ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/8 ojú ìwé 20-23
  • Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láìséwu Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láìséwu Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kọ́ Ọmọdé Náà
  • Kọ́ Ajá Náà
  • Ajá Rírorò
  • Bí Ajá Ṣe Ń Gbóòórùn
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Ohun Ọ̀sìn Àtàtà Ni àbí Panipani Ẹhànnà?
    Jí!—2002
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Ajá Mi Ló Ń Gbọ́rọ̀ fún Mi!
    Jí!—1999
Jí!—1997
g97 7/8 ojú ìwé 20-23

Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láìséwu Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ bí?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

SYDNEY ọmọ ọdún méjì ṣeré sún mọ́ ajá rírorò kan, tí ó jẹ́ ẹ̀yà Rottweiler, tí wọ́n so mọ́lẹ̀, jù. Ajá náà gbéjà kò ó, ó ya awọ orí Sydney, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gé etí òsì rẹ̀ já. Ọmọdékùnrin náà yóò nílò ọ̀wọ́ àwọn àfirọ́pò awọ.

Nítorí pé àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ti ń lo ajá fún ààbò, a ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nípa àwọn ajá tí ń ṣe àwọn ọmọdé léṣe. Àwọn ajá kan tí a ti mọ̀ pé wọ́n máa ń gé àwọn ọmọdé jẹ ni ẹ̀yà Rottweiler, ẹ̀yà Doberman pinscher, bullmastiff, ẹ̀yà Alsatian (àwọn olùṣọ́ àgùntàn Germany), àti àwọn bullterrier. Ìwádìí kan tí a ṣe ní Gúúsù Áfíríkà fi hàn pé lára àwọn ọ̀ràn tí a gbé yẹ̀ wò, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé tí ajá bù jẹ ló jẹ́ àwọn ajá tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ló ṣe wọ́n léṣe. Iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn ló jẹ́ pé ajá àwọn aládùúgbò wọn ló bù wọ́n jẹ, ìdámẹ́rin lára wọn sì ni ajá tiwọn bù jẹ. Àwọn ajá tí wọ́n sọ nù ni a mú fún ìpín 10 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìṣeléṣe náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, òjìyà ìpalára náà ti mú ajá náà bínú ní ọ̀nà kan, láìmọ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ìṣeléṣe ajá ni a lè yẹra fún bí àwọn olówó ajá àti àwọn òbí bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ ṣíṣekókó kan.

Kọ́ Ọmọdé Náà

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ń kọ́ ajá lẹ́kọ̀ọ́ tẹnu mọ́ ọn pé, a kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn ajá sílẹ̀ láwọn nìkan láìsí àbójútó àgbàlagbà. Àwọn ọmọ kéékèèké kò mọ bí a ṣe ń hùwà sí ajá. A gbọ́dọ̀ kọ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fi ìlànà náà sílò pé, bí àgbàlagbà tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ kan kò bá lè sí lárọ̀ọ́wọ́tó, a óò fi àwọn ajá sí ibi tó yàtọ̀ síbi tí àwọn ọmọ kéékèèké wà. Olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ náà, Brian Kilcommons, sọ nínú ìwé náà, Childproofing Your Dog, pé: “Láti inú àwọn ìròyìn tí a ń gbọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìṣòro ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn àgbàlagbà kò bá fojú síbẹ̀.”

Lọ́pọ̀ ìgbà, a ní láti dáàbò bo àwọn ẹranko kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọdé! Wọ́n ké sí Kilcommons fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ajá ìdílé kan pa kuuru mọ́ ọmọdé kan. Bàbá tí ìpayà bá náà ṣàlàyé pé, ọmọkùnrin òun ọlọ́dún méjì ààbọ̀ sáré lọ sọ́dọ̀ ajá náà níbi tí ó sùn sí, ó sì ta á nípàá gidigidi. Ajá náà, tí ó hàn gbangba pé ó wà nínú ìrora, dáhùn pa dà ní pípa kuuru mọ́ ọmọdé náà. Nínú ipò yí, ajá náà ṣàkóso ara rẹ̀ lọ́nà tí ó yẹ kí a gbóríyìn fún nípa ṣíṣàì bu ọmọ náà jẹ. Olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ yìí gbani nímọ̀ràn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ ṣe ohun tí o kò ní jẹ́ kí ó ṣe fún ọmọ mìíràn fún ajá kan.”

Kọ́ ọmọ rẹ bí a ti ń ṣe àwọn ẹranko jẹ́jẹ́. Kọ́ ọ láti má ṣe yọ ajá kan lẹ́nu. Ó yẹ kí àwọn òbí wà lójúfò láti rí ewukéwu tó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọdé àti àwọn ajá bá wà pọ̀. Bí o bá ṣàkíyèsí pé ajá náà ń gbìyànjú láti sá lọ tàbí láti sá pamọ́ fún ọmọ kan, ní kí ọmọ náà yé lé e mọ́. Bí ọmọ náà bá tẹ̀ lé ajá náà, tí ó sì ká a mọ́ kọ̀rọ̀, ohun ìgbèjà kan ṣoṣo tí ó ku ajá náà kù ni gbígbó, kíkùn hùnnùhùnnù, tàbí bíbunijẹ pàápàá. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa pèsè ìbáwí léraléra, kí ajá àti ọmọ pẹ̀lú lè mọ̀ pé òbí náà kò ṣeré.

Má ṣe bá ajá náà lò bí ohun àṣátì. Bí tọkọtaya kan tí wọ́n ní ajá kan bá bí àkọ́bí ọmọ wọn, ìtẹ̀sí náà lè wà pé kí wọ́n pa ajá náà tì, kí wọ́n sì lé e dà nù sí ẹ̀yìnkùlé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu láti lo ìṣọ́ra, olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ náà, Richard Stubbs, gbani nímọ̀ràn pé: “A kò gbọ́dọ̀ bá ajá náà lò bí ohun àṣátì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ajá náà máa bá ìgbòkègbodò rẹ̀ lọ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kí ẹ sì fún un ní àfiyèsí tí ó pọ̀ tó.”

Ronú nípa bí ọmọ rẹ yóò ṣe hùwà pa dà sí àjèjì ajá. Bí ó bá rí àjèjì kan tí ń mú ajá kan lọ ní ojú pópó, kí ni yóò ṣe? Yóò ha kù gbù sáré lọ láti fọwọ́ pa ajá náà lára bí? Kọ́ ọ láti má ṣe èyí. Ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gba àṣẹ lọ́wọ́ olówó ajá náà. Lẹ́yìn náà, bí olówó ajá náà bá gbà, ó lè sún mọ́ ajá náà díẹ̀díẹ̀, kí ó má baà dẹ́rù bà á. Ó yẹ kí ó fi ara rẹ̀ hàn nípa dídúró síbi tí ó jìnnà díẹ̀, kí ó sì fara balẹ̀ bá ajá náà sọ̀rọ̀. Ajá tí ó jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ yóò sún mọ́ ọmọ rẹ. Ó sàn jù lọ láti má ṣe sún mọ́ àwọn ajá tí wọ́n bá ń rìn lójú pópó láìsí ẹnì kan pẹ̀lú wọn rárá.—Wo àpótí náà, “Ìfarasọ̀rọ̀ Ajá,” ojú ìwé 22.

Kọ́ Ajá Náà

Máa gbóríyìn fún ajá rẹ nígbà gbogbo, sì máa wọ̀nà fún rere. Ìfìyàjẹ àti ọ̀rọ̀ adánilágara kì í mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ yára, àmọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ní ìyọrísí òdì kejì. Ó dára kí ajá kan kọ́ láti wá tí a bá pè é, kí ó sì ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ ìpìlẹ̀ bíi “jókòó!” Ajá náà ń kọ́ títẹríba fún ọ̀gá rẹ̀, èyí sì ń jẹ́ kí olówó rẹ̀ lè darí rẹ̀ dáradára nínú àwọn ipò tí ó le koko. Àwọn ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ ṣókí-ṣókí máa ń gbéṣẹ́ jù lọ. Máa lo àwọn irú ọ̀rọ̀ kan náà. Nígbà tí ajá rẹ bá ṣe ohun tí o fẹ́, san án lẹ́san kan lójú ẹsẹ̀, bí ìgbóríyìn, fífọwọ́ pa á lára, tàbí kí o fún un ní awẹ́ oúnjẹ kan tí ó yàn láàyò. Láti rí ipa afúnnilókun tí o nífẹ̀ẹ́ sí, o gbọ́dọ̀ san án lẹ́san náà lójú ẹsẹ̀ lẹ́yìn tí ó ṣe ohun náà. Ipa tí ó tún ṣe pàtàkì ni àṣetúnṣe títí tí ìhùwàsí rẹ̀ yóò fi fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in.

Bí o bá ní ajá kan, yálà ọmọ ajá tàbí àgbà ajá kan, ó lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti lè máa ṣe dáradára sí àwọn ọmọdé. Àwọn ọmọdé máa ń hùwà lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí ọ̀nà tí àwọn àgbàlagbà ń hùwà. Wọ́n máa ń pariwo jù, wọ́n sì túbọ̀ máa ń hùwà láìronújinlẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n sáré mọ́ ajá kan, èyí sì lè dẹ́rù bà á. Ó dára láti jẹ́ kí irú àwọn ìhùwà ṣíṣàjèjì bẹ́ẹ̀ mọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ lára. Nígbà tí àwọn ọmọ kò bá sí nílé, fi ariwo òjijì kọ́ ajá náà. Sọ ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà di eré àṣedárayá. Pa àṣẹ kan fún ajá náà, kí o sì pa kuuru mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, san ajá rẹ lẹ́san lójú ẹsẹ̀. Mú kí ariwo rẹ máa ga sókè sí i díẹ̀díẹ̀. Máa parí rẹ̀ sí yíyin ohun ọ̀sìn rẹ àti fífọwọ́ pa á lára. Láìpẹ́, yóò máa gbádùn eré àṣedárayá yìí.

Àwọn ọmọ kéékèèké fẹ́ràn láti máa gbá ajá mọ́ra, àmọ́, ó yẹ kí a kọ́ wọn láti máà máa ṣe èyí, nítorí pé irú ìfarakanra pẹ́kípẹ́kí bẹ́ẹ̀ máa ń dẹ́rù ba àwọn ajá kan. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọdé máa ń gbá ajá rẹ mọ́ra, o lè kọ́ ajá náà láti gba èyí. Gbá ajá rẹ mọ́ra fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà, fún un ní awẹ́ oúnjẹ kan tí ó yàn láàyò, kí o sì yìn ín. Jẹ́ kí àkókò tí o fi ń gbá a mọ́ra máa gùn sí i díẹ̀díẹ̀. Bí ajá rẹ bá ń kùn hùnnùhùnnù tàbí tí ó ń kanra mọ́ni tìbínútìbínú, wá ìrànlọ́wọ́ olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ tí ó tóótun.

Ajá Rírorò

Ó jọ pé àwọn ajá kan rorò láti ilẹ̀ wá, wọ́n sì lè jẹ́ ewu fún àwọn mẹ́ńbà agbo ilé. Ó ṣeé ṣe kí àwọn akọ ajá ní àwọn àmì ànímọ́ ìwà rírorò wọ̀nyí jù lọ.

Ajá tí ń jẹ gàba kì í fẹ́ kí a di òun mú, pàápàá jù lọ ní àwọn àgbègbè ara tí ó ṣẹlẹgẹ́ bí iwájú àti ọrùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn àkókò míràn, ajá náà lè wá bá ọ, kí ó fara tì ọ́, tàbí kí ó tilẹ̀ gbé ìkúùkù rẹ̀ lé ọ lẹ́sẹ̀, kí ó máa “béèrè” àfiyèsí. Ó lè dáàbò bo àwọn ibi pàtàkì kan nínú ilé, kí ó tilẹ̀ má gba àwọn mẹ́ńbà ìdílé láyè láti dé ibẹ̀. Ó sábà máa ń rakaka lé àwọn nǹkan bí ohun ìṣiré, ó sì lè kùn hùnnùhùnnù tàbí kí ó dáwọ́ dídeyín mọ́ àwọn ohun ìṣiré náà dúró tí a bá lọ bá a nígbà tí ó ń fi wọ́n ṣeré lọ́wọ́.

Láti lè fún ipò ìbátan wọn lókun, irú àwọn ajá bẹ́ẹ̀ yóò mọ̀ọ́mọ̀ kọtí ikún sí àwọn àṣẹ tí ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n lè rọ́ lu àwọn ọmọdé tàbí kí wọ́n retí láti jẹ́ ẹni tí yóò kọ́kọ́ gba ẹnu ọ̀nà kan kọjá. Wọ́n tún lè ní ìtẹ̀sí láti gun ènìyàn. Brian Kilcommons sọ pé, èyí jẹ́ “ìwà ìjẹgàba,” bẹ́ẹ̀ ni “kì í ṣe nípa ìbálòpọ̀.” Ó kìlọ̀ pé, èyí “máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ àmì pé ajá náà ń ronú pé òun lọ̀gá. Ó dájú pé wàhálà ń bọ̀ lọ́nà.” Ajá náà tún lè ní àṣà gbígbé ọwọ́ olówó rẹ̀ sẹ́nu láti gba àfiyèsí.

A kò gbọ́dọ̀ kọtí ikún sí àwọn àmì ìwà òǹrorò wọ̀nyí. Ìwà òǹrorò náà kò wulẹ̀ ní lọ; ó ṣeé ṣe kí ó pọ̀ sí i, àwọn ọmọ tí wọ́n wà nílé sì lè wà nínú ewu. Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ dámọ̀ràn títẹ irú ajá bẹ́ẹ̀ lọ́dàá, láìka ẹ̀yà tí ó lè jẹ́ sí, níwọ̀n bí èyí ti ń jẹ́ kí ìwà òǹrorò dín kù ní gbogbogbòò.

Kò bọ́gbọ́n mu láti pe ajá rírorò kan níjà láti fi ẹni tí ó jẹ́ ọ̀gá hàn án. Gbígbéjà ìrorò kò ó àti ìbáwí lọ́nà tí ń dáni lágara lè léwu, ní gidi. Lọ́nà tí ó túbọ̀ jáfáfá, a lè fi ẹni tí ó jẹ́ ọ̀gá han ajá náà.

Gbogbo ìgbà tí ajá rírorò kan bá wá bá ọ fún àfiyèsí, tí o sì fún un, ńṣe ni o ń fún èrò ajá náà, pé oun lọ̀gá, lókun. Nítorí náà, nígbà tí irú ajá bẹ́ẹ̀ bá béèrè fún àfiyèsí, máà dá a lóhùn. Ìdílé lódindi gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní bíbá a lò lọ́nà yí. Lákọ̀ọ́kọ́, ṣìbáṣìbo yóò bá ajá náà, ó sì tilẹ̀ lè gbó, kí ó sì wò ọ́ lọ́nà tí ń wúni lórí, àmọ́ dènà ìdánwò láti juwọ́ sílẹ̀ fún un. Nígbà tí ó bá jáwọ́, tí ó sì ṣeé ṣe pé ó lọ dọ̀bálẹ̀ sí àyè rẹ̀, ìgbà yẹn ni àkókò láti fún un ní àfiyèsí díẹ̀. Lọ́nà yí, ajá rẹ ń kẹ́kọ̀ọ́ pé ìwọ ni olórí, ìwọ ni o sì pinnu ìgbà tí a fún un láfiyèsí.

Àwọn eré àṣedárayá líle bíi fàmí-n-fà-ọ́, àti gídígbò lè fún àwọn ìtẹ̀sí ìjẹgaba ajá náà níṣìírí, a sì gbọ́dọ̀ yẹra fún èyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, fi àwọn eré àṣedárayá tí kò ní ìtẹ̀sí òǹrorò rọ́pò rẹ̀.

Ó sàn jù kí ajá náà máà máa sùn nínú iyàrá. Iyàrá jẹ́ ibi àyè àǹfààní kan, sísùn síbẹ̀ sì lè gbé ipò tí ajá náà ń finú rò ga ju ti àwọn ọmọ lọ nínú ilé náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbé ibùsùn ajá náà sí ilé ìgbọ́únjẹ tàbí sí ilé ajá níta. Inú iyàrá ni àwọn ajá rírorò ti sábà máa ń kọ́kọ́ gé àwọn olówó wọn jẹ.

Bí ajá rẹ kò bá hùwà pa dà sí àwọn ìsapá rẹ, tàbí bóyá tí o bá nímọ̀lára pé ó ń halẹ̀ mọ́ ọ nígbà tí o bá ń kọ́ ọ, tàbí ní àkókò míràn, ní kí olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ tí ó tóótun kan wá ràn ọ́ lọ́wọ́. Olùtọ́jú-ẹranko rẹ lè dámọ̀ràn ẹnì kan. Kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí ó máa ń gbà kọ́ ajá, sì rí i dájú pé inú rẹ dùn sí ìtóótun rẹ̀ kí o tó gbà á. Olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ náà, Richard Stubbs, kìlọ̀ pé: “Nígbà tí ajá rírorò kan lè gbọ́ ẹ̀kọ́ amọṣẹ́dunjú olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ kan, èyí kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé yóò ṣe bákan náà pẹ̀lú olówó rẹ̀.” Olówó ajá náà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun lè máa darí ajá rẹ̀ ní àwọn ipò lílekoko.

Àwọn ajá díẹ̀ yóò ṣì rorò kódà lẹ́yìn kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára jù lọ, níní wọn nílé sì ń fi ìdílé sínú ewu. Lẹ́yìn kíkọ́ ajá náà bí o ti lè ṣe tó, o lè ronú pé ó sàn jù láti jọ̀wọ́ ajá náà ju wíwà nínú ewu ìpalára. Ó dára láti kàn sí olùtọ́jú-ẹranko tàbí olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ kan fún ìmọ̀ràn. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti rí ilé mìíràn tí ajá rẹ lè lọ gbé, àmọ́ lọ́nà àdánidá, ó di dandan fún ọ láti sọ fún olówó rẹ̀ tuntun nípa àwọn ìṣòro tí o ti ní pẹ̀lú ajá náà.

Olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ náà, Peter Neville, gbani nímọ̀ràn pé: “A gbọ́dọ̀ bá àwọn ajá ajẹgàba lò pẹ̀lú àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà tí a fìṣọ́ra ṣe gidigidi àti pẹ̀lú àyẹ̀wò àfìṣọ́raṣe nípa ẹni tí yóò máa wà nínú ewu lọ àti bí yóò ti pọ̀ tó. Bí kò bá sí ẹ̀rí ìdánilójú ààbò fún ẹni tí ó wà nínú ewu jù lọ nínú ìdílé, nígbà náà, ó sàn jù láti mú ajá náà lọ sí ilé mìíràn, sọ́dọ̀ ẹni tí yóò jẹ́ olówó rẹ̀ tuntun, tí a fìṣọ́ra yàn, tàbí kí a pa á.”

Àwọn ọmọdé lè kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì lè jàǹfààní ní ti èrò ìmọ̀lára láti inú níní àwọn ajá gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn. Nípa pípèsè àbójútó tí ó níláárí, àwọn òbí ń ṣèrànwọ́ láti rí i dájú pé gbogbo ohun tí àwọn ọmọ wọn ń rántí nípa àwọn ohun ọ̀sìn wọn jẹ́ ohun ayọ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Ìfarasọ̀rọ̀ Ajá

Ìhùwàsí ajá rírorò ń fi àwọn èrò aláìjẹ́-bí-ọ̀rẹ́ hàn. Nípa kíkọ́ ọmọ rẹ̀ láti mọ ọ̀nà ìfarasọ̀rọ̀ ajá yìí, o lè ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ipò eléwu.

● Ajá rírorò yóò gbìyànjú láti ṣe bíi pé ó tóbi sí i. Irun ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀ lè dìde dúró ṣánṣán. Ajá náà lè kùn hùnnùhùnnù tàbí kí ó gbó, kí ó sì na ìrù rẹ̀ sókè gbọọrọ. Bí ìrù rẹ̀ bá ń jù fìrìfìrì bí èyí tí a ru sókè, ní líle gbagidi, kò fi ipò ìbániṣọ̀rẹ́ hàn. A kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ajá yìí.

● Ajá tí ń bẹ̀rù lè dàyà délẹ̀, kí ó gbé orí àti etí rẹ̀ lélẹ̀, kí ó sì gbé ìrù rẹ̀ lélẹ̀ tàbí sáàárín àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀. Bí a bá sún mọ́ ajá yìí, ìbẹ̀rù lè mú kí ó jà. Máà sún mọ́ ọn.

● Ajá tí ara rẹ̀ balẹ̀ máa ń dúró ní gbígbé orí rẹ̀ sókè láìga jù tàbí láìlọsílẹ̀ jù, yóò la ẹnu rẹ̀ sílẹ̀, ìrù rẹ̀ yóò sì fi díẹ̀ lọ sísàlẹ̀ ilà ẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ kò ní gbé e sílẹ̀. Ìrù tí ń jù náà jẹ́ àmì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́. Ní gbogbogbòò, kò léwu láti ba ajá yìí ṣọ̀rẹ́.

(A ṣàmúlò rẹ̀ láti inú ìwé náà, Childproofing Your Dog, tí Brian Kilcommons àti Sarah Wilson ṣe.)

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ààbò Ajá

1. Bójú tó àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn ajá.

2. Kọ́ ọmọ rẹ láti má ṣe yọ ajá lẹ́nu.

3. Gba àṣẹ lọ́wọ́ olówó àjèjì ajá kan kí o tó fọwọ́ pa á lára.

4. Kọ́ ajá rẹ láti ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ ìpìlẹ̀ kan.

5. Fi gbígbé ajá mọ́ra kọ́ ajá rẹ.

6. Yẹra fún àwọn eré àṣedárayá tí ó mú ìwà òǹrorò dání.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́