Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
Àwọn àǹfààní gidi wo lò ń rí gbà nísinsìnyí láti inú rírìn pẹ̀lú Jèhófà? Báwo lo ṣe lè dènà ìdẹwò jíjẹ́ kí àwọn ìlépa tí kì í ṣe ti ìṣàkóso Ọlọ́run ti àwọn ire Ìjọba náà kúrò ní ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ? (Mát. 6:33) Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ láti mọ ohun tí ó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́ nínú ayé kan tó máa ń mú kí ohun tí kò tọ́ dà bíi pé ó tọ́? (Héb. 5:14) A óò jíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ní àpéjọ àyíká náà, “Jàǹfààní Nísinsìnyí Nípa Rírìn ní Ọ̀nà Ọlọ́run,” tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù January 2000.—Sm. 128:1.
Ṣíṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ yóò jẹ́ apá tuntun kan ní ọjọ́ Saturday àpéjọ àyíká yìí. Alábòójútó àyíká yín yóò sọ fún àwọn ìjọ nípa àwọn ohun tí a wéwèé, kí gbogbo yín lè múra wá láti gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
Apá tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ̀yin Aṣáájú Ọ̀nà—Ẹ Máa Kíyè Sára Gidigidi Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Rìn” yóò fi hàn wá bí a ṣe lè máa lo ọgbọ́n àti òye láti lè máa ra àkókò rírọgbọ padà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. (Éfé. 5:15-17) Kókó ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Ṣọ́ra fún Àwọn Ọ̀Ọ̀nà Tó Dà Bí Eyí Tó Tọ́,” yóò kọ́ wa bí a ṣe lè ní ìdánilójú nípa ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Àsọyé náà, “Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ní Ìmúṣẹ Ṣe Ń Ní Ipa Lórí Wa,” yóò ṣèrànwọ́ láti fi ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún èrò inú àti ọkàn-àyà wa. Àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tó ní àkọlé náà, “Ọ̀nà Ọlọ́run Ń Ṣàǹfààní Gidigidi!,” yóò tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní gidi tí a ń rí gbà nísinsìnyí nínú ṣíṣe gbogbo ohun tí òdodo Jèhófà ń béèrè.
Ǹjẹ́ o fẹ́ láti fi hàn ní gbangba nípa ìrìbọmi pé o ń fẹ́ láti rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣèyàsímímọ́? Nígbà náà, bá alábòójútó olùṣalága sọ̀rọ̀, kí ó lè ṣe àwọn ètò tó bá yẹ.
Jẹ́ kó jẹ́ ìpinnu rẹ láti má ṣe pa àpéjọ àyíká tó bágbà mu yìí jẹ. Wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ méjèèjì tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò fi wáyé, nítorí “aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”—Sm. 128:1.