ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/96 ojú ìwé 3-4
  • Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Kárí Ayé Ń Ṣètìlẹyìn fún Ìmúgbòòrò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Kárí Ayé Ń Ṣètìlẹyìn fún Ìmúgbòòrò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyọ Ayọ̀ Ìbísí tí Ọlọ́run Ń Fi Fúnni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Túbọ̀ Wàásù
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 8/96 ojú ìwé 3-4

Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Kárí Ayé Ń Ṣètìlẹyìn fún Ìmúgbòòrò

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú Aísáyà 54:2, 3, ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ń bá a lọ láti gbòòrò sí i jákèjádò ilẹ̀ ayé. Èyí ní onírúurú orílẹ̀-èdè ní àgbáálá ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn erékùṣù tí ó wà nítòsí nínú. Ní àwọn ọdún mẹ́wàá tí ó ti kọjá, a ti gbé ìfòfindè kúrò lórí ìgbòkègbodò Ìjọba náà ní irú àwọn ilẹ̀ bí Àǹgólà, Cameroon, Equatorial Guinea, Etiópíà, Madagascar, Màláwì, Mòsáḿbíìkì, àti Tógò. Àwọn míṣọ́nnárì ilé ẹ̀kọ́ Gilead, àwọn tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àti àwọn mìíràn, tí lọ ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, àti ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, tí pápá ti funfun fún kíkórè.—Mat. 9:37, 38.

Dájúdájú, ìbísí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ nínú ètò àjọ Jèhófà ń béèrè fún kíkọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Ó tún ti pọn dandan láti wéwèé fún àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn ilé ẹ̀ka tuntun tàbí èyí tí a mú gbòòrò sí i. Gbígbé ẹrù ìnáwó àwọn ìdáwọ́lé wọ̀nyí, ní àfikún sí mímú kí iṣẹ́ Ìjọba náà máa tẹ̀ síwájú, kì í ṣe ní Áfíríkà nìkan, ṣùgbọ́n ní àwọn apá ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ àpò ọrẹ tí a ń ṣe fún iṣẹ́ Society kárí ayé.

Àwọn fọ́tò àti àwòrán, tí ó wà lójú ewé méjì àkìbọnú yìí, yóò mú kí o lóye díẹ̀ nípa ohun tí Society ti ń sakun láti ṣe parí ní pápá Áfíríkà. Díẹ̀ lára àwọn ìkọ́lé tí ń lọ lọ́wọ́ ní pẹrẹu àti àwọn ìdáwọ́lé tí a óò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́, ni a fi hàn.

Bí o bá wo ṣáàtì iṣẹ́ ìsìn pápá, nínú 1996 Yearbook, o lè túbọ̀ lóye gudugudu méje tí àwọn akéde ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìbísí títayọ lọ́lá ti wáyé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, iye gígọntiọ tí ó sì pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí fi ṣíṣeé ṣe láti túbọ̀ gbèrú sí i hàn. Nígbà tí a bá fi ohun tí a ń ṣe parí gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba àti sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn kárí ayé, tí a ń ṣe níhìn-ín ní Áfíríkà àti ní àwọn àgbáálá ilẹ̀ míràn sọ́kàn, ó ń tẹ àǹfààní tí a ní láti fi ohun ti ara ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́ mọ́ wa lọ́kàn.—Luk. 16:9; 1 Tim. 6:18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Gbọ̀ngàn Ìjọba ní KwaZulu-Natal, Gúúsù Áfíríkà, tí a fi ọjọ́ 9 kọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a kọ́ lọ́nà ìsúnwó ná, ní Nàìjíríà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Gbọ̀ngàn Àpéjọ ní Mòsáḿbíìkì tí ó lè gba ìjókòó 1,500 ènìyàn, tí a óò parí ní òpin ọdún 1996

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn ilé ẹ̀ka ní Mòsáḿbíìkì, tí yóò ti wà fún gbígbé ní òpin ọdún 1996

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ẹ̀ka Sierra Leone, tí a ṣètò láti parí ní òpin ọdún yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Gbọ̀ngàn Àpéjọ gbalasa tí a ti kọ́ parí ní Mauritius, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé ẹ̀ka, tí a óò parí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1997

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ẹ̀ka Zimbabwe tí a ń kọ́ lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Gbọ̀ngàn Àpéjọ gbalasa àti ẹ̀ka tuntun tí a ń kọ́ lọ́wọ́ ní Senegal

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ẹ̀ka tuntun ní Kenya, ní olú ìlú rẹ̀, Nairobi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ẹ̀ka Madagascar, tí a óò parí láìpẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn ilé ẹ̀ka tí a ń wéwèé fún Màláwì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́