ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/98 ojú ìwé 8
  • ‘Má Fawọ́ Sẹ́yìn’ Láti Jẹ́ Kí Wọ́n Gbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Má Fawọ́ Sẹ́yìn’ Láti Jẹ́ Kí Wọ́n Gbọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Péye?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 12/98 ojú ìwé 8

‘Má Fawọ́ Sẹ́yìn’ Láti Jẹ́ Kí Wọ́n Gbọ́

1 A ń fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run hàn nígbà tí a bá ń fi aápọn lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà gbà wá nímọ̀ràn pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tí Jèhófà ti fi ìwà ọ̀làwọ́ fi fún wa ni a gbọ́dọ̀ pòkìkí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ní oṣù December àti January, a ní àǹfààní láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè nípa fífi àdìpọ̀ oríṣi ìwé lọni ní ẹ̀dínwó.

2 Fi Ìmọrírì Hàn fún Àwọn Ìtẹ̀jáde Náà: Àwọn ìtẹ̀jáde náà ní ìsọfúnni ṣíṣe kókó tí àwọn ènìyàn nílò ní kánjúkánjú nínú. Ìdáhùnpadà tí a rí nígbà tí a fi ìwé wọ̀nyí lọni sẹ́yìn lọ́dún yìí fi hàn pé àwọn ènìyàn ní ìfẹ́-ọkàn sí wọn. Láti oṣù June jálẹ̀ oṣù August, a fi 169,925 ìwé sóde ní Nàìjíríà ní àsìkò ìgbétáásì àkànṣe yìí! Góńgó tuntun 73,375 nínú iye ìwé tí a fi sóde ní oṣù August ni ó tíì pọ̀ jù lọ láti ọdún 1982 wá. Ó yẹ kí ìmọrírì sún wa láti jẹ́ onítara ní gbígbé àwọn ìwé wọ̀nyí jáde lẹ́ẹ̀kan sí i.

3 Ìgbékalẹ̀ Tí A Dábàá: “Bí ìlànà ìwà rere ṣe ń yára kánkán yí padà lónìí tí ọjọ́ ọ̀la wa kò sì dáni lójú, o ha gbà pé a ń fẹ́ amọ̀nà tí ó ṣeé gbára lé nínú ìgbésí ayé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ni ìwé tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ, ó ń pèsè ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún ìgbé ayé òde òní àti ìgbésí ayé ìdílé tí ó láyọ̀.” Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé tí o fẹ́ fi lọ̀ ọ́ sí orí àti ìpínrọ̀ tí ó bá yẹ kí o sì ka ìpínrọ̀ kan tàbí méjì. Ka 2 Tímótì 3:16, 17. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́, ṣàlàyé nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí a ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ kí o sì gbìyànjú láti fi bí a ṣe ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ hàn án bí àyè bá wà. Bí o bá ronú pé yóò dára jù láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ yóò rí àfikún ọ̀nà tí o lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò ní ojú ìwé 8 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti oṣù June àti July.

4 Àwọn ènìyàn díẹ̀ ló ń ka Bíbélì, àwọn tí ó sì lóye ìlànà tí ó pèsè fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́ kò tó nǹkan. Ó yẹ kí wọ́n mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ní ipa rere lórí ìgbésí ayé wọn àti pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí ìwà àìlábòsí, ìwà rere, àti ìgbésí ayé ìdílé lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro òde òní. Bí a kò bá fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó yẹ kí a ṣe é fún, ó yẹ kí a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ṣíṣe kókó wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí a fi ìmọrírì wa hàn fún àǹfààní àgbàyanu yìí nípa fífi àwọn ìwé wọ̀nyí lọni tìtaratìtara ní oṣù December.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́