Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2002
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fojú kéré agbára ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ ẹnu jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ó ń jẹ́ ká lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ èrò wa àti bí ọ̀ràn ṣe rí lára wa. Pàtàkì jù lọ ni pé, a lè lò ó láti yin Ọlọ́run wa.—Sm. 22:22; 1 Kọ́r. 1:4-7.
2 A ń kọ́ àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láti polongo orúkọ Jèhófà. (Sm. 148:12, 13) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ ti ọdún 2002 yóò kárí onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwa fúnra wa lè jàǹfààní látinú rẹ̀, tí a sì lè lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí a bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ náà tí a sì ń kópa nínú rẹ̀, ìmọ̀ àti òye wa gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò pọ̀ sí i.—Sm. 45:1.
3 Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́: Bá a bá ń jẹ́ kí Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa nígbà gbogbo, a ó lè lo àyè èyíkéyìí tó bá yọ láti kà á. Ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń ní ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lóòjọ́ tá a lè lò fún un. Ó mà ń ṣeni láǹfààní o láti ka ojú ewé kan, ó kéré tán lójoojúmọ́! Ìyẹn ti tó fún wa láti lè máa bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tí a ṣètò fún ilé ẹ̀kọ́ náà lọ.—Sm. 1:1-3.
4 Mímọ Bíbélì í kà dáadáa yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ lọ́kàn, á sì mú kí wọ́n yin Jèhófà. Àwọn arákùnrin tí a bá yan Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì fún ní láti fi apá ibi tí a yàn fún wọn dánra wò dáadáa nípa kíkà á sókè ketekete. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á gbóríyìn fún wọn á sì dámọ̀ràn àwọn apá ibi tó kù díẹ̀ káà tó fún wọn kí wọ́n bàa lè máa kàwé já gaara.
5 Máa Lo Ìwé Ìmọ̀ àti Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé: Inú ìwé Ìmọ̀ àti ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé la ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kẹta àti ìkẹrin jáde. Ó yẹ kí a gbìyànjú láti máa lo àwọn àrànṣe tó wúlò wọ̀nyí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí àwọn arábìnrin lo àwọn ìgbékalẹ̀ tó bá ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń wàásù mu. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sì fiyè gidigidi sí bí wọ́n ṣe ń kọ́ni àti bí wọ́n ṣe ń lo Ìwé Mímọ́.
6 Ǹjẹ́ kí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ran gbogbo wa lọ́wọ́ ká lè máa bá a lọ ní lílo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa láti máa polongo ìhìn rere náà, kí a sì máa yin Ọlọ́run wa atóbilọ́lá, Jèhófà!—Sm. 34:1; Éfé. 6:19.