Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1998
Láti jẹ́ ẹni tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí “kí a kọ́ni tàbí gbin ìmọ̀ kan pàtó tàbí òye iṣẹ́ síni lọ́kàn.” Nípasẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, a ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìmọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Bákan náà, kíkópa tí a bá ń kópa nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí ń jẹ́ kí a mú ìjáfáfá wa nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ sí i. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ fún 1998 yóò fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Bí o ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ fún ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò rí i pé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3 ni a gbé ka ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tàbí Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro. Nígbàkigbà tí a bá gbé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 4 ka ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, kí arákùnrin kan sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ àsọyé fún ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí, kò sí ẹnì kankan tí ó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ náà tí ó gbọ́dọ̀ kọjá àkókò.
Ohun Tuntun Kan: Fún àǹfààní tiwa, “Àfikún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” ni a fi sínú àkámọ́ tẹ̀ lé nọ́ńbà orin fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbé apá kankan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ karí rẹ̀, fi í ṣe góńgó rẹ láti máa kà á déédéé. Èyí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti sọ kíka Bíbélì lójoojúmọ́ dàṣà bí o kì í bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Fún ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa àwọn iṣẹ́ àyànfúnni, ìmọ̀ràn, àti àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, jọ̀wọ́ fara balẹ̀ ka àwọn ìtọ́ni tí ó wà nínú “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1998,” àti ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
Bí o kò bá tí ì forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, a ké sí ọ láti forúkọ sílẹ̀ nísinsìnyí. Ilé ẹ̀kọ́ aláìlẹ́gbẹ́ yìí ń bá a nìṣó láti kó ipa pàtàkì nínú dídá àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti àwọn ìrànṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn lẹ́kọ̀ọ́ láti túbọ̀ tóótun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀.—1 Tím. 4:13-16.