Mo Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan!
1 Ọ̀pọ̀ nínú wa ni ó ti sọ pé ó wù wá pé kí a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, ìdí tí a sì fi sọ bẹ́ẹ̀ dára. Ibi iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni a ti ń dé orí góńgó wa tí ó jẹ́ sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn tuntun. (Mát. 28:19, 20) Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú wa ti jáde fún ọ̀pọ̀ oṣù, bóyá fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá, láìní ayọ̀ àrà ọ̀tọ̀ tí ó máa ń wá láti inú fífi òtítọ́ kọ́ ẹnì kan. Kí ni a lè ṣe nípa èyí ní November? Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìwé Ìmọ̀ ni a ń fi lọni ní oṣù yìí, a lè ṣe ìsapá lọ́nà àkànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun.
2 Ya Òpin Ọ̀sẹ̀ Kan Tàbí Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ Sọ́tọ̀: A gba olúkúlùkù níyànjú láti ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ nínú oṣù yìí láti pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun. Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ní láti yan àwọn òpin ọ̀sẹ̀ tí a óò lò fún ète yìí ní pàtó, lẹ́yìn náà, kí wọ́n sì ṣètò àwùjọ wọn láti jùmọ̀ sapá láti kọ́wọ́ ti ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò.
3 Máa mú ìwé àkọsílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò rẹ lọ́wọ́ wá sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn. Lẹ́yìn náà, ṣe ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó ti fi ìfẹ́ hàn, àwọn tó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, tàbí àwọn tó ti wá sí ìpàdé. Ṣe ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ní pàtó.
4 Ṣe Àṣefihàn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan: Àṣefihàn tí a ti múra sílẹ̀ dáadáa tí ń fi bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ níbi ìpadàbẹ̀wò hàn ni kí a ṣe ní àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn tí a yàn. O lè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ní Bíbélì, ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ̀ pé ó ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèré pàtàkì tí gbogbo wa dojú kọ nínú ìgbésí ayé. [Fi kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé Ìmọ̀ hàn, kí o sì ka àwọn àkòrí tí ó wà ní orí 3, 5, 6, 8, àti 9.] Ní lílo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọ̀sẹ̀, o lè jèrè ìpìlẹ̀ ìmọ̀ Bíbélì láàárín oṣù díẹ̀ péré. Bí o bá fẹ́ láti mú ọ̀kan lára àwọn àkòrí wọ̀nyí, inú mi yóò dùn láti fi bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣe máa ń rí hàn ọ́.” Bí ẹni náà bá lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí, ṣàlàyé fún un pé a tún ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ké kúrú. Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè hàn án, kí o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ kúkúrú fún ìṣẹ́jú 15 sí 30 lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lọ̀ ọ́.
5 Bí gbogbo wa bá jùmọ̀ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a sì gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá wa, dájúdájú a óò rí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun! (1 Jòh. 5:14, 15) Bí o bá ń fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí lè jẹ́ àkókò àǹfààní tìrẹ láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan.