Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
Ní èyí tó kù fún ayé ògbólógbòó tó ti dìdàkudà yìí, ó ṣe pàtàkì pé ká tọ́jú aṣọ tẹ̀mí wa ká sì rí i pé ohunkóhun ò gba àmì ìdánimọ̀ Kristẹni wa lọ́wọ́ wa. (Ìṣí. 16:15) Fún ìdí yìí, ó bá a mu pé ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká wa ti ọdún 2006 ni “Ẹ . . . Fi Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Wọ Ara Yín Láṣọ.”—Kól. 3:10.
Ọjọ́ Àkọ́kọ́: Àpínsọ àsọyé àkọ́kọ́, “Máa Fi Àwọn Ànímọ́ Tó Jẹ́ Ara Àkópọ̀ Ìwà Tuntun Hàn,” yóò tẹnu mọ́ bí gbígbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ ṣe ń ṣe wa láǹfààní ní gbogbo ọ̀nà nígbèésí ayé wa. Báwo la ṣe lè máa fi àkópọ̀ ìwà tuntun ṣèwà hù? Ìbéèrè yìí ni àwọn àsọyé méjì tó máa kádìí ọjọ́ àkọ́kọ́ yóò jíròrò, ẹṣin ọ̀rọ̀ àwọn àsọyé náà ni, “Kọ́ Ara Rẹ Láti Máa Ṣàṣàrò Bó Ṣe Yẹ” àti “Ẹ̀kọ́ Tó Ń Sọ Wá Dẹni Tó Ní Àkópọ̀ Ìwà Tuntun.”
Ọjọ́ Kejì: Àpínsọ àsọyé kejì tá a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní, “Ẹ Máa Lo Ahọ́n Lọ́nà Ọgbọ́n,” yóò jíròrò bí àkópọ̀ ìwà tuntun ṣe ń nípa lórí ọ̀nà tá a gbà ń lo ahọ́n wa. “Ǹjẹ́ Ò Ń Sapá Láti Ṣẹ́gun Ẹni Burúkú Náà?” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo èèyàn tó máa tànmọ́lẹ̀ sí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àwọn ète Sátánì. Àwọn àsọyé méjì tó máa kádìí àpéjọ náà, “Pa Ara Rẹ Mọ́ Láìní Èérí Kúrò Nínú Ayé,” àti “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Sọ Irú Ẹni Tá A Jẹ́ ní Inú Dọ̀tun Lójoojúmọ́,” yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn ìṣesí àti ìwà tó tako àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọ́run ká sì máa bá a lọ ní fífi ìdúróṣinṣin sìn ín.
Ó mà dáa o tá à ń fojú sọ́nà láti gba ìṣírí tó máa jẹ́ ká lè gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ tí yóò sì lè jẹ́ kó máa wà lọ́rùn wa nìṣó!