ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/98 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 6
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 27
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 4/98 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 6

Orin 27

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán gbogbo àwùjọ létí nípa ibi tí a óò ti ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní Saturday, April 11, àti àkókò tí a óò ṣe é. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.

15 min: “Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa—Àfihàn Ìfẹ́ Tòótọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ọ̀rọ̀ ṣókí láti inú Ilé-ìṣọ́nà, February 1, 1987, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 3 sí 7 kún un.

20 min: “Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà.” Alàgbà ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ pẹ̀lú àwùjọ akéde ẹlẹ́ni mẹ́ta tàbí mẹ́rin tí wọ́n dáńgájíá nínú fífi ìwé ìròyìn sóde. Jíròrò àwọn apá fífani mọ́ra inú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, dábàá àwọn ọ̀nà tí a fi lè mú àwọn kókó wọ̀nyí wọnú àwọn ìgbékalẹ̀ wa. Ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè mú kí ìpínkiri ìwé ìròyìn pọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ àdúgbò. Ní lílo àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́, tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè, irú bí àwọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ti ìdílé, tàbí ti ìlú. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ṣókí méjì tàbí mẹ́ta.

Orin 205 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 13

Orin 90

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàlàyé pé kò tíì pẹ́ jù láti fi ìwé ìwọṣẹ́ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù May sílẹ̀.

15 min: Àìní àdúgbò.

20 min: “Pésẹ̀ sí Àwọn Ìpàdé ‘Pàápàá Jù Lọ.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, ṣàtúnyẹ̀wò ìṣílétí tí ó wà nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 64 àti 65. Gbóríyìn tọ̀yàyàtọ̀yàyà fún gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń wá sí ìpàdé déédéé.

Orin 119 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 20

Orin 5

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan tí ó fi inú rere sọ àwọn ọ̀nà pàtó tí a fi lè ṣe ìmúsunwọ̀n sí i ládùúgbò.

25 min: “Fífi Ìdùnnú Kúnjú Àìní Ìkórè Náà.” Ìjíròrò àpilẹ̀kọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí alàgbà títóótun kan bójú tó o. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní kíkàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ṣáájú bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ran gbogbo àwùjọ lọ́wọ́ láti rí ìdí tí ó fi yẹ kí a fi ọgbọ́n lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wa tí a yà sí mímọ́ nípa fífarabalẹ̀ ra àwọn nǹkan, ìpète ilé rírọrùn, àti ìlànà ìṣírò owó tí ó kún rẹ́rẹ́.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 27

Orin 100

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Kéde orúkọ àwọn tí yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù May. Sọ àfikún ìṣètò tí a ti ṣe ládùúgbò fún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn. Ṣàlàyé àwọn àbá díẹ̀ tí ń ṣèrànwọ́ fún mímúra àwọn ìgbékalẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ jáde lákànṣe.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, ojú ìwé 8.

15 min: Bí Àwọn Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn Ṣe Ń Sìn Ọ́. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, March 15, 1996, ojú ìwé 24 sí 27.

18 min: Ní Ìṣarasíhùwà Rere Nígbà Tí O Bá Ń Wàásù Ní Ìpínlẹ̀ Tí A Máa Ń Ṣe Lemọ́lemọ́. Alàgbà kan jíròrò yíyẹ tí èyí yẹ pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ti rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìdáhùnpadà tí kò tó nǹkan ní ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe léraléra. Ó ṣàtúnyẹ̀wò Ilé-Ìṣọ́nà, July 15, 1988, ojú ìwé 16 sí 19, ìpínrọ̀ 4 sí 14 pẹ̀lú wọn. Wọ́n fi ẹ̀mí ìfojúsọ́nà fún rere sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà láti lo àwọn àbá wọ̀nyí ládùúgbò.

Orin 191 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́