo fi gbàdúrà pé kí n bá a pàdé. Láìpẹ́ yìí, a dáhùn àdúrà mi níkẹyìn, mo sì bá a pàdé, mo sì ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú rẹ̀. Ó lóye àwọn àyíká ipò tó mú kí n gbé e sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ dáradára. Ìmọ̀ràn mi fún àwọn obìnrin tó wà nínú ipò yí ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà nìṣó. Bóyá yóò ṣẹlẹ̀ pé ìwọ àti ọmọ rẹ yóò tún pàdé. Bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, Ọlọ́run yóò fún ọ ní ìbàlẹ̀ àyà àti ti ọkàn bí o bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní kíkún.
G. S., United States