ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/05 ojú ìwé 5
  • Àtúnyẹ̀wò Àpéjọ Àyíká

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Àpéjọ Àyíká
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 12/05 ojú ìwé 5

Àtúnyẹ̀wò Àpéjọ Àyíká

Kí ẹ lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti fi gbé ohun tẹ́ ẹ máa gbọ́ ní àpéjọ àyíká ti ọdún 2006 yẹ̀ wò nígbà tó bá kù díẹ̀ tẹ́ ẹ máa lọ, kẹ́ ẹ sì tún lò ó láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ àyíká náà láìpẹ́ sígbà tẹ́ ẹ bá dé. Kí alága àwọn alábòójútó ṣètò láti jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ṣáájú àti lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ṣe àpéjọ àyíká yín bó ṣe wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2004 ní ojú ìwé 4. Nígbà àtúnyẹ̀wò náà, ẹ rí i dájú pé gbogbo ìbéèrè náà lẹ béèrè, kí ẹni tó máa bójú tó àtúnyẹ̀wò náà rí i pé àwọn ará mọ bí wọ́n ṣe máa fi ohun tí wọ́n gbọ́ ní àpéjọ náà sílò.

ỌJỌ́ ÀKỌ́KỌ́

1. Báwo la ṣe lè gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, kí sì nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa wà lọ́rùn wà nìṣó?

d2. Ọ̀nà wo làwọn kan ti gbà tẹpá mọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?

3. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn?

4. Ọ̀nà wo làwọn tó para pọ̀ jẹ́ ìdílé lè gbà fi àkópọ̀ ìwà tuntun ṣèwà hù nínú ilé wọn?

5. Báwo la ṣe lè fi ìdúróṣinṣin ṣètìlẹyìn nínú ìjọ?

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àkópọ̀ ìwà tuntun ṣèwà hù nígbà tá a bá wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá?

7. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣàṣàrò bó ṣe yẹ, báwo la sì ṣe ń jàǹfààní láti inú irú àṣàrò bẹ́ẹ̀?

8. Àwọn ànímọ́ wo ló máa mú kí Jèhófà lè fi wá mọ ohun tó bá wù ú?

ỌJỌ́ KEJÌ

9. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa lo ahọ́n wa lọ́nà tó dáa?

10. Àǹfààní wo ló wà nínú sísọ̀rọ̀ tó gbámúṣé nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn ẹlòmíràn?

11. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 4:25-32 sílò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa?

12. Kí lohun tó lọ́lá jù lọ tá à ń fi ahọ́n wa ṣe?

13. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ṣẹ́gun ẹni burúkú náà?

14. Àwọn apá ibo la ti gbọ́dọ̀ máa sakun láti ṣọ́ra ká lè máa bá a nìṣó láìléèérí nínú ayé?

15. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa sọ irú ẹni tá a jẹ́ ní inú dọ̀tun lójoojúmọ́, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

16. Èwo lára àwọn ìtọ́ni inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká ọdún yìí lò ń gbèrò àtiṣiṣẹ́ lé lórí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́