Jàǹfààní Láti Inú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún Ọdún 1999
1 Àgbà Olùkọ́ ni Jésù. ‘Háà ṣe àwọn ènìyàn sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.’ (Máàkù 1:22) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè sọ̀rọ̀ tí ó sì lè kọ́ni bí ti Jésù, a lè sakun láti fara wé e. (Ìṣe 4:13) Láti lè ṣe ìyẹn, kíkópa tí a bá ń kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti mú kí òye wa pọ̀ sí i nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.
2 Ní ọdún 1999, orí àwọn àpilẹ̀kọ láti inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ọdún 1997 ni a óò gbé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 1 kà ní pàtàkì. A óò mú kí òye tí a ní nípa àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí pọ̀ sí i gidigidi bí a bá ka ìsọfúnni náà ṣáájú kí a sì wá gbọ́ ọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́. Kí àwọn tí a bá yan ọ̀rọ̀ ìtọ́ni wọ̀nyí fún fi bí àkójọ ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò hàn, kí wọ́n sọ ọ́ lọ́nà tí ń fani lọ́kàn mọ́ra tí ó sì ń tani jí. Orí ìwé Ayọ̀ Ìdílé ni a óò gbé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3 kà, a óò sì gbé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 4 ka “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ náà kí ó tó yan àwọn apá náà fúnni. Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tí a óò yanṣẹ́ fún láti sọ̀rọ̀ lórí àkójọ ọ̀rọ̀ láti inú ìwé Ayọ̀ Ìdílé gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìgbésí ayé ìdílé wọn.
3 Fi Ìmọ̀ràn Sílò Kí O Sì Múra Sílẹ̀ Dáadáa: Gbogbo ìjọ lè sunwọ̀n sí i nínú bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń kọ́ni. (1 Tím. 4:13) Nítorí náà, ó yẹ kí a wá ìmọ̀ràn kí a má sì ṣe wò ó bí ohun tí ó yẹ kí a yẹra fún. (Òwe 12:15; 19:20) Sísọ òtítọ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní àwọn ìpàdé àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ń béèrè ju wíwulẹ̀ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tàbí wíwulẹ̀ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà àṣà. Ó yẹ kí a dé inú ọkàn àwọn tí ń tẹ́tí sí wa kí a sì sún wọn ṣiṣẹ́. A lè ṣe èyí nípa sísọ òtítọ́ lọ́nà tí ó dáni lójú láti inú ọkàn wa. (Fi wé Ìṣe 2:37.) Ìmọ̀ràn tí a ń rí gbà ní ilé ẹ̀kọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí.
4 Gbàrà tí o bá ti gba iṣẹ́ àyànfúnni kan, ronú nípa ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí o ní láti ṣiṣẹ́ lé lórí, bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ. Ṣàyẹ̀wò ohun tí ó yẹ kí o ṣe láti fi ìmọ̀ràn tí o rí gbà níṣàájú sílò. Ṣàṣàrò nípa ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ, ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tí ìwọ yóò lò bí a bá sọ pé kí o ṣe bẹ́ẹ̀, àti bí ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé ìwúlò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó wà nínú àkójọ ọ̀rọ̀ tí a yàn fún ọ. Fẹ̀sọ̀ ronú nípa ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí o fi lè lo ìsọfúnni náà láti kọ́ni kí o sì súnni ṣiṣẹ́.—1 Tím. 4:15, 16.
5 Bí fíforúkọsílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ bá ń bà ọ́ lẹ́rù, gbàdúrà nípa rẹ̀ kí o sì bá alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ jíròrò nípa ìmọ̀lára rẹ. Gbogbo wa lè jèrè nípa lílo àǹfààní ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní kíkún, èyí tí a óò gbé jáde nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọdún 1999.