ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/97 ojú ìwé 3-4
  • Ó Yẹ Kí A Jẹ́ Olùkọ́, Kì Í Ṣe Oníwàásù Nìkan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Yẹ Kí A Jẹ́ Olùkọ́, Kì Í Ṣe Oníwàásù Nìkan
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àyẹ̀wò Tó Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Ìjẹ́kánjúkánjú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 12/97 ojú ìwé 3-4

Ó Yẹ Kí A Jẹ́ Olùkọ́, Kì Í Ṣe Oníwàásù Nìkan

1 A ti kíyè sí i pé “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ìjẹ́rìí wọn dé gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” Báwo ni èyí ti ṣeé ṣe? Kì í ṣe nípa okun tàbí agbára ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń ṣiṣẹ́ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ti ń lo onírúurú àwọn ìpèsè láti mú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn ṣe.—Sek. 4:6; Ìṣe 1:8.

2 Ìwé tí a tẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù wa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwé, ìwé ìléwọ́, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn, àti àṣàrò kúkúrú ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ tí wọ́n sì ti pín kiri láti mú kí ìhìn rere Ìjọba náà di mímọ̀. Ìròyìn inú ìwé 1997 Yearbook fi hàn pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ti tẹ̀ jáde ti dórí ìwọ̀n tí kò lẹ́gbẹ́. Títí di ìsinsìnyí, ẹ̀dà Bíbélì New World Translation tí ó ju mílíọ̀nù 91 ni a ti tẹ̀. Ní ọdún kan ṣoṣo, iye ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí a tẹ̀ ní United States fi ìpín 7.1 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè. Ní Germany, ìwé ìròyìn tí a tẹ̀ fi ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè. Èyí tí ó ju ìdá mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìròyìn tí a tẹ̀ níbẹ̀ wà fún pápá ilẹ̀ Rọ́ṣíà.

3 Èé ṣe tí a fi nílò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Yíká ilẹ̀ ayé, ìdáhùnpadà púpọ̀ gan-an ní ń bẹ sí ìṣírí tí a fún wa láti jẹ́rìí níbikíbi tí a ti lè rí àwọn ènìyàn. Bí púpọ̀ nínú wa ti ń mú iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa gbòòrò sí i—ní àwọn ibi tí gbogbo ènìyàn ń lò, ní òpópónà, àti ní àwọn ìpínlẹ̀ iṣẹ́ ajé—ọ̀pọ̀ yanturu ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ni a ń fún àwọn ènìyàn tí ó fi ìfẹ́ ọkàn hàn. Bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ni ó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tẹ́lẹ̀. Láti lè kúnjú àìní yìí, àwọn ìjọ máa ń ní onírúurú ìtẹ̀jáde lọ́wọ́ tí wọ́n lè lò nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́.

4 Kí Ni Ète Tí A Fi Ń Pín Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́? Ète wa kì í ṣe wíwulẹ̀ fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde. Àṣẹ náà láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn ní apá méjì nínú—wíwàásù àti kíkọ́ni. Lákọ̀ọ́kọ́, a ní àǹfààní náà láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ní jíjẹ́ kí ó di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn pé òun nìkan ṣoṣo ni ìrètí aráyé. (Mát. 10:7; 24:14) Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tí a gbé karí Bíbélì ni ẹ̀rí ti fi hàn pé ó gbéṣẹ́, ó sì jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti ru ọkàn ìfẹ́ sókè, tí a sì fi ń fún àwọn ẹlòmíràn ní ìmọ̀ nípa Ìjọba náà.

5 Èkejì, bí a óò bá sọni di ọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ kọ́ni ní gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ. (Mát. 11:1; 28:19, 20) Síwájú sí i, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ń kó ipa pàtàkì nínú gbígbin òtítọ́ sínú ọkàn àyà àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn.

6 Àwọn tí ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lè jẹ́ “olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà,” ṣùgbọ́n agbára káká ni wọ́n fi lè di olùṣe ọ̀rọ̀ náà bí a bá pa wọ́n tì. (Ják. 1:22-25) Àwọn kéréje ni yóò di ọmọ ẹ̀yìn àyàfi bí ẹnì kan bá tọ́ wọn sọ́nà. (Ìṣe 8:30, 31) Wọ́n nílò olùkọ́ tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú òtítọ́ tí a rí nínú Ìwé Mímọ́ dá wọn lójú. (Ìṣe 17:2, 3) Góńgó ìlépa wa ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí, kí a sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti di ẹni tí ó tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.—2 Tím. 2:2.

7 A Túbọ̀ Nílò Olùkọ́ Púpọ̀ Sí I: Nígbà tí a bá wàásù, a ń polongo ìhìn rere náà ní gbangba. Ṣùgbọ́n, kíkọ́ni ní fífún ẹnì kan nítọ̀ọ́ni lọ́nà tí ń tẹ̀ síwájú nínú. Nígbà tí ó jẹ́ pé wíwàásù ń mú kí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, kíkọ́ni ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀. (Lúùkù 8:15) Olùkọ́ ń ṣe ju pípòkìkí; ó ń ṣàlàyé, ó ń fi àlàyé tí ó kúnná báni ronú pọ̀, ó ń pèsè ẹ̀rí, ó sì ń yíni lérò pa dà.

8 Púpọ̀ lára wa bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó ni ó yẹ kí ó jẹ́ olùkọ́, kì í ṣe oníwàásù nìkan. (Héb. 5:12a) Pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n ṣíṣe àṣeyọrí ohun kejì tí a ń lépa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sinmi pátápátá lórí ohun tí a bá ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa máa ń dùn nígbà tí a bá fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde, láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, a kò gbọ́dọ̀ wo ìwé tí a fi sóde gẹ́gẹ́ bí òpin góńgó wa. (2 Tím. 4:5) Àwọn ìwé tí a ń fi sóde jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti ṣí ilẹ̀kùn sí àwọn àǹfààní láti fi òtítọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn.

9 Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Láti Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Ó ṣeé ṣe kí gbogbo wa ti fi ọ̀pọ̀ ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé ìròyìn sóde, tí ó para pọ̀ jẹ́ ìpadàbẹ̀wò. Ó yẹ kí a máa ṣètò àkókò déédéé láti pa dà lọ ru ọkàn ìfẹ́ sókè. Ète pàtàkì tí a fi ń pa dà lọ kì í ṣe láti wulẹ̀ lọ fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i sóde, ṣùgbọ́n láti fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti ka èyí tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì jàǹfààní láti inú rẹ̀. Báwo ni àwa fúnra wa ì bá ti tẹ̀ síwájú tó nípa tẹ̀mí ká ní ẹnì kan kò pa dà wá léraléra láti ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye?—Jòhánù 17:3.

10 Pa dà ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́ tí a fi hàn pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yálà nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwọn ìtẹ̀jáde méjèèjì yí gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà tí ó rọrùn láti lóye. Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tí ó kún rẹ́rẹ́, ó kárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì. Ìwé Ìmọ̀ ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti túbọ̀ fi kúlẹ̀kúlẹ̀ òtítọ́ kọ́ni, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó rọrùn, tí ó ṣe kedere, tí ó sì ṣe ṣókí.

11 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí a mú rọrùn sí i, tí a ṣàlàyé nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, mú kí ó rọrùn fún olùkọ́ láti kọ́ni àti fún akẹ́kọ̀ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Tọ́jú ẹ̀dà àkìbọnú yẹn sí ibi tí ọwọ́ rẹ ti lè tètè tó o láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀nà àti ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ti gbéṣẹ́. Díẹ̀ lára àwọn àbá tí ó fúnni jẹ́ bí a ṣe lè ní ojúlówó ọkàn ìfẹ́ nínú akẹ́kọ̀ọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a óò kárí ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan yóò ti pọ̀ tó, bí a ṣe lè bójú tó àwọn ìbéèrè tí kò jẹ mọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà, bí olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè múra sílẹ̀ ṣáájú fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àti bí a ṣe lè darí akẹ́kọ̀ọ́ sí ètò àjọ Jèhófà. Nípa títẹ̀lé àwọn àbá náà, púpọ̀ sí i nínú wa, títí kan àwọn ẹni tuntun, ni yóò ṣeé ṣe fún láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń tẹ̀ síwájú.

12 Ìròyìn Nípa Àṣeyọrí Sí Rere Láti Pápá: Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ ti jẹ́ àrànṣe tí ó ṣeyebíye ní mímú kí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yára kánkán. Lẹ́yìn tí ó ti rí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè gbà, arákùnrin kan ní Bolivia lò ó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọkùnrin kan. Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà ní àpéjọpọ̀ àgbègbè, akẹ́kọ̀ọ́ yìí wà lára àwọn aláyọ̀ tí ó ṣe batisí!

13 Ọ̀pọ̀ ni a ń sún láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nínú ìwé Ìmọ̀. Nínú ìjọ kan ní Angola, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn akéde ń darí lọ sókè láti 190 sí 260, iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé sì di ìlọ́po méjì láti 180 sí 360 ní oṣù mẹ́rin péré lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo ìwé Ìmọ̀ ní àgbègbè yẹn. Kété lẹ́yìn náà, ó di dandan láti dá ìjọ mìíràn sílẹ̀.

14 Lẹ́yìn tí arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìmọ̀, ó sọ pé dídarí rẹ̀ “rọrùn bí olùdarí náà bá wulẹ̀ ń béèrè àwọn ìbéèrè, tí ó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan tí ó tan mọ́ ọn, tí ó sì rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ náà lóye rẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti máa ń rò pé àwọn akéde tí ó tóótun dáadáa nìkan ni ó lè darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń tẹ̀ síwájú àti pé òun kò lè ṣe é láé, ó wá rí i pé òun lè ṣe é, ó sọ pé: “Bí mo bá lè ṣe é, ẹnikẹ́ni lè ṣe é.”

15 Nípa dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni a fi lè ṣàṣeparí ìlépa wa láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn tí wọ́n ti mú agbára láti nípìn-ín nínú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí dàgbà ti rí i pé ó ń tẹ́ni lọ́rùn ní tòótọ́ tí ó sì ń mú èrè jìngbìnnì wá. Ǹjẹ́ kí a lè sọ nípa wa pé àwa pẹ̀lú ‘ń wàásù ìjọba Ọlọ́run . . . tí a sì ń kọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà.’—Ìṣe 28:31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́