Róbọ́ọ̀tì Kan Ṣàtúpalẹ̀ Pílánẹ́ẹ̀tì Mars
TAYỌ̀TAYỌ̀ ni èmi àti ìdílé mi wòran bí rọ́kẹ́ẹ̀tì tí ń gbé ọkọ̀ àgbéresánmà Mars Pathfinder ṣe gbéra láti ibi tí ó ti ń gbéra ní Cape Canaveral, Florida. A ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ yóò gúnlẹ̀ láyọ̀ sínú pílánẹ́ẹ̀tì Mars? Àwọn àwárí wo ló sì ń bọ̀?’
Àwọn ìrìn àjò àwárí méjì tí àwọn ọkọ̀ àgbéresánmà Mars Observer àti Mars 96 ti rìn lọ sínú pílánẹ́ẹ̀tì Mars láìṣe àṣeyọrí kankan ló ń múni ṣe kàyéfì nípa bóyá ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder yóò ṣàṣeyọrí. Ní àfikún sí i, a pète pé kí ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder gbìyànjú láti balẹ̀ lọ́nà kan tó ṣòro, tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí.
Ọkọ̀ àgbéresánmà náà bẹ̀rẹ̀ sí í wọ àyíká pílánẹ́ẹ̀tì Mars ní nǹkan bí ìwọ̀n ìsáré 27,000 kìlómítà ní wákàtí kan. Lẹ́yìn tí ó ti ta ohun èlò bí abùradà tí yóò mú kí eré rẹ̀ dín kù, tí ó sì wálẹ̀ dé nǹkan bí mítà 98 sí orí pílánẹ́ẹ̀tì Mars, ó yin àwọn rọ́kẹ́ẹ̀tì ẹ̀yìn rẹ̀ kí ó lè túbọ̀ dín ìwọ̀n ìsáré rẹ̀ kù. Nígbà kan náà, a pèsè àwọn àpò afẹ́fẹ́ ńláńlá, tí gáàsì kún inú wọn fún ọkọ̀ àgbéresánmà náà. Ní July 4, 1997, ọkọ̀ àgbéresánmà Mars Pathfinder gúnlẹ̀ sórí pílánẹ́ẹ̀tì Mars, ní ìwọ̀n ìsáré kìlómítà 65 ní wákàtí kan.
Bíbalẹ̀ ti ọkọ̀ àgbéresánmà náà balẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ sọ ọ́ sókè tó mítà 15. Lẹ́yìn tí ó ti balẹ̀ bí ìgbà 15 mìíràn, ó wá dúró jẹ́ẹ́. Àwọn àpò afẹ́fẹ́ náà tú afẹ́fẹ́ inú wọn dà nù, wọ́n sì fà padà sí àyè wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder lọ́nà tí yóò fi lè gúnlẹ̀ sóròó, ẹ̀gbẹ́ òsì ló fi lélẹ̀. Níkẹyìn, ó tú àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bí ti òdòdó jáde, tí ó fi àwọn ohun èlò ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àwọn ọ̀pá rédíò, àwọn àtòpọ̀ bátìrì tí ń bá oòrùn ṣiṣẹ́, àti ọkọ̀ kékeré tí wọ́n ń pè ní Sojourner, tí bátìrì ń gbé ṣiṣẹ́ nínú pílánẹ́ẹ̀tì Mars, hàn.
Ṣíṣèwákiri Nínú Pílánẹ́ẹ̀tì Mars
Láìpẹ́, àwọn kámẹ́rà ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder ṣàyẹ̀wò ojú ilẹ̀ àyíká náà. Ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder fi ojú ilẹ̀ olókùúta tí ó rí págunpàgun àti àwọn òkè jíjìnnà—tí ó dára kí ọkọ̀ Sojourner ṣàwárí rẹ̀—hàn pé ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan tí wọ́n sọ ní Chryse Planitia, tí ó túmọ̀ sí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Wúrà,” nítòsí àgbègbè kan tí wọ́n ń pè ní Ares Vallis, tàbí “Àfonífojì Mars.” A retí pé kí róbọ́ọ̀tì kékeré tó lágbára gan-an yìí, tí ó gùn ní sẹ̀ǹtímítà 65, fi àwọn kámẹ́rà rẹ̀ ṣèwádìí tó ṣeé fojú rí, kí ó sì fi ohun èlò ìdíwọ̀n ìtànṣán kan díwọ̀n bí àwọn èròjà oníkẹ́míkà ṣe pọ̀ tó nínú àwọn àpáta àti ilẹ̀.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tí ń ṣiṣẹ́ náà gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ pẹ̀lú ọkọ̀ Sojourner. Àwọn adarí ẹ̀rọ iṣẹ́ náà kò lè wa ọkọ̀ Sojourner ní tààràtà nítorí pe iṣẹ́ tí a bá rán lórí rédíò, láàárín pílánẹ́ẹ̀tì Ayé àti pílánẹ́ẹ̀tì Mars, ń gba ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú. Nítorí náà, ọkọ̀ Sojourner gbára lé agbára tirẹ̀ fúnra rẹ̀ lọ́nà tó pọ̀ jù láti máa yẹra fún àwọn ewu ojú ilẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì Mars. Ó ń ṣe èyí nípa lílo ìtànṣán alágbára laser láti fi mọ bí àwọn àpáta tó wà lójú ọ̀nà rẹ̀ ṣe tóbi tó àti ibi tí wọ́n wà. Ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà rẹ̀ yóò wá darí rẹ̀ láti kọjá lórí àwọn àpáta náà, tí wọ́n bá kéré tó bẹ́ẹ̀, tàbí kí ó darí rẹ̀ láti ṣẹ́nà gbà, bí wọ́n bá tóbi jù.
Ìdáwọ́lé Eléwu àti Àwárí
Àwọn ìròyìn inú àwọn ìwé ìròyìn ń fi àwọn àwòrán ojú ilẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì Mars tí ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder yà han àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn. Bí àwọn ìran tuntun ṣe ń dé láti inú pílánẹ́ẹ̀tì Mars náà ni a ń fi àwọn kísà tí ọkọ̀ tí ń lọ káàkiri náà ń ṣe dá àwọn ará ayé lára yá, àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère ti ojú ilẹ̀ tó ní ọ̀pọ̀ àpáta àti òkè nínú náà ń ru wọ́n lọ́kàn sókè, àwọn ìran kùrukùru àti wíwọ̀ oòrùn ní òfuurufú pílánẹ́ẹ̀tì Mars sì ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Láàárín oṣù kìíní tí iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀, ojú ìwé Ìgbékalẹ̀ Ìsokọ́ra Alátagbà lórí Internet fún ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder ti ní “ìlóhùnsí” tó lé ní 500 mílíọ̀nù láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìgbòkègbodò ọkọ̀ àgbéresánmà náà.
Ọkọ̀ àgbéresánmà Pathfinder pèsè ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni, tí ó pọ̀ ju ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń ṣe iṣẹ́ náà pàápàá retí lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ láìka ti pé ojú ọjọ́ tutù jù láti ìwọ̀n tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa mú nǹkan dì, ìwọ̀n òdo lórí òṣùwọ̀n Celsius, dé orí ìwọ̀n 80 nísàlẹ̀ òdo. Kí ni ìdáwọ́lé yìí ti fi hàn?
Àwọn kámẹ́rà àti ohun èlò ṣàwárí àwọn àpáta, ilẹ̀, eruku inú afẹ́fẹ́ tó ni onírúurú kẹ́míkà tó para pọ̀, onírúurú àwọ̀, àti onírúurú ànímọ́ ìdáǹkanmọ̀, tí o fi hàn pé a ti ṣe àwọn ìwádìí tó díjú nípa ohun tó para pọ̀ di pílánẹ́ẹ̀tì Mars nínú rẹ̀. Àwọn àgbájọ iyanrìn kéékèèké tó wà láyìíká jẹ́ ẹ̀rí pé afẹ́fẹ́ láti ìhà ìlà oòrùn àríwá ti gbá ekuru iyanrìn jọ síbẹ̀. Òfuurufú náà ní àwọn omi dídì wẹẹrẹ tó di kùrukùru tí ń wà kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí kùrukùru náà ti ń tú ká tí ilẹ̀ sì ń mọ́, òfuurufú náà ní àwọ̀ pupa nítorí àwọn eruku kíkúnná tó wà nínú afẹ́fẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, màjàsà, ìjì afẹ́fẹ́ àti iyanrìn, ń kọjá lórí ọkọ̀ àgbéresánmà náà.
Ọkọ̀ àgbéresánmà Mars Pathfinder ti fún wa ní ìrírí ohun tó wà lẹ́yìn òde ayé wa. United States àti Japan ń wéwèé láti dáwọ́ lé ìrìn àjò ìwádìí sínú pílánẹ́ẹ̀tì Mars sí i jálẹ̀jálẹ̀ ẹ̀wádún tí ń bọ̀. Ọkọ̀ àgbéresánmà tí ń yí pílánẹ́ẹ̀tì po kan tí ń jẹ́ Mars Global Surveyor ti dé sí pílánẹ́ẹ̀tì Mars láti ṣe àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn. Dájúdájú, a óò túbọ̀ máa di ojúlùmọ̀ pílánẹ́ẹ̀tì Mars bí a ṣe ń fi ọkọ̀ àgbéresánmà róbọ́ọ̀tì rìnrìn àjò nínú pílánẹ́ẹ̀tì pupa náà.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Gbígbéra
Bíbalẹ̀
Lórí Pílánẹ́ẹ̀tì Mars
[Credit Line]
Gbogbo àwòrán: NASA/JPL