Múra Sílẹ̀ fún Ìgbòkègbodò Ìwé Ìròyìn ní April
Bí a ti fi hàn lórí 1996 Calendar wa, ní ọdún yìí, a óò ṣàṣeyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ní April 2. Bí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ atóbilọ́lá yìí ti fún wa níṣìírí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wá fi tìtaratìtara ṣàjọpín nínú ìpínkiri ìwé ìròyìn jálẹ̀ April. Ẹ wo àwọn ìwé ìròyìn tí ó bá ìgbà mú tí a óò máa lò! Ilé-Ìṣọ́nà April 1 yóò kó àfiyèsí jọ sórí ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ti àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún tí ó kọjá, “Ẹ Yin Ọba Ayérayé!” Ilé-Ìṣọ́nà April 15 yóò dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé ìtagbangba ti April tí ó kọjá, “Òpin Ìsìn Èké Ti Sún Mọ́lé.” Àkànṣe ọ̀rọ̀ àsọyé fún ọdún yìí ní April 21, “Wíwà Láìlẹ́bi Láàárín Ìran Oníwà Wíwọ́ Kan,” yẹ kí ó túbọ̀ fún wa ní ìwúrí sí i. A óò gbé Ji! April 22 jáde lákànṣe, pẹ̀lú àkòrí náà, “Nígbà tí Ogun Kì Yóò Sí Mọ́.”
Ní ṣíṣiṣẹ́ lórí ìgbétásì Ìròyìn Ìjọba ti October tí ó kọjá, April yìí yóò jẹ́ oṣù àrà ọ̀tọ̀ kan fún ìpínkiri ìwé ìròyìn. A ní láti bẹ̀rẹ̀ sí i wéwèé láti ìsinsìnyí lọ. Ọ̀pọ̀ yóò fẹ́ láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà. Ẹ kọ̀wé béèrè fún àfikún ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn April bí ẹ bá ṣe nílò rẹ̀ tó. Ẹ lè ṣètò fún àwọn Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn, tí gbogbo àwọn tí ó bá ṣeé ṣe fún yóò sì máa ṣàjọpín—láàárọ̀, lọ́sàn-án, àti/tàbí nírọ̀lẹ́. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wá “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Messia, nínú Orin Dafidi 69:9, ǹjẹ́ kí àwa pẹ̀lú lè sọ pé: “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí tán.”—Jak. 1:22; Joh. 2:17.