“Awọn Obinrin Ti Wọn Nṣiṣẹ Kára Ninu Oluwa”
“Ẹ ki Tirifena ati Tirifosa, awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kára ninu Oluwa.”—ROOMU 16:12, NW.
1. Ni ọna wo ni iṣẹ-ojiṣẹ Jesu ti ori ilẹ-aye gbà jasi ibukun fun awọn obinrin?
IṢẸ-OJIṢẸ Jesu lori ilẹ-aye jẹ ibukun nitootọ fun awọn obinrin Juu. Iṣẹ ti oun bẹrẹ yoo mu itunu, ireti ati iyì wa fun awọn obinrin ẹya iran gbogbo. Oun ko kọbiara si awọn ẹkọ atọwọdọwọ isin Juu awọn ti o “sọ ofin Ọlọrun di asan.” (Matiu 15:6) Ọpọlọpọ ninu awọn ẹkọ atọwọdọwọ wọnni tako awọn ẹtọ ipilẹ ti Ọlọrun fifun awọn obinrin.
Iṣarasihuwa Jesu Si Awọn Obinrin
2. Eeṣe ti a fi le sọ pe ọna ti Jesu gba huwa si awọn obinrin jẹ iyipada patapata fun akoko naa?
2 Ẹ wo iyatọ gédégédé ti o wa laaarin iṣarasihuwa Jesu si awọn obinrin ati ti awọn aṣaaju isin Juu! Lati fa ọrọ Encyclopaedia Judaica yọ, awọn onitibi ka awọn obinrin si “wọbia, olófòófó, ọlẹ, ati ojowu.” Ijumọsọrọpọ pẹlu obinrin ni a ko fọwọsi, ati pe “o jẹ ohun itiju fun ọmọwe kan lati sọrọ pẹlu obinrin ni opopona.” (Jerusalem in the Time of Jesus, lati ọwọ Joachim Jeremias; fiwe Johanu 4:27.) Pupọpupọ ni a le sọ nipa iṣesi ti o kun fun ẹgan ti awọn aṣaaju isin Juu si awọn obinrin. Ṣugbọn eyi ti o wà loke ti to lati fihan bi ọna ti Jesu gba huwa si awọn obinrin ṣe jẹ iyipada patapata nitootọ fun akoko wa.
3. Awọn iṣẹlẹ wo nigba iṣẹ-ojiṣẹ Jesu ni o fihan pe oun muratan lati kọ́ awọn obinrin ni awọn otitọ tẹmi jijinlẹ?
3 Jesu pese apẹẹrẹ pipe ti bi awọn ọkunrin ṣe le ni ipo ibatan ọlọyaya sibẹ ti o jẹ oniwa mimọ pẹlu awọn obinrin. Kii ṣe kiki pe oun ba wọn sọrọ nikan ṣugbọn oun tun kọ wọn ni awọn otitọ tẹmi jijinlẹ. Nitootọ, ẹni akọkọ ti oun ṣipaya ipo Mesaya rẹ fun ni gbangba jẹ obinrin kan, ti o tun wa jẹ obinrin ara Samaria. (Johanu 4:7, 25, 26) Siwaju sii, iṣẹlẹ ti o mu Mata ati Maria lọwọ fihan kedere pe laidabi awọn aṣaaju isin Juu, Jesu ko nimọlara pe obinrin ko ni ẹtọ lati fi idi ìkòkò ati abọ́ silẹ fun igba diẹ ki o ba le mu imọ tẹmi rẹ pọ si. Ni akoko yẹn, Maria “yan ipa rere naa,” ni fifi awọn nǹkan tẹmi ṣe akọkọ. (Luuku 10:38-42) Ṣugbọn oṣu diẹ lẹhin naa, lẹhin ti arakunrin wọn ti ku, Mata ni ẹni ti o fi ìháragàgà pupọ sii han lati pade Ọga naa, kii ṣe Maria. Bawo ni eyi ti dun mọ wa to ani lonii paapaa nigba ti a ba nka ijumọsọrọpọ tẹmi jijinlẹ yẹn laaarin Jesu ati Mata nipa ireti ajinde! (Johanu 11:20-27) Anfaani wo ni o jẹ fun Mata!
Awọn Obinrin Ti Wọn Seranṣẹ Fun Jesu
4, 5. Yatọ si awọn apọsteli, awọn wo ni wọn tẹle Jesu lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ ni Galili, bawo si ni wọn ṣe ṣeranṣẹ fun?
4 Jesu tun tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ awọn obinrin gẹgẹ bi oun ti nrinrin ajo la ilẹ naa ja. Ninu akọsilẹ Ihinrere rẹ, Maaku mẹnukan ‘awọn obinrin ti wọn ntọ̀ ọ́ [Jesu] lẹhin, ti wọn si nṣe iranṣẹ fun nigba ti o wa ni Galili.’ (Maaku 15:40, 41) Awọn wo ni awọn obinrin wọnyi, bawo si ni wọn ṣe ṣiṣẹsin Jesu? A ko mọ orukọ gbogbo wọn, ṣugbọn Luuku da diẹ mọ o si ṣalaye ọna ti wọn gba ṣiṣẹ iranṣẹ fun Jesu.
5 Luuku kọwe pe: “O si ṣe lẹhin naa, ti o nla gbogbo ilu ati ileto lọ, o nwaasu, o nro ihin ayọ Ijọba Ọlọrun: awọn mejila si nbẹ lọdọ rẹ. Ati awọn obinrin kan ti a ti mularada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npe ni Magidaleni, lara ẹni ti ẹmi eṣu meje ti jade kuro ati Joana aya Kusa, tii ṣe iriju Herọdu, ati Susana, ati awọn pupọ miiran, ti wọn nṣe iranṣẹ fun un ninu ohun ìní wọn.” (Luuku 8:1-3) Jesu nfẹ ki awọn obinrin wọnyi tẹle oun ki wọn si lo awọn nǹkan ìní wọn lati ṣe iranṣẹ fun awọn aini rẹ nipa ti ara ati awọn wọnni ti apọsteli rẹ.
6. (a) Awọn wo ni wọn tọ Jesu lẹhin nigba irin ajo rẹ ikẹhin si Jerusalẹmu? (b) Awọn wo ni wọn duro ti Jesu titi di igba iku rẹ, bawo si ni a ṣe san ere fun diẹ ninu wọn? (c) Ni ọna igbawoye awọn ẹko-igbagbọ isin awọn Juu, ki ni o pafiyesi nipa akọsilẹ ni Johanu 20:11-18?
6 Nigba ti wọn pa Jesu, “awọn obinrin pupọ ni wọn wa nibẹ, ti wọn ngbe okeere wo, awọn ti o ba Jesu ti Galili wa, ti wọn si nṣe iranṣẹ fun un: ninu awọn ẹni ti Maria Magidaleni wa, ati Maria iya Jakọbu, ati Jose.” (Matiu 27:55, 56) Nipa bayii, ọpọlọpọ awọn obinrin olootọ ni wọn duro ti Jesu lakooko iku rẹ. O tun yẹ fun afiyesi pe awọn obinrin ni awọn ẹlẹrii akọkọ ti wọn ri ajinde rẹ. (Matiu 28:1-10) Eyi funraarẹ jẹ àjálù fun igbagbọ atọwọdọwọ awọn Juu nitori laaarin isin Juu awọn obinrin ni a ka si alaiyẹ lati jẹ ẹlẹrii ti o ba ofin mu. Pẹlu eyi ni ọkan, ka Johanu 20:11-18, ki o si gbiyanju lati woye imọlara mímúná ti Maria Magidaleni ti nilati ni nigba ti Ọga ti o ti jí dide naa farahan an ti o pè é ni orukọ rẹ, ti o si lo o gẹgẹ ẹlẹrii rẹ lati fi to awọn ọmọ-ẹhin rẹ leti pe oun ti walaaye nitootọ!
Awọn Obinrin Kristian Oluṣotitọ Lẹhin Pẹntikọsti
7, 8. (a) Bawo ni a ṣe mọ pe awọn obinrin wà nibẹ nigba ti a tu ẹmi mimọ jade ni Pẹntikọsti? (b) Bawo ni awọn obinrin Kristian ṣe ṣajọpin ninu imugbooro isin Kristian ijimiji?
7 Lẹhin igoke re ọrun Jesu, awọn obinrin oniwa bi Ọlọrun wa nibẹ pẹlu awọn apọsteli oluṣotitọ ninu iyàrá oke ni Jerusalẹmu. (Iṣe 1:12-14) Pe awọn obinrin wa laaarin awọn wọnni ti a tu ẹmi mimọ lé lori ni Pẹntikọsti ni o hàn gbangba. Eeṣe? Nitori pe nigba ti Peteru ṣalaye ohun ti o ti ṣẹlẹ, oun fa awọn ọrọ Joẹli 2:28-30, yọ eyi ti o mẹnu kan “ọmọbinrin” ati “awọn ọmọ-ọdọ obinrin,” tabi “awọn ẹrubinrin” ni pataki. (Iṣe 2:1, 4, 14-18) Nitori naa bi a ti fi ẹmi bi wọn, awọn obinrin Kristian ẹni ami ororo jẹ apakan ijọ Kristian gan an lati ipilẹṣẹ rẹ.
8 Awọn obinrin kó ipa pataki, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe ti onipo aṣaaju, ninu itankalẹ isin Kristian. Maria, iya Maaku ti o jẹ àǹtí Banaba, fi ile rẹ ti o ṣe kedere pe o tobi si ikawọ ijọ Jerusalẹmu. (Iṣe 12:12) Oun si muratan lati ṣe eyi ni akoko ti akọtun inunibini lodisi awọn Kristian waye. (Iṣe 12:1-5) Awọn ọmọbinrin mẹrin Filipi ajihinrere lanfaani lati jẹ Kristian wolii obinrin.—Iṣe 21:9; 1 Kọrinti 12:4, 10.
Iṣarasihuwa Pọọlu Si Awọn Obinrin
9. Imọran wo ni Pọọlu fifunni niti awọn obinrin Kristian ninu lẹta rẹ akọkọ si awọn ara Kọrinti, ilana atọrunwa wo si ni o nfun awọn obinrin niṣiiri lati bọwọ fun?
9 Nigba miiran apọsteli Pọọlu ni a fi ẹsun kan pe o jẹ olódì obinrin, iyẹn ni pe, ẹni ti o koriira ti ko si nigbẹkẹle ninu awọn obinrin. Lootọ, Pọọlu ni o fidandan le e pe ki awọn obinrin pa ipo wọn ti o tọna mọ́ laaarin ijọ Kristian. Bi awọn nǹkan ba nlọ bi o ṣe yẹ, wọn kò nilati maa kọni ninu awọn ipade ijọ. (1 Kọrinti 14:33-35) Nitori pe ko si Kristian ọkunrin kankan nitosi tabi nitori pe o sọ asọtẹlẹ labẹ idari ẹmi mimọ, ti obinrin Kristian kan ba sọrọ ni ipade, a beere pe ki o ta ibori. Ibori yii jẹ “ami aṣẹ,” ẹri ti o ṣee fojuri pe obinrin naa mọyi iṣeto Ọlọrun ti ipo ori.—1 Kọrinti 11:3-6, 10.
10. Nipa ki ni awọn kan fẹsun kan apọsteli Pọọlu, ṣugbọn ki ni o fẹri han pe ifẹsunkanni yii jẹ eke?
10 Pọọlu ni kedere ri pe o pọndandan lati rán awọn Kristian ijimiji leti awọn ilana ti Ijọba Ọlọrun wọnyi ki ‘ohun gbogbo ba le wa tẹyẹtẹyẹ’ ni awọn ipade ijọ. (1 Kọrinti 14:40) Ṣugbọn eyi ha tumọsi pe Pọọlu jẹ ọta obinrin gẹgẹ bi awọn kan ti sọ? Bẹẹkọ, ko tumọ si bẹẹ. Kii ha ṣe Pọọlu ni ẹni ti o fi awọn ikini ọlọyaya ranṣẹ si awọn obinrin Kristian mẹsan ninu ori ti o pari lẹta rẹ si awọn ara Roomu? Oun ko ha fi imọriri jijinlẹ han fun Febe, Pirisika (Pirisikila), Tirifena, ati Tirifosa, ni pipe awọn meji ti o kẹhin wọnyi ni “awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kára ninu Oluwa”? (Roomu 16:1-4, 6, 12, 13, 15) Pọọlu si ni ẹni ti o kọwe labẹ imisi pe: “Nitori pe ẹyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ. Ko le si Juu tabi Giriiki, ẹru tabi ominira, ọkunrin tabi obinrin: nitori pe ọkan ni gbogbo yin jẹ ninu Kristi Jesu.” (Galatia 3:27, 28) Ni kedere Pọọlu fẹran o si mọriri awọn Kristian arabinrin rẹ, papọ pẹlu Lidia ẹni ti o fi ẹmi alejo ṣiṣe awofiṣapẹẹrẹ han lakooko idanwo.—Iṣe 16:12-15, 40; Filipi 4:2, 3.
Awọn Obinrin Alaapọn Lonii
11, 12. (a) Bawo ni Saamu 68:11 (NW) ṣe nni imuṣẹ niti gidi lonii? (b) Ninu ipo wo ni ọpọ awọn arabinrin wa ba ara wọn, eesitiṣe ti wọn fi nilo ifẹni ati adura wa?
11 Laaarin ijọ Kristian lonii, ọpọlọpọ awọn obinrin Kristian ni wọn wa ti wọn “nṣiṣẹ kára ninu Oluwa.” Nitootọ, awọn akọsilẹ iwadii fihan pe “awọn obinrin ti wọn nsọ ihinrere jẹ ẹgbẹ ọmọ ogun nla,” ni didi apa pupọ julọ lara ọmọ-ogun awọn Ẹlẹrii tí Jehofa nlo ni akoko opin yii. (Saamu 68:11, NW) Awọn obinrin Kristian oṣiṣẹ kára wọnyi ti jere orukọ rere fun ara wọn gẹgẹ bi wọn ti ntiraka lati mu ojuṣe wọn gẹgẹ bi aya, iya, atọju ile, olumounjẹ wale, ati bakan naa ojiṣẹ Kristian ṣẹ.
12 Melookan ninu awọn arabinrin rere wọnyi ní ọkọ alaigbagbọ. Wọn nilati maa koju ipo yii lojoojumọ ayé. Awọn kan ti ntiraka fun ọpọlọpọ ọdun lati jẹ aya rere nigba ti wọn nde oju iwọn awọn ohun ti a beere lọwọ awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin. Ko rọrun, ṣugbọn wọn farada a, wọn ńńírètí nigba gbogbo pe ọkọ wọn ‘ni a le jere laisọrọ’ nipasẹ iwa Kristian rere wọn. Ẹ si wo idunnu ti a ṣajọpin nipasẹ gbogbo idile naa nigba ti iru ọkọ bẹẹ ba dahun pada! (1 Peteru 3:1, 2) Lakooko yii ná, awọn arabinrin oluṣotitọ wọnyi dajudaju nilo ifẹni ará ati adura awọn mẹmba ijọ yooku. Ani gẹgẹ bi “ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu” ti wọn gbiyanju lati fihan ṣe jẹ iyebiye niwaju Ọlọrun,” bẹẹ ni iduroṣanṣan iwatitọ wọn ṣe ṣeyebiye ni oju wa.—1 Peteru 3:3-6.
13. Eeṣe ti a fi le sọ niti awọn arabinrin wa aṣaaju-ọna pe wọn jẹ “awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kára ninu Oluwa,” bawo si ni a ṣe nilati kà wọn si ninu awọn ijọ wọn kọọkan?
13 Awọn arabinrin ti wọn ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ni a le sọ ni ọna ti o daju hanun hanun julọ pe wọn “nṣiṣẹ kára ninu Oluwa.” Ọpọlọpọ ninu wọn ni ile, ọkọ, ati awọn ọmọ lati bojuto, ni afikun si iṣẹ iwaasu wọn. Awọn kan nṣe iṣẹ àbọ̀ṣẹ́ lati le gbọ bukata wọn. Gbogbo eyi beere fun iṣeto rere, ipinnu, iforiti, ati ọpọ iṣẹ aṣekára. Awọn obinrin Kristian wọnyi nilati le nimọlara ifẹ ati itilẹhin awọn wọnni ti ipo wọn ko yọnda fun wọn lati ya awọn wakati aṣaaju-ọna sọtọ ninu iṣẹ ijẹrii naa.
14. (a) Apẹẹrẹ rere ti iforiti wo ni a mẹnukan? (b) Awọn obinrin Kristian miiran wo ni wọn lẹtọọ si oriyin, eesitiṣe? Menukan awọn apẹẹrẹ adugbo eyikeyii.
14 Awọn obinrin Kristian kan ti fi ẹmi itẹpẹlẹmọ ara ọtọ han ninu iṣẹ-isin aṣaaju ọna. Ni Canada, Grace Lounsbury ni itọwo akọkọ rẹ ninu iṣẹ aṣaaju-ọna ni 1914. Oun nilati fi aṣaaju-ọna silẹ ni 1918 nitori ailera, ṣugbọn ni 1924 o pada sinu iṣẹ-isin alakooko kikun naa. Ni akoko ikọwe yii, o ṣì wa ninu akọsilẹ aṣaaju-ọna sibẹ, bi o tilẹ jẹ pe o jẹ ẹni ọdun 104! Ọpọlọpọ awọn arabinrin ojihin iṣẹ Ọlọrun awọn ti a dalẹkọ ni awọn ọdun 1940 ni ibẹrẹ kilaasi ti Watchtower Bible School of Gilead ṣì nṣiṣẹsin pẹlu iṣotitọ sibẹ, yala ni papa ijihin iṣẹ Ọlọrun tabi gẹgẹ bi mẹmba idile Bethel ni Brooklyn tabi ọkan lara awọn ẹka Watch Tower Society. Gbogbo awọn obinrin Kristian wọnyi, ati nitootọ gbogbo awọn arabinrin ti wọn fi ara wọn silo ninu iṣẹ-isin Bethel, fi ẹmi ifara ẹni rubọ ati apẹẹrẹ rere han. Njẹ awa nigba kankan ri jẹ ki wọn mọ pe a mọriri wọn bi?
Aya Awọn Alaboojuto Arinrin-ajo
15, 16. Awujọ awọn obinrin Kristian wo ni pataki ni wọn lẹtọọ si oriyin ọlọyaya wa, eesitiṣe?
15 Aya awọn alaboojuto arinrin-ajo tun jẹ awujọ awọn obinrin Kristian miiran ti wọn lẹtọọ si oriyin ati iṣiri ọlọyaya. Awọn arabinrin ọwọn wọnyi ti muratan lati tẹle ọkọ wọn gẹgẹ bi awọn wọnyi ti nlọ lati ijọ de ijọ, tabi lati ayika de ayika, ki wọn ba le gbe awọn arakunrin wọn ró nipa tẹmi. Ọpọjulọ ninu wọn ti fi awọn idẹra ile silẹ; wọn nsun lori oriṣiriṣi ibusun lọsọọsẹ, kii sii ṣe ibusun ti o dara nigba gbogbo. Ṣugbọn wọn layọ lati tẹwọgba ohun ti awọn arakunrin ba le pese. Wọn jẹ apẹẹrẹ rere fun awọn arabinrin wọn nipa tẹmi.
16 Awọn Kristian obinrin wọnyi tun pese itilẹhin alaiṣeediyele fun awọn ọkọ wọn, lọna pupọ gan an gẹgẹ bi awọn obinrin ti wọn tẹle Jesu “ti wọn ntọ̀ ọ́ lẹhin, ti wọn si nṣe iranṣẹ fun un.” (Maaku 15:41) Wọn ko le lo ọpọlọpọ akoko ni awọn nikanṣoṣo pẹlu ọkọ wọn, ẹni ti o saba maa ‘nni pupọ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa.’ (1 Kọrinti 15:58) Diẹ ninu wọn, bii Rosa Szumiga ni France, ẹni ti o kowọnu iṣẹ-isin alakooko kikun ni 1948, ti ndi apoti ifalọwọ fun awọn ọkọ wọn ti wọn si nrinrin ajo pẹlu wọn fun 30 tabi 40 ọdun. Wọn muratan lati ṣe awọn irubọ fun Jehofa ati fun awọn arakunrin ati arabinrin wọn. Wọn lẹtọọ si imọriri, ifẹ, ati adura wa.
Aya Awọn Alagba
17, 18. (a) Awọn animọ wo ni a beere fun lọwọ awọn aya arakunrin ti a yàn si awọn ipo iṣẹ-isin? (b) Awọn irubọ wo ni awọn aya alagba ti fohunṣọkan lati ṣe fun Jehofa ati fun awọn arakunrin wọn, bawo si ni awọn aya miiran ṣe le ran awọn ọkọ wọn lọwọ?
17 Nigba ti a nka awọn ẹri itootun fun awọn arakunrin ti a le yàn gẹgẹ bi alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, apọsteli Pọọlu tun mẹnukan awọn obinrin, ni kikọwe pe: “Bẹẹ gẹgẹ ni o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa agba, ki wọn ma jẹ asọrọ ẹni lẹhin bikoṣe alairekọja, olootọ ni ohun gbogbo.” (1 Timotiu 3:11) Lootọ, imọran gbogbogboo yii ṣee fisilo fun gbogbo awọn obinrin Kristian. Ṣugbọn ni oju-iwoye ayika ọrọ naa, o han gbangba pe aya awọn arakunrin ti a yan si awọn ipo iṣẹ-isin nilati tẹle e ni ọna awofiṣapẹẹrẹ.
18 Lọna ti o muni layọ, bayii ni ọran ri pẹlu ọpọlọpọ ẹgbẹgbẹrun aya awọn alabojuto Kristian. Wọn wa niwọntunwọnsi ninu iṣe ati iwọṣọ wọn, wọn jẹ onironu nipa igbesi-aye Kristian, oniṣọra nipa ohun ti wọn nsọ, wọn si fi otitọ inu sapa lati jẹ olootọ ninu ohun gbogbo. Wọn tun fohunṣọkan lati ṣe awọn irubọ, ni gbigba pe ki ọkọ wọn fi akoko pupọ fun awọn ọran ijọ ti oun iba ti lo pẹlu wọn. Awọn obinrin Kristian oluṣotitọ wọnyi lẹtọọ si ifẹ ọlọyaya ati iṣiri wa. Boya awọn arakunrin pupọ sii le naga fun awọn anfaani laaarin ọpọlọpọ ijọ bi awọn aya wọn ba fohunṣọkan pẹlu irẹlẹ lati ṣe iru awọn irubọ bẹẹ fun ire alaafia gbogbo eniyan.
“Awọn Agba Obinrin” Oluṣotitọ
19. Eeṣe ti a fi mọriri ọpọlọpọ “awọn agbalagba obinrin” oluṣotitọ ninu ijọ wọn, ki ni o si nilati jẹ imọlara wa si wọn?
19 Atunyẹwo wa nipa awọn obinrin ti a mẹnukan ninu Bibeli ti mu ki o ṣeeṣe fun wa lati ri pe ọjọ ori ko di awọn obinrin igbagbọ lọwọ ninu sisin Ọlọrun. Otitọ yii ni a ṣapejuwe ninu awọn ọran ti Sera, Elisabẹti, ati Anna. Lonii, ọpọlọpọ awọn obinrin Kristian ti ọdun wọn ti pẹ ti wọn jẹ apẹẹrẹ rere ti igbagbọ ati ifarada ni wọn wa. Ni afikun, wọn fi ọgbọn ti awọn alagba lẹhin nipa riran awọn arabinrin ọdọ lọwọ. Ni lilo iriri pipẹ wọn, wọn le fun awọn ọdọ obinrin ni imọran ọlọgbọn, ani gẹgẹ bi Iwe mimọ ti fun wọn laṣẹ lati ṣe. (Titu 2:3-5) O le jẹ pe nigba miiran arabinrin agbalagba kan ni a nilati fun nimọran funraarẹ. Bi o ba ri bẹẹ, awọn alagba ti wọn yoo ṣe bẹẹ nilati ‘gbà a niyanju gẹgẹ bi iya.’ Awọn alagba nilati “bọwọ fun awọn opo” ati, bi aini ba wà, ki wọn ṣeto iranlọwọ ohun ti ara fun wọn. (1 Timotiu 5:1-3, 5, 9, 10) Awọn agba arabinrin wa ọwọn ni wọn nilati ni imọlara pe a fẹ a si mọriri wọn dajudaju.
Awọn Oluṣakoso Pẹlu Kristi
20. Anfaani gigajulọ wo ni a ti pese fun ọpọlọpọ awọn obinrin Kristian, eesitiṣe ti awọn agutan miiran fi nilati layọ nipa eyi?
20 O ṣe gbangba kedere lati inu Iwe mimọ pe “ojuṣaaju eniyan ko si lọdọ Ọlọrun” niti iran tabi ẹya. (Roomu 2:10, 11; Galatia 3:28) Eyi si jẹ otitọ ninu ọna ti Jehofa gba ṣayan awọn wọnni ti wọn nilati wà papọ pẹlu Ọmọkunrin rẹ ninu iṣakoso Ijọba naa pẹlu. (Johanu 6:44) Bawo ni awọn ogunlọgọ ti agutan miiran ti nilati kun fun ọpẹ to pe awọn obinrin oluṣotitọ, iru gẹgẹ bi Maria iya Jesu, Maria Magidaleni, Pirisikila, Tirifena, Tirifosa, ati ọgọọrọ awọn miiran ninu ijọ Kristian ijimiji, nṣajọpin nisinsinyi ninu iṣakoso Ijọba naa, ni fifi òye ti o ṣe timọtimọ ti imọlara awọn obinrin kún ọrọ̀ ijọba yẹn! Iru oju-iwoye ririn jinna onifẹẹ ati ọlọgbọn wo ni eyi jẹ ni apa ọdọ Jehofa!—Roomu 11:33-36.
21. Ki ni awọn imọlara wa lonii si “awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kára ninu Oluwa”?
21 Awa lonii le ṣajọpin awọn imọlara apọsteli Pọọlu naa nigba ti oun sọrọ pẹlu ifẹ ati imọriri nipa “awọn obinrin wọnyi ti wọn ti lakaka ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu mi ninu ihinrere.” (Filipi 4:3, NW) Gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, lọkunrin ati lobinrin, kà á si ayọ ati anfaani lati ṣiṣẹ ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ‘ogun nla ti awọn obinrin ti wọn nsọ ihinrere,’ bẹẹni, “awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kara ninu Oluwa.”—Saamu 68:11; Roomu 16:12, NW.
Awọn Ibeere Atunyẹwo
◻ Bawo ni Jesu ṣe fihan pe oun ko ṣajọpin ẹtanu awọn aṣaaju isin Juu lodisi awọn obinrin?
◻ Bawo ni awọn obinrin olubẹru Ọlọrun ṣe ṣeranṣẹ fun Jesu, anfaani titobi wo si ni diẹ ninu wọn gba?
◻ Imọran wo ni Pọọlu fi funni nipa awọn obinrin ninu awọn ipade ijọ?
◻ Isọri awọn arabinrin wo ni wọn lẹtọọ si ifẹni akanṣe ati itilẹhin wa, eesitiṣe?
◻ Bawo ni a ṣe nilati nimọlara si gbogbo awọn wọnni ti wọn jẹ “awọn obinrin ti wọn nṣiṣẹ kára ninu Oluwa” lonii?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Awọn obinrin ṣeranṣẹ fun Jesu ati awọn apọsteli rẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Awọn aya olufara ẹni rubọ ti awọn alaboojuto arinrin-ajo ati ti awọn alagba miiran nṣe itilẹhin oniyebiye fun iṣẹ Ọlọrun