ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 47-ojú ìwé 51
  • Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì
  • Ọ̀rọ̀ Ìtọ́ni
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Àwọn Àpéjọ Àyíká, Àkànṣe, àti Àgbègbè
  • Má Fòní Dónìí, Fọ̀la Dọ́la
  • Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tí A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ṣíṣe Ìlapa Èrò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mímúra Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 47-ojú ìwé 51

Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀

A ṢÈTÒ ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tí gbogbo ìjọ yóò fi jàǹfààní níbẹ̀. A sì tún máa ń gba ìsọfúnni tó ṣeyebíye ní àwọn ìpàdé ìjọ yòókù àti ní àwọn àpéjọ àyíká, àkànṣe àti ti àgbègbè. Bí a bá yan apá kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí fún ọ láti ṣe, ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà lo gbà yẹn o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì tó jẹ́ Kristẹni alábòójútó pé ìgbà gbogbo ni kó máa fiyè sí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni. (1 Tím. 4:16) Àkókò tó ṣeyebíye ni àwọn tó ń wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni yà sọ́tọ̀, tí àwọn kan sì sapá gidigidi kí wọ́n tó lè wà ní ìpàdé láti gba ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ fúnni láti pèsè irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀! Ọ̀nà wo lo lè gbà fi ọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní yẹn?

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Bíbélì

Orí Bíbélì kíkà tá a yàn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni a máa ń gbé apá yìí ní ilé ẹ̀kọ́ kà. Bí ìsọfúnni inú Bíbélì yẹn ṣe kàn wá lóde òní ni kí á tẹnu mọ́. Gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà 8:8 ṣe sọ, ńṣe ni Ẹ́sírà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sétígbọ̀ọ́ gbogbo èèyàn, wọ́n ṣàlàyé rẹ̀, ‘wọ́n ń fi ìtumọ̀ sí i,’ wọ́n sì ń mú kí òye rẹ̀ yéni. Àǹfààní láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe yẹn ló ṣí sílẹ̀ fún ìwọ náà bí o ṣe fẹ́ mú àwọn kókó pàtàkì jáde látinú Bíbélì.

Báwo ló ṣe yẹ kó o múra irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sílẹ̀? Tètè ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ nínú Bíbélì sílẹ̀ ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣáájú, bó bá ṣeé ṣe. Kí o sì wá ronú nípa ìjọ rẹ àti àwọn ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí níbẹ̀. Gbàdúrà nípa rẹ̀. Ìmọ̀ràn wo, àpẹẹrẹ wo, ìlànà wo ló lè yanjú nǹkan wọ̀nyẹn nínú ibi tó o kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí?

Ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣèwádìí. Ǹjẹ́ atọ́ka kókó àpilẹ̀kọ tó máa ń wà nínú Ilé Ìṣọ́ níparí ọdún wà lédè tìrẹ? Bó bá wà, ṣèwádìí nínú rẹ̀. Tó o bá ṣèwádìí lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o yàn láti lò yìí, o lè rí ìsọfúnni tó lani lóye nípa ìtàn tó yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn ká, àlàyé nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ibẹ̀ ṣe ṣẹ, àgbéyẹ̀wò nípa ohun tí àwọn ẹsẹ kan ṣí payá nípa Jèhófà, tàbí ìjíròrò nípa àwọn ìlànà kan. Má ṣe gbìyànjú láti kárí àwọn kókó púpọ̀ jù. Yan àwọn ẹsẹ mélòó kan péré kí o sì gbájú mọ́ ìyẹn. Ó sàn pé kó jẹ́ ìwọ̀nba ẹsẹ mélòó kan lo kárí, kí o sì ṣàlàyé wọn dáadáa.

Iṣẹ́ rẹ tún lè gba pé kí o ní kí àwùjọ sọ ohun tí wọ́n ti jàǹfààní látinú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ yẹn. Kí ni wọ́n ti rí tí yóò ṣàǹfààní fún wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ tiwọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ti ìdílé tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn wọn tàbí nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé? Àwọn ànímọ́ wo ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà hùwà sí àwọn èèyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè níbẹ̀ fi hàn nípa Jèhófà? Ẹ̀kọ́ wo ni àwùjọ rí kọ́ níbẹ̀ tó fún ìgbàgbọ́ wọn lágbára tó sì mú kí wọ́n túbọ̀ mọyì Jèhófà? Má ṣe jókòó ti àlàyé ọ̀rínkinniwín àwọn kókó ibẹ̀ o. Ohun tí àwọn kókó tó o yàn túmọ̀ sí àti ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà lò wọ́n ni kó o tẹnu mọ́.

Ọ̀rọ̀ Ìtọ́ni

A gbé e karí àwọn ìsọfúnni inú ìtẹ̀jáde kan, irú bí àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí ibì kan nínú ìwé kan. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó wà níbẹ̀ máa ń ju èyí tó o lè kárí láàárín àkókò tá a yàn fún ọ. Báwo ló ṣe yẹ kó o bójú tó iṣẹ́ yẹn ná? Ṣe é bí ẹni tó jẹ́ olùkọ́, kì í ṣe bí ẹni tó kàn ṣáà ń mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ inú ìwé kan. Alábòójútó ní láti jẹ́ “ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni.”—1 Tím. 3:2.

Kọ́kọ́ ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ yẹn ná láti fi bẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ rẹ. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀. Ṣàṣàrò nípa rẹ̀. Gbìyànjú láti tètè ṣe ìyẹn ṣáájú ọjọ́ tó o máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Rántí pé a ti rọ àwọn ará láti ka ìtẹ̀jáde tí o máa gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà sílẹ̀. Kì í ṣe nítorí kó o kàn wá ṣàyẹ̀wò rẹ̀ tàbí pé kó o ṣáà wá ṣàkópọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ṣe yàn án fún ọ, bí kò ṣe pé kí o ṣàlàyé bí a ó ṣe lò ó. Lo àwọn ibi tó bá yẹ nínú ìsọfúnni náà lọ́nà tí ìjọ yóò fi lè jàǹfààní nínú rẹ̀ lóòótọ́.

Gẹ́lẹ́ bí ọmọ kọ̀ọ̀kan ṣe ní ìwà tirẹ̀ ni ìjọ kọ̀ọ̀kan náà ṣe ní àwọn ànímọ́ tirẹ̀ lọ́tọ̀. Òbí tó mọ bí a ṣe ń kọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́ kò ní kàn máa ka àwọn ohun tó jẹ́ ìwà ọmọlúwàbí sétígbọ̀ọ́ ọmọ rẹ̀. Ńṣe ni yóò ṣàlàyé rẹ̀ yé ọmọ yẹn. Yóò ro ti ìwà ọmọ yẹn mọ́ ọn, àti ìṣòro tó ń bá ọmọ náà fínra. Ní ọ̀nà kan náà, àwọn tó jẹ́ olùkọ́ inú ìjọ a máa gbìyànjú láti mọ ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí nínú àwùjọ tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀, wọ́n á sì gbìyànjú láti yanjú rẹ̀. Àmọ́ o, olùkọ́ tó ń lo òye yóò yàgò fún lílo àwọn àpẹẹrẹ tó lè dójú ti ẹnikẹ́ni nínú àwùjọ. Yóò mẹ́nu kan àwọn àǹfààní tí ìjọ ti ń jẹ nítorí pé wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà, yóò sì wá tọ́ka sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tí yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní.

Ẹ̀kọ́ tí a bá kọ́ àwùjọ lọ́nà tó yé wọn dáadáa máa ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Èyí túmọ̀ sí pé a ò ní sọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ nìkan ṣáá, ṣùgbọ́n a óò tún mú kí ìjọ mọyì ohun tí kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń sọ pé kí wọ́n ṣe pẹ̀lú. Ìyẹn gba pé kí ọ̀ràn àwọn tí a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹni lógún gidigidi. Ó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí mọ agbo wọn dunjú. Bí wọ́n bá fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àwọn ìṣòro tí àwọn ará lónírúurú ń dojú kọ sọ́kàn, wọ́n á lè sọ̀rọ̀ ìṣírí, lọ́nà tó gba tẹni rò, lọ́nà oníyọ̀ọ́nú, àti ti ẹlẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò.

Ohun tí àwọn ògbóṣáṣá olùkọ́ mọ̀ ni pé, ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ń sọ gbọ́dọ̀ ní ohun pàtó kan nínú, tó hàn kedere, tó ń fẹ́ kéèyàn ṣe. A ní láti sọ ọ̀rọ̀ wa lọ́nà tí àwọn kókó pàtàkì inú rẹ̀ yóò fi hàn kedere, kí àwùjọ má sì gbàgbé wọn. Ó yẹ kí àwùjọ lè rántí àwọn kókó pàtàkì tó wúlò, tí yóò ní ipa lórí ìgbésí ayé wọn.

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Tí o bá fẹ́ lo àpilẹ̀kọ inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa láti fi sọ̀rọ̀, ìpèníjà tìyẹn tún yàtọ̀ díẹ̀. Wàá rí i pé ohun tá a sábà máa ń fẹ́ kí o ṣe níbẹ̀ ni pé kó o sọ ohun tó ti wà nínú àpilẹ̀kọ yẹn fún àwùjọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kì í ṣe pé kó o yan èyí tó o bá rí pé ó bá a mu jù lọ. Ńṣe ni kó o mú kí àwùjọ ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé ìmọ̀ràn tí àpilẹ̀kọ yẹn ń fúnni kà. (Títù 1:9) Àkókò tó wà fún un máa ń kúrú, débi pé, lọ́pọ̀ ìgbà kì í sáyè fún àfikún ìsọfúnni mìíràn rárá.

Àmọ́ ṣá o, a lè ní kí o sọ̀rọ̀ lórí nǹkan kan tó jẹ́ pé kò sí àpilẹ̀kọ rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ó lè jẹ́ àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ la tọ́ka rẹ sí tàbí pé kó o lo àlàyé ṣókí kan tá a ṣe nípa iṣẹ́ yẹn. Ó kù sí ọ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ láti wo bó o ṣe lè fi ọ̀rọ̀ tá a yàn fún ọ yìí yanjú ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí nínú ìjọ. Ó lè béèrè pé kí o lo àpèjúwe kúkúrú kan tó sojú abẹ níkòó, tàbí kí o sọ ìrírí kan tó bá a mu. Rántí pé kì í ṣe pé kí o kàn sáà ti sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn ni iṣẹ́ rẹ o, bí kò ṣe pé kó o ṣe é lọ́nà tí yóò fi ran ìjọ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là sílẹ̀, kí ó sì dùn mọ́ wọn láti ṣe.—Ìṣe 20:20, 21.

Bí o ṣe ń múra iṣẹ́ rẹ, ronú nípa bí àwọn nǹkan ṣe rí fún àwọn èèyàn inú ìjọ. Yìn wọ́n fún ohun tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá. Báwo ni fífi tí wọ́n bá fi àwọn àbá inú ibi tó o ti mú ọ̀rọ̀ rẹ sílò yóò ṣe mú kí wọ́n túbọ̀ já fáfá kí wọ́n sì láyọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?

Ǹjẹ́ àṣefihàn tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wà nínú iṣẹ́ rẹ? Bí ó bá wà níbẹ̀, ó yẹ kó o ti ṣètò rẹ̀ dáadáa sílẹ̀ ṣáájú. Ó lè ṣeni bíi pé ká kàn sọ fún ẹnì kan pé kó bá wa ṣètò rẹ̀, ṣùgbọ́n ìyẹn kì í sábà yọrí sí bó ṣe yẹ. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ fi àṣefihàn tàbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà dánra wò ṣáájú ọjọ́ ìpàdé yẹn. Rí i dájú pé wọ́n ṣe apá yìí nínú iṣẹ́ rẹ lọ́nà tí yóò túbọ̀ gbé ìtọ́ni tí iṣẹ́ rẹ ń fúnni yọ dáadáa.

Àwọn Àpéjọ Àyíká, Àkànṣe, àti Àgbègbè

Àwọn arákùnrin tó bá ti fi àwọn ànímọ́ tó dára nípa tẹ̀mí kọ́ra, tó sì dẹni tó lè bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó múná dóko àti olùkọ́ tó pegedé, lè di ẹni tá a yàn láti kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní àpéjọ àyíká, ti àkànṣe tàbí ti àgbègbè nígbà tó bá yá. Ìgbà àkànṣe gbáà ni ìpàdé wọ̀nyí jẹ́ fún dídánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà ti ìjọba Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ iṣẹ́ tó jẹ́ ìwé kíkà, ọlọ́rọ̀ tààràtà, ọ̀rọ̀ ìtọ́ni nípa àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bá ohun tó ń lọ lóde òní mu, tàbí kó jẹ́ àwọn ìtọ́ni tí kò gbà ju ìpínrọ̀ kan péré lọ. Bí o bá láǹfààní láti kópa nínú irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ dáadáa. Kà á lákàtúnkà títí tí wàá fi lóye rẹ̀.

Ńṣe ni kí àwọn tá a bá yan iṣẹ́ tó jẹ́ ìwé kíkà fún ka ọ̀rọ̀ inú ìwé náà jáde látòkèdélẹ̀ gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe kọ ọ́ síbẹ̀. Wọ́n kì í ṣàfikún tàbí ṣe àyọkúrò tàbí kí wọ́n ṣe àtúntò ọ̀rọ̀ inú ìwé yẹn. Ṣe ni wọ́n máa ń fara balẹ̀ kà á dáadáa láti lè fòye mọ àwọn ohun tó jẹ́ kókó pàtàkì inú ibẹ̀ àti bí wọ́n á ṣe gbé e yọ. Wọ́n a máa kàwé yẹn síta láti fi dánra wò títí tí wọ́n á fi lè kà á kí wọ́n sì lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀, ìtara, ohùn tó tura, ohùn bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, ìtara ọkàn, àti ìdánilójú, pẹ̀lú ohùn tó ròkè tó sì dún ketekete níwọ̀n tó yẹ kí a lò fún ìwé kíkà sétígbọ̀ọ́ àwùjọ ńlá kan.

Àwọn arákùnrin tá a bá yan iṣẹ́ tó ní ìlapa èrò fún ni yóò fúnra wọn gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ lọ́nà tó bá ìlapa èrò tí wọ́n gbà mu. Kí olùbánisọ̀rọ̀ sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara rẹ̀ látọkànwá ni o, kó má ṣe jẹ́ pé ńṣe ló ń ka ìlapa èrò rẹ̀ jáde nígbà tó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kó má sì múra iṣẹ́ rẹ̀ bíi pé iṣẹ́ oníwèé-kíkà ni. Ó ṣe pàtàkì pé kó tẹ̀ lé àkókò tó wà lórí ìlapa èrò rẹ̀ láti lè ṣàlàyé gbogbo kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ yéni kedere. Kí olùbánisọ̀rọ̀ lo àwọn èrò àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tò sábẹ́ àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ dáadáa. Kí ó má ṣe mú àwọn àfikún kókó mìíràn tó wù ú wọnú rẹ̀ débi pé kò ní lè sọ àwọn ohun tó wà nínú ìlapa èrò yẹn. Ó dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìpìlẹ̀ fún ìtọ́ni yẹn. Ojúṣe Kristẹni alàgbà sì ni láti “wàásù ọ̀rọ̀ náà.” (2 Tím. 4:1, 2) Nípa bẹ́ẹ̀, olùbánisọ̀rọ̀ ní láti fún àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìlapa èrò rẹ̀ láfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀, kí ó ṣàlàyé wọn kí ó sì sọ bí ó ṣe kan ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Má Fòní Dónìí, Fọ̀la Dọ́la

Ǹjẹ́ inú ìjọ tí àǹfààní ti wà fún ọ láti máa sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà lo wà? Báwo ni wàá ṣe máa fún gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ láfiyèsí tó yẹ? Ńṣe ni kó o yẹra fún dídúró di ìgbà tí àsìkò iṣẹ́ rẹ bá fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tán kó o tó múra.

Ọ̀rọ̀ tá a bá fara balẹ̀ ronú sí tẹ́rùn ló máa ń ṣe ìjọ láǹfààní ní ti gidi. Nípa bẹ́ẹ̀, sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa ka ibi tí wọ́n yàn fún ọ ní gbàrà tí iṣẹ́ yẹn bá ti tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè máa dà á rò bí o ṣe ń bá ìgbòkègbodò rẹ yòókù nìṣó. Láàárín àwọn ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú ìgbà tó o máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ, o lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣàlàyé ìsọfúnni yẹn. Àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tí yóò fi bí ìsọfúnni yẹn ṣe bọ́ sí àsìkò tó hàn. Kíka ibi tá a yàn fún ọ, àti ríronú lé e lórí ní gbàrà tó o bá ti gbà á ń gba àsìkò lóòótọ́, àmọ́ ohun tó tọ́ láti ṣe ni. Nígbà tó o bá wá jókòó láti gbé ọ̀rọ̀ inú ìlapa èrò náà kalẹ̀, wàá jàǹfààní ríronú tó o ti ronú dáadáa nípa rẹ̀ ṣáájú. Tó o bá ń ṣe báyìí múra iṣẹ́ rẹ, yóò dín ìdààmú rẹ kù gan-an ni, wàá sì lè sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó múná dóko tó sì wọ àwọn èèyàn inú ìjọ lọ́kàn ṣinṣin.

Bí o bá ti mọrírì ẹ̀bùn tá a gbé lé ọ lọ́wọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà gbé kalẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀, wàá bọlá fún Jèhófà, wàá sì jẹ́ ìbùkún fún gbogbo àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀.—Aísá. 54:13; Róòmù 12:6-8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́