Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún February
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 5
Orin 96
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọrun.
15 min: “Pípolongo Òtítọ́ Lójoojúmọ́ ní Fífara Wé Jesu.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5.
20 min: “Wíwà Láàyè Títí Láé Nínú Paradise Lórí Ilẹ̀ Ayé.” Jíròrò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn, kí o sì jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
Orin 14 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 12
Orin 191
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe.” Ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ àpéjọ yín tí ó tẹ̀ lé e, bí o bá mọ̀ ọ́n. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti wà níbẹ̀.
15 min: “Múra Sílẹ̀ fún Ìgbòkègbodò Ìwé Ìròyìn ní April.” Tẹnu mọ́ ìníyelórí Ilé-Ìṣọ́nà àti Ji! nínú sísọ ìhìn rere náà di mímọ̀. Ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ onípìn-ínrọ̀ méjì náà, kí o sì to ohun ti ìjọ àdúgbò yóò ṣe láti mú ki April jẹ́ oṣù àkànṣe fún ìpínkiri ìwé ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ.
20 min: “Jehofa Ń Ranti Awọn Alaisan ati Awọn Agbalagba.” Ọ̀rọ àsọyé láti ẹnu alàgbà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1993, ojú ìwé 26 sí 30.
Orin 133 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 19
Orin 72
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 2.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Tẹnu mọ́ yíyẹ tí ó yẹ láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lójoojúmọ́.
20 min: “Pípadà Lọ sí Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Wọ́n Fi Ọkàn-Ìfẹ́ Hàn.” Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Alàgbà jíròrò pẹ̀lú àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta nípa àwọn apá ẹ̀ka ìwé Walaaye Titilae àti bí a ṣe lè tẹnu mọ́ wọn. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì. Fúnni ní àbá lórí bí a ṣe lè mú ọkàn-ìfẹ́ dàgbà dórí bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
Orin 53 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní February 26
Orin 28
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Mímúra Àwọn Ìgbékalẹ̀ Fífani Lọ́kàn Mọ́ra Sílẹ̀. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míràn jíròrò àǹfààní tí ó wà nínú lílo àwọn ìgbékalẹ̀ ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà tí ń sọ nípa ohun tí àwọn ènìyàn ní àdúgbò lọ́kàn-ìfẹ́ sí, pẹ̀lú àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta. Fún àpẹẹrẹ, ìròyìn àdúgbò nípa àwọn ìsapá tí a ń ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i; àwọn ìṣòro ìgbéyàwó tí ń ga sí i, ìyapòkìí àwọn ọmọdé tàbí ìṣòro rírí iṣẹ́ ṣe; tàbí àwọn ìròyìn tí ń fi ìdí tí àwọn ènìyàn fi túbọ̀ ń ṣiyè méjì nípa àwọn ojútùú tí àwọn òṣèlú àti àwọn àlùfáà ń fi fúnni hàn. Ẹ mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ ní àgbègbè yín, kí ẹ sì jíròrò bí a ṣe lè lò wọ́n láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.
20 min: Fífi Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lọni ní March. Tọ́ka sí apá ẹ̀ka fífani mọ́ra mélòó kan nínú ìwé náà, tí a lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. (1) Pe àfiyèsí sí àwọn àwòrán fífani mọ́ra, irú bí èyí tí ó wà ní ojú ìwé 4 àti 5, 86, 124 àti 125, 188 àti 189. (2) Fi hàn bí orí kọ̀ọ̀kan ṣe parí pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò, kí o sì ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìgbékalẹ̀. O lè béèrè lọ́wọ́ onílé bí òun yóò bá fẹ́ láti mọ ìdáhùn. Fa díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí a tò lẹ́sẹẹsẹ ní ojú ìwé 11, 22, 61, 149 yọ. (3) Tọ́ka sí àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 102, kí o sì fúnni ní àbá tí ń fi bí a ṣe lè lo “Díẹ̀ Lára Àwọn Apá-Ẹ̀ka Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè hàn. (4) Tẹnu mọ́ bí a ṣe pète ìwé náà ní pàtàkì fún dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń tẹ̀ síwájú. Àwọn orí náà kúrú, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà rọrùn láti lóye, a tọ́ka sí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ lílágbára, àwọn ìbéèrè tí ń wádìí jinlẹ̀ sì dá lórí àwọn kókó pàtàkì. Rọ àwùjọ láti fi ìwé náà lọni pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
Orin 151 àti àdúrà ìparí.