Ọkùnrin àti Obìnrin Ipò Iyì Ni Ọlọ́run Fi Kálukú Wọn Sí
ÁDÁMÙ ni Jèhófà Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, lẹ́yìn ìyẹn ló wá dá Éfà. Ádámù ní ọ̀pọ̀ ìrírí nítorí ó ti wà láyé kí Ọlọ́run tó dá Éfà. Ní ìgbà yẹn, Jèhófà fún Ádámù láwọn ìtọ́ni kan. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-20) Ádámù wá jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ mọ àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un wọ̀nyí. Nítorí àwọn ìdí yìí, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ sí mímú ipò iwájú nínú gbogbo ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ìjọsìn.
Bí Ọlọ́run ṣe yan Ádámù sí ipò orí yìí, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣètò ipò orí nínú ìjọ Kristẹni, a óò sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ tá a bá gbé ètò yìí yẹ̀ wò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò gba obìnrin láyè . . . láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Nítorí Ádámù ni a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá, lẹ́yìn náà Éfà.” (1 Tímótì 2:12, 13) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ò túmọ̀ sí pé àwọn obìnrin ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ rárá bí wọ́n bá wà nípàdé o. Ohun tí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí ni pé àwọn obìnrin ò gbọ́dọ̀ máa bá ọkùnrin jiyàn, tàbí kí wọ́n tẹ́ńbẹ́lú ipò tí Ọlọ́run fàwọn ọkùnrin sí, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò gbọ́dọ̀ sọ pé àwọn fẹ́ máa kọ́ni nínú ìjọ. Àwọn ọkùnrin ni Ọlọ́run yàn láti máa ṣe iṣẹ́ àbójútó àti iṣẹ́ kíkọ́ni nínú ìjọ, àmọ́ àwọn obìnrin náà máa ń ṣe ipa tiwọn ní onírúurú ọ̀nà láti mú kí ìpàdé kẹ́sẹ járí.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká mọ ipò tí Ọlọ́run fi ọkùnrin sí àti ipò tó fi obìnrin sí, ó ní: “Ọkùnrin kò ti ara obìnrin jáde, ṣùgbọ́n obìnrin ti ara ọkùnrin jáde . . . Yàtọ̀ sí èyí, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa, kò sí obìnrin láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọkùnrin láìsí obìnrin [ìyẹn ni pé ọ̀kan ò lè wà láìsí ìkejì]. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí obìnrin ti ti ara ọkùnrin jáde, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wá; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde.”—1 Kọ́ríńtì 11:8-12.
Àwọn Obìnrin Ní Àǹfààní Ńlá
Láyé ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lábẹ́ Òfin Mósè, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní làwọn obìnrin wọn ní, wọ́n sì lómìnira láti dánú ṣe nǹkan fúnra wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Òwe 31:10-31 sọ̀rọ̀ nípa “aya tí ó dáńgájíá” tó lọ ra ojúlówó aṣọ tó sì fi rán ẹ̀wù tó dáa fáwọn ará ilé rẹ̀. Àní ó tiẹ̀ “ṣe àwọn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ pàápàá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tà wọ́n”! (Ẹsẹ 13, 21-24) Obìnrin dáadáa yìí “dà bí àwọn ọkọ̀ òkun tí í ṣe ti olówò kan” nítorí pé ó máa ń wá oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, ì báà gba pé kó wá a lọ sọ́nà jíjìn. (Ẹsẹ 14) “Ó gbé pápá kan yẹ̀ wò, ó sì tẹ̀ síwájú láti rí i gbà,” ó tún “gbin ọgbà àjàrà.” (Ẹsẹ 16) Níwọ̀n bí ‘òwò rẹ̀ ti dára,’ ó rí èrè níbẹ̀. (Ẹsẹ 18) Yàtọ̀ sí pé obìnrin tó tẹpá mọ́ṣẹ́ tó sì bẹ̀rù Jèhófà yìí “ń ṣọ́ àwọn ohun tí ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀,” ó tún ń ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíràn. (Ẹsẹ 20, 27) Abájọ táwọn èèyàn fi yìn ín!—Ẹsẹ 31.
Òfin tí Jèhófà tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ káwọn obìnrin wọn láǹfààní tó pọ̀ láti lè mú kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá lágbára sí i. Bí àpẹẹrẹ, Jóṣúà 8:35 sọ pé: “Kò sì sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pa láṣẹ tí Jóṣúà kò kà sókè ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn àtìpó tí ń rìn ní àárín wọn.” Nígbà tí Bíbélì sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ẹ́sírà àlùfáà, ó ní: “Ẹ́sírà àlùfáà mú òfin náà wá síwájú ìjọ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀, ní ọjọ́ kìíní oṣù keje. Ó sì ń bá a lọ láti kà á sókè ní ojúde ìlú tí ó wà ní àtidé Ẹnubodè Omi, láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọjọ́kanrí, ní iwájú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn yòókù tí ó ní làákàyè; etí gbogbo ènìyàn náà sì ṣí sí ìwé òfin náà.” (Nehemáyà 8:2, 3) Ìwé òfin tí wọ́n kà yìí ṣe àwọn obìnrin láǹfààní gan-an. Àwọn obìnrin náà tún máa ń kópa nínú àjọyọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. (Diutarónómì 12:12, 18; 16:11, 14) Àǹfààní tó ga jù lọ táwọn obìnrin wọ̀nyí ní ni pé, kálukú wọn lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì lè máa gbàdúrà sí i.—1 Sámúẹ́lì 1:10.
Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run láǹfààní láti ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù. (Lúùkù 8:1-3) Àpẹẹrẹ kan ni ti obìnrin kan tó da òróró sórí Jésù tó sì tún fi pa ẹsẹ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ nílé ẹnì kan nílùú Bẹ́tánì. (Mátíù 26:6-13; Jòhánù 12:1-7) Àwọn obìnrin wà lára àwọn tí Jésù fara hàn lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. (Mátíù 28:1-10; Jòhánù 20:1-18) Lẹ́yìn tí Jésù lọ sọ́run, “àwọn obìnrin kan àti Màríà ìyá Jésù” wà lára nǹkan bí ọgọ́fà èèyàn tó lọ pàdé pọ̀ níbì kan. (Ìṣe 1:3-15) Ó dájú pé púpọ̀ lára àwọn obìnrin wọ̀nyí tàbí kó jẹ́ gbogbo wọn ló wà lára àwọn tó pàdé pọ̀ lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, lọ́jọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n sì ń fi onírúurú èdè sọ̀rọ̀ lọ́nà ìyanu.—Ìṣe 2:1-12.
Àtọkùnrin àtobìnrin ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jóẹ́lì 2:28, 29 ṣẹ sí lára. Àsọtẹ́lẹ̀ náà ni àpọ́sítélì Pétérù mẹ́nu kàn lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ó ní: “Èmi [Jèhófà] yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ . . . Ṣe ni èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní ọjọ́ wọnnì.” (Ìṣe 2:13-18) Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni rí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ gbà fún sáà àkókò kan. Wọ́n ń fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, àmọ́ ó lè má jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú bí kò ṣe ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́.
Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó sọ̀rọ̀ dáadáa nípa “Fébè arábìnrin wa,” ó dámọ̀ràn pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà á. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa Tírífénà àti Tírífósà, ó ní wọ́n jẹ́ “obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa.” (Róòmù 16:1, 2, 12) Òótọ́ ni pé àwọn obìnrin wọ̀nyí kì í ṣe alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, síbẹ̀ àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn láǹfààní láti wà lára àwọn tí Ọlọ́run yàn pé kó bá Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ jọba lọ́run.—Róòmù 8:16, 17; Gálátíà 3:28, 29.
Àwọn obìnrin tó wà lóde òní náà ò gbẹ́yìn, àǹfààní tiwọn náà kì í ṣe kékeré! Sáàmù 68:11 sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.” A gbóríyìn fáwọn obìnrin wọ̀nyí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà tó jáfáfá tí wọ́n gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóde ẹ̀rí ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí. Àwọn obìnrin míì tá a tún gbóríyìn fún ni àwọn ìyàwó ilé tí wọ́n ń ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́, tí wọ́n sì ń ti ọkọ wọn lẹ́yìn bí ọkọ wọn ṣe ń bójú tó ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. (Òwe 31:10-12, 28) Àyè iyì ni Ọlọ́run fáwọn obìnrin tí ò tíì lọ́kọ náà sí nínú ètò rẹ̀, Bíbélì sì gba àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa “pàrọwà fún . . . àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”—1 Tímótì 5:1, 2.
Onírúurú Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Yàn fún Ọkùnrin
Ipò kan wà tí Ọlọ́run fi àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni sí, ó sì fẹ́ kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn ní ipò náà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ọkùnrin náà ní orí tiẹ̀, ìyẹn ni Kristi. Wọ́n á jíhìn fún Kristi, èyí tó fi hàn pé wọ́n á jíhìn fún Ọlọ́run tí í ṣe orí Kristi nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn ọkùnrin fi tìfẹ́tìfẹ́ lo ipò orí wọn. (Éfésù 5:25) Bó sì ṣe rí nìyẹn látìgbà téèyàn ti wà lórí ilẹ̀ ayé.
Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run fún ọkùnrin láwọn iṣẹ́ kan láti ṣe níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ló fi sí ipò orí. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà àwọn èèyàn nígbà Ìkún-omi. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9–7:24) Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun máa tipasẹ̀ irú-ọmọ rẹ̀ bù kún gbogbo ìdílé àti orílẹ̀-èdè tó wà láyé. Kristi Jésù ni olórí lára irú-ọmọ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:3; 22:18; Gálátíà 3:8-16) Ọlọ́run yan Mósè láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde nílẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 3:9, 10, 12, 18) Mósè náà ni Ọlọ́run tipasẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin tá a mọ̀ sí májẹ̀mú Òfin tàbí Òfin Mósè. (Ẹ́kísódù 24:1-18) Ọkùnrin ni gbogbo àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì.
Jésù, Orí ìjọ Kristẹni, “fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” láti àárín àwọn ọkùnrin. (Éfésù 1:22; 4:7-13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tó lè di alábòójútó, àwọn ọkùnrin ló tọ́ka sí. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9) Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ọkùnrin ló máa ń ṣe alábòójútó, ìyẹn alàgbà, àwọn ni wọ́n sì máa ń yàn sípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Fílípì 1:1, 2; 1 Tímótì 3:8-10, 12) Àwọn ọkùnrin nìkan ni Bíbélì fọwọ́ sí pé kó máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:1-4) Àmọ́ gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, Ọlọ́run fáwọn obìnrin náà ní àǹfààní ńlá.
Wọ́n Ń Láyọ̀ Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe Ojúṣe Wọn
Bí ọkùnrin àtobìnrin bá ń ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run fún wọn, èyí á mú kí wọ́n láyọ̀. Tí ọkọ bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí ìyàwó náà sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìjọ Ọlọ́run, ayọ̀ máa wà láàárín wọn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un . . . Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” (Éfésù 5:25-33) Nítorí náà, àwọn ọkọ ní láti fi ìfẹ́ lo ipò orí wọn, kí wọ́n má ṣe jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Aláìpé làwọn tó wà nínú ìjọ Kristi, wọn kì í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀, Jésù nífẹ̀ẹ́ ìjọ rẹ̀ ó sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀. Bákan náà, àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ní láti nífẹ̀ẹ́ aya wọn kí wọ́n sì máa ṣìkẹ́ wọn.
Aya tó jẹ́ Kristẹni ní láti “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Tó bá dọ̀rọ̀ níní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, àwọn aya lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára ìjọ. Éfésù 5:21-24 sọ pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi. Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ, bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí. Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya pẹ̀lú wà fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo.” Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà míì lè wà tó máa ṣòro fún aya láti tẹrí bá fún ọkọ rẹ̀, síbẹ̀ títẹríba jẹ́ ohun tí ó “yẹ nínú Olúwa.” (Kólósè 3:18) Táwọn aya bá ń rántí pé ohun tínú Jésù Kristi Olúwa dùn sí ni pé kí wọ́n máa tẹrí bá fún ọkọ wọn, èyí á túbọ̀ jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Kódà bí ọkọ rẹ kì í bá ṣe Kristẹni bíi tìẹ, o ṣì ní láti tẹrí bá fún un. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:1, 2) Sárà aya Ábúráhámù jẹ́ ẹnì kan tó bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, Ọlọ́run sì fún un láǹfààní láti bí ọmọ kan tí wọ́n ń pè ní Ísáákì àti láti di ìyá ńlá Jésù Kristi. (Hébérù 11:11, 12; 1 Pétérù 3:5, 6) Ó ti dájú pé Ọlọ́run yóò bù kún àwọn aya tó bá ṣe bíi ti Sárà.
Tí ọkùnrin àtobìnrin bá ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run fún wọn, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan yóò gbilẹ̀ láàárín wọn. Èyí á sì mú kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀. Kò tán síbẹ̀ o, tí kálukú wọn bá ń tẹ̀ lé ìlànà inú Ìwé Mímọ́, wọ́n á ní iyì àti ẹ̀yẹ nínú ipò tí Ọlọ́run fi wọ́n sí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ojú Tí Wọ́n Fi Wo Ipò Tí Ọlọ́run Fi Wọ́n Sí
Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Susan sọ pé: “Tìfẹ́tìfẹ́ lọkọ mi ń lo ipò orí rẹ̀, kì í kanra mọ́ mi. Tá a bá fẹ́ ṣe ohun kan, a sábà máa ń kọ́kọ́ jíròrò ẹ̀ pa pọ̀. Tí ọkọ mi bá wá sọ pé a máa ṣe nǹkan ọ̀hún tàbí tó sọ pé a ò ní ṣe é, mo máa ń fara mọ́ ohun tó bá sọ torí pé mo mọ̀ pé fún àǹfààní àwa méjèèjì ni. Ká sòótọ́, ipò tí Jèhófà fi àwa aya tó jẹ́ Kristẹni sí múnú mi dùn, ó sì mú kí àjọṣe èmi àtọkọ mi túbọ̀ dán mọ́rán sí i. A fẹ́ràn ara wa gan-an, tá a bá sì wéwèé láti ṣe ohun kan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, ńṣe la máa ń pawọ́ pọ̀ ṣe é.”
Obìnrin mìíràn tó ń jẹ́ Mindy sọ pé: “Ipò tí Jèhófà fi àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ obìnrin sí mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Mo wò ó pé bí mo ṣe ń bọlá fún ọkọ mi, tí mò ń bọ̀wọ̀ fún un, tí mo sì ń tì í lẹ́yìn bó ṣe ń gbé ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ, ó jẹ́ ọ̀nà tí mo lè gbà fi hàn pé mo mọrírì ètò tí Jèhófà ṣe.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Nítorí ipò orí tí ọkùnrin wà, Ọlọ́run fún Nóà, Ábúráhámù, àti Mósè ní onírúurú iṣẹ́ láti ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá”