Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọrun
Albania: Àwọn 600 akéde tí ó ròyìn ní August jẹ́ góńgó kejìdínlọ́gbọ̀n tẹ̀lératẹ̀léra.
Angola: Ní ìparí ọdún iṣẹ́ ìsìn, a dé góńgó tuntun tí a tí ì ní rí nínú akéde tí ó jẹ́ 26,129. A tún ni góńgó aṣáájú ọ̀nà déédéé tí ó jẹ́ 1,309. Àwọn akéde ní ìpíndọ́gba wákàtí 15, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli méjì ní August.
Britain: Inú wá dùn láti ròyìn pé a dé góńgó tuntun tí a tí ì ní rí nínú akéde tí ó jẹ́ 132,440 ní August. Èyí dúró fún ìbísí ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún lórí ọdún iṣẹ́ ìsìn tí ó kọjá.
Chile: Nínú oṣù August, a dé góńgó tuntun tí a tí ì ní rí nínú akéde pẹ̀lú àròpọ̀ tí ó jẹ́ 50,283! Fún ìgbà àkọ́kọ́, a ré kọjá góńgó 50,000. Àwọn akéde lo ìpíndọ́gba wákàtí 12 nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. A dárí 63,732 àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.