Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
Benin: Àwọn akéde 5,331 ni ó ròyìn ní oṣù November, ìyẹn sì jẹ́ góńgó kọkàndínlọ́gọ́ta tẹ̀lératẹ̀léra ti àwọn akéde.
Cyprus: Ìbísí 2 nínú ọgọ́rùn-ún ní oṣù November mú góńgó tuntun 1,758 akéde wá. Góńgó tuntun tún wà nínú iye àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé, àwọn 136 ní ó ròyìn.
Íńdíà: Ìtẹ̀síwájú títayọ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni a rí ní oṣù November nígbà tí 18,077 akéde ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Èyí ni góńgó kọkàndínlógójì tẹ̀lératẹ̀léra.
Liberia: Góńgó tí ó ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 2,120 akéde ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ní oṣù November.
Solomon Islands: A dé góńgó tuntun nínú iye akéde, 1,393 ni wọ́n ròyìn ní oṣù November.
Taiwan: Níbi tí a ṣì bá a dé lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yìí, ìpíndọ́gba iye àwọn akéde jẹ́ 3,516, ìyẹn sì dúró fún ìbísí 6 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ọdún tó kọjá.