Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Oct. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé àwọ́n á jayé òní torí pé àwọn ò mẹ̀yìn ọ̀la. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù sọ̀rọ̀ kan tó fani lọ́kàn mọ́ra. [Ka Mátíù 6:34.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè múra sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la tá ò sì ní máa ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ.”
Ile Iṣọ Nov. 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí á sàn jù báyìí lọ táwọn èèyàn bá túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nípa ànímọ́ yìí. [Ka Mátíù 23:12.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká níwà ìrẹ̀lẹ̀, kódà nínú ayé onípàákìràkìtà yìí.”
Jí! Oct.–Dec.
“Ibo lo rò páwọn òbí ti lè rí ìmọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wọn dáadáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [2 Tímótì 3:16.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí Bíbélì ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi máa láyọ̀.”
“Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ lẹni tó ò ń wàásù fún, o lè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ bíi tìẹ làwọn èèyàn ti fi àhesọ ọ̀rọ̀ bà lórúkọ jẹ́. Ǹjẹ́ wọ́n ti sọ irú àhesọ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa ẹ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì fún wa nímọ̀ràn tó dáa tá a lè tẹ̀ lé bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ wa láìdáa. Ó tún jẹ́ ká mọ báwa fúnra wa ò ṣe ní máa báwọn dá sí ọ̀rọ̀ àhesọ tó lè ba ẹlòmíì lórúkọ jẹ́.” Lẹ́yìn náà ni kó o fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn án, kó o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan látinú àpilẹ̀kọ náà.