Àwọn Kristian Obìnrin yẹ fún Ọlá àti Ọ̀wọ̀
“Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé . . . ní ìbámu pẹlu ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.”—1 PETERU 3:7.
1, 2. (a) Ìdàníyàn wo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Jesu pẹ̀lú obìnrin ará Samaria létí kànga fà, èésìtiṣe? (Tún wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni Jesu ṣàṣefihàn rẹ̀ nípa wíwàásù fún obìnrin ará Samaria?
NÍ ÌDÍ kànga àtijọ́ kan lẹ́bàá ìlú-ńlá Sikari ní ìgbà òṣùpá ní apá ìparí 30 C.E., Jesu ṣí bí ó ti lérò pé a gbọ́dọ̀ bá àwọn obìnrin lò payá. Ó ti lo òwúrọ̀ láti rìn jákèjádò Samaria orílẹ̀-èdè olókè náà ó sì darí wá sí ìdí kànga pẹ̀lú àárẹ̀, ebi, àti òùngbẹ. Bí ó ti jókòó sẹ́bàá kànga náà, obìnrin ará Samaria kan wá láti fa omi. Jesu wí fún un pé: “Fún mi mu.” Obìnrin náà ti níláti wò ó pẹ̀lú ìyàlẹ́nu. Ó béèrè pé: “Èétirí tí iwọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Júù ni ọ́, fi ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo jẹ́ obìnrin ará Samaria?” Lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ra oúnjẹ, ó yà wọ́n lẹ́nu, ní ṣíṣe kàyéfì nípa ìdí tí Jesu fi “ń bá obìnrin sọ̀rọ̀.”—Johannu 4:4-9, 27.
2 Kí ni ó fa ìbéèrè obìnrin yìí àti àníyàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn? Ó jẹ́ ará Samaria, àwọn Júù kì í sìí ní ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samaria. (Johannu 8:48) Ṣùgbọ́n ẹ̀rí fi hàn pé ìdí mìíràn wà fún àníyàn náà. Ní àkókò náà, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi kò fún kí àwọn ọkùnrin máa bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba ní ìṣírí.a Síbẹ̀, Jesu wàásù ní gbangba fún obìnrin olóòótọ́-ọkàn yìí, ó tilẹ̀ ṣí i payá fún un pé òun ni Messia náà. (Johannu 4:25, 26) Jesu tipa báyìí fi hàn pé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, títí kan àwọn wọnnì tí ń rẹ àwọn obìnrin sílẹ̀ kò lè ká òun lọ́wọ́ kò. (Marku 7:9-13) Ní òdìkejì rẹ̀, nípa ohun tí ó ṣe àti nípa ohun tí ó fi kọ́ni, Jesu fi hàn pé àwọn obìnrin ni a gbọ́dọ̀ bálò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀.
Bí Jesu Ṣe Bá Àwọn Obìnrin Lò
3, 4. (a) Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà sí obìnrin tí ó fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀? (b) Báwo ni Jesu ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn Kristian ọkùnrin, pàápàá ní pàtàkì àwọn alábòójútó?
3 Ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jesu ní fún àwọn ènìyàn hàn nínú ọ̀nà tí ó gbà hùwà sí àwọn obìnrin. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan obìnrin kan tí ó ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún 12 wá Jesu kiri láàárín èrò. Ipò tí ó wà mú kí ó jẹ́ aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀, nítorí náà kò yẹ kí ó wà níbẹ̀. (Lefitiku 15:25-27) Ṣùgbọ́n ó gbékútà tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi yọ́ lọ sẹ́yìn Jesu. Nígbà tí ó fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, ara rẹ̀ yá lọ́gán! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń lọ sí ilé Jairu, ẹni tí ọmọbìnrin rẹ̀ wà ní bèbè ikú, Jesu dúró. Níwọ̀n bí ó ti nímọ̀lára pé agbára jáde lọ lára òun, ó wò yíká láti wá ẹni tí ó fọwọ́ kàn òun. Paríparí rẹ̀, obìnrin náà jáde wá ó sì wólẹ̀ sí iwájú rẹ̀ ó ń wárìrì. Jesu yóò ha bá a wí fún wíwà láàárín èrò tàbí fún fífọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ láì gbàṣẹ bí? Kàkà bẹ́ẹ̀, obìnrin náà rí i pé ó lọ́yàyà ó sì jẹ́ onínúrere. Ó sọ pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Èyí ni ìgbà kanṣoṣo tí Jesu tọ́ka sí obìnrin ní tààràtà gẹ́gẹ́ bí “ọmọbìnrin.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn yóò ti mú ọkàn rẹ̀ balẹ̀ tó!—Matteu 9:18-22; Marku 5:21-34.
4 Jesu wò rékọjá ohun tí Òfin sọ. Ó rí ẹ̀mí tí ó wà lẹ́yìn rẹ̀ àti ìdí fún àánú àti ìyọ́nú. (Fiwé Matteu 23:23.) Jesu ṣàkíyèsí àyíká ipò ìgbékútà obìnrin aláìsàn náà ó sì ronú pé ìgbàgbọ́ ni ó sún un. Ó tipa báyìí fi àpẹẹrẹ dídára lélẹ̀ fún àwọn Kristian ọkùnrin, ní pàtàkì àwọn alábòójútó. Bí Kristian arábìnrin kan bá ń dojúkọ àwọn ìṣòro ti ara-ẹni tàbí ìṣòro kan tí ó lekoko tàbí tí ń dánniwò gidigidi, àwọn alàgbà níláti gbìyànjú láti wò rékọjá àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìwà ojú-ẹsẹ̀ kí wọ́n sì ronú nípa àyíká ipò àti ète ìsúnniṣe. Irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ lè fi hàn pé sùúrù, òye, àti ìyọ́nú ni ó nílò dípò ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà.—Owe 10:19; 16:23; 19:11.
5. (a) Ní ọ̀nà wo ni àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi ṣe ká àwọn obìnrin lọ́wọ́ kò? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.) (b) Àwọn wo ni ẹni àkọ́kọ́ láti rí àti láti jẹ́rìí sí àjíǹde Jesu?
5 Nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi tí ó há wọn mọ́, àwọn obìnrin tí ń gbé nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé ni a kálọ́wọ́kò láti máṣe ṣe ẹlẹ́rìí lábẹ́ òfin.b Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí a jí Jesu dìde kúrò nínú òkú ní òwúrọ̀ Nisan 16, 33 C.E. Ta ni yóò kọ́kọ́ rí Jesu tí a jí dìde tí yóò sì jẹ́rìí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù pé a ti jí Oluwa wọn dìde? Ó yọrí sí pé àwọn obìnrin tí wọ́n ti dúró níbi tí kò jìnnà sí ibi tí wọ́n ti kàn án mọ́gi títí tí ó fi gbẹ́mìímì ni.—Matteu 27:55, 56, 61.
6, 7. (a) Kí ni Jesu sọ fún àwọn obìnrin tí wọ́n wá sí ibojì? (b) Báwo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ṣe hùwàpadà lákọ̀ọ́kọ́ sí ẹ̀rí tí àwọn obìnrin jẹ́, kí sì ni a lè rí kọ́ lára èyí?
6 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ọ̀sẹ̀, Maria Magdalene àti àwọn obìnrin mìíràn lọ sí ibojì pẹ̀lú àwọn ìpara olóòórùn dídùn láti fi pa Jesu lára. Nígbà tí wọ́n ríi pé ibojì náà ṣófo, Maria sáré lọ sọ fún Peteru àti Johannu. Àwọn obìnrin yòókù dúró síbẹ̀. Láìpẹ́, áńgẹ́lì kan yọ sí wọn ó sì sọ fún wọn pé a ti jí Jesu dìde. Áńgẹ́lì náà fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ẹ . . . lọ ní kíákíá kí ẹ sì sọ fún awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.” Bí àwọn obìnrin wọ̀nyí ti ń sáré lọ láti lọ jẹ́ iṣẹ́ náà, Jesu fúnra rẹ̀ yọ sí wọn. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún awọn arákùnrin mi.” (Matteu 28:1-10; Marku 16:1, 2; Johannu 20:1, 2) Láìmọ̀ nípa ìbẹ̀wò áńgẹ́lì náà, tí ẹ̀dùn-ọkàn sì ti bò ó mọ́lẹ̀, Maria Magdalene padà lọ sí ibojì tí ó ṣófo náà. Jesu yọ sí i níbẹ̀, nígbà tí Maria sì ti dá a mọ̀ níkẹyìn, ó sọ pé: “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n lọ sọ́dọ̀ awọn arákùnrin mi kí o sì wí fún wọn pé, ‘Emi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín ati sọ́dọ̀ Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’”—Johannu 20:11-18; fiwé Matteu 28:9, 10.
7 Jesu ti lè kọ́kọ́ yọ sí Peteru, Johannu, tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yàn láti ṣojúrere sí àwọn obìnrin wọ̀nyí nípa fífi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí olùfojúrí àkọ́kọ́ fún àjíǹde rẹ̀ àti nípa pípa á láṣẹ fún wọn láti jẹ́rìí nípa rẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ọkùnrin. Báwo ni àwọn ọkùnrin náà ṣe kọ́kọ́ hùwàpadà? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àsọjáde wọnyi farahàn bí ìsọkúsọ lójú wọn wọn kò sì gba awọn obìnrin naa gbọ́.” (Luku 24:11) Ó ha jẹ́ pé ó ṣòro fún wọn láti gba ìsọfúnni náà gbọ́ nítorí pé ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó yá wọ́n rí ẹ̀rí tí ó pọ̀ yanturu gbà pé a ti jí Jesu dìde kúrò nínú ikú. (Luku 24:13-46; 1 Korinti 15:3-8) Lónìí, àwọn Kristian ọkùnrin ń hùwà pẹ̀lú ọgbọ́n nígbà tí wọ́n bá gba àkíyèsí àwọn arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí rò.—Fiwé Genesisi 21:12.
8. Kí ni Jesu ṣípayá nípa ọ̀nà tí ó gbà hùwà sí àwọn obìnrin?
8 Ó jẹ́ ohun tí ó mọ́kànyọ̀ nítòótọ́ láti kíyèsí ọ̀nà tí Jesu gbà hùwà sí àwọn obìnrin. Ní gbogbo ìgbà ni ó máa ń fi ìyọ́nú hàn tí ó sì máa ń wà déédéé délẹ̀délẹ̀ nínú ìhùwà rẹ̀ sí àwọn obìnrin, kò gbé wọn ga bẹ́ẹ̀ ni kò fojúkéré wọn rí. (Johannu 2:3-5) Ó kọ̀ láti faramọ́ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi tí ó gba iyì wọn tí ó sì sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun di asán. (Fiwé Matteu 15:3-9.) Nípa bíbá àwọn obìnrin lò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀, Jesu ṣí bí Jehofa Ọlọrun ṣe ronú pé ó yẹ kí a bá wọn lò payá ní tààràtà. (Johannu 5:19) Jesu tún fi àpẹẹrẹ tí ó gbámúṣé lélẹ̀ fún àwọn Kristian ọkùnrin láti tẹ̀lé.—1 Peteru 2:21.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Jesu Nípa Àwọn Obìnrin
9, 10. Báwo ni Jesu ṣe já àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi nípa àwọn obìnrin níkoro, kí sì ni ó sọ lẹ́yìn tí àwọn Farisi gbé ìbéèrè kan dìde nípa ìkọ̀sílẹ̀?
9 Jesu já ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi ní koro ó sì gbé iyì fún àwọn obìnrin kì í ṣe nínú ìṣe rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò, ohun tí ó fi kọ́ni nípa ìkọ̀sílẹ̀ àti panṣágà.
10 Nípa ìkọ̀sílẹ̀, a bi Jesu ní ìbéèrè yìí pé: “Ó ha bófinmu fún ọkùnrin lati kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?” Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Marku, Jesu sọ pé: “Ẹni yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ [bíkòṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè] tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i, bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹlu òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.” (Marku 10:10-12; Matteu 19:3, 9) Àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ wẹ́rẹ́ wọ̀nyẹn fi ọ̀wọ̀ hàn fún iyì àwọn obìnrin. Báwo ni ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
11. Ọ̀rọ̀ Jesu náà “bíkòṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè” fi kí ni hàn nípa ìdè ìgbéyàwó?
11 Àkọ́kọ́ ni pé, nípa ọ̀rọ̀ náà “bíkòṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè” (tí a rí nínú àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere Matteu), Jesu fi hàn pé ìdè ìgbéyàwó ni a kò gbọdọ̀ fi ojú kékeré wò tàbí fàjá túẹ́. Ẹ̀kọ́ àwọn rabi tí ó gbòdekan fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan bíi pé kí ìyàwó ba oúnjẹ jẹ́ tàbí pé kí ó bá ọkùnrin àjèjì sọ̀rọ̀. Họ́wù, ìkọ̀sílẹ̀ ni a tilẹ̀ fàyè gbà bí ọkọ kan bá rí obìnrin tí ó wọ̀ ọ́ lójú! Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli kan ṣàkíyèsí pé: “Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ bí ó ṣe sọ ọ́ yìí ó . . . ń gbèjà àwọn obìnrin nípa gbígbìyànjú láti mú ìgbéyàwó wá sí ipò tí ó yẹ kí ó wà.” Nítòótọ́, ìgbéyàwó yẹ kí ó jẹ́ àjọṣepọ̀ kan tí ó wà gbére nínú èyí tí obìnrin kan ti lè nímọ̀lára ìbalẹ̀-ọkàn.—Marku 10:6-9.
12. Nípa ọ̀rọ̀ náà “ṣe panṣágà lòdì sí i,” ìpilẹ̀ èrò wo ni Jesu ń nasẹ̀ rẹ̀?
12 Èkejì ni pé, nípa ìsọjáde náà “ṣe panṣágà lòdì sí i,” Jesu nasẹ̀ ojú-ìwòye kan tí ilé-ẹjọ́ rabi kò tẹ́wọ́gbà—ìpìlẹ̀-èrò náà pé ọkọ kan ṣe panṣágà lòdì sí aya rẹ̀. Ìwé The Expositor’s Bible Commentary ṣàlàyé pé: “Nínú ìsìn àwọn Júù ti rabi obìnrin kan nípa àìṣòótọ́ lè ṣe panṣágà lòdì sí ọkọ rẹ̀; ọkùnrin kan sì lè, ṣe panṣágà lòdì sí ọkùnrin mìíràn, nípa níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó ọkùnrin náà. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan kò lè ṣe panṣágà lòdì sí ìyàwó rẹ̀, ohun yòówù kí ó ṣe. Nípa fífi ọkùnrin sábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe kan náà pẹ̀lú obìnrin níti ìwàhíhù, Jesu gbé ipò àti iyì àwọn obìnrin ga.”
13. Nípa ìkọ̀sílẹ̀, báwo ni Jesu ṣe fi hàn pé lábẹ́ ètò-ìgbékalẹ̀ Kristian, ọ̀pá-ìdiwọ̀n kan ni yóò wà fún àtọkùnrin àtobìnrin?
13 Ẹ̀kẹta ni pé, nípa àpólà-ọ̀rọ̀ náà “lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀,” Jesu mọ ẹ̀tọ́ obìnrin láti kọ ọkọ aláìṣòótọ́ sílẹ̀—àṣà tí a mọ̀ dájúdájú ṣùgbọ́n tí kò wọ́pọ̀ lábẹ́ òfin Júù ní àkókò náà.c Wọ́n sọ pé “obìnrin kan ni a lè kọ̀ sílẹ̀ bóyá ó tẹ́ ẹ lọ́rùn tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n níti ọkùnrin kìkì bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Bí ó ti wù kí ó rí, bí Jesu ti sọ, lábẹ́ ètò-ìgbékalẹ̀ Kristian, ọ̀pá-ìdiwọ̀n kan náà ni a óò lò fún àtọkùnrin àtobìnrin.
14. Kí ni Jesu gbé yọ nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀?
14 Àwọn ẹ̀kọ́ Jesu ní kedere ṣí àníyàn tí ó jinlẹ̀ fún ire àwọn obìnrin payá. Nítorí náà, kò ṣòro láti lóye ìdí tí àwọn obìnrin kan fi nímọ̀lára irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Jesu débi pé wọ́n bìkítà fún àwọn àìní rẹ̀ láti ara ohun-ìní wọn. (Luku 8:1-3) Jesu sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣugbọn ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Johannu 7:16) Nípasẹ̀ ohun tí ó fi kọ́ni, Jesu fi ìgbatẹnirò oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jehofa ní fún àwọn obìnrin hàn.
“Ẹ Máa fi Ọlá fún Wọn”
15. Kí ni aposteli Peteru kọ nípa ọ̀nà tí àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ gbà bá aya wọn lò?
15 Aposteli Peteru ṣàyẹ̀wò ní tààràtà ọ̀nà tí Jesu gbà hùwà sí àwọn obìnrin. Ní nǹkan bí 30 ọdún lẹ́yìn náà, Peteru fún àwọn aya ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ ó sì kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé ní irú-ọ̀nà kan naa ní ìbámu pẹlu ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ̀yin tún ti jẹ́ ajogún ojúrere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́sí pẹlu wọn, kí àdúrà yín má baà ní ìdílọ́wọ́.” (1 Peteru 3:7) Kí ni ohun tí Peteru ní lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ náà “ẹ máa fi ọlá fún wọn”?
16. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-orúkọ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ọlá”? (b) Báwo ni Jehofa ṣe bọlá fún Jesu nígbà ìpaláradà rẹ̀, kí sì ni a rí kọ́ láti inú èyí?
16 Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí olùtúmọ̀-èdè kan sọ, ọ̀rọ̀-orúkọ Griki náà tí a pè ní “ọlá” (ti·meʹ) túmọ̀ sí “iye-owó, ìníyelórí, ọlá, ọ̀wọ̀.” Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ Griki yìí ni a pè ní “ẹ̀bùn” àti “iyebíye.” (Ìṣe 28:10; 1 Peteru 2:7) Bí a bá ṣàyẹ̀wò bí Peteru ṣe lo ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ kan náà nínú 2 Peteru 1:17, a óò rí ìjìnlẹ̀ òye sínú ohun tí ó túmọ̀ sí láti bọlá fún ẹnì kan. Níbẹ̀ ni ó ti sọ ní ìtọ́kasí ìpaláradà Jesu pé: “Oun gba ọlá ati ògo lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ògo ọlọ́lá-ńlá gbé awọn ọ̀rọ̀ bí irú iwọnyi wá fún un pé: ‘Èyí ni ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí emi tìkára mi ti fi ojúrere tẹ́wọ́gbà.’” Nígbà ìpaláradà Jesu, Jehofa bọlá fún Ọmọkùnrin rẹ̀ nípa sísọ ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà Jesu, Ọlọrun sì sọ èyí ní etígbọ̀ọ́ àwọn mìíràn. (Matteu 17:1-5) Nígbà náà, ọkùnrin tí ó bá bọlá fún aya rẹ̀, kò ní tẹ́ ẹ lógo tàbí rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fi hàn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀—ní kọ̀rọ̀ àti ní gbangba—pé òun gbé e ga.—Owe 31:28-30.
17. (a) Èéṣe tí ọlá fi yẹ fún àwọn Kristian aya? (b) Èéṣe tí ọkùnrin kan kò fi gbọdọ̀ ronú pé òun níyelórí ju obìnrin lọ lójú Ọlọrun?
17 Ọlá yìí, ni Peteru sọ pé, àwọn Kristian ọkọ níláti ‘fi fún’ àwọn aya wọn. Èyí ni a níláti ṣe, kì í ṣe bí ojúrere, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn aya wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí. Èéṣe tí àwọn aya fi lẹ́tọ̀ọ́ sí irú ọlá bẹ́ẹ̀? Peteru ṣàlàyé pé nítorí “ẹ̀yin tún . . . jẹ́ ajogún ojúrere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́sí pẹlu wọn.” Ní ọ̀rúndún kìn-ínní C.E., gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n gba lẹ́tà Peteru ni a pè ní ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. (Romu 8:16, 17; Galatia 3:28) Wọn kò ní ẹrù-iṣẹ́ kan náà nínú ìjọ, ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn gbẹ́yín wọn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6) Bákan náà, lónìí, nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ènìyàn Ọlọrun ní ìrètí orí ilẹ̀-ayé, yóò jẹ́ àṣìṣe ńláǹlà fún Kristian ọkùnrin èyíkéyìí láti rò pé nítorí àǹfààní tí òun lè ní nínú ìjọ, òun níyelórí lójú Ọlọrun ju àwọn obìnrin lọ. (Fiwé Luku 17:10.) Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní ìdúró kan náà nípa tẹ̀mí lójú Ọlọrun, nítorí ikú ìràpadà Jesu ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àǹfààní kan náà fún àtọkùnrin àtobìnrin—èyí ni dídi ẹni tí a dásílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun ní iwájú wọn.—Romu 6:23.
18. Ìdí tí ó pọndandan wo ni Peteru fún ọkọ kan láti bọlá fún aya rẹ̀?
18 Peteru fún wa ní ìdí mìíràn tí ó fi di dandan fún ọkọ kan láti bọlá fún aya rẹ̀, “kí àdúrà [rẹ̀] má baà ní ìdílọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ náà “ní ìdílọ́wọ́” wá láti inú ọ̀rọ̀-ìṣe Griki náà (en·koʹpto) tí ó túmọ̀ ní òwuuru si “láti jálù.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Expository Dictionary of New Testament Words ti Vine ti sọ, “a ń lò ó fún dídí ẹnì kan lọ́wọ́ nípa bíba ọ̀nà jẹ́, tàbí nípa gbígbé ohun ìdìgbòlù tí ó lágbára sí ojú ọ̀nà.” Nípa báyìí, ọkọ kan tí ó kùnà láti bọlá fún aya rẹ̀ lè rí i pé ohun ìdènà kan wà láàárín àdúrà òun àti kí Ọlọrun gbọ́ ọ. Ọkùnrin náà lè nímọ̀lára àìtóótun láti tọ Ọlọrun lọ, tàbí Jehofa lè má ní inúdídùn sí títẹ́tísílẹ̀. Ó ṣe kedere pé, Jehofa dàníyàn gidigidi nípa bí àwọn ọkùnrin ṣe bá àwọn obìnrin lò.—Fiwé Ẹkun Jeremiah 3:44.
19. Báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin nínú ìjọ ṣe lè ṣiṣẹ́sìn papọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún tọ̀túntòsì?
19 Àìgbọdọ̀máṣe ti fífi ọlá hàn kò mọ sọ́dọ̀ àwọn ọkọ nìkan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ níláti bọlá fún aya rẹ̀ nípa bíbá a lò pẹ̀lú ìfẹ́ àti pẹ̀lú iyì, aya kan níláti bọlá fún ọkọ rẹ̀ nípa wíwà ní ìtẹríba kí ó sì fi ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ hàn. (1 Peteru 3:1-6) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Paulu gba àwọn Kristian nímọ̀ràn láti ‘bu ọlá fún ara wọn lẹ́nìkínní kejì.’ (Romu 12:10) Èyí jẹ́ ìpè fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin nínú ìjọ láti ṣiṣẹ́sìn papọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ fún tọ̀túntòsì. Nígbà tí irú ẹ̀mí báyìí bá gbilẹ̀, àwọn Kristian obìnrin kì yóò sọ̀rọ̀ jáde ní ọ̀nà tí ń jin ọlá-àṣẹ àwọn tí ń mú ipò iwájú lẹ́sẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́wọ́ti àwọn alàgbà wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn. (1 Korinti 14:34, 35; Heberu 13:17) Níti wọn, àwọn Kristian alábòójútó yóò bá “awọn àgbà obìnrin” lò “gẹ́gẹ́ bí ìyá, awọn ọ̀dọ́ obìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹlu gbogbo ìwàmímọ́.” (1 Timoteu 5:1, 2) Pẹ̀lú ọgbọ́n, àwọn alàgbà yóò fi ìgbatẹnirò onínúrere hàn sí ohùn àwọn Kristian arábìnrin wọn. Nípa báyìí, nígbà tí arábìnrin kan bá fi ọ̀wọ̀ hàn fún ipò orí ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ó sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ìbéèrè tàbí tí ó tilẹ̀ tọ́ka sí ohun kan tí ó ń béèrè àfiyèsí, àwọn alàgbà yóò fi pẹ̀lú ìdùnnú ronú lórí ìbéèrè tàbí ìṣòrò rẹ̀.
20. Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́, báwo ni a ṣe níláti bá àwọn obìnrin lò?
20 Láti ìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní Edeni, àwọn obìnrin nínú ọ̀pọ̀ àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ni a ti rẹ̀sílẹ̀ sí ipò àìlọ́lá. Ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe irú ìbálò tí Jehofa pète láti ilẹ̀ wá fún wọn láti ní ìrírí rẹ̀. Ojú-ìwòye àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ sí àwọn obìnrin yòówù kí ó gbilẹ̀, àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti Griki fi hàn ní kedere pé àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run ni a níláti bálò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀. Ó jẹ́ ẹ̀tọ́ tí Ọlọrun fi fún wọn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé gbédègbẹyọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Àwọn obìnrin kì í bá àwọn àlejò ọkùnrin jẹun, a kò sì fún àwọn ọkùnrin ní ìṣírí láti máa bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀. . . . Bíbá obìnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba ní pàtàkì jẹ́ ìwà láìfí atinilójú.” Ìwé The Mishnah ti àwọn Júù, tí ó jẹ́ àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn rabi, gbani nímọ̀ràn pé: “Sọ̀rọ̀ mọníwọ̀n pẹ̀lú àwọn obìnrin. . . . Ẹni tí kò bá sọ̀rọ̀ mọníwọ̀n pẹ̀lú àwọn obìnrin ń mú ègún wá sí orí ara rẹ̀ ó sì ń ṣàìnáání ìkẹ́kọ̀ọ́ Òfin yóò sì jogún Gehenna nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.”—Aboth 1:5.
b Ìwé náà Palestine in the Time of Christ sọ pé: “Nínú àwọn ọ̀ràn kan, obìnrin ni a wò bí ọgbọọgba pẹ̀lú ẹrú. Fún àpẹẹrẹ, kò lè jẹ́rìí ní ilé-ẹjọ́, yàtọ̀ sí láti jẹ́rìí sí ikú ọkọ rẹ̀.” Ní títọ́ka sí Lefitiku 5:1, ìwé The Mishnah ṣàlàyé pé: “[Òfin nípa] ‘ìbúra ìjẹ́rìí’ kan ọkùnrin ṣùgbọ́n kì í ṣe obìnrin.”—Shebuoth 4:I.
c Òpìtàn Júù ọ̀rúndún kìn-ínní Josephus ròyìn pé Salome arábìnrin Ọba Herodu rán ọkọ rẹ̀ ní “àkọsílẹ̀ kan tí ń tú ìgbéyàwó wọn ká, èyí tí kò bá òfin àwọn Júù mu. Nítorí ọkùnrin (nìkan) ni a fàyè gbà láti ṣe èyí.”—Jewish Antiquities, XV, 259 [vii, 10].
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fi hàn pé Jesu bá àwọn obìnrin lò pẹ̀lú ọlá àti ọ̀wọ̀?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ Jesu ṣe fi ọ̀wọ̀ hàn fún iyì àwọn obìnrin?
◻ Èéṣe tí ọkọ kan fi níláti bọlá fún Kristian aya rẹ̀?
◻ Àìgbọdọ̀máṣe láti fi ọlá hàn wo ni gbogbo àwọn Kristian ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Sí ìdùnnú wọn, àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run ní ẹni àkọ́kọ́ tí ó rí Jesu tí a jí dìde náà, ẹni tí ó ní kí wọ́n jẹ́rìí nípa èyí fún àwọn arákùnrin rẹ̀