ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/10 ojú ìwé 1
  • Ǹjẹ́ Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Ọ Lọ́rùn Kó O Lè Túbọ̀ Máa Yin Ọlọ́run
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Fún Ojú
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 6/10 ojú ìwé 1

Ǹjẹ́ Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan?

1. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ‘ojú wa mú ọ̀nà kan’?

1 Ohun tí ojú wa bá ń rí máa ń nípa lórí àwọn ohun tá a bá ń ṣe. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò.” (Mát. 6:22) Bí ‘ojú wa bá mú ọ̀nà kan’ nípa tẹ̀mí, ohun tó máa jẹ wá lógún jù lọ ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. A ó fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní, a ò sì ní jẹ́ kí àwọn nǹkan ti ara tí kò pọn dandan tàbí àwọn ìgbòkègbodò míì dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

2. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣàkóbá fún ojú tá a fi ń wo nǹkan, àmọ́ kí ló lè ràn wá lọ́wọ́?

2 Ó Yẹ Ká Ṣàyẹ̀wò Ara Wa: Àwọn ohun táwọn iléeṣẹ́ ìpolówó ọjà ń gbé jáde tàbí àwọn ohun táwọn ẹlòmíì ní lè ṣàkóbá fún ojú tá a fi ń wo nǹkan. Ká tó dáwọ́ lé ohun kan tàbí ká tó ra ohunkóhun tó ṣeé ṣe kó gba àkókò púpọ̀, owó tàbí okun wa, ó yẹ ká máa “gbéṣirò lé ìnáwó náà” nípa bíbi ara wa pé, ‘Ṣé ohun tí mo fẹ́ rà tàbí tí mo fẹ́ ṣe yìí máa jẹ́ kí n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àbí ṣe ló máa dí mi lọ́wọ́?’ (Lúùkù 14:28; Fílí. 1:9-11) Ó tún bọ́gbọ́n mu ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa látìgbàdégbà, ká máa ronú nípa bá a ṣe lè jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wa lọ́rùn ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.—2 Kọ́r. 13:5; Éfé. 5:10.

3. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára arábìnrin tó ṣe àwọn ìyípadà kan nípa jíjẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn?

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí arábìnrin kan máa rí nídìí iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ máa tó o gbọ́ bùkátà rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, síbẹ̀ kò wù ú láti fi iṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi sílẹ̀. Nígbà tó yá, ó tún èrò ara rẹ̀ pa, ó sọ pé: “Kò sí ẹni tó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì. Àfi kí n mójú kúrò nínú àwọn ohun tó kàn ń wù mí kí n lè gbájú mọ́ àwọn ohun tí mo nílò gan-an. Kì í pẹ́ tí àwọn nǹkan ìní ti ara fi máa ń ṣá lójú ẹni, bí mo bá sì sọ pé gbogbo nǹkan tó bá wù mí ni mo fẹ́ máa ní, ṣe ni màá kàn fi iṣẹ́ àṣekúdórógbó ṣe ara mi léṣe.” Nígbà tó ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀, ó wá rí i pé òun lè ṣe àwọn ìyípadà kan nípa jíjẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn, ó fi iṣẹ́ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nìṣó.

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú pé ká jẹ́ ki ojú wa mú ọ̀nà kan lákòókò tá a wà yìí?

4 Torí pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan. Bí ilẹ̀ ṣe ń ṣú tí ilẹ̀ ń mọ́ la túbọ̀ ń sún mọ́ ìparí ètò àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ náà la sì tún ń sún mọ́ ayé tuntun ti Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 7:29, 31) Tá a bá ń gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, a ó lè gba ara wa àtàwọn tó bá ń fetí sí wa là.—1 Tím. 4:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́