Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe
1 Èé ṣe tí ó fi yẹ kí á polongo ìhìn rere láìdábọ̀? Kí ni àwọn ohun àbéèrèfún láti jẹ́ oníwàásù ìhìn rere? Báwo ni àwọn ‘onítìjú’ pàápàá ṣe lè lo ìdánúṣe láti ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? A óò dáhùn ìwọ̀nyí àti àwọn ìbéèrè míràn tí ń múni ronú jinlẹ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní March, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “A Tóótun Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ìhìn Rere.”—Fi wé 2 Korinti 3:5.
2 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jehofa, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nínú ìwà wa. Àwọn ọ̀dọ́ yóò sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí nípa bí wọ́n ti gbéjà ko ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn. A óò pèsè ìṣírí onífẹ̀ẹ́ fún àwọn òbí nípa ojúṣe wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bí òjíṣẹ́ Ọlọrun. A óò ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti mọrírì àìgbọdọ̀máṣe ti wíwàásù àti ìbùkún tí ń jẹ yọ fún àwa fúnra wa àti àwọn tí ń tẹ́tí sílẹ̀ sí wa.—1 Tim. 4:16.
3 Dájúdájú, ìrìbọmi yóò jẹ́ kókó pàtàkì kan fún ọjọ́ náà. Ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, a óò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé Bibeli, tí a darí sí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́ ní pàtàkì. Àmọ́ ṣáá o, gbogbo àwọn tí ó wà ní ìjókòó yóò fẹ́ láti tẹ́tí sílẹ̀ dáradára bí a ti ń jíròrò kókó ọ̀rọ̀ ìrìbọmi, tí a sì ń mú ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣe kedere. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi ní ọjọ àpéjọ àkànṣe gbọ́dọ̀ sọ èyí fún alábòójútó olùṣalága tipẹ́tipẹ́ ṣáájú, kí òún lè ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti ṣètò fún àwọn alàgbà láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí a yàn pẹ̀lú àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìrìbọmi.
4 Lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a gbà lálejò yóò sọ yóò jẹ́ kókó pàtàkì míràn. A pe àkọlé rẹ̀ ní, “A Tóótun A sì Gbara Dì Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọrun.” A óò jíròrò àwọn ìpèsè pàtàkì mẹ́rin tí ń mú wa gbara dì gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, ọ̀rọ̀ àsọyé náà yóò sì ní àwọn ìrírí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun nínú.
5 Wéwèé nísinsìnyí láti wà níbẹ̀ láti gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkèdélẹ̀. Rí i dájú pé o ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí àwọn pẹ̀lú lè jàǹfààní láti inú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìṣàkóso Ọlọrun fún ọjọ́ yìí. Ní ọ̀nà yìí, a lè ní ìdánilójú pé a “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn” gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere.