ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Òṣì Ń Ní Lórí Àyíká
  • Ewu Àìnírètí
  • Ọ̀pọ̀ Ọdún Lórí Ìrìn
  • Àkókò ní Agbedeméjì Ìlà Oòrùn
  • Àníyàn Nípa Èdè Faransé
  • Wíwá Ọ̀nà Láti Fòpin sí Owó Ẹ̀yìn
  • Àṣà Ìgbàlódé ti Jíjẹ Mùkúlú
  • Ǹjẹ́ A Lè Ṣàtúnṣe Ìbàjẹ́ Tí Sìgá Mímu Ń Fà?
  • Kò Sí Àtúnṣesípò Ojú
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ewu Wo Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Jí!—1998
g98 6/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ipa Tí Òṣì Ń Ní Lórí Àyíká

Láìka ètò ọrọ̀ ajé tó ń dára sí i sí, bílíọ̀nù 1.3 ènìyàn kárí ayé kì í rí tó dọ́là méjì lójúmọ́. Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ àjọ UN sọ pé, kì í ṣe pé òṣì ń bá àwọn ènìyàn fínra nìkan ni, àmọ́ ńṣe ló ń burú sí i. Ó lé ní bílíọ̀nù kan ènìyàn tí owó tí ń wọlé fún wọn nísinsìnyí kò tó èyí tí ń wọlé fún wọn ní 20, 30, tàbí 40 ọdún pàápàá sẹ́yìn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé èyí ń mú kí a máa ba àyíká jẹ́ sí i, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Sources ti àjọ UNESCO ṣe wí, ńṣe ni “òṣì ń fipá mú kí àwọn ènìyàn máa kó àwọn ohun àdánidá láìtọ́ ní kíákíá lọ́nà tí kò lè jẹ́ kí ìsapá ìdáàbòbo àwọn ohun àdánidá bẹ́ẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ kẹ́sẹ járí. Bí nǹkan bá ń lọ bó ṣe ń lọ nísinsìnyí, àwọn igbó ilẹ̀ Carib yóò pòórá kí ó tó tó 50 ọdún sí i . . . Ipò náà tilẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan: Àwọn igbó tó kù ní Philippines kò lè kọjá 30 ọdún, ti Afghanistan kò lè kọjá ọdún 16, ti Lebanon kò sì lè kọjá ọdún 15.”

Ewu Àìnírètí

Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì . . . wí pé àìnírètí lè ṣe ìwọ̀n ìpalára kan náà tí mímu 20 sìgá lóòjọ́ lè ṣe fún ọkàn-àyà. Ìwádìí tí wọ́n fi àwọn ọkùnrin ará Finland tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,000 ṣe fún ọdún mẹ́rin fi hàn pé àìnírètí yọrí sí ewu ìkójọpọ̀ ọ̀rá sínú iṣan ẹ̀jẹ̀, tàbí dídí òpó ẹ̀jẹ̀ gan-an ni.” Ìwádìí náà fi hàn pé ipò èrò orí ẹni lè nípa gidigidi lórí ìlera ẹni. Dókítà Susan Everson, tó jẹ́ aṣáájú nídìí ìwádìí náà, sọ pé: “Léraléra ni a ń rí i pé ipò tí ìrònú àti ìmọ̀lára bá wà ń nípa lórí ìlera. Ó yẹ kí àwọn oníṣègùn mọ̀ pé àìnírètí ń nípa búburú lórí ìlera ó sì ń dá kún ìnira àrùn náà. Ó yẹ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá ń nímọ̀lára àìnírètí, ó yẹ kí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́.”

Ọ̀pọ̀ Ọdún Lórí Ìrìn

Àwọn olùgbé àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ Ítálì ń lo ọ̀pọ̀ àkókò lórí ìrìn lọ síbi iṣẹ́ tàbí sílé ìwé, kí wọ́n sì padà sílé. Báwo ni àkókò náà ṣe pọ̀ tó? Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ agbátẹrù àyíká kan nílẹ̀ Ítálì, Legambiente, ṣe wí, àwọn olùgbé Naples ń lo 140 ìṣẹ́jú lórí ìrìn lójúmọ́. Ká gbà pé ìpíndọ́gba ọdún ìgbésí ayé jẹ́ 74, ẹnì kan tí ń gbé Naples yóò tipa bẹ́ẹ̀ lo ọdún 7.2 ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ìrìn. Ará Róòmù kan tí ń lo ìṣẹ́jú 135 lórí ìrìn lójúmọ́, yóò lo ọdún 6.9. Ipò náà fẹ́rẹ̀ẹ́ burú bákan náà ní àwọn ìlú mìíràn. Àwọn ènìyàn ní Bologna yóò lo ọdún 5.9, àwọn tó n gbé Milan yóò sì lo ọdún 5.3, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn La Repubblica ṣe wí.

Àkókò ní Agbedeméjì Ìlà Oòrùn

Ìyípadà àkókò lè di ohun tí ń díjú pọ̀ ní Agbedeméjì Ìlà Oòrùn. Àpẹẹrẹ kan ni Iran, tí ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé láti ọdún gbọọrọ wá ló ti “ń mú kí agogo rẹ̀ fi wákàtí mẹ́ta àbọ̀ yá ju agogo ibi ìlà Greenwich dípò wákàtí kan, bí ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀ èdè tó kù ti ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ká ní o fẹ́ gbọ́ ìròyìn agogo márùn-ún òwúrọ̀ lórí rédíò BBC, o gbọ́dọ̀ yí rédíò rẹ síbẹ̀ ní agogo mẹ́jọ ààbọ̀ kí o sì sa gbogbo agbára rẹ láti má ka àwọn Ìró Agogo orí rédíò tí ó yàtọ̀ sí ohun tí agogo rẹ ń wí sí.” Nígbà tí ó sì jẹ́ àṣà àgbègbè náà láti máa ṣírò ìyípadà wákàtí kan ṣáájú àkókò gbogbogbòò ní òpin ọ̀sẹ̀ tó bá kẹ́yìn ní September, ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe ìyípadà náà ní September 13, lọ́dún tó kọjá. Ó tún ṣòro láti pinnu òpin ọ̀sẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Páṣíà ń ka Thursday àti Friday bí òpin ọ̀sẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Íjíbítì àti àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè é, Friday àti Saturday ni òpin ọ̀sẹ̀, nígbà tí Lebanon ka Saturday àti Sunday sí òpin ọ̀sẹ̀. Ìwé ìròyìn Times sọ pé: “Ká ní arìnrìn-àjò kan wéwèé láti dé sí Abu Dhabi ní agogo 12 ọ̀sán ọjọ́ Wednesday, kí ó sì wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Beirut nírọ̀lẹ́ Friday, yóò rí i pé òun ní ọjọ́ mẹ́rin bí òpin ọ̀sẹ̀. Ẹni tó bá jẹ́ oníṣẹ́ àṣekúdórógbó wulẹ̀ ní láti yí ìṣètò ìrìn náà padà lásán ni.”

Àníyàn Nípa Èdè Faransé

Ìwé ìròyìn Le Figaro ti Paris ròyìn pé láìpẹ́ yìí ni àwọn aṣojú àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti ń sọ èdè Faransé ṣe àpérò ọlọ́jọ́ mẹ́ta kan ní Hanoi, Vietnam, láti ṣayẹyẹ “bí èdè Faransé ṣe jẹ́ ti kárí ayé.” Àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Faransé déédéé lé ní 100 mílíọ̀nù. Nígbà tí èdè Faransé wà lójú ọpọ́n gan-an ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, òun ni a ń lò fún ọ̀ràn àjọṣe àwọn orílẹ̀-èdè. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ní Yúróòpù tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, èdè Faransé ni a fi ń kọ àwọn àdéhùn tí a fi ń fòpin sí àwọn ogun àti aáwọ̀.” Àmọ́ ní báyìí, èdè Faransé “ń wá àyè rẹ̀ nínú ayé padà.” A lè sọ pé bí èdè Gẹ̀ẹ́sì ṣe ń lókìkí sí i, ní pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí èdè ìṣòwò, ló ń dín ìlò èdè Faransé kù. Nínú ìgbìyànjú kan láti dí àlàfo náà, ààrẹ ilẹ̀ Faransé rọ àwọn ènìyàn láti gbé èdè Faransé lárugẹ lórí kọ̀ǹpútà. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí òṣèlú kan ń sọ àníyàn rẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú èdè Faransé, ó wí pé: “Lílo èdè Faransé jákèjádò àgbáyé kò ru ìfẹ́-ọkàn sókè nínú èrò àwọn ènìyàn, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, tàbí àwọn òṣèlú. Ó ṣeé ṣe kí àìní ìfẹ́-ọkàn yìí ṣeé kíyè sí jù lọ ní orílẹ̀-èdè France gan-an ju ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn lọ.”

Wíwá Ọ̀nà Láti Fòpin sí Owó Ẹ̀yìn

Ní China, wọ́n ń pè é ní huilu; àwọn ará Kẹ́ńyà ń pè é ní kitu kidogo. Ní Mexico, wọ́n ń pè é ní una mordida; Rọ́ṣíà ń pè é ní vzyatka; àwọn ará Agbedeméjì Ìlà Oòrùn sì ń pè é ní baksheesh. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, owó ẹ̀yìn wọ́pọ̀, nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà ṣòwò, tí a lè gbà ní àwọn nǹkan kan, tàbí tí a lè gbà rí ìdájọ́ gbà pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ yìí, àwọn orílẹ̀-èdè 34 ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn láti kásẹ̀ owó ẹ̀yìn nílẹ̀ nínú àwọn ìṣòwò orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè. Àwọn ni àwọn orílẹ̀-èdè 29 tó wà nínú Àjọ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ìdàgbàsókè Ètò Ọrọ̀ Ajé, pẹ̀lú Ajẹntínà, Brazil, Bulgaria, Chile, àti Slovakia. Àwọn tó tún ń gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ìwà ìbàjẹ́ onípò ni àwọn àjọ elétò ìṣúnná gíga jù lágbàáyé—Báńkì Àgbáyé àti Àjọ Àbójútó Ọ̀ràn Owó Lágbàáyé. Wọ́n gbé àwọn ìgbésẹ̀ yìí lẹ́yìn tí ìwádìí kan tí Báńkì Àgbáyé ṣe ti fi hàn pé ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo òwò tí a ń ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè 69 ni a ti ń san owó ẹ̀yìn. Àjọ méjèèjì ti fohùn ṣọ̀kan láti má pèsè owó ìrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ń lọ́wọ́ sí ìwà ìbàjẹ́.

Àṣà Ìgbàlódé ti Jíjẹ Mùkúlú

Tipẹ́tipẹ́ ni mùkúlú mopane ti jẹ́ apá kan oúnjẹ àwọn tálákà tí ń gbé àrọko Gúúsù Áfíríkà, níbi tí àwọn ènìyàn ti gbára lé wọn bí orísun èròjà protein. A sọ mùkúlú mopane tó jẹ́ irú ọmọ kòkòrò emperor lórúkọ yẹn nítorí igi mopane ni oúnjẹ rẹ̀. Ní April àti December, àwọn obìnrin máa ń ṣa mùkúlú náà jọ, lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti yọ wọ́n nínú ilé wọn, wọ́n ń sè wọ́n, wọ́n sì ń sá wọn lóòrùn. A lè fi ìwọ̀n èròjà protein, ọ̀rá, fítámì, àti ohun afáralókun inú wọn wé ti ẹran àti ẹja. Bí ó ti wù kí ó rí, ní báyìí, mùkúlú mopane ti ń di àṣà oúnjẹ tó lòde ní àwọn ilé àrójẹ Gúúsù Áfíríkà. Àṣà ìgbàlódé yìí tún ti gbilẹ̀ dé Yúróòpù àti United States, èyí sì ti kó ìdágìrì bá àwọn olùgbé àrọko ilẹ̀ Áfíríkà. Kí ló fà á? Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Bí a ṣe ń wá irú ọ̀wọ́ náà sí i ni ẹ̀rù túbọ̀ ń bani sí i bóyá yóò máa wà nìṣó.” Ní báyìí ná, “a kò rí mùkúlú mopane mọ́ ní apá ibi púpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè Botswana àti Zimbabwe tó fara kan Gúúsù Áfíríkà.”

Ǹjẹ́ A Lè Ṣàtúnṣe Ìbàjẹ́ Tí Sìgá Mímu Ń Fà?

Ìwádìí àìpẹ́ yìí kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí ìbàjẹ́ tí sìgá mímu ń fà nínú òpó ẹ̀jẹ̀ máà ní àtúnṣe. Nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association, àwọn olùwádìí sọ pé sìgá mímu àti fífimú kó èéfín sìgá tí ẹlòmíràn mu lè ba òpó ẹ̀jẹ̀ jẹ́ láìní àtúnṣe. Àwọn 10,914 ènìyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 45 sí 65 la fi ṣe ìwádìí náà. Àwùjọ náà ní àwọn tí ń mu sìgá, àwọn tó ti ṣíwọ́ sìgá mímu, àti àwọn tí ń fimú kó èéfín sìgá tí àwọn mìíràn ń mu déédéé nínú. Àwọn olùwádìí fi ìró tó kọjá àfetígbọ́ díwọ̀n bí òpójẹ̀ tí ń gbẹ́jẹ̀ lọ sí orí ṣe nípọn tó nínú ọrùn. Wọ́n tún ṣe wíwọ̀n náà lẹ́yìn ọdún mẹ́ta.

Bí wọ́n ti retí, òpójẹ̀ àwọn tí ń mu sìgá déédéé nípọn sí i gan-an—ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ní ti àwọn tó ti mu ìpíndọ́gba páálí sìgá kan lóòjọ́ fún ọdún 33. Òpójẹ̀ àwọn tó ti ṣíwọ́ sìgá mímu tún ń yára nípọn ní ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti àwọn tí kì í mu sìgá rárá lọ—lẹ́yìn tí àwọn kan tilẹ̀ ti ṣíwọ́ sìgá mímu ní 20 ọdún sẹ́yìn. Òpójẹ̀ àwọn tí kì í mu sìgá rárá, àmọ́ tí wọ́n ń fimú kéèéfín sìgá ń nípọn ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ju àwọn tí kì í fimú kéèéfín lọ. Bí ìwádìí náà ṣe fojú bù ú, ní United States nìkan, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ fífimú kéèéfín sìgá tí ẹlòmíràn ń mu ló ń pa 30,000 sí 60,000 ènìyàn lọ́dún.

Kò Sí Àtúnṣesípò Ojú

Lẹ́yìn ọdún méje tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò ère Ṣènìyàn-Ṣẹranko kan tó wà ní Íjíbítì, wọ́n tú àwọn ohun tí wọ́n fi dì í kúrò nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ahmad al-Haggar, olùdarí àkójọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé àdúgbò náà sọ pé: “Wọ́n lo 100,000 òkúta láàárín 1990 sí 1997 láti ṣàtúnṣe ère Ṣènìyàn-Ṣẹranko náà.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó fi kún un pé iṣẹ́ àtúnṣesípò náà kò kan ojú “ère apá-kan-ènìyàn apá-kan-kìnnìún tí wọ́n fi òkúta ẹfun ṣe náà” tó ti bàjẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́