Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
1 Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run jẹ́ àgbà ọkùnrin nípa tẹ̀mí, tí ó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni tí ó sì yẹ fún ọ̀wọ̀ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa. (1 Tím. 5:17) Kí ni àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀?
2 Abẹ́ àbójútó rẹ̀ ni ibi ìkówèésí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wà. Ó ní ọkàn-ìfẹ́ gidigidi nínú fífún gbogbo àwọn tí ó bá tóótun láti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ náà níṣìírí. Ó ń rí i dájú pé òun ń pa àkọsílẹ̀ tí ó péye mọ́ kí ó lè máa yanṣẹ́ fúnni lọ́nà tí ó wà létòlétò ó kéré tán ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ṣáájú àkókò tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ kọ̀ọ̀kan ni ilé ẹ̀kọ́ náà yóò wáyé. Ó yẹ kí ó mọ ìjọ dáadáa, kí ó fi akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan àti òye tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní sọ́kàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin mìíràn lè máa ràn án lọ́wọ́ láti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ náà, pípín àwọn apá náà lọ́nà yíyẹ ń béèrè àfiyèsí alábòójútó náà fúnra rẹ̀.
3 Láti lè kọ́ni dáadáa ní ilé ẹ̀kọ́ náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ múra dáadáa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí ó ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a pín fúnni dáadáa. Èyí yóò jẹ́ kí ó mú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ náà ta ìjọ jí, yóò jẹ́ kí ó mọ̀ bí a bá kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a yàn fúnni lọ́nà yíyẹ, yóò sì jẹ́ kí ó tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì tí a óò fi kún àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀.
4 Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, alábòójútó yóò gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò sì ṣàlàyé ìdí tí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan ní pàtó fi dára tàbí ìdí tí ó fi yẹ kí a mú un sunwọ̀n sí i. Nígbà tí ẹnì kan bá ń fẹ́ ìtọ́ni sí i láti múra iṣẹ́ tí a yàn fún un ní ilé ẹ̀kọ́, alábòójútó tàbí ẹnì kan tí òun yàn lè ran ẹni yẹn lọ́wọ́.
5 Láti lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú iṣẹ́ àṣekára tí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ń ṣe àti èyí tí àwọn olùgbaninímọ̀ràn mìíràn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó rẹ̀ ń ṣe, ó yẹ kí a máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà déédéé. Ó yẹ kí a tún ṣe àwọn iṣẹ́ tí a bá yàn fún wa kí a sì fi ìmọ̀ràn tí a bá fún wa àti èyí tí a bá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn sílò. Lọ́nà yìí, agbára wa láti sọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ní gbangba àti láti ilé dé ilé yóò máa sunwọ̀n sí i lọ́nà tí ń tẹ̀ síwájú.—Ìṣe 20:20; 1 Tím. 4:13, 15.