ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/08 ojú ìwé 4-7
  • Ojú Wo Ni Ọlọ́run Àti Kristi Fi Ń wo Àwọn Obìnrin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojú Wo Ni Ọlọ́run Àti Kristi Fi Ń wo Àwọn Obìnrin?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Ṣojúure Sí
  • “Aya Tí Ó Dáńgájíá”
  • Máa Bọlá fún Wọn
  • Àwọn Kristian Obìnrin yẹ fún Ọlá àti Ọ̀wọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ipa-iṣẹ́ Oníyì Ti Àwọn Obìnrin Láàárín Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Ní Ìjímìjí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Wọ́n Wà Ní Ipò Ọ̀wọ̀ àti Iyì Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 1/08 ojú ìwé 4-7

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Àti Kristi Fi Ń wo Àwọn Obìnrin?

BÁWO la ṣe lè ní òye kíkún nípa ojú tí Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ni pé ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà àti ìṣe Jésù Kristi, tó jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí” tó sì fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin. (Kólósè 1:15) Ọ̀nà tí Jésù gbà báwọn obìnrin lò nígbà tó wà láyé fi hàn pé Jèhófà àti Jésù ka àwọn obìnrin sí, ó sì jẹ́ ká rí i dájú pé àwọn méjèèjì ò fọwọ́ sí i pé káwọn èèyàn máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba bí wọ́n ṣe ń ṣe lọ́pọ̀ ilẹ̀ lóde òní.

Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá kànga. Ìwé Ìhìn Rere ti Jòhánù sọ pé: “Obìnrin ará Samáríà kan wá fa omi. Jésù wí fún un pé: ‘Fún mi mu.’” Jésù ṣe tán láti bá obìnrin ará Samáríà náà sọ̀rọ̀ ní gbangba, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù kì í báwọn ará Samáríà da nǹkan pọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan, ìyẹn The International Standard Bible Encyclopedia, tiẹ̀ sọ pé lójú àwọn Júù, “ìwà tí kò bójú mu ni pé kéèyàn máa bá obìnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba.” Àmọ́ ṣá o, Jésù fọ̀wọ̀ tó yẹ àwọn obìnrin wọ̀ wọ́n, ó gba tiwọn rò, kò ṣe ẹ̀tanú sí wọn bóyá nítorí pé ẹ̀yà tiwọn yàtọ̀ sí tiẹ̀ tàbí pé wọn kì í ṣe ọkùnrin bíi tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, obìnrin ará Samáríà yẹn gan-an ni Jésù kọ́kọ́ sọ fún pé òun ni Mèsáyà.—Jòhánù 4:7-9, 25, 26.

Lákòókò mìíràn, obìnrin kan tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀, tí àìsàn burúkú náà sì ti ń ṣe é láti ọdún méjìlá sẹ́yìn, tọ Jésù wá. Nígbà tó fọwọ́ kan Jésù, lọ́gán lara ẹ̀ yá. “Jésù yíjú padà àti pé, ní kíkíyèsí i, ó wí pé: ‘Mọ́kànle, ọmọbìnrin; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.’” (Mátíù 9:22) Gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ṣe sọ, kò yẹ kí obìnrin tó bá wà nírú ipò tó wà yẹn wá sáàárín èrò, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kó tún wá lọ fọwọ́ kan ẹlòmíì. Síbẹ̀, Jésù ò nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yọ́nú sí i, ó sì fi í lára balẹ̀ nípa pípè é ní “ọmọbìnrin.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Jésù yẹn á ṣe mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ tó! Inú Jésù náà sì ti ní láti dùn gan-an pé òun mú un lára dá!

Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, Màríà Magidalénì àti òmíràn lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí Bíbélì pè ní “Màríà kejì,” ló kọ́kọ́ fara hàn. Jésù lè kọ́kọ́ fara han Pétérù, Jòhánù, tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ míì tó jẹ́ ọkùnrin. Àmọ́, ó buyì kún àwọn obìnrin nípa kíkọ́kọ́ fara hàn wọ́n lẹ́yìn tó jíǹde. Áńgẹ́lì kan sọ fáwọn obìnrin náà pé kí wọ́n lọ ròyìn ohun àgbàyanu tí wọ́n rí yìí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin. Jésù sọ fáwọn obìnrin náà pé: “Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi.” (Mátíù 28:1, 5-10) Àwọn Júù ìgbà ayé Jésù gbà pé kò yẹ kéèyàn máa fi obìnrin ṣe ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́, àmọ́ Jésù ò bá wọn lọ́wọ́ sí irú ẹ̀tanú tó wọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, dípò kí Jésù máa ṣe ẹ̀tanú sáwọn obìnrin tàbí kó máa tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí, ó máa ń fi ọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n, ó sì mọrírì wọn. Fífìyà jẹ obìnrin lòdì pátápátá sí ohun tí Jésù fi kọ́ni, ó sì dá wa lójú pé ìwà rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ pípé nípa ojú tí Bàbá rẹ̀, Jèhófà fi ń wo nǹkan.

Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Ṣojúure Sí

Nígbà tí ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì kan ń ṣàpèjúwe ọwọ́ táwọn èèyàn fi ń mú àwọn obìnrin láyé àtijọ́, ó sọ pé: “Kò síbì kankan ní Mẹditaréníà ìgbàanì tàbí láwọn orílẹ̀-èdè kan tí Bíbélì mẹ́nu bà lágbègbè ibẹ̀ táwọn obìnrin ti ní irú òmìnira tí wọ́n ní lóde òní láwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù. Ohun tó wọ́pọ̀ jù nígbà yẹn ni pé káwọn ọkùnrin tẹ àwọn obìnrin lórí ba, bí ẹrú tí kò lẹ́nu ọ̀rọ̀ níwájú ẹni tó wà lómìnira, àti bí ọmọdé tí kò gbọ́dọ̀ yẹ àgbà lẹ́nu wò. . . . Ọmọkùnrin nìkan ni wọ́n kà sọ́mọ gidi, wọ́n sì máa ń fàwọn ọmọbìnrin sílẹ̀ láìtọ́jú nígbà míì kí wọ́n bàa lè kú.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú ẹrú ni wọ́n fi máa ń wò wọ́n.

Àkókò tírú àṣà àti ìwà yìí gbilẹ̀ gan-an ni wọ́n kọ Bíbélì. Síbẹ̀ náà, òfin Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ò kóyán àwọn obìnrin kéré, ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí àṣà tó gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn ìgbàanì.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ níbi tí Jèhófà ti dá sí ọ̀ràn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ obìnrin fi hàn pé kò fẹ́ wọn fún ìyà rárá. Ẹ̀ẹ̀mejì ló dá sí ọ̀ràn Sárà, ìyàwó Ábúráhámù tó rẹwà lóbìnrin, kí wọ́n má bàa fipá bá a lò pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 12:14-20; 20:1-7) Ọlọ́run ṣojúure sí Léà, tí Jékọ́bù ọkọ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn, nípa ‘ṣíṣí ilé ọlẹ̀’ rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan. (Jẹ́nẹ́sísì 29:31, 32) Nígbà táwọn méjì tó jẹ́ agbẹ̀bí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn ọmọkùnrin táwọn Hébérù bá bí káwọn ará Íjíbítì má bàa pa wọ́n, Jèhófà fi ìmọrírì hàn fún ohun tí wọ́n ṣe, ó sì “fún wọn ní àwọn ìdílé.” (Ẹ́kísódù 1:17, 20, 21) Ó tún dáhùn àdúrà tí Hánà fi tọkàntọkàn gbà. (1 Sámúẹ́lì 1:10, 20) Nígbà tó sì di pé ayánilówó wá bá aya wòlíì kan tó di opó, tó sì fẹ́ fi àwọn ọmọ rẹ̀ dí owó tí opó náà jẹ ẹ́, Jèhófà ò dá opó náà dá ìṣòro ẹ̀. Tìfẹ́tìfẹ́ ni Ọlọ́run fi mú kó ṣeé ṣe fún wòlíì Èlíṣà láti sọ òróró obìnrin náà di púpọ̀ kó lè tà á láti fi san gbèsè tó jẹ, kí èyí tóun àti ìdílé rẹ̀ á máa rí lò sì tún ṣẹ́ kù. Ọlọ́run tipa báyìí bò ó láṣìírí ó sì tún buyì kún un.—Ẹ́kísódù 22:22, 23; 2 Àwọn Ọba 4:1-7.

Lemọ́lemọ́ làwọn wòlíì Ọlọ́run ń sọ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run ò fẹ́ kí wọ́n máa kó àwọn obìnrin nífà kò sì fẹ́ kí wọ́n máa fìyà jẹ wọ́n. Wòlíì Jeremáyà sọ fáwọn Ọmọ Ísírẹ́lì lórúkọ Jèhófà pé: “Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo, ẹ sì dá ẹni tí a ń jà lólè nídè kúrò lọ́wọ́ oníjìbìtì; má sì ṣe àtìpó èyíkéyìí, ọmọdékùnrin aláìníbaba tàbí opó níkà. Má ṣe ohun àìtọ́ kankan sí wọn. Má sì ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ èyíkéyìí sílẹ̀ ní ibí yìí.” (Jeremáyà 22:2, 3) Ṣáájú ìgbà yẹn, Ọlọ́run dẹ́bi fáwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn alágbára nílẹ̀ Ísírẹ́lì nítorí pé wọ́n lé àwọn obìnrin jáde kúrò nínú ilé wọn, wọ́n sì fìyà jẹ àwọn ọmọdé. (Míkà 2:9) Ọlọ́run ẹ̀san rí ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọ wọn, ó sì dẹ́bi fún irú ìwà búburú bẹ́ẹ̀.

“Aya Tí Ó Dáńgájíá”

Òǹkọ̀wé ìgbàanì tó kọ ìwé Òwe inú Bíbélì sọ ojú tó dáa kéèyàn máa fi wo aya tó dáńgájíá. Níwọ̀n bí Jèhófà ti yọ̀ǹda ká kọ àpèjúwe tó fani mọ́ra yìí nípa ojúṣe àti ipò aya nínú ilé sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó dájú pé ó fọwọ́ sí i nìyẹn. Dípò kí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ aya tó dáńgájíá bí ẹni àtẹ̀mẹ́rẹ̀ tàbí ẹni rírẹlẹ̀, ó sọ pé ó jẹ́ obìnrin tá a mọrírì rẹ̀, tá a kà sí, tá a sì gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́.

“Aya tí ó dáńgájíá” tí ìwé Òwe orí 31 sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ akíkanjú àti òṣìṣẹ́ kára. Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára kó bàa lè ṣe “ohun yòówù tí ọwọ́ ara rẹ̀ ní inú dídùn sí,” ó máa ń ṣòwò, ó sì máa ń bójú tó ọ̀ràn dúkìá ilé àti ilẹ̀. Ó rí pápá kan, ó sì rà á. Ó ń hun aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ó sì ń tà wọ́n. Ó ń fi ìgbànú fáwọn ọkùnrin oníṣòwò. Ó lágbára, kì í sì í fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré. A tún mọrírì ọgbọ́n rẹ̀ àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi. Nítorí èyí, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọyì rẹ̀ gan-an. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Jèhófà náà mọyì rẹ̀.

Nítorí náà, àwọn obìnrin kì í ṣe aláraágbàyà táwọn ọkùnrin tí kì í gba tẹni rò á máa fìyà jẹ, tí wọ́n á sì máa fòòró ẹ̀mí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí obìnrin tó bá ti ṣègbéyàwó máa láyọ̀, kó sì máa ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àṣekún” ọkọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18.

Máa Bọlá fún Wọn

Nígbà tí Pétérù, òǹkọ̀wé Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí, ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó jẹ́ ọkọ nípa ọwọ́ tó yẹ kí wọ́n máa fi mú àwọn aya wọn, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa fi ìwà Jèhófà àti ti Jésù Kristi ṣe àwòkọ́ṣe. Ó kọ̀wé pé: ‘Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní fífi ọlá fún wọn.’ (1 Pétérù 3:7) Béèyàn bá ń fi ọlá fún ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé èèyàn mọrírì onítọ̀hún, èèyàn sì ń kà á sí gidigidi. Nítorí náà, ọkùnrin tó bá ń fi ọlá fún ìyàwó rẹ̀ ò ní máa dójú tì í, kò ní máa wọ́ ọ nílẹ̀, kò sì ní máa fìyà jẹ ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, yálà ní ìkọ̀kọ̀ tàbí ní gbangba, pé òun ń ṣìkẹ́ rẹ̀ òun sì fẹ́ràn rẹ̀.

Fífi ọlá fún ìyàwó ẹni máa ń mú kí ayọ̀ wà nínú ìgbéyàwó. Jẹ́ ká wo bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Carlos àti Cecilia. Lẹ́yìn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé bíi tọkọtaya, ó di pé kí wọ́n máa bára wọn jiyàn, láìfi orí ọ̀rọ̀ tì síbì kan. Wọ́n sì tún máa ń yan ara wọn lódì nígbà míì. Wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro wọn. Ọkọ ya oníjàgídíjàgan; ìyàwó lágídí ó sì máa ń gbéra ga. Àmọ́, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí sunwọ̀n sí i fún wọn. Èyí ìyàwó, ìyẹn Cecilia, sọ pé: “Mo mọ̀ pé ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ló ran èmi àti ọkọ mi lọ́wọ́ láti yí ìwà wa padà. Ọpẹ́lọpẹ́ àpẹẹrẹ Jésù, mo ti wá níwà ìrẹ̀lẹ̀ àti òye tó pọ̀ sí i báyìí. Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Ọkọ mi náà túbọ̀ ní ìpamọ́ra, ó sì ń kó ara rẹ̀ níjàánu, ó ti wá mọ bó ṣe lè máa bọlá fún mi bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó ṣe.”

Kì í ṣe pé kò sí àléébù kankan nínú ìgbéyàwó wọn o, àmọ́ ọjọ́ pẹ́ báyìí tí wọ́n ti jọ ń bá a bọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, ìṣòro tó le koko bá Carlos àti ìyàwó rẹ̀ fínra, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ nítorí pó ní àrùn jẹjẹrẹ. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn ìṣòro wọ̀nyí ń peléke sí i, mìmì kan ò tìtorí ẹ̀ mi ìgbéyàwó wọn.

Látìgbà táráyé ti di aláìpé lọ̀pọ̀ èèyàn nílé lóko ò ti ka àwọn obìnrin sí mọ́. Wọ́n máa ń fìyà jẹ wọ́n, wọ́n máa ń fòòró wọn, wọ́n sì máa ń fipá bá wọn lò pọ̀. Àmọ́, Jèhófà ò pe tàwọn obìnrin níyà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì tiẹ̀ fi hàn kedere pé kì í ṣe ojú táwọn èèyàn nílé lóko fi ń wo ọ̀ràn náà ló jà jù, bí kò ṣe pé Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn máa fi ọlá fáwọn obìnrin níbi gbogbo ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún wọn nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Obìnrin ará Samáríà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Obìnrin aláìsàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Màríà Magidalénì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Jèhófà dáàbò bo Sárà lẹ́ẹ̀mejì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìgbéyàwó Carlos àti Cecilia wà nínú ìṣòro

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Carlos àti Cecilia rèé báyìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́