Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní February; Efik, Gẹ̀ẹ́sì, àti Igbo—Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ fún ₦80 tàbí Revelation—its Grand Climax At Hand! fún ₦240. Àwọn èdè yòókù—Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ fún ₦80 tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ńlá, ₦120; kékeré, ₦120). March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. April àti May: Àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! Fún ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, a tún lè lo ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí (yàtọ̀ sí ìwé pẹlẹbẹ Education àti School). Níbi tí a bá ti fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi àsansílẹ̀ owó lọni. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàtúnyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí èyíkéyìí nínú wọn bá ní ìṣòro dídójú ìlà wákàtí tí a béèrè fún, àwọn alàgbà ní láti ṣètò kí a lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. Ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn kókó inú ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti April 29, 1996, a óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ A óò ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní Tuesday, April 2, 1996. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àsọyé náà lè tètè bẹ̀rẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ rántí pé gbígbé búrẹ́dì àti wáìnì Ìṣe Ìrántí kò gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀, àfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ ní àgbègbè yín. Kò gbọdọ̀ sí ìpàdé kankan yàtọ̀ sí ti iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ yẹn. Bí ìjọ yin bá sábà máa ń ṣe àwọn ìpàdé ní ọjọ́ Tuesday, ẹ lè fẹ́ láti yí àwọn ìpàdé wọ̀nyí sí ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ bí Gbọ̀ngàn Ìjọba bá ṣí sílẹ̀.
◼ Àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní March, April, àti May ní láti ṣe àwọn ìwéwèé wọn nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ wọn sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tí ó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó Nísinsìnyí:
Efik, Igbo, Isoko, àti Yorùbá: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Hausa: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun; Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bi? Igala: Ẹmi Àwọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? Tiv: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun; Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá; Ki Ni Ete Igbesi-Aye?— Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?