ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 7/1 ojú ìwé 8-13
  • Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Dá a Gẹgẹ bi Ekeji Ọkunrin
  • Ipa Ti O Ba Ọgbọn Mu Ti Obinrin
  • Ẹṣẹ Lọ́ Ojuṣe Obinrin Po
  • Awọn Obinrin Labẹ Ofin Mose
  • Awọn Obinrin Titayọ
  • Awọn Obinrin Labẹ Isin Awọn Juu
  • Awọn Obinrin Oluṣotitọ Ti Wọn Nduro De Mesaya Naa
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ipa Wo Ni Àwọn Obìnrin Ń Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ipa-iṣẹ́ Oníyì Ti Àwọn Obìnrin Láàárín Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Ní Ìjímìjí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọkùnrin àti Obìnrin Ipò Iyì Ni Ọlọ́run Fi Kálukú Wọn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 7/1 ojú ìwé 8-13

Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ

“Ẹni yii ni a o pe ni Obinrin, nitori lati ara ọkunrin ni a ti mu un yii jade wá.”—JẸNẸSISI 2:23, NW.

1, 2. (a) Oju wo ni awọn kan ro pe Bibeli fi wo awọn obinrin? (b) Laiṣe ojuṣaaju, ifiwera wo ni a nilati ṣe, ki si ni iwe itọka kan sọ?

OJU wo ni Iwe Mimọ fi nwo awọn obinrin? Awọn ero lori eyi yatọ sira. Iwe lọ́ọ́lọ́ọ́ lori koko ẹkọ naa wipe: “Ero ànítẹ́lẹ̀ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ni pe Bibeli foju tin-inrin awọn obinrin.” Awọn eniyan kan sọ pe ninu awọn apa rẹ ti ede Heberu ati ti ede Giriiki, Bibeli lekoko mọ́ awọn obinrin. Otitọ ha ni eyi bi?

2 Laiṣe ojuṣaaju, o yẹ lakọọkọ lati ṣayẹwo bi a ṣe nhuwa si awọn obinrin ni awọn akoko Bibeli laaarin awọn eniyan ti wọn ko sin Jehofa. Ninu diẹ lara awọn awujọ ọlaju igbaani ti wọn nṣe ijọsin yèyé abo-ọlọrun, awọn obinrin ni a bọla fun gẹgẹ bi ami ọlọ́mọyọyọ. O farahan pé a gbé wọn niyi gidigidi ni Babiloni ati Ijibiti. Ṣugbọn nibomiran a ko ṣe wọn daradara tobẹẹ. Ni Asiria igbaani ọkunrin kan le lé aya rẹ lọ bi o ba fẹ́ o si le pa á paapaa bi aya naa ba jẹ alaiṣootọ. Lẹhin ode ile, oun nilati wọ iboju kan. Ni Giriisi ati Roomu, kiki awọn obinrin ọlọrọ, ọpọ ninu awọn ti wọn jẹ aṣẹwo onipo giga, ni wọn ni anfaani fun imọ ẹkọ ti wọn si gbadun iwọn ominira kan. Fun idi yii, o tuni lara lati ka ninu The New International Dictionary of New Testament Theology pe:a “Ni odikeji si aye (onisin) ti gabasi, oun [obinrin ninu Iwe Mimọ Lede Heberu] ni a mọ gẹgẹ bi ẹnikan ati gẹgẹ bi ẹnikeji ọkunrin.” Eyi ni a sọ daradara ninu iwe ti o kẹhin ninu Iwe mimọ lede Heberu, nibi ti wolii Jehofa ti ṣapejuwe aya ọkunrin gẹgẹ bi “ẹnikeji,” rẹ ni fifi kun un pe: “Njẹ ki ẹnikẹni ki o maṣe ni ibalo adakadeke pẹlu aya ewe rẹ.”—Malaki 2:14, 15, NW.

A Dá a Gẹgẹ bi Ekeji Ọkunrin

3 ati akiyesi ẹsẹ-iwe. (a) Lẹhin dida Adamu, iṣẹ wo ni Jehofa fifun un? (b) Ani bi o tilẹ jẹ pe oun ko ni aya kankan sibẹ, ki ni o jẹ otitọ nipa Adamu ṣaaju dida Efa, ki ni o si tun jẹ otitọ nipa “Adamu ikẹhin,” Jesu?

3 Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, Jehofa dá Adamu ‘lati inu erupẹ ilẹ’ o si fi i sinu ọgba Edeni, lati maa ro o. Ọlọrun mu awọn ẹranko igbẹ ati awọn ẹda ti nfo tọ Adamu wá lati wò wọn daradara ki o si fun wọn ni orukọ. Laaarin akoko yoowu ti o gba Adamu lati ṣe eyi, oun danikan wa, fun awọn iṣẹ ti o ti gba lati ọdọ Jehofa titi de akoko yii, oun jẹ pipe, ẹni pipe perepere, ti ko ṣalaini ohun kan.b Ko si ‘oluranlọwọ gẹgẹ bi aṣekun rẹ.’ fun un.—Jẹnẹsisi 2:7, 15, 19, 20.

4, 5. (a) Nigba ti ko dara mọ fun Adamu lati maa danikan wa, ki ni Jehofa ṣe? (b) Iṣẹ alakooko gigun wo ni Jehofa fifun Adamu ati Efa, ki ni eyi yoo si beere fun lọwọ awọn mejeeji?

4 Bi o ti wu ki o ri, lẹhin ti akoko diẹ ti kọja, Jehofa polongo pe “ko dara ki ọkunrin naa ki o nikan maa gbe,” o si tẹsiwaju lati pese alabaakẹgbẹ kan fun Adamu lati ṣajọpin pẹlu rẹ ninu awọn iṣẹ takuntakun ti o wà niwaju. Oun fi oorun ìjìkà kun Adamu, o fa ọkan ninu awọn egungun iha rẹ yọ, o si fi mọ obinrin kan, ‘egungun ninu awọn egungun Adamu ati ẹran ara ninu awọn ẹran ara rẹ.’ Nisinsinyi Adamu yoo ni “oluranlọwọ kan,” “aṣekun,” tabi ekeji kan. Siwaju sii, “Ọlọrun si sure fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, ẹ maa bi sii ki ẹ si maa rẹ, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ; ki ẹ si maa jọba lori ẹja okun, ati lori ẹyẹ oju ọrun, ati lori ohun alaaye gbogbo ti nrako lori ilẹ.”—Jẹnẹsisi 1:25, 28; 2:18, 21-23.

5 Ṣakiyesi pe iṣẹ yii ni a fi fun “wọn,” ati ọkunrin ati obinrin. Ajọṣiṣẹpọ wọn ni a ko ni fi mọ si kíkún ilẹ-aye. Yoo tun ni ninu ṣiṣe ikawọ ilẹ-aye ati lilo jijọba lọna ti o bojumu lori gbogbo awọn ẹ̀dá ti o rẹlẹ. Yoo beere fun awọn animọ ọlọgbọlọye ati tẹmi, ọkunrin ati obinrin naa sì ní agbara ti wọn nilo fun mimu iwọnyi dagba ni ibamu pẹlu ifẹ inu Ọlọrun.

Ipa Ti O Ba Ọgbọn Mu Ti Obinrin

6. (a) Ki ni Bibeli fihan nipa okun ara alaala ti ọkunrin ati ti obinrin? (b) Bawo ni yoo ti dara to fun awọn obinrin lati ronu ki wọn ba le tẹwọgba iṣeto awọn nǹkan ti Jehofa?

6 Nitootọ, ṣiṣekawọ ilẹ-aye yoo tun gba okun ti ara. Ninu ọgbọn ainipẹkun rẹ, Jehofa kọ́kọ́ dá Adamu, lẹhin naa, Efa. O dá a ‘lati inu ara ọkunrin,’ “nitori ọkunrin,” ati ni kedere pẹlu okun ti ara ti o rẹlẹ ju ti ọkunrin. (1 Timoti 2:13; 1 Kọrinti 11:8, 9; fiwe 1 Peteru 3:7.) Otitọ igbesi-aye kan ti o dabi ẹnipe o ṣoro fun ọpọlọpọ awọn ajafẹtọọ obinrin, ati awọn obinrin diẹ miiran pẹlu, lati gba. Dajudaju wọn yoo layọ ju bi wọn ba gbiyanju lati mọ idi ti Jehofa fi ṣeto awọn nǹkan ni ọna yii, ni titipa bayii tẹwọgba ipa ti Ọlọrun fifun wọn lati kó. Awọn eniyan ti wọn ńráhùn nipa awọn iṣeto Ọlọrun ni a le fiwe ẹyẹ olohun iyọ kan ti o fajuro ninu itẹ rẹ nitori pe ko lagbara gẹgẹ bi ẹyẹ gọ̀lọ̀mìṣọ̀, dipo ti iba fi fo lọ sori ẹka igi giga ki o si maa kọrin ni imoore fun awọn ẹbun alailẹgbẹ ti Ọlọrun ti fifun un.

7. Eeṣe ti Adamu fi wa ni ipo rere lati lo ipo ori lori Efa ati awọn ọmọ eyikeyi ti wọn yoo bi, ṣugbọn eyi ha jẹ si ipalara Efa bi?

7 Ṣaaju ki a to dá Efa, laiṣiyemeji Adamu ti jere ọpọ iriri ninu gbigbe igbesi-aye. Ni akoko yii, Jehofa fun un ni awọn itọni kan ni pataki. Adamu ni yoo ta iwọnyi látaré si aya rẹ, ni titipa bayii ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbọrọsọ fun Ọlọrun. Lọna ti o ba ọgbọn mu, oun ti nilati mu ipo iwaju ninu gbogbo ọran ti o kan ijọsin ati awọn igbokegbodo oniwa bi Ọlọrun ti wọn nilati ṣe pẹlu ireti ṣiṣaṣepari iṣẹ ti a yan fun wọn. Nigba ti wọn ba bí awọn ọmọ, oun nilati jẹ ori idile naa. Ṣugbọn eyi ki yoo jẹ si ipalara aya rẹ. Kaka bẹẹ, yoo jẹ fun anfaani rẹ nitori pe oun yoo ni ẹnikan lati tì í lẹhin nigba ti o ba nmu aṣẹ tirẹ ti Ọlọrun fi fun un lò lori awọn ọmọ rẹ.

8. Iṣeto awọn nǹkan lati ọrun wo ni a là lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli?

8 Ni ibamu pẹlu iṣeto awọn nǹkan lati ọrun, Adamu ni ẹru ijihin lọdọ Jehofa, Efa wa ni abẹ ipo ori Adamu, awọn ọmọ eyikeyi yoo wa labẹ itọni awọn obi wọn, awọn ẹranko si wa ni itẹriba fun eniyan. Ọkunrin ati obinrin ní awọn ojuṣe wọn lẹnikọọkan, olukuluku si le gbe igbesi-aye alayọ ti o si mesojade. Nipa bayii, ‘ohun gbogbo le wáyé tẹyẹtẹyẹ ati ni ibamu iwaletoleto.’—1 Kọrinti 11:3; 14:33, 40, NW, akiyesi ẹsẹ-iwe.

Ẹṣẹ Lọ́ Ojuṣe Obinrin Po

9, 10. Ki ni awọn abajade iṣubu sinu ẹṣẹ fun ọkunrin ati obinrin, sí ki ni eyi si ti yọrisi fun ọpọlọpọ awọn obinrin?

9 Lọna ti ẹda, iwọle ẹṣẹ ati aipe sinu Paradise ipilẹṣẹ ba iṣeto awọn nǹkan letoleto yii jẹ́. (Roomu 7:14-20) O mu inira wa fun ọlọtẹ ọkunrin naa ati aya rẹ alaigbọran. (Jẹnẹsisi 3:16-19) Lati igba naa, ọpọlọpọ awọn ọkunrin onimọtara ẹni nikan ti lo ipo ori wọn ti o tọna ni ilokulo, ni mimu ipọnju pupọ wa fun awọn obinrin lati ibẹrẹ ọjọ.

10 Ni riri abajade ẹṣẹ yii ṣaaju ni pataki, Jehofa wi fun Efa pe: “Lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yoo ma fà si, oun ni yoo si maa ṣe olori rẹ.” (Jẹnẹsisi 3:16) Ijọba lenilori aṣilo yii kii ṣe ìlò ipo ori lọna ti o tọ́. O ti fi ipo ẹlẹṣẹ ọkunrin ati aipe obinrin pẹlu han, nitori nigba miiran awọn obinrin ti jiya nitori pe wọn ti gbidanwo lati já aṣẹ ọkọ wọn gbà.

11. Ki ni o jẹ otitọ nipa ọpọlọpọ awọn obinrin, ki si ni onṣewe kan kọ nipa awọn obinrin ni akoko awọn babanla atijọ?

11 Ṣugbọn dé iwọn ti wọn ti dirọ timọtimọ mọ awọn ilana Bibeli, ọpọlọpọ awọn obinrin ti ri itẹlọrun ati ayọ. Eyi ri bẹẹ ni akoko awọn babanla atijọ. Ni sisọrọ nipa saa akoko yẹn ninu iwe rẹ La Bible au Féminin (Bibeli ni Ọrọ Ede Ti A Nlo Fun Obinrin), onkọwe Laure Aynard kọwe pe: “Ohun ti o gbafiyesi ni pataki ninu gbogbo awọn akọsilẹ wọnyi ni ipa pataki ti awọn obinrin kó, iyì ti wọn ni oju awọn babanla atijọ, idanuṣe onigboya wọn, ati ayika olominira ninu eyi ti wọn ngbe.”

Awọn Obinrin Labẹ Ofin Mose

12, 13. (a) Ki ni ipo awọn obinrin labẹ Ofin Mose? (b) Bawo ni nǹkan ṣe ri nipa tẹmi pẹlu awọn obinrin labẹ Ofin?

12 Ni ibamu pẹlu awọn ofin Jehofa ti a fifunni nipasẹ Mose, awọn aya ni a nilati “ṣikẹ.” (Deutaronomi 13:6, NW) Iyì awọn aya ni a nilati bọwọ fun ninu awọn ọran ibalopọ takọtabo, ko sì sí obinrin kankan ti a nilati lo ni ilokulo lọna ibalopọ takọtabo. (Lefitiku 18:8-19) Awọn ọkunrin ati obinrin dọgba loju Ofin bi a ba ri wọn ti wọn jẹbi panṣaga, ibalopọ pẹlu ibatan ti o sunmọra, tabi biba ẹranko dapọ. (Lefitiku 18:6, 23; 20:10-12) Ofin karun beere pe ọla kan naa ni ki a fifun iya ati baba.—Ẹkisodu 20:12.

13 Leke gbogbo rẹ, Ofin pese anfaani kikun fun awọn obinrin lati mu ipo tẹmi wọn dagba. Wọn janfaani lati inu kika Ofin naa. (Joṣua 8:35; Nehemaya 8:2, 3) A beere lọwọ wọn lati pa awọn ajọdun isin mọ. (Deutaronomi 12:12, 18; 16:11, 14) Wọn ṣajọpin ninu Isinmi ọsọọsẹ wọn si le jẹ́ ẹ̀jẹ́ Nasiri. (Ẹkisodu 20:8; Numeri 6:2) Wọn ni ipo ibatan ara ẹni pẹlu Jehofa wọn si gbadura si i lẹnikọọkan.—1 Samuẹli 1:10.

14. Ki ni ọmọwe Bibeli ti o jẹ Katoliki kan sọ nipa awọn obinrin Heberu, ki ni a si le sọ nipa ipa ti awọn obinrin kó labẹ ofin?

14 Ni sisọrọ lori awọn obinrin Heberu, akẹkọọ Bibeli jinlẹ Roland de Vaux ti o jẹ Katoliki kọwe pe: “Gbogbo iṣẹ aṣekara ni ile dajudaju já lori rẹ; o nbojuto awọn ọ̀wọ́ ẹran, ṣiṣẹ ninu papa, se ounjẹ, ṣe ìránwùú, ati bẹẹbẹẹ lọ. Bi o ti wu ki o ri, gbogbo ohun ti o jọ opo aṣekara yii, ko rẹ ipo rẹ walẹ rara, o mu un jere ìkàsí ni. . . . Ati awọn ayọka ṣiṣọwọn wọnni ti o fun wa ni ikofiri sinu isunmọra pẹkipẹki igbesi-aye idile fihan pe aya Isirẹli kan ni ọkọ rẹ fẹran ti o si tẹtisilẹ sí, ti o si baa lo gẹgẹ bi ẹni ti o dọgba pẹlu rẹ kan. . . . Ko sì sí iyemeji pe eyi jẹ aworan ti o wà deedee. O jẹ ifihan olootọ ti ẹkọ ti a pamọ ni mimọ ninu Jẹnẹsisi, nibi ti a ti sọ pe Ọlọrun da obinrin gẹgẹ bi oluranlọwọ fun ọkunrin, ẹni ti oun gbọdọ fà mọ́ (Jẹn. 2:18, 24); ori ti o sì kẹhin ninu Owe yin ti aya ile rere, ti awọn ọmọ rẹ bukun, ati ẹni afiyangan ọkọ rẹ (Owe 31:10-31).” (Ancient Israel—Its Life and Institutions) Laiṣiyemeji, nigba ti a tẹle Ofin naa ni Isirẹli, awọn obinrin ni a ko huwa si lọna buburu.

Awọn Obinrin Titayọ

15. (a) Bawo ni iwa Sara ṣe ṣakawe ipo ibatan ti o tọna laaarin ọkunrin kan ati aya rẹ? (b) Eeṣe ti ọran ti Rahabu fi yẹ fun afiyesi?

15 Iwe mimọ lede Heberu ni ọpọlọpọ apẹẹrẹ awọn obinrin ti wọn jẹ iranṣẹ titayọ ti Jehofa Ọlọrun. Sara pese akawe rere ti bi obinrin oniwa bi Ọlọrun kan ṣe le jẹ onitẹriba si ọkọ rẹ ki o si jẹ oluranlọwọ nigba kan naa fun un ninu ṣiṣe awọn ipinnu. (Jẹnẹsisi 21:9-13; 1 Peteru 3:5, 6) Ọran ti Rahabu yẹ fun akiyesi. O jadi irọ naa pe Jehofa Ọlọrun ni ẹtanu ẹya iran o si lekoko mọ awọn obinrin. Rahabu jẹ aṣẹwọ kan ti kii ṣe ọmọ Isirẹli. Kii ṣe kiki pe Jehofa tẹwọgba a gẹgẹ bi olujọsin kan ni ṣugbọn nitori igbagbọ nla rẹ, ti o fi iṣẹ papọ pẹlu iyipada ọna igbesi-aye tì lẹhin, o polongo rẹ gẹgẹ bi olododo. Ni afikun, o san ere ti o kọyọyọ ti didi iya-nla Mesaya naa fun un.—Matiu 1:1, 5; Heberu 11:31; Jakọbu 2:25.

16. Ki ni apẹẹrẹ Abigẹli ṣakawe, eesitiṣe ti a fi dá ọna igbesẹ rẹ lare?

16 Eyi ti nṣakawe rẹ pe Jehofa ko beere pe ki aya kan jẹ onitẹriba lọna ainironu fun ọkọ rẹ ni ọran ti Abigẹli. Ọkọ rẹ jẹ ọlọ́rọ̀ eniyan, ti o ni agbo nla agutan ati ewurẹ. Ṣugbọn ó jẹ “onroro ati oniwa buburu.” Abigẹli kọ̀ lati tẹle ọkọ rẹ ninu ipa-ọna buburu rẹ. Ni lilo idajọ rere, ọgbọn rere, irẹlẹ ọkan, ati ijafara, ó ṣedena ipo ti iba ti yọrisi ajalu ibi fun agbo ile rẹ, Jehofa si bukun fun un lọna jingbinni.—1 Samuẹli 25:2-42.

17. (a) Anfaani titayọ wo ni awọn obinrin kan ní ni Isirẹli? (b) Ẹkọ wo ni apẹẹrẹ Miriamu ni ninu fun awọn Kristian obinrin ti a le fun ni awọn anfaani iṣẹ-isin kan?

17 Awọn obinrin diẹ tilẹ jẹ wolii paapaa. Bẹẹ ni ọran ri pẹlu pẹlu Debora, lakooko awọn Onidajọ. (Awọn Onidajọ, ori 4 ati 5) Huldah ni a lo gẹgẹ bi wolii obinrin ni Juda, kete ṣaaju iparun Jerusalẹmu. (Ọba 22:14-20) Ọran ti Miriamu yẹ fun akiyesi. Bi o tilẹ jẹ pe a sọrọ nipa rẹ gẹgẹ bi wolii obinrin kan, ti Jehofa ran, lọna ti o han gbangba anfaani yii mu ki o gbọn loju ara rẹ ni akoko kan. O kuna lati mọyi aṣẹ ti Jehofa ti fun aburo rẹ ọkunrin Mose lati ṣaaju Isirẹli, a si fiya jẹ ẹ́ fun eyi, bi o tilẹ jẹ pe o ṣe kedere pe oun ronupiwada ti a si mu un padabọsipo.—Ẹkisodu 15:20, 21; Numeri 12:1-15; Mika 6:4.

Awọn Obinrin Labẹ Isin Awọn Juu

18, 19. Ki ni ipo awọn obinrin labẹ isin awọn Juu, bawo si ni eyi ṣe ṣẹlẹ?

18 Gẹgẹ bi a ti rii, Ofin Mose daabo bo ẹtọ awọn obinrin ati, nigba ti wọn ba tẹle e, yọnda awọn obinrin lati ni igbesi-aye ti o ntẹnilọrun. Ṣugbọn gẹgẹ bi akoko ti nlọ, ni pataki lẹhin iparun Jerusalẹmu ni 607 B.C.E., isin awọn Juu jẹ jade, eyi ti a gbekari awọn ofin atọwọdọwọ ọlọrọ ẹnu ju Ofin Jehofa ti a kọ silẹ lọ. Lati ọrundun kẹrin B.C.E. lọ, isin awọn Juu gba ọpọlọpọ ẹkọ ero-ori Giriiki wọle. Ni gbogbogboo afiyesi diẹ ni awọn ọmọran Giriiki ní si ẹtọ awọn obinrin, nitori naa ilọsilẹ ti o ṣe rẹgi niti ipo awọn obinrin laaarin isin awọn ara Juu waye. Lati ọrundun kẹta B.C.E., awọn obinrin ni a bẹrẹ sii yà sọtọ kuro lara awọn ọkunrin ninu sinagọgu awọn Juu a si ṣí wọn lọ́wọ́ kuro ninu kika Torah (Ofin Mose) Encyclopaedia Judaica jẹwọ pe: “Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀ awọn obinrin diẹ ni wọn mọwe.” Imọ ẹkọ ni o wa fun awọn ọdọmọkunrin nikan.

19 Ninu iwe rẹ Jerusalem in the Time of Jesus, J. Jeremias kọwe pe: “Lapapọ ipo awọn obinrin ninu ofin isin ni a ṣalaye lọna didara julọ ninu ètò awọn ọrọ ti a ntun sọ lemọlemọ yii: ‘Awọn obinrin, awọn ẹru (Keferi) ati ọmọ.’ . . . A le fi kun gbogbo eyi pe ọpọ yanturu awọn ero ti o kun fun iṣaata ti a nsọ si awọn obinrin ni wọn wa. . . . Nitori naa ero ti o tẹ mọ wa lọkan ni pe isin awọn Juu ni akoko Jesu ni ero ti o rẹlẹ gidigidi nipa awọn obinrin pẹlu.”

Awọn Obinrin Oluṣotitọ Ti Wọn Nduro De Mesaya Naa

20, 21. (a) Laika ẹmi-ironu ti o kun fun ẹgan ti awọn aṣaaju isin Juu si awọn obinrin si, awọn wo ni a o ri laaarin awọn wọnni ti wọn nṣọna gẹgẹ bi akoko fun Mesaya naa ti sunmọle? (b) Ki ni o fihan pe Elisabẹti ati Maria ni ifọkansin oniwa bi Ọlọrun jijinlẹ?

20 Ẹmi-ironu ti o kun fun ẹgan yii si awọn obinrin jẹ ọna miiran ninu eyi ti awọn rábì Juu gba “sọ ọrọ Ọlọrun di asan.” (Maaku 7:13) Ṣugbọn laika iṣaata yii si, gẹgẹ bi akoko fun dide Mesaya ti sunmọle, awọn obinrin oniwa bi Ọlọrun diẹ wa lojufo ṣamṣam. Ọkan lara awọn wọnyi ni Elisabẹti, aya alufaa Lefi naa Sekaraya. Oun ati ọkọ rẹ jẹ “olododo niwaju Ọlọrun, wọn nrin ni gbogbo ofin ohun ilana Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Luuku 1:5, 6) Elisabẹti ni Jehofa ṣoju rere si niti pe, bi o tilẹ jẹ pe oun ya àgàn ti o si ti darugbo, o di iya Johanu Arinibọmi.—Luuku 1:7, 13.

21 Oun ti a sun nipasẹ ẹmi mimọ, Elisabẹti fi ifẹ jijinlẹ han fun obinrin oniwa bi Ọlọrun miiran ni ọjọ rẹ, ibatan kan ti a npe ni Maria. Nigba ti o fẹrẹẹ di opin 3 B.C.E., angẹli Geburẹli sọ fun Maria pe oun yoo loyun ọmọ kan (Jesu) lọna iyanu, O sọ taarata fun pe, “Iwọ ẹni ti a ṣe oju rere ti o ga si,” o fikun pe: “Jehofa wà pẹlu rẹ.” Laipẹ lẹhin naa, Maria bẹ Elisabẹti wo, ẹni ti o súre fun un ati ọmọ ti a ko tii bí naa ti oun loyun rẹ, ni pipe Jesu ni “Oluwa” rẹ ani ṣaaju ki a to bi paapaa. Bakan naa, Maria ki ẹnu bọ ọrọ iyin si Jehofa eyi ti o jẹrii daradara si ifọkansin oniwa bi Ọlọrun jijinlẹ rẹ.—Luuku 1:28, 31, 36-55.

22. Lẹhin ìbí Jesu, obinrin olubẹru Ọlọrun wo ni o fihan pe oun ti wa laaarin awọn wọnni ti wọn nduro de Mesaya?

22 Nigba ti a bi Jesu ti Maria si mu un wa sinu tẹmpili ni Jerusalẹmu lati fihan niwaju Jehofa, obinrin olubẹru Ọlọrun miiran, Hana wolii obinrin arugbo naa, fi idunnu rẹ han. O dá ọpẹ pada sọdọ Jehofa o si sọ nipa Jesu fun gbogbo awọn ti wọn nfi aniyan reti Mesaya ti a ti ṣeleri naa.—Luuku 2:36-38.

23. Bawo ni apọsteli Peteru ṣe sọrọ nipa iṣotitọ awọn obinrin ṣaaju akoko Kristian, awọn ibeere wo ni a o si gbé yẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e?

23 Nipa bayii, gẹgẹ bi akoko fun iṣẹ-ojiṣẹ Jesu ti orilẹ-aye ti sunmọle, ‘awọn obinrin mimọ ti wọn gbẹkẹle Ọlọrun’ ṣi walaaye sibẹ. (1 Peteru 3:5) Diẹ lara awọn obinrin wọnyi di ọmọ-ẹhin Kristi. Bawo ni Jesu ṣe huwa si wọn? Awọn obinrin ha wà lonii ti wọn tẹwọgba ojuṣe wọn gẹgẹ bi a ti là á lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli? Awọn ibeere wọnyi ni a o ṣayẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Idipọ 3, oju-iwe 1055.

b “Adamu ikẹhin,” Jesu Kristi, bakan naa jẹ eniyan pipe, ti ko lábùkù, bi o tilẹ jẹ pe oun ko ni aya ẹda eniyan kankan.—1 Kọrinti 15:45.

Awọn Ibeere fun Atunyẹwo

◻ Bawo ni ọna ti a ngba huwa si awọn obinrin ni Isirẹli ṣe yatọ gidigidi si ti awọn ilẹ miiran?

◻ Ki ni awọn ipo alaala ti Adamu ati Efa, eesitiṣe?

◻ Ipo wo ni awọn obinrin Isirẹli ni labẹ Ofin, wọn ha si padanu nipa tẹmi bi?

◻ Ki ni awọn ẹkọ diẹ ti a le kọ lati inu igbesi-aye awọn obinrin titayọ ninu Iwe mimọ lede Heberu?

◻ Awọn apẹẹrẹ rere ti igbagbọ wo ni a le ri laika oju-iwoye isin awọn Juu si?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

“OBINRIN NAA TI O BẸRU JEHOFA”

“10 Ta ni yoo ri obinrin oniwa rere? Nitori ti iye rẹ kọja iyun. 11 Àyà ọkọ rẹ gbẹkẹle laibẹru, bẹẹni oun ki yoo ṣe alaini ere iṣẹ. 12 Rere ni obinrin naa yoo ma ṣe fun un, kii ṣe buburu ni ọjọ aye rẹ gbogbo. 13 Obinrin naa yoo maa ṣafẹri irun agutan ati ọ̀gbọ̀, o si fi ọwọ rẹ ṣiṣẹ tinutinu. 14 O dabi ọkọ̀ oniṣowo: O si mu ounjẹ rẹ lati ọna jijin réré wá. 15 Oun a si dide nigba ti ilẹ ko tii mọ, a si fi ounjẹ fun eniyan ile rẹ, ati iṣẹ oojọ fun awọn ọmọbinrin rẹ. 16 O kiyesi oko, o si mu un: Èrè ọwọ rẹ ni o fi gbin ọgba ajara. 17 O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ́ rẹ ní ọja, o si mu apa rẹ̀ mejeeji le. 18 O kiyesi pe ọja oun dara: Fitila rẹ̀ kò kú ní òru. 19 O fi ọwọ rẹ le kẹkẹ òwú, ọwọ́ rẹ̀ si di ìránwúù mu. 20 O na ọwọ rẹ si talaka; nitootọ, ọwọ rẹ si kan alaini. 21 Oun ko si bẹru sno [“ojo didi,” NW] fun awọn ara ile rẹ; nitori pe gbogbo awọn ara ile rẹ ni a wọ ni aṣọ iṣẹpo meji. 22 Oun si wun aṣọ títẹ́ fun araarẹ; ẹwu daradara ati elése aluko ni aṣọ rẹ. 23 A mọ ọkọ rẹ ni ẹnu ibode, nigba ti o ba jokoo pẹlu awọn agba ilẹ naa. 24 O da aṣọ ọ̀gbọ̀ daradara, o si tà á, pẹlupẹlu o fi ọ̀já àmùrè fun oniṣowo tà. 25 Agbara ati iyin ni aṣọ rẹ̀; oun o si yọ si ọjọ́ ti nbọ. 26 O fi ọgbọn ya ẹnu rẹ; ni ahọn rẹ ni ofin iṣehun. 27 O fi oju silẹ wo iwa awọn ara ile rẹ. Ko si jẹ ounjẹ imẹlẹ. 28 Awọn ọmọ rẹ dide, wọn si pè é ni alabukunfun, ati baale rẹ pẹlu, oun si fi iyin fun un pe, 29 Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin ni o nhuwa rere, ṣugbọn iwọ ta wọn yọ. 30 Oju daradara ni ẹtan, ẹwa si jasi asan: Ṣugbọn obinrin [naa] ti o bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ni ki a fi iyin fun. 31 Fi fun un ninu eso iṣẹ ọwọ rẹ; jẹ ki iṣẹ ọwọ rẹ ki o si yin in ni ẹnubode.”—Owe 31:10-31.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ipo obinrin ninu idile ni a buyin kun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́