ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 34 ojú ìwé 202-ojú ìwé 205 ìpínrọ̀ 4
  • Sọ Ohun Tó Ń Gbéni Ró Tó Sì Ṣàǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ Ohun Tó Ń Gbéni Ró Tó Sì Ṣàǹfààní
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 34 ojú ìwé 202-ojú ìwé 205 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 34

Sọ Ohun Tó Ń Gbéni Ró Tó Sì Ṣàǹfààní

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Dípò tí wàá fi máa ránnu mọ́ àìdáa tó wà nínú ọ̀ràn kan, ńṣe ló yẹ kí o sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí yóò tún ọ̀ràn náà ṣe tàbí nípa nǹkan tí yóò sì fọkàn ẹni balẹ̀.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ayé aláìnífẹ̀ẹ́ tí à ń gbé yìí ti fọ̀rọ̀ ìgbésí ayé sú àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìṣòro ńláńlá ń bá fínra. Bí a bá ṣàlàyé ìhìn Bíbélì bó ṣe yẹ, ó máa ń jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn gbà pé ọjọ́ ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára.

ÌHÌN tí Ọlọ́run ní ká lọ wàásù jẹ́ ìhìn rere. Jésù ní: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa pípolongo “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) A ṣàpèjúwe ìwàásù àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú pé ó jẹ́ “ìhìn rere Ọlọ́run” àti “ìhìn rere nípa Kristi.” (1 Tẹs. 2:2; 2 Kọ́r. 2:12) Irú ìhìn bẹ́ẹ̀ ń gbéni ró, ó sì ṣàǹfààní.

Ńṣe là ń rọ àwọn èèyàn níbàámu pẹ̀lú “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” tí ‘áńgẹ́lì tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run’ ń polongo, pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.” (Ìṣí. 14:6, 7) À ń sọ̀rọ̀ fáwọn èèyàn níbi gbogbo nípa Ọlọ́run tòótọ́, nípa orúkọ rẹ̀, nípa àwọn ànímọ́ àgbàyanu tó ní, nípa àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀, nípa ète rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, nípa pé òun la ó padà wá jíhìn fún àti nípa ohun tó ń fẹ́ kí á máa ṣe. Ara ìhìn rere yìí tún ni pé Jèhófà Ọlọ́run yóò pa àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń tàpá sí i tí wọ́n sì ń bayé jẹ́ fáwọn èèyàn yòókù run. Ṣùgbọ́n a ò láṣẹ láti máa ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí à ń wàásù fún. Ohun tó jẹ wá lógún ni pé kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tí à ń bá wọn sọ, kí ó fi lè já sí ìhìn rere fún wọn lóòótọ́.—Òwe 2:20-22; Jòh. 5:22.

Mẹ́nu Kan Ohun Àìdáa Níwọ̀nba. Lóòótọ́, ohun àìdáa máa ń wáyé nínú ìgbésí ayé ọmọ èèyàn. A kò ní ṣàìka ìyẹn sí. Láti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀, o lè béèrè ọ̀rọ̀ nípa kókó kan tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ rẹ, kí ẹ sì jọ sọ̀rọ̀ ráńpẹ́ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í fi bẹ́ẹ̀ dára pé ká sọ̀rọ̀ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní nípa rẹ̀. Ìgbà gbogbo làwọn èèyàn máa ń gbọ́ ìròyìn tó ń bani nínú jẹ́, tó bá tún wá jẹ́ àwọn nǹkan tí kò múnú ẹni dùn la tún dẹ́nu lé, wọ́n lè máà dúró gbọ́ tàbí kí ọ̀rọ̀ wa má wọ̀ wọ́n létí. Láti apá ìbẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn ni kí o ti gbìyànjú láti pé àfiyèsí wọn sí òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣí. 22:17) Tó bá tiẹ̀ wá di pé onítọ̀hún ò fẹ́ máa bá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn lọ mọ́, yóò ti gbọ́ nǹkan kan tó ṣàǹfààní tó lè máa ronú lé lórí. Èyí lè mú kó fẹ́ láti fetí sílẹ̀ nígbà mìíràn.

Bákan náà, bí a bá yan ọ̀rọ̀ sísọ fún ọ, má kàn torí pé ohun àìdáa tó ń ṣẹlẹ̀ pọ̀ káàkiri kí o wá máa rọ̀jò ìròyìn nípa wọn lu àwùjọ. Bí olùbánisọ̀rọ̀ bá ń ránnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìkùnà àwọn alákòóso èèyàn, ìròyìn nípa ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá tàbí ọ̀rọ̀ nípa bí ìṣekúṣe ṣe gbòde kan, ìbànújẹ́ ni yóò kó bá àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Àyàfi tí o bá rí i pé àǹfààní kan wà nínú pé kí o mẹ́nu kan ohun àìdáa tó jẹ mọ́ kókó tí ò ń sọ ni kó o tó mú un wọnú ọ̀rọ̀. Bí o bá mẹ́nu kàn án ráńpẹ́, ó lè jẹ́ kó hàn pé kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí bóde mu. Ó tún lè fi àwọn nǹkan pàtàkì tó túbọ̀ ń dá kún ọ̀ràn kan hàn, tí wàá sì wá fi ìyẹn ṣàlàyé ìdí tí ojútùú tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ fi wúlò lóòótọ́. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ńṣe ni kí o sọ ohun tí ìṣòro yẹn jẹ́ ní pàtó láìsọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ nípa ìṣòro yẹn.

Kì í sábàá ṣeé ṣe pé ká yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá sáà ti jẹ́ ohun àìdáa dà nù nínú ọ̀rọ̀ kan tí a fẹ́ sọ, kò tiẹ̀ tọ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá. Ohun tó ṣe kókó ni pé ká mọ bí a ṣe lè sọ ìhà tó dáa àti èyí tí kò dáa nínú ọ̀rọ̀ kan lọ́nà tí àpapọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn yóò fi gbéni ró. Kí èyí lè ṣeé ṣe, o ní láti yan ohun tí o máa sọ àti èyí tí o kò ní sọ àti ọ̀rọ̀ tí o máa tẹnu mọ́. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù gba àwọn olùgbọ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n yẹra fún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni tí àwọn akọ̀wé àti Farisí ní, ó sì mẹ́nu kan àpẹẹrẹ mélòó kan láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn. (Mát. 6:1, 2, 5, 16) Ṣùgbọ́n kàkà tí Jésù ó fi máa wá ka ìwà àìdáa tí àwọn aṣáájú ìsìn ń hù sílẹ̀ rẹpẹtẹ, yíyẹ tó yẹ kéèyàn mọ àwọn ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́ kó sì fi ṣèwà hù ló tẹnu mọ́. (Mát. 6:3, 4, 6-15, 17-34) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì di ohun tó ṣe àwọn èèyàn láǹfààní gan-an.

Sọ̀rọ̀ Lọ́nà Tí Wọn Yóò Fi Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́. Bí a bá yan iṣẹ́ fún ọ nínú ìjọ pé kí o sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀ka kan lára ìgbòkègbodò Kristẹni, gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró dípò tí wàá fi máa ṣàríwísí. Rí i dájú pé ìwọ fúnra rẹ ń ṣe ohun tí ò ń gba àwọn ará níyànjú láti máa ṣe. (Róòmù 2:21, 22; Héb. 13:7) Dípò tí wàá fi máa fìkanra sọ̀rọ̀, ìfẹ́ ni kó sún ọ sọ ọ́. (2 Kọ́r. 2:4) Bí o bá ní ìdánilójú pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ yòókù ń fẹ́ láti ṣe ohun tó wu Jèhófà, ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu rẹ á fi hàn bẹ́ẹ̀, èyí á sì ṣe wọ́n láǹfààní. Ṣàkíyèsí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ ìdánilójú bẹ́ẹ̀, nínú 1 Tẹsalóníkà 4:1-12; 2 Tẹsalóníkà 3:4, 5; Fílémónì 4, 8-14, 21.

Nígbà mìíràn, ó lè pọn dandan pé kí àwọn alàgbà ṣèkìlọ̀ nípa ìwà kan tí kò bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò sún wọn láti fi ìwà tútù bá ìjọ sọ̀rọ̀. (Gál. 6:1) Ọ̀nà tí a gbà sọ̀rọ̀ ní láti fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn ará inú ìjọ. (1 Pét. 5:2, 3) Bíbélì gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa jẹ́ kí kókó yìí wà nínú ọkàn wọn. (1 Tím. 4:12; 5:1, 2; 1 Pét. 5:5) Nígbà tó bá di pé ó yẹ ká báni wí láti mú àwọn nǹkan tọ́, ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ wí ni kí á gbé e kà. (2 Tím. 3:16) Kí olùbánisọ̀rọ̀ má ṣe fẹ ọ̀nà tí a lè gbà lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójú kọjá bó ṣe yẹ, kó má sì lọ́ ọ po láti fi ṣètìlẹyìn fún èrò tirẹ̀ nípa ọ̀ràn kan. Kódà bí ó bá di pé ká sọ̀rọ̀ láti fi tọ́ ìjọ sọ́nà, ọ̀nà tí à ń gbà sọ̀rọ̀ ṣì lè gbéni ró bí a bá ń tẹnu mọ́ ọ̀nà tí wọn ò fi ní jìn sí ọ̀fìn ìṣekúṣe, ọ̀nà tí wọn ó gbà yanjú ìṣòro, ọ̀nà tí wọn ó gbà borí ìnira, ọ̀nà tí wọ́n ó gbà yí ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó padà àti ọ̀nà tí ohun tí Jèhófà ní ká ṣe gbà ń kó wá yọ nínú ewu.—Sm. 119:1, 9-16.

Nígbà tí o bá ń múra iṣẹ́ rẹ, fara balẹ̀ ronú nípa ọ̀nà tí o máa gbà parí kókó kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ àti bí o ṣe máa parí ọ̀rọ̀ náà lápapọ̀. Ọ̀rọ̀ tí o sọ kẹ́yìn ló sábà máa ń pẹ́ lọ́kàn àwọn èèyàn jù lọ. Ṣé wọ́n á rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀?

Nígbà Tí A Bá Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọyì àǹfààní tó wà nínú ìfararora nígbà àwọn ìpàdé Kristẹni. Àkókò ìtura nípa tẹ̀mí ni wọ́n sábà máa ń jẹ́. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa fi sọ́kàn pé ńṣe la fẹ́ “máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì” nígbà tí a bá kóra jọ síbi ìjọsìn wa. (Héb. 10:25) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí a bá ń sọ látorí pèpéle tàbí ìdáhùn wa nínú ìpàdé nìkan la fi ń fún ara wa níṣìírí, a tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí a ṣe jọ ń tàkúrọ̀sọ ṣáájú ìpàdé tàbí lẹ́yìn ìpàdé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú pé ká sọ̀rọ̀ nípa àtijẹ-àtimu àti ìlera wa, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí ló máa ń fúnni níṣìírí jù lọ. Àwọn ìrírí aláyọ̀ tí à ń ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sì wà lára irú nǹkan tẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Bí a bá ń ṣaájò àwọn ará wa ìyẹn náà tún ń gbéni ró pẹ̀lú.

Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká máa ṣọ́ra kí àṣà ayé tí à ń gbé yìí má lọ kéèràn ràn wá. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù, ó sọ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfé. 4:25) Sísọ òtítọ́ dípò èké ṣíṣe kan ọ̀ràn pé kí á má máa pọ́n àwọn nǹkan tàbí àwọn èèyàn tí aráyé ń júbà fún. Bákan náà, Jésù kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra fún “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” (Mát. 13:22) Nípa bẹ́ẹ̀, a ní láti ṣọ́ra kí á má ṣe máa pọ́n ohun ìní ti ara nígbà tí a bá ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ nítorí èyí yóò mú kí á máa gbé ìtànjẹ yẹn lárugẹ.—1 Tím. 6:9, 10.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fún wa nímọ̀ràn nípa yíyẹ tó yẹ ká máa gbéni ró, ó rọ̀ wá pé ká má ṣe dẹ́bi fún Kristẹni ará wa tàbí ká kẹ́gàn rẹ̀ bí ó bá ń yẹra fún àwọn nǹkan kan nítorí ti “àwọn àìlera nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀,” ìyẹn ni pé, nítorí pé kò mọ bí òmìnira Kristẹni ṣe tó. Ní tòdodo, bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa yóò bá gbéni ró, a ní láti máa fi ipò ìgbésí ayé àwọn èèyàn látilẹ̀wá àti bí wọ́n ṣe dàgbà tó nípa tẹ̀mí sọ́kàn tí a bá ń sọ̀rọ̀. Kò ní bójú mu rárá bí a bá lọ “fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí okùnfà fún ìgbéniṣubú sí iwájú arákùnrin [tàbí arábìnrin]” kan!—Róòmù 14:1-4, 13, 19.

Ó máa ń dùn mọ́ àwọn tó ní ìṣòro ńlá, irú bí àìsàn tí kò gbóògùn, bí wọ́n bá rẹ́ni bá fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró. Ẹni tó ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lè sapá gidigidi láti rí i pé òun ò pa ìpàdé jẹ. Àwọn tó mọ̀ nípa irú ìṣòro tí ó ní lè kí i pé: “Báwo lara yín o?” Ó sì dájú pé yóò dùn mọ́ ọn pé wọ́n ṣaájò òun. Ṣùgbọ́n onítọ̀hún lè máà fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣe é. Ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ọ̀rọ̀ ìṣírí lè jẹ́ ohun tí yóò túbọ̀ mú inú rẹ̀ dùn. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ṣì fẹ́ràn Jèhófà àti ẹ̀rí nípa bí ó ṣe ń fara da ìpọ́njú náà? Ǹjẹ́ ìdáhùn rẹ̀ nípàdé máa ń fún ọ níṣìírí? Ǹjẹ́ kò ní sàn pé ká máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan rere tó ń ṣe wọ̀nyí àti bí ó ṣe ń gbé ìjọ ró dípò tí a ó fi máa ránnu mọ́ àìlera rẹ̀?—1 Tẹs. 5:11.

Tí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa yóò bá jẹ́ èyí tó ń gbéni ró, ó ṣe pàtàkì gidi pé ká máa ronú nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Ọlọ́run bínú gidigidi sí àwọn tó sọ̀rọ̀ àwọn aṣojú Jèhófà láìdáa tí wọ́n sì ń kùn nípa mánà. (Núm. 12:1-16; 21:5, 6) Bí a bá ti fi ọ̀ràn tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n, yóò hàn nínú bí a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún àwọn alàgbà àti bí a ṣe ń mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye.—1 Tím. 5:17.

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nǹkan rere ló wà tí a lè fi bá àwọn Kristẹni ará wa tàkúrọ̀sọ. Àmọ́, tó bá wá di pé ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ lẹ́nu kò dára rárá, ńṣe ni kí o lo ìdánúṣe láti darí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn sórí nǹkan mìíràn tó ń gbéni ró.

Ì báà jẹ́ pé ńṣe là ń wàásù fúnni, tàbí à ń sọ̀rọ̀ látorí pèpéle tàbí à ń bá àwọn ará wa sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kí á máa lo òye láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí yóò tinú ìṣúra ọkàn wa jáde jẹ́ “àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfé. 4:29.

BÍ O ṢE LÈ DI ẸNI TÓ Ń SỌ̀RỌ̀ TÓ Ń GBÉNI RÓ TÓ SÌ ṢÀǸFÀÀNÍ

  • Jẹ́ kó máa wà lọ́kàn rẹ pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ni Ọlọ́run yàn fún wa láti ṣe.

  • Máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró dípò tí wàá fi máa ṣàríwísí ẹni.

  • Fi kọ́ra láti máa fojú ẹni iyì wo àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀.

  • Nígbà tí ẹ bá jọ ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, máa ronú nípa bí ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ yóò ṣe rí lára ọmọnìkejì rẹ.

ÌDÁNRAWÒ: Kàn sí ẹnì kan tó jẹ́ abirùn tàbí ẹni tí kò lè jáde nílé mọ́. Bá a tàkúrọ̀sọ lọ́nà tó gbéni ró. Lo ẹ̀mí ìgbatẹnirò, àmọ́ rí i pé ọ̀rọ̀ tó gbé e ró lo sọ. Múra bí o ṣe máa ṣe é sílẹ̀ kí èyí lè ṣeé ṣe fún ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́