Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn August
Av. Av. Av. Av.
Iye: Hrs. Mags. R.V. Bi.St.
Aṣá. Àkàn. 407 139.0 13.0 66.0 11.0
Aṣá. Déédé 19,554 68.0 6.0 25.0 6.0
Aṣá. Olù. 6,605 57.0 4.0 16.0 4.0
Akéde 176,554 11.0 1.0 4.0 1.0
ÀRÒPỌ̀ 203,110 Àwọn Tí A Batisí: 813
A láyọ̀ láti ròyìn pé ìròyìn wa ti August mú ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997 wá sí òpin aláyọ̀ gan-an pẹ̀lú góńgó tuntun tí ó tí ì ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 203,110 akéde. Iye 19,554 aṣáájú ọ̀nà déédéé tí wọ́n ròyìn jẹ́ góńgó tuntun pẹ̀lú. Nísinsìnyí, a ní 3,944 ìjọ tí wọ́n forúkọ sílẹ̀.
Apá kan nínú ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 1997 tí ó fúnni níṣìírí gidigidi ni pé, fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn iṣẹ́ Ìjọba náà ní Nàìjíríà, a ní 17,304 tí wọ́n ṣe batisí nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn kan ṣoṣo. Pẹ̀lúpẹ̀lù, iye àwọn tí ó wá sí Ìṣe Ìrántí ní 1997 jẹ́ 598,717. Èyí dúró fún ìlọsókè ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún ju 520,413 tí wọ́n wá ní 1996. A kún fún ìmoore sí Jèhófà fún bíbùkún iṣẹ́ wa lọ́nà tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní ọdún yìí. A fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti fún fífi àsansílẹ̀ owó sóde ní àfiyèsí púpọ̀ sí i, nítorí pé ó lọ sílẹ̀ ní ìpín 2.9 nínú ọgọ́rùn-ún ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá.