Ajá Mi Ló Ń Gbọ́rọ̀ fún Mi!
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
“MI Ò rò pé mo lè dá ṣe nǹkan kan tí ò bá sí ajá kékeré mi nítòsí!” Ohun tí Dorothy sọ nìyẹn, bó ti ń fi tìfẹ́tìfẹ́ wo ajá aláwọ̀ funfun àdàpọ̀ mọ́ àwọ̀ ilẹ̀, tó jẹ́ ẹ̀yà àdàlù Jack Russell, tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ síbi tó dọ̀bálẹ̀ sí lábẹ́ àga obìnrin náà. “Oṣù mélòó kan péré ni Twinkie dé ọ̀dọ̀ mi, àmọ́ ó ti sọ ayé dẹ̀rọ̀ fún mi!”
Nígbà tí mo wò ó dáadáa, mo rí i pé aṣọ aláwọ̀ ìyeyè kan wà lọ́rùn Twinkie, ó lẹ̀ pẹ́kí mọ́ ọn lára, wọ́n sì fi ọ̀dà dúdú kọ ọ̀rọ̀ gàdàgbà-gàdàgbà sára rẹ̀ pé “AJÁ TÍ Ń GBỌ́RỌ̀ FÚN ADITÍ.” ‘Ẹranko àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni!’ Ohun tí mo rántí pé mo ń rò nínú mi nìyẹn. ‘Kí ló lè ṣe?’
A ṣèèṣì pàdé láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì ènìyàn tí wọ́n wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbáyé “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní July ọdún tó kọjá ní London, England, ni. Nípa jíjókòó sítòsí gbohùngbohùn kan, ó ṣeé ṣe fún Dorothy láti gbọ́ àwọn ìjíròrò tó wáyé nípàdé náà, nítorí náà, kí ló tún fẹ́ fi ajá tí ń gbọ́rọ̀ fúnni ṣe? Nígbà tí èmi àti Dorothy jókòó tí a ń sọ̀rọ̀ lákòókò ìsinmi ló sọ nípa ara rẹ̀ fún mi.
Iṣẹ́ Twinkie
Etí Dorothy di gan-an ni, èyí sì ṣẹlẹ̀ sí i lákòókò tí ibà aromọléegun ṣe é nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta. Látìgbà tí ọkọ ẹ̀ ti kú lọ́dún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn, ńṣe ló ń dá gbé, àmọ́, Dorothy ṣàlàyé pé, òun nílò ju alábàákẹ́gbẹ́ lọ bí òun ṣe ń dàgbà sí i. Ó sọ pé: “Àwọn adití máa ń nímọ̀lára àìláàbò gan-an tí wọ́n bá wà ní ọjọ́ orí mi. Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin ni mí, kíátikà ló ń bójú tó ilé tí mo ń gbé, ṣùgbọ́n ìgbàkigbà tí kíátikà bá ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi, n kì í gbọ́ tó bá ń kanlẹ̀kùn. Ńṣe ló máa rò pé ara mi ò yá, á bá wọlé láìjẹ́ pé mo mọ̀; ìyẹn sì máa ń bà mí lẹ́rù gan-an. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Twinkie máa ń gbọ́ tí èèyàn kan bá ń kanlẹ̀kùn, á wá lù mí lẹ́sẹ̀ pẹ́pẹ́pẹ́, á sì mú mi lọ sídìí ilẹ̀kùn. Bákan náà, tí Twinkie bá gbọ́ tí agogo tó wà lára ẹ̀rọ ìdáná mi ń dún, á sáré wá bá mi, èmi náà á sì tẹ̀ lé e. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé nǹkan ń ṣèéfín tàbí tí agogo ìdágìrì iná bá ń dún, wọ́n ti kọ́ Twinkie bí yóò ṣe pe àfiyèsí mi, kí ó sì dọ̀bálẹ̀ láti fi hàn pé ewu ń bọ̀. Ìgbàkigbà tó bá ràn mí lọ́wọ́, mo máa ń fún un ní oúnjẹ aládùn tó fẹ́ràn gan-an.”
Fífòye Kọ́ Ọ Lẹ́kọ̀ọ́
Mo fẹ́ rídìí ọ̀rọ̀. Mo béèrè pé: “Báwo ni ajá náà ṣe di tiẹ̀, ta ló kọ́ ọ?” Ìyẹn ló fún Dorothy láǹfààní láti sọ nǹkan kan fún mi nípa Àjọ Tí Ń Pèsè Ajá Tí Ń Gbọ́rọ̀ fún Àwọn Adití, àjọ ọlọ́rẹ àánú kan tí ète wọn jẹ́ láti ran àwọn adití ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́wọ́ láti túbọ̀ lómìnira, kí ayé sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹ̀rọ̀ fún wọn. Láti ọdún 1982 wá, wọ́n ti fún àwọn tí wọ́n dití ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ajá. Bí wọ́n bá ti kọ́ ajá náà dáadáa, wọ́n á mú un lọ fún olówó ẹ̀ tí yóò gbà á sọ́dọ̀, lọ́fẹ̀ẹ́.
Àwọn ajá tí a máa ń yàn sábà máa ń jẹ́ àwọn ajá tó sọ nù, tí wọ́n máa ń lọ gbà ní àwọn ilé iṣẹ́ tó rí wọn he, tó wà jákèjádò ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ àwọn kan wà tí àwọn tó ń sìn wọ́n fi tọrẹ. Ó máa ń gbà tó ọdún kan láti kọ́ ajá kan. Ọrẹ ẹni tó ṣonígbọ̀wọ́, yálà ilé iṣẹ́ tàbí ẹgbẹ́ kan tí a pa owó díẹ̀díẹ̀ tí wọ́n fi tọrẹ pọ̀, ni wọ́n máa ń fi sanwó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Dorothy sọ fún mi pé ẹgbẹ́ kan tí ń dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè fọn, ló ṣenúure, tó sì sanwó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Twinkie.
Tí wọ́n bá ti yan ajá èyíkéyìí láti lò fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀, tó máa ń jẹ́ nǹkan bí ọmọ oṣù méje sí ọdún mẹ́ta, wọ́n á kọ́ ọ bí yóò ṣe máa ṣe tó bá gbọ́ àwọn ìró kan. Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n á mú un fún olùkọ́ni-níwà-yíyẹ, ẹnì kan tó yọ̀ǹda láti mú ajá náà lọ sílé fún nǹkan bí oṣù méjì sí mẹ́jọ, níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti ìrírí ajá náà. Kíkọ́ ọ níwà yíyẹ lè ní àwọn ẹ̀kọ́ ilé pàtàkì nínú, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni fífojú ajá náà mọ àwọn ibi tí èrò ń pọ̀ sí àti ọkọ̀ ìrìnnà, kó sì jẹ́ kó mọ onírúurú ènìyàn tí ọjọ́ orí wọ́n yàtọ̀ síra, títí kan àwọn ọmọdé àti ìkókó. Ètè èyí jẹ́ láti kọ́ ajá náà láti ṣe bó ṣe yẹ lọ́nà tí wọ́n fi máa tẹ́wọ́ gbà á ní ilé èyíkéyìí tí wọ́n bá mú un lọ níkẹyìn.
Ní àfikún sí i, mo gbọ́ pé àwọn àjọ mìíràn máa ń fi ajá ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ní àìní àkànṣe. Bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ajá wọ̀nyí láti ṣe ohun tí a bá ní kí wọ́n ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ń jẹ́ kí wọ́n rí àwọn ohun pàtó kan, kí wọ́n sì gbọ́ àwọn òórùn pàtó kan. Ajá ẹ̀yà retriever kan tó ń bójú tó obìnrin kan tó ń lo àga arọ ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pé kó máa bá obìnrin náà gbé tẹlifóònù, kó sì máa lọ kó lẹ́tà fún un, kó sì máa fitọ́ sí sítáǹpù tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ lẹ́tà! Ajá mìíràn máa ń ṣe oríṣi ọgọ́fà nǹkan tí wọ́n bá ní kó ṣe, ó tilẹ̀ máa ń bá a mú agolo, àti páálí nǹkan lórí pẹpẹ ilé ìtajà ńlá. Olówó rẹ̀ tó jẹ́ abirùn máa ń lo ìtànṣán kan láti tọ́ka sí ohun tó fẹ́, ajá rẹ̀ yóò sì mú un fún un.
Alájọgbé Tí Ń Mọ́kàn Yọ̀
Mo béèrè pé: “Ṣé gbogbo èèyàn ló mọyì Twinkie?” Dorothy fèsì pé: “Olùtajà kan kò jẹ́ kí ajá mi wọlé. Mo rò pé nítorí pé ó kó àwọn ohun jíjẹ kan sórí àtẹ rẹ̀ ni, àmọ́ ohun tó ṣe yẹn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, nítorí pé kò mọ ìdí tí mo fi nílò Twinkie.”
Mo ti wá lóye bí ajá tí ń gbọ́rọ̀ fúnni ti ṣeyebíye tó nínú ilé, àmọ́ ìbéèrè mi kùkan. Àǹfààní wo ni Twinkie ń ṣe fún Dorothy nígbà tó ní ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú wọn? Dorothy ṣàlàyé pé: “Mo máa ń mọ ohun tí ẹnì kan ń sọ tí mo bá ń wo ẹnu rẹ̀, ẹ̀rọ tí mo ń fi sétí gbọ́rọ̀ sì ń ràn mí lọ́wọ́ láti lè máa gbọ́rọ̀ ẹni tó bá ń bá mi jíròrò. Bí àwọn èèyàn bá wo aṣọ aláwọ̀ ìyeyè tó wà lọ́rùn Twinkie, wọ́n á mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé adití ni mí. Nígbà náà ni wọ́n á wá kọjú sí mi sọ̀rọ̀ bí wọ́n bá ṣe lè sọ ọ́ kó dún ketekete tó. Nípa bẹ́ẹ̀, mi ò ní máa ṣàlàyé ìṣòro tí mo ní, ìyẹn sì ń mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún mi.”
Ìpàdé ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀, Twinkie sì fẹ́ rìn kiri kó tó wá jókòó fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán. Kí n tó máa lọ, mo bẹ̀rẹ̀, mo sì fọwọ́ pa ajá náà lára. Twinkie gbé ojú rẹ̀ tó ṣe rekete sókè, ó wo Dorothy, ó sì ń jùrù. Ọ̀rẹ́ rúbútú onígbọràn yìí mà kúkú wúlò o—wọ́n sì mọwọ́ ara wọn gan-an!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 45]
Ìrànlọ́wọ́ tí Twinkie ń ṣe ní àwọn àpéjọpọ̀ kì í ṣe kékeré